Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó dá ayé àtàwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀, àmọ́ ohun táwọn kan sọ ni pé kò sí Ẹlẹ́dàá kan níbì kan. Tó o bá ka ìwé yìí, wàá rí àwọn ohun tó gbàfiyèsí tó sì ń múni ronú jinlẹ̀ gan-an lórí ọ̀rọ̀ yìí, wàá sì lè mọ̀ bóyá Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́ àbí kò sí. Ṣé ayé àtọ̀run àtàwọn ohun tó wà níbẹ̀ ṣàdédé wà ni àbí iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá kan ni? Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó o mọ ìdáhùn ìbéèrè yìí.