ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g22 No. 1 ojú ìwé 7-9
  • 2 | Ṣe Ohun Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Àtijẹ Àtimu Nira Fún Ẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2 | Ṣe Ohun Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Àtijẹ Àtimu Nira Fún Ẹ
  • Jí!—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí
  • Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Bọ́ Lọ́wọ́ Gbèsè
    Jí!—1996
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Nípa Gbèsè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Jí!—2022
g22 No. 1 ojú ìwé 7-9
Káfíńtà ń kan ìṣó mọ́ igi.

AYÉ DOJÚ RÚ

2 | Ṣe Ohun Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Àtijẹ Àtimu Nira Fún Ẹ

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kìràkìtà torí àtijẹ àtimu lójoojúmọ́, ṣe nìyẹn sì túbọ̀ ń nira torí bí nǹkan ṣe ń dojú rú láyé yìí. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?

  • Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ níbì kan tàbí tí nǹkan ò rí bó ṣe yẹ kó rí, àwọn nǹkan á gbówó lórí, irú bí owó ilé àti owó oúnjẹ.

  • Tí nǹkan bá dojú rú nílùú, iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tàbí kí owó tó ń wọlé fún wọn dín kù.

  • Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó lè ba ohun ìní àwọn èèyàn jẹ́, kíyẹn sì sọ wọ́n di òtòṣì.

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀

  • Tó o bá mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná, ìyẹn ò ní jẹ́ kí nǹkan nira jù fún ẹ nígbà ìṣòro.

  • Fi sọ́kàn pé nǹkan lè yí pa dà nígbàkigbà. Owó tàbí ohun ìní rẹ lè má níyì mọ́ tó bá dọ̀la.

  • Tẹ́nì kan bá lówó, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó máa láyọ̀ tàbí pé ìdílé ẹ̀ máa wà níṣọ̀kan.

Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí

Bíbélì sọ pé: “Tí a bá ti ní oúnjẹ àti aṣọ, àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.”​—1 Tímótì 6:8.

Tó o bá ní ìtẹ́lọ́rùn, o ò ní máa wá àwọn nǹkan tó kàn wù ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ẹ á máa dùn ọkàn ẹ á sì balẹ̀ tó o bá ti rí àwọn ohun pàtàkì tó o nílò. Èyí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an tí nǹkan bá yí pa dà fún ẹ.

Kó o lè ní ìtẹ́lọ́rùn, o máa ní láti ṣe àwọn àtúnṣe pàtàkì kan. Bí àpẹẹrẹ, á dáa kó o máa ṣọ́wó ná, kó o má sì ṣe ju agbára ẹ lọ. Torí tó o bá ń ná ju iye tó ń wọlé fún ẹ, ìyẹn lè mú kí nǹkan nira.

KÍ LỌ̀NÀ ÀBÁYỌ?​—Ohun Tó O Lè Ṣe

Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àtijẹ àtimu ò ní nira fún ẹ tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ tàbí tí nǹkan ò rí bó ṣe yẹ kó rí nílùú

DÍN ÌNÁWÓ RẸ KÙ

  • Ìyá àgbàlagbà kan ń kórè kárọ́ọ̀tì nínú ọgbà.

    Dín ìnáwó rẹ kù

    Àwọn ohun tó o nílò nìkan ni kó o máa rà. Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé dandan ni kí n ra mọ́tò? Ṣé mo lè dáko kí n lè dín àwọn nǹkan tí mò ń fowó rà kù?’

  • Kó o tó ra ohunkóhun, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mo nílò nǹkan yìí? Ṣé máa lè bójú tó o lẹ́yìn tí mo bá rà á tán?’

  • Tí ohun kan bá wà tí ìjọba tàbí àwọn ará ìlú ṣètò láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, o lè ní kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́.

“Èmi àti ìdílé mi ronú lórí àwọn nǹkan tá à ń náwó lé. Ìyẹn mú ká dín iye tá à ń ná lórí eré ìnàjú kù. Lẹ́yìn náà, a bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àwọn oúnjẹ tí ò ní ná wa lówó púpọ̀.”​—Gift.

ṢÈTÒ BÓ O ṢE MÁA NÁWÓ

Obìnrin kan ń ṣírò owó, ó sì ń kọ àwọn nǹkan tó rà látinú rìsíìtì.

Ṣètò bó o ṣe máa náwó

Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere, àmọ́ ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.” (Òwe 21:5) Tó o bá ṣètò bó o ṣe máa náwó, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o máa ná ju iye tó ń wọlé fún ẹ.

  • Kọ iye tó o rò pé ó máa wọlé fún ẹ lóṣù sílẹ̀.

  • Ronú lórí iye tó ò ń ná lóṣooṣù lórí oúnjẹ, iná mànàmáná àtàwọn nǹkan míì, kó o wá kọ ọ́ sílẹ̀.

  • Lẹ́yìn náà, fi iye tó ò ń ná wéra pẹ̀lú iye tó ń wọlé fún ẹ. Tó o bá wá rí i pé iye tó o fẹ́ ná ti pọ̀ ju iye tó ń wọlé fún ẹ, á dáa kó o dín àwọn nǹkan tó ò ń náwó lé lórí kù.

“Oṣooṣù la máa ń kọ iye tó ń wọlé fún wa àti iye tá a fẹ́ ná sílẹ̀. A sì máa ń fi owó kan pamọ́ tá a lè ná nígbà tí nǹkan pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. Ohun tá a ṣe yìí máa ń jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ torí pé a ti mọ bá a ṣe fẹ́ ná owó tó ń wọlé fún wa.”​—Carlos.

MÁ ṢE JẸ GBÈSÈ / MÁA FOWÓ PA MỌ́

  • Ìyá kan ń kọ́ ọmọ ẹ̀ kó lè mọ báá ṣe máa tọ́jú owó sínú kóló.

    Má ṣe jẹ gbèsè / máa fowó pa mọ́

    Ṣètò bó o ṣe máa ná owó kó o máa bàa yá owó tó pọ̀ jù tàbí kó o má tiẹ̀ yáwó rárá. Dípò ìyẹn, ńṣe ni kó o máa fowó pa mọ́ kó o lè ra àwọn nǹkan tó o nílò.

  • Máa fi iye kan pa mọ́ lóṣooṣù torí ohun àìròtẹ́lẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ nígbàkigbà.

MÁA ṢIṢẸ́ KÁRA / MÁ JẸ́ KÍṢẸ́ BỌ́ MỌ́ Ẹ LỌ́WỌ́

Bíbélì sọ pé: “Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè.”​—Òwe 14:23.

  • Káfíńtà ń kan ìṣó mọ́ igi.

    Máa ṣiṣẹ́ kára / má jẹ́ kíṣẹ́ bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́

    Máa ní èrò tó dáa nípa iṣẹ́ ẹ. Tó ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ tó ò ń ṣe báyìí, rántí pé ibẹ̀ lo ṣáà ti ń rówó tó o fi ń gbọ́ bùkátà ara ẹ.

  • Gbìyànjú láti jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé kó o sì máa ṣiṣẹ́ kára. Ìyẹn ò ní jẹ́ kíṣẹ́ bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Tí nǹkan bá sì yí pa dà fún ẹ, wàá tètè ríṣẹ́.

“Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni mo máa ń ṣe, bíṣẹ́ náà ò bá tiẹ̀ wù mí tàbí tí owó ẹ̀ ò pọ̀ tó bí mo ṣe fẹ́. Ọwọ́ pàtàkì ni mo fi múṣẹ́, ojúlówó iṣẹ́ ni mo sì máa ń ṣe. Tí mo bá ń bá ẹnì kan ṣiṣẹ́, ńṣe ni mo máa ń ṣe é bí iṣẹ́ tara mi.”​—Dmitriy.

Ohun tó o lè ṣe tó o bá ń wáṣẹ́ . . .

  • Má jókòó tẹtẹrẹ. Wáṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ tó o gbà pé wọ́n máa ní iṣẹ́ tó o lè ṣe, tí wọn ò bá tiẹ̀ sọ pé àwọn ń wá ẹni tó máa ṣe irú iṣẹ́ náà. Sọ fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ pé ò ń wáṣẹ́.

  • Jẹ́ kí iṣẹ́ tó o bá rí tẹ́ ẹ lọ́rùn. Fi sọ́kàn pé o lè má ríṣẹ́ tó ní gbogbo nǹkan tó o fẹ́.

Àwọn ọmọ ń ṣeré lẹ́yìnkùlé nígbà táwọn òbí wọn ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa náwó.

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I. Ka àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́