Àìṣòótọ́ Nínú Ìgbéyàwó—Aburú Tó Ń gbẹ̀yìn rẹ̀
“Mo ti jáde nílé o,” lẹni náà sọ lórí tẹlifóònù—ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ bíbaninínújẹ́ jù lọ tí Pata tí ì gbọ́ lẹ́nu ọkọ rẹ̀ rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé ó lè dà mí. Nǹkan burúkú tí mo ń bẹ̀rù gan-an láti ọjọ́ yìí—pé ọkọ mi lè já mi sílẹ̀ lọ bá ẹlòmíràn—ti wá ṣẹlẹ̀.”
LÁÌSÍ tàbí-tàbí, Pat ń fẹ́ kí ìgbéyàwó wọn kẹ́sẹ járí; ọkọ rẹ tí fi í lọ́kàn balẹ̀ pé òun ò ní já a sílẹ̀ láé. Pat rántí pé: “A jẹ́jẹ̀ẹ́ pé a ó ṣe ara wa lóṣùṣù ọwọ̀ nígbà òjò tàbí nígbà ẹ̀ẹ̀rùn. Ọkàn mi balẹ̀ pé òótọ́ ló ń sọ. Àmọ́, . . . ó wá kọjú mi sóòrùn alẹ́. Ó wá kù mí ku etí mi báyìí!”
Hiroshi ò jẹ́ gbàgbé ọjọ́ tí àṣírí ṣìná ìyá rẹ̀ tú. Ó rántí pé: “Ọmọ ọdún mọ́kànlá péré ni mí nígbà yẹn. Ńṣe ni Mọ́mì já wọlé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dalé rú. Dádì ń tẹ̀ lé e kiri, ó sì ń wí fún un pé, ‘Fara balẹ̀ ná. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.’ Mo róye pé nǹkan burúkú kan ti ṣẹlẹ̀. Orí Dádì gbóná. Ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀ ò tán lára ẹ̀. Àti pé kò lálábàárò. Ló bá yíjú sí mi. Àá ti í gbọ́ ọ: kí ẹni tó ti lé lógójì ọdún wá fi ọmọkùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá ṣe olùtùnú àti alábàárò rẹ̀!”
Yálà ìṣekúṣe tí ń fa àbùkù tó ti gbo àwọn lọ́balọ́ba, àwọn òṣèlú, àwọn gbajúmọ̀ òṣèré sinimá, àti àwọn aṣáájú ìsìn ni tàbí ìwà ọ̀dàlẹ̀ àti omijé tó ń fà nínú ìdílé tiwa alára, àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó ṣì ń bani nínú jẹ́. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ó jọ pé bí ìgbéyàwó ṣe pọ̀ tó ni àwọn ènìyàn ṣe ń ṣe panṣágà tó níbi gbogbo.” Àwọn olùwádìí kan fojú díwọ̀n rẹ̀ pé nǹkan bí ìpín àádọ́ta sí márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n ti ṣègbéyàwó ló ti hùwà àìṣòótọ́ rí. Zelda West-Meads, tó jẹ́ olùwádìí nípa ìgbéyàwó, sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìwà àìṣòótọ́ tí àwọn ènìyàn ń hù nínú ìgbéyàwó ni kò hàn síta, “gbogbo ẹ̀rí ń fi hàn pé ńṣe ni ìwà ìṣekúṣe náà ń pọ̀ sí i.”
Ìmọ̀lára Tí Ń Pelemọ
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń yani lẹ́nu, iye àwọn tí ń hùwà àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó àti iye ìkọ̀sílẹ̀ tí ń wáyé kò fi gbogbo ipa tó ń ní lórí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn hàn. Ní àfikún sí ìṣòro ìnáwó ńlá tó ń kóni sí, ronú nípa bí ìmọ̀lára àwọn tí a ṣírò iye wọn náà ṣe ga tó—ẹkún àsun-ùn-suntán àti ìdàlọ́kànrú tí kò láfiwé, ìbànújẹ́, àìfọkànbalẹ̀, àti ìrora gógó lílékenkà tí wọ́n ń ní àti làásìgbò tí kì í jẹ́ kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé sùn lóròòru. Àwọn tó ní ìṣòro náà lè la ìrírí agbonijìgì náà já, ṣùgbọ́n ọgbẹ́ tó dá sí wọn lọ́kàn lè máà tán bọ̀rọ̀. Ìrora ọkàn àti jàǹbá náà kì í lọ bọ̀rọ̀.
Ìwé How to Survive Divorce ṣàlàyé pé: “Ìgbéyàwó tó forí ṣánpọ́n sábà máa ń mú ọkàn gbọgbẹ́ gan-an, nígbà mìíràn, ọgbẹ́ náà sì máa ń ṣe bí èyí tí kò ní jẹ́ kí nǹkan ṣe kedere sí ọ. Kí ló wá yẹ kí o ṣe? Báwo ló ṣe yẹ kí o hùwà padà? Báwo ni wàá ṣe kojú ìṣòro náà? Ọkàn rẹ lè máa ṣe ọ bíi pe bóyá òótọ́ ló ṣẹlẹ̀ tàbí kò ṣẹlẹ̀, kí o máa ti orí ìbínú bọ́ sórí dídá ara rẹ lẹ́bi tàbí dípò níní ìgbẹ́kẹ̀lé kí o di ẹni tí ń fura.”
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pedro nìyẹn lẹ́yìn tí àṣírí ìwà àìṣòótọ́ ìyàwó rẹ̀ tú sí i lọ́wọ́. Ó sọ ọ́ láṣìírí pé: “Bí ẹnì kan bá hùwà àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó, ọkàn ẹni yóò pòrúurùu.” Ọ̀ràn náà dojú rú gan-an fún àwọn tí ìṣòro náà bá láti lóye rẹ̀—ká máà wá sọ ti àwọn ará ìta tí wọn kò mọ púpọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀. Pat sọ pé: “Kò sí ẹni tó mọ bó ṣe rí lára mi ní gidi. Bí mo bá ronú débi pé ọkọ mi wà pẹ̀lú obìnrin náà, ara ríro àti ẹ̀fọ́rí tí kò ṣeé ṣàlàyé bó ṣe ń ṣe mí fún ẹnikẹ́ni, yóò sì bẹ̀rẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Àwọn ìgbà kan wà tí màá rò pé orí mi ti dàrú. Màá rò pé mo lè kápá ìṣòro náà lónìí; tó bá di ọ̀la kò ní rí bẹ́ẹ̀ mọ́. Aáyun rẹ̀ á máa yun mí lónìí; tó ba di ọ̀la gbogbo ètekéte, irọ́, àti ìtẹ́nilógo ni mo máa rántí.”
Ìbínú àti Ìdààmú
Ẹnì kan tí ẹnì kejì rẹ̀ hùwà àìṣòótọ́ sọ pé: “Nígbà mìíràn, ìbínú gbáà ló ń máa wà lọ́kàn ẹni.” Kì í ṣe pé ènìyàn kàn ń bínú nípa ohun burúkú àti ìpalára tí ẹnì kejì náà ṣe. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí akọ̀ròyìn kan ṣe ṣàlàyé, ó jẹ́ “ìbínú nípa bí ìgbéyàwó tó bà jẹ́ náà ì bá ṣe jẹ́ aláyọ̀ tó.”
Ìmọ̀lára àìkúnjú ìwọ̀n iyì ara ẹni àti àìtóótun tún wọ́pọ̀. Pedro sọ ọ́ láṣìírí pé: “Àwọn ohun tí yóò máa wá sọ́kàn rẹ ni pé: ‘Ṣé mi ò fani mọ́ra tó ni? Ṣé a rí ibi tí n kò ti kúnjú ìwọ̀n ni?’ Wàá wá bẹ̀rẹ̀ sí wá fìn-ín ìdí kókò nípa ara rẹ láti mọ àṣìṣe rẹ.” Nínú ìwé tí Zelda West-Meads, tí ó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Agbani-Nímọ̀ràn Lórí Ìgbéyàwó Ti Ìjọba Àpapọ̀ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, kọ náà, To Love, Honour and Betray, ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun tó le jù láti kojú . . . ni títẹ́ iyì ara ẹni rẹ lógo.”
Ẹ̀bi àti Ìsoríkọ́
Ìmọ̀lára ẹ̀bi ló sábà máa ń tẹ̀ lé irú ìmọ̀lára wọ̀nyí. Ìyàwó kan tó sorí kọ́ sọ pé: “Mo lérò pé àwọn obìnrin ló ń jìyà ìmọ̀lára ẹ̀bi jù. Wàá dá ara rẹ lẹ́bi, wàá wá máa ṣe kàyéfì pé: ‘Kí ni mo ṣe tó kù díẹ̀ káàtó?’”
Ọkọ kan tí aya rẹ̀ dà sọ apá mìíràn nínú ohun tí ó pè ní ìmọ̀lára ìrírí àìròtẹ́lẹ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Ìsoríkọ́ ti di ohun mìíràn tí ń ṣẹlẹ̀ bí ìgbà tí ojú ọjọ́ kò tura.” Ìyàwó kan tí ọkọ rẹ̀ já sílẹ̀ rántí pé kò sí ọjọ́ kan tí òun kì í sunkún. Ó sọ pé: “Mo rántí ọjọ́ àkọ́kọ́ tí n kò sunkún lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan tó ti já mi sílẹ̀. Ó tó oṣù mélòó kan kí ó tó di pé n kò sunkún fún odindi ọ̀sẹ̀ kan. Àwọn ọjọ́ àti ọ̀sẹ̀ tí n kò fi sunkún wọ̀nyẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn.”
Àdàkàdekè Ọ̀nà Méjì
Ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kò mọ̀ ni pé lọ́pọ̀ ìgbà, ìyà ọ̀nà méjì ni onípanṣágà náà fi jẹ ẹnì kejì rẹ̀. Lọ́nà wo? Pat fún wa ní ẹ̀rí kan pé: “Kò rọrùn fún mi. Kì í ṣe ọkọ mi nìkan ló jẹ́, ọ̀rẹ́ mi ló jẹ́ pẹ̀lú—ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi—fún ọ̀pọ̀ ọdún.” Òtítọ́ ni, bí ó ti máa ń ṣẹlẹ̀ níbi púpọ̀ jù lọ, ọkọ ni alábàárò ìyàwó nígbà ìṣòro. Nísinsìnyí, kì í ṣe pé ọkọ náà ti wá di okùnfà àwọn ìṣòro adanilórírú gan-an nìkan ni ṣùgbọ́n kì í tún ṣe alátìlẹ́yìn tí a nílò gidigidi mọ́. Ohun kan ṣoṣo tó ṣe yẹn ti fa ìrora ọkàn lílé koko bákan náà ni kò tún jẹ́ kí ìyàwó rẹ̀ ní ẹni àáfinútán tó gbẹ́kẹ̀ lé mọ́.
Ní àbáyọrí rẹ̀, èrò lílágbára náà pé a da òun àti pé ìgbẹ́kẹ̀lé òun ti fọ́ yángá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìrònú lílágbára jù lọ tí ẹni tó ṣe olóòótọ́ náà máa ń ní. Olùgbani-nímọ̀ràn lórí ìgbéyàwó kan ṣàlàyé ìdí tí dída ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó fi lè dani lọ́kàn rú gan-an pé: “Orí ìgbéyàwó ni ìsapá, ìrètí, àti ìfojúsọ́nà wa dá lé . . . , bí a ti ń wá ẹni tí a lè gbẹ́kẹ̀ lé ní gidi, ẹni tí a lérò pé a lè gbára lé nígbà gbogbo. Bí ìgbẹ́kẹ̀lé yẹn bá kúrò níbẹ̀ lójijì, ó lè dà bíi káàdì títa tí a kó sílẹ̀ tí afẹ́fẹ́ wá gbé lójijì.”
Ní kedere, bí a ṣe sọ ọ́ nínú ìwé How to Survive Divorce, àwọn tí ìṣòro náà bá “nílò ìrànlọ́wọ́ láti yanjú ìdààmú ọkàn wọn . . . Wọ́n lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti pinnu àwọn ohun tí wọ́n lè yàn àti bí wọ́n ṣe lè yàn wọ́n.” Ṣùgbọ́n kí ni àwọn yíyàn náà?
O lè ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ yíyanjú ọ̀rọ̀ ni yóò parí rẹ̀ fún wa?’ ‘Tàbí ṣé kí n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni?’ Ní pàtàkì bí àbààwọ́n bá ti ta bá ìgbéyàwó náà, ó lè mú kí o kù gììrì ronú pé ìkọ̀sílẹ̀ ni yóò yanjú àwọn ìṣòro rẹ. O lè ronú pé, ‘Ó ṣe tán, Bíbélì fàyè gba jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀ bí ẹnì kan bá hùwà àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó.’ (Mátíù 19:9) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, o lè tún ronú pé Bíbélì kò rin kinkin mọ́ jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀. O lè torí èyí ronú pé yóò sàn jù láti yanjú ọ̀rọ̀ náà, kí ẹ ṣàtúnṣe ìgbéyàwó náà, kí ẹ sì gbé e ró.
Yálà a fẹ́ jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fún ẹnì kejì wa tó hùwà àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó tàbí a kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìpinnu ara ẹni. Síbẹ̀, báwo lo ṣe lè mọ ohun tó yẹ kí o ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, jọ̀wọ́ gbé díẹ̀ lára àwọn kókó pàtàkì tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pinnu bóyá ó ṣeé ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.