ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g21 No. 3 ojú ìwé 8-9
  • Àwọn Nǹkan Táwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ò Lè Ṣàlàyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Nǹkan Táwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ò Lè Ṣàlàyé
  • Jí!—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Onímọ̀ Nípa Ọlẹ̀ Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́
    Jí!—2016
  • Báwo Ni Àgbáálá Ayé àti Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀?
    Jí!—2002
  • Àǹfààní Tí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ń Ṣe fún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ẹlẹ́dàá Lè Mú Kí Ayé Rẹ Nítumọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Jí!—2021
g21 No. 3 ojú ìwé 8-9
Olùkọ́ kan tó ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ń jíròrò pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀.

Àwọn Nǹkan Táwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ò Lè Ṣàlàyé

Ọ̀pọ̀ ìwádìí làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe nípa ayé àtàwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ṣe pàtàkì ni wọn ò lè dáhùn.

Ṣé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀? Rárá! Àwọn kan gbà pé àwọn onímọ̀ nípa àgbáyé lè ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Marcelo Gleiser tó ń ṣiṣẹ́ ní Dartmouth College sọ fi hàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Onímọ̀ nípa àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run ni Gleiser, ó sì gbà pé kò sí béèyàn ṣe lè mọ̀ bóyá Ọlọ́run wà tàbí kò sí. Ó ní: “Títí di báyìí, a ò tíì lè ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀.”

Bákan náà, nígbà tí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Science News ń sọ̀rọ̀ lórí báwọn nǹkan alààyè ṣe dé ayé, ó sọ pé: “Kò jọ pé a máa lè ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa báwọn nǹkan alààyè ṣe dé ayé yìí. Torí pé kò sí bá a ṣe lè rí àwọn òkúta, egungun èèyàn àti tẹranko tá a lè fi ṣèwádìí ká lè mọ bí nǹkan ṣe rí níbẹ̀rẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ tá a tọ́ka sí yìí jẹ́ ká rí i pé títí di báyìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lè ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀.

Àmọ́ o lè máa rò ó pé, ‘Tí ayé yìí àtàwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀ ò bá ṣàdédé wà, ta ló dá wọn?’ Ó tún ṣeé ṣe kó o ti rò ó rí pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tó sì tún nífẹ̀ẹ́ wa, kí ló dé táwa èèyàn fi ń jìyà? Kí nìdí tí oríṣiríṣi ẹ̀sìn fi wà? Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run fi ń hùwà burúkú?’

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò sí bó o ṣe lè mọ ìdáhùn. Kódà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti jẹ́ kí Bíbélì ran àwọn lọ́wọ́ láti mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè náà, ohun tí wọ́n rí nínú Bíbélì sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.

Àwọn kan lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ti wá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà. Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó mú kí wọ́n gbà bẹ́ẹ̀, lọ sórí ìkànnì jw.org. Tẹ àkòrí náà “Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ìṣẹ̀dá” síbi tó o ti lè fi ọ̀rọ̀ wá nǹkan, kó o sì wo àwọn fídíò tó wà ní abala náà.

Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti Bíbélì ló mú kí wọ́n yí èrò wọn pa dà

Georgiy N. Koidan, onímọ̀ nípa kẹ́míkà

“Iṣẹ́ mi gba pé kí n máa to àwọn èròjà tín-tìn-tín pa pọ̀. Iṣẹ́ ọpọlọ niṣẹ́ yìí, torí ó gba pé kéèyàn ronú jinlẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan lèèyàn sì máa ní láti ṣe kíṣẹ́ náà lè yọrí. Téèyàn bá lọ fo ọ̀kan lára ìgbésẹ̀ tó yẹ kó gbé láti to àwọn èròjà náà pọ̀, gbogbo nǹkan tẹ́ni náà ti ń ṣe lè dà rú. Òótọ́ ni pé iṣẹ́ mi ò rọrùn rárá, àmọ́ kò tó nǹkan kan tá a bá fi wéra pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àyípadà tó ń wáyé nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú àwọn ohun alààyè kí wọ́n tó lè mú ọ̀pọ̀ àwọn èròjà tín-tìn-tín jáde. Ìyẹn ló jẹ́ kí n rí i pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó ní ìmọ̀ tó kún rẹ́rẹ́ nípa kẹ́míkà ju ẹnikẹ́ni lọ.

“Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo rí i pé ó yàtọ̀ sáwọn ìwé tó kù. Òótọ́ ni pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti kọ Bíbélì parí, síbẹ̀ mo rí i pé àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹ̀ ṣì wúlò lóde òní. Àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ nípa béèyàn ṣe lè yanjú aáwọ̀ nínú ìdílé, níbi iṣẹ́ àti ládùúgbò wúlò gan-an. Ìyẹn mú kí n gbà pé ẹnì kan tí ìmọ̀ ẹ̀ ga ju tàwa èèyàn lọ fíìfíì ló fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹ̀.”

Yan-Der Hsuuw, onímọ̀ nípa ọlẹ̀

“Bí ẹyin tó wà nínú ọlẹ̀ bá ṣe ń dàgbà, ṣe làwọn sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú ẹ̀ á máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí àwọn kan nínú wọn lè di iṣan, egungun, ẹ̀jẹ̀, òpó ẹ̀jẹ̀ àtàwọn ẹ̀yà ara míì títí táá fi di èèyàn. Títí di báyìí, a ò tíì mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí ẹyin tó wà nínú ọlẹ̀ ṣe máa ń di èèyàn. Èyí mú kí n gbà pé ó ní láti jẹ́ pé ẹnì kan tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye ló dá àwọn nǹkan alààyè.

“Nígbà tí mo ronú lórí àlàyé táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe láwọn ọdún àìpẹ́ yìí nípa bí ọmọ ṣe ń dàgbà nínú ilé ọlẹ̀, tí mo sì fi wé ohun tí Bíbélì sọ ní Sáàmù 139:​15, 16, mo rí i pé ó bára mu. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ náà sínú Bíbélì. Báwo làwọn tó kọ Bíbélì ṣe lè mọ àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa àwọn nǹkan alààyè tí kì í bá ṣe pé Ẹlẹ́dàá àwọn nǹkan náà ló jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n?”

Wo fídíò Davey Loos: Onímọ̀ Ìjìnlẹ̀ Ìṣètò Ìgbésí Ayé Ṣàlàyé Ìgbàgbọ́ Rẹ̀. Wá fídíò náà lórí ìkànnì jw.org.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́