ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 12/22 ojú ìwé 8-12
  • Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Bọ́ Lọ́wọ́ Gbèsè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Bọ́ Lọ́wọ́ Gbèsè
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣẹ́pá Ìdènà sí Ìwéwèé Ìnáwó
  • Bíbẹ̀rẹ̀
  • Ṣíṣàkọsílẹ̀ Ìnáwó Rẹ Lóṣooṣù
  • Ó Ha Pọn Dandan Bí?
  • Dín Iye Gbèsè Tí O Ń Jẹ Kù
  • Ìwọ Yóò Ha Ṣàṣeyọrí Bí?
  • Bí O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
    Jí!—2012
  • 2 | Ṣe Ohun Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Àtijẹ Àtimu Nira Fún Ẹ
    Jí!—2022
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná?
    Jí!—2006
  • Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 12/22 ojú ìwé 8-12

Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Bọ́ Lọ́wọ́ Gbèsè

NÍ ÀWỌN àkókò tí ń yí padà yìí, bíbójú tó ohun ìní ìdílé lè jẹ́ ìpèníjà. Báwo ni o ṣe lè kojú àwọn ìpèníjà náà pẹ̀lú àṣeyọrí?

Ìdáhùn náà kò fi dandan jẹ́ ọ̀ràn pé kí owó púpọ̀ sí i máa wọlé. Àwọn ògbóǹkangí nínú ọ̀ràn ìnáwó sọ pé ìdáhùn náà ní í ṣe pẹ̀lú mímọ̀ nípa bí a ṣe ń rí owó náà àti bí a ṣe ń ná an àti pẹ̀lú mímúra tán láti ṣe ìpinnu látàrí ohun tí a mọ̀. Láti ṣe èyí, o nílò ìwéwèé ìnáwó.

Ṣíṣẹ́pá Ìdènà sí Ìwéwèé Ìnáwó

Bí ó ti wù kí ó rí, olùgbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìnáwó, Grace Weinstein, sọ pé ìwéwèé ìnáwó “ń gbé onírúurú èrò tí ń bani nínújẹ́ wá sọ́kàn àwọn ènìyàn.” Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò wulẹ̀ ní í ṣe ọ̀kan. Àwọn kan tún so àìní fún ìwéwèé ìnáwó mọ́ owó kékeré tí ń wọlé tàbí àìkàwé. Ṣùgbọ́n àwọn amọṣẹ́dunjú pàápàá, tí owó púpọ̀ ń wọlé fún, ní àwọn ìṣòro owó. Olùgbaninímọ̀ràn kan lórí ọ̀ràn ìnáwó sọ pé: “Dọ́là 187,000 ń wọlé lọ́dún fún ọ̀kan lára àwọn oníbàárà tí mo kọ́kọ́ ní . . . Gbèsè káàdì ìrajà àwìn wọn nìkan kù díẹ̀ kí ó tó 95,000 dọ́là.”

Michael, tí a mẹ́nu kan níṣàájú, lọ́ra láti wá ìmọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìnáwó fún ìdí mìíràn. Ó jẹ́wọ́ pé: “Mo bẹ̀rù pé àwọn mìíràn yóò wò mí bí ọ̀gbẹ̀rì àti òmùgọ̀.” Ṣùgbọ́n irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ kò fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ṣíṣún owó ná àti pípa owó wọlé ń béèrè fún òye ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn kò sì ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣeé ṣún owó ná. Òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan sọ pé: “A ń jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ní mímọ̀ nípa ìṣirò ohun onígun mẹ́ta tí méjì dọ́gba, ju mímọ̀ nípa bí a ti í fowó pamọ́ lọ.”

Bí ó ti wù kí ó rí, wíwéwèé ìnáwó rọrùn láti kọ́ dé ìwọ̀n àyè kan. Ó ní nínú, ṣíṣe àkọsílẹ̀ owó tí ń wọlé àti iye tí a ń ná—àti lẹ́yìn náà jíjẹ́ kí iye tí a ń ná mọ sórí iye tí ń wọlé. Ní gidi, ṣíṣàkọsílẹ̀ ìwéwèé ìnáwó kan lè gbádùn mọ́ni, títẹ̀ lé e sì lè tẹ́ ni lọ́rùn.

Bíbẹ̀rẹ̀

Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àkọsílẹ̀ iye tí ń wọlé. Fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa, ó yẹ kí èyí rọrùn, nítorí pé ó kan ìwọ̀nba ohun díẹ̀ péré ní gbogbogbòò—owó oṣù, èlé láti inú àkáǹtì ìfowópamọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n má ṣe wéwèé lórí àwọn owó tí kò dájú pé yóò wọlé, irú bí èyí tí ń wá láti inú owó àṣekún iṣẹ́, àwọn àjẹmọ́nú, tàbí ẹ̀bùn. Àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀ràn ìnáwó kìlọ̀ pé wíwéwèé lórí àwọn orísun owó tí kò dájú pé yóò wọlé lè kó ọ sínú gbèsè. Bí irú àwọn orísun owó bẹ́ẹ̀ bá mú nǹkan jáde, o lè yàn láti fi owó náà ṣe yọ̀tọ̀mì fúnra rẹ àti ìdílé rẹ, láti ran àwọn tí wọ́n ṣaláìní lọ́wọ́, tàbí láti ṣèdáwó fún ohun kan tí ó tọ́.

Bí ó ti wù kí ó rí, ṣíṣàkọsílẹ̀ ìnáwó lè túbọ̀ kún fún ẹ̀tàn. Robert àti Rhonda, tí a mẹ́nu kàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, kò mọ ibi tí owó iṣẹ́ àṣelàágùn wọn ń gbà lọ. Robert ṣàlàyé bí wọ́n ṣe yanjú ìṣòro náà pé: “Fún oṣù kan gbáko, àwa méjèèjì ń mú abala bébà kan, a sì ń ṣàkọsílẹ̀ kọ́bọ̀ kọ̀ọ̀kan tí a bá ná. A tilẹ̀ ṣàkọsílẹ̀ owó tí a fi ra ife kọfí kan pàápàá. Lópin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, a ń ṣàkọsílẹ̀ gbogbo iye tí ó jẹ́ sínú ìwé ìwéwèé ìnáwó tí mo rà.”

Fífi tìṣọ́ratìṣọ́ra ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ohun tí o ná yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí o ná ‘àwáàrí owó’ èyíkéyìí lé lórí. Bí ó ti wù kí ó rí, bí o bá mọ ìṣọwọ́náwó rẹ, o lè pinnu láti yẹ ṣíṣàkọsílẹ̀ ìnáwó rẹ ojoojúmọ́ sílẹ̀, kí o sì máa ṣàkọsílẹ̀ ìnáwó rẹ lóṣooṣù.

Ṣíṣàkọsílẹ̀ Ìnáwó Rẹ Lóṣooṣù

O lè fẹ́ láti ṣe ìlapa kan tí ó jọ èyí tí a fi hàn lókè. Nínú àyè “Ìnáwó Gidi,” kọ iye tí o ń ná sórí ohun kọ̀ọ̀kan ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Jẹ́ kí iye lájorí ìsọ̀rí mọ níwọ̀n, ní lílo àwọn àkọlé bíi “oúnjẹ,” “ilé,” àti “aṣọ.” Bí ó ti wù kí ó rí, má ṣe yẹ àwọn ìsọ̀rí abẹ́ ìsọ̀rí tí wọ́n fara pẹ́ ẹ sílẹ̀. Ní ti Robert àti Rhonda, èyí tí ó pọ̀ nínú owó wọn ní ń lọ sórí jíjẹun nílé àrójẹ, nítorí náà yíya “jíjẹun nílé àrójẹ” kúrò lára “awóróbo” ń ṣèrànwọ́. Bí o bá fẹ́ràn ṣíṣe aájò àlejò, èyí pẹ̀lú lè jẹ́ ìsọ̀rí kan lábẹ́ “oúnjẹ.” Ohun tí a ń sọ ni láti jẹ́ kí ìlapa náà gbé ànímọ́ rẹ àti ohun tí o fẹ́ràn jù lọ yọ.

Bí o bá ń lo ìlapa rẹ, má ṣe gbà gbé àwọn ìnáwó ẹlẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún, ẹlẹ́ẹ̀mejì lọ́dún, ọlọ́dọọdún, àti àwọn ti àtìgbàdégbà, bíi sísan owó ìbánigbófò àti àwọn owó orí. Bí ó ti wù kí ó rí, láti kọ wọ́n sábẹ́ ìlapa olóṣooṣù, ìwọ yóò ní láti pín iye owó náà sí iye oṣù tí ó yẹ.

Ohun pàtàkì kan nínú àkọsílẹ̀ ìnáwó ni “owó àfipamọ́.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn lè ṣàìronú nípa owó àfipamọ́ gẹ́gẹ́ bí ìnáwó, ìwọ yóò máa fi pẹ̀lú ọgbọ́n wéwèé níná díẹ̀ lára owó rẹ tí ń wọlé fún ọ lóṣooṣù lórí àwọn ipò pàjáwìrì tàbí àwọn ète pàtàkì. Grace Weinstein tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì fífi owó àfipamọ́ kún àkọsílẹ̀ ìnáwó rẹ pé: “Bí o kò bá lè sapá láti fi, ó kéré tán, ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún nínú iye tí ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn sísan owó orí (ìyẹn sì jẹ́ iye rírẹlẹ̀ pátápátá), pamọ́, ìwọ yóò ní láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó túbọ̀ le koko. Jáwọ́ nínú rírajà àwìn, ṣàtúntò ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ, kí o sì gbé àwọn ohun tí o nílò ní gidi yẹ̀ wò.” Bẹ́ẹ̀ ni, rántí láti fi owó àfipamọ́ kún ìwéwèé ìnáwó rẹ oṣooṣù.

Fún ohun tí ó lè dẹwọ́ ìdíwọ́ ní sáà tí iṣẹ́ lè ṣàìsí, a ti ń dámọ̀ràn níbi gbogbo nísinsìnyí pé kí o gbìyànjú fífi, ó kéré tán, iye tí ó tó owó oṣù mẹ́fà pamọ́. Olùgbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìnáwó kan sọ pé: “Bí owó tí ń wọlé fún ọ bá pọ̀ sí i, fi ìdajì lára rẹ̀ pamọ́.” O ha lérò pé kò ṣeé ṣe fún ọ láti fowó pamọ́ bí?

Gbé ọ̀ràn Laxmi Bai, tí ó tòṣì gan-an bíi ti ọ̀pọ̀ ènìyàn ní àrọko Íńdíà, yẹ̀ wò. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í da ẹ̀kúnwọ́ kan ìrẹsì lára oúnjẹ ojoojúmọ́ tí ó ń sè fún ìdílé rẹ̀ pamọ́ sínú ìkòkò amọ̀ kan. Látìgbàdégbà, yóò máa ta ìrẹsì náà, yóò sì fi owó náà pamọ́ sí báńkì. Ìgbésẹ̀ kan sípa rírí ẹ̀yáwó báńkì láti ran ọmọkùnrin rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣí sọ́ọ̀bù ìtúnkẹ̀kẹ́ṣe kan nìyí. Ìwé ìròyìn India Today sọ pé irú àwọn owó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí a fi pamọ́ bẹ́ẹ̀ ti yí ìgbésí ayé ẹni púpọ̀ padà gan-an. Èyí ti sọ òmìnira àbójútó agboolé di ohun gidi fún àwọn kan.

Síbẹ̀síbẹ̀, mímú ìwéwèé ìnáwó kan wà déédéé ju ṣíṣàkọsílẹ̀ owó tí ń wọlé àti àwọn ìnáwó lọ. Ó kan fífi àwọn ìnáwó mọ sí ààlà owó tí ń wọlé, tí ó lè béèrè fún dídín ìnáwó rẹ kù.

Ó Ha Pọn Dandan Bí?

Ṣàkíyèsí àkọlé náà “Ó Ha Pọn Dandan?” lórí fọ́ọ̀mù tí ó wà lójú ìwé 9. Àyè yìí ṣe pàtàkì láti gbé yẹ̀ wò, pàápàá jù lọ bí o bá rí i pé àròpọ̀ ní àyè “Iye Tí A Wéwèé” pọ̀ ju iye tí ń wọlé fún ọ lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, pípinnu bóyá ohun kan pọn dandan àti iye tí ó yẹ kí a ná lé e lè jẹ́ ìpèníjà kan. Èyí rí bẹ́ẹ̀, pàápàá jù lọ ní àwọn àkókò tí gbogbo nǹkan ń yí padà yìí, tí wọ́n ti fi ìṣejáde àwọn ohun tuntun tí wọ́n ń polówó bí ohun kòṣeémánìí pá wa lórí láìdábọ̀. Ríronú nípa ìnáwó kọ̀ọ̀kan ní ti ohun kòṣeémánìí gidi, ohun tí kò dájú pé a nílò, tàbí ohun afẹ́ tí ó dára láti ní yóò ṣèrànwọ́.

Wo ìnáwó kọ̀ọ̀kan tí o ti kọ sílẹ̀, lẹ́yìn ìdíyelé tí ó gbàrònú, kọ “B” sí abẹ́ “Ó Ha Pọn Dandan?” bí ohun náà bá pọn dandan ní pàtó; kọ “?” bí kò bá dájú pé a nílò rẹ̀; àti “D” bí ó bá jẹ́ ohun tí ó dára láti ní. Rántí, àpapọ̀ iye owó tí a kọ síbi “Iye Tí A Wéwèé” kò lè pọ̀ ju iye tí ń wọlé fún ọ lóṣooṣù!

Ó hàn gbangba pé àwọn ohun tí a kọ “?” àti “D” sí yóò jẹ́ àwọn tí a óò bẹ̀rẹ̀ sí í yọ kúrò. A lè máà ní láti yọ àwọn ìnáwó wọ̀nyí kúrò pátápátá. Èrò náà jẹ́ láti gbé ohun kọ̀ọ̀kan yẹ̀ wò láti rí i bí ìnáwó náà bá yẹ fún ìgbádùn tí ìnáwó náà mú wà, kí a sì ṣe àyọkúrò bí ó ṣe yẹ. Robert àti Rhonda rí i láti inú àkọsílẹ̀ wọn pé àwọ́n ń ná 500 dọ́là lóṣù lórí jíjẹun ní ilé àrójẹ. Wọ́n ti sọ ọ́ dàṣà nítorí pé kò sí èyí tí ó mọ bí a ti ń se oúnjẹ nínú wọn. Ṣùgbọ́n Rhonda gbé ìgbésẹ̀ láti kọ́ ọ, ó sì wí pé: “Nísinsìnyí, oúnjẹ sísè ti di ohun gbígbádùn mọ́ni, a sì ń jẹun nílé lọ́pọ̀ ìgbà.” Robert fi kún un pé: “Nísinsìnyí, ní àwọn àkókò pàtàkì tàbí nígbà tí ó bá pọn dandan nìkan ni a máa ń jẹun ní ilé àrójẹ.”

Ìyípadà nínú ipò ọ̀ràn rẹ lè mú kí o tún ṣàtúnyẹ̀wò délẹ̀délẹ̀ lórí ohun tí ó pọn dandan. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́, owó tí ń wọlé fún Anthony lọ sílẹ̀ dòò. Ó lọ láti orí 48,000 dọ́là lọ́dọọdún sí iye tí kò tó 20,000 dọ́là, ó sì wà ní iye yẹn fún ọdún méjì. Bí èyí bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, o lè ní láti gbé ìwéwèé ìnáwó kan kalẹ̀, kí ó sì gé gbogbo ohun ríré kọjá ààlà nínú ìnáwó rẹ dà nù.

Ohun tí Anthony ṣe gan-an nìyẹn. Nípa ṣíṣe ìgékúrò tí ó mọ́yán lórí nínú owó tí ó ń ná lórí oúnjẹ, aṣọ, ọkọ̀ wíwọ̀, àti ìgbafẹ́, pẹ̀lú ìsapá ńlá, ó san owó ìfidúkìá-dúró fún ilé rẹ̀.a Ó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, a ní láti pinnu àwọn ohun kòṣeémánìí gidi, a sì ti jàǹfààní láti inú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. A ti wá mọ̀ nísinsìnyí bí a ṣe lè ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun tí a ní.”

Dín Iye Gbèsè Tí O Ń Jẹ Kù

Bí o kò bá ṣàkóso gbèsè jíjẹ, ó lè mú ìjákulẹ̀ bá àwọn ìsapá rẹ láti máa lo ìwọ̀nba ohun tí o bá ní. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn gbèsè onígbà gígùn tí a ná sórí ríra àwọn ohun ṣíṣeyebíye bí ilé tí ìdíyelé rẹ̀ ń pọ̀ sí i lè ṣàǹfààní, àwọn gbèsè tí a fi káàdì ìrajà àwìn jẹ láti bójú tó ọ̀ràn ìnáwó ìgbésí ayé ojoojúmọ́ lè jẹ́ ìjábá. Nítorí náà, ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, “má ṣe san kọ́bọ̀ lórí ìdáwóléni káàdì kankan.”

Àwọn ògbóǹkangí nínú ọ̀ràn ìnáwó fúnni níṣìírí sísan àwọn gbèsè orí káàdì ìrajà àwìn kódà bí o bá ní láti mú un láti inú owó tí o ń fi pamọ́. Kò wulẹ̀ lọ́gbọ́n nínú láti máa jẹ gbèsè pẹ̀lú èlé gọbọi nígbà tí o ń fowó pamọ́ pẹ̀lú èlé kékeré. Ní mímọ èyí, Michael àti Reena san àwọn gbèsè orí káàdì ìrajà àwìn wọn nípa gbígba owó láti inú ìwé ẹ̀rí èlé ìfowópamọ́ wọn, wọ́n sì pinnu láti má ṣe kó wọnú ipò yẹn mọ́.

Nítorí pé Robert àti Rhonda kò ní irú orísùn owó bẹ́ẹ̀, wọ́n lo ìwéwèé ìnáwó ìlàájá. Robert sọ pé: “Mo ṣe ìlapa ìfiwéra ìsọfúnni oníṣirò sórí pátákó funfun kan tí ń fi bíi gbèsè wa yóò ṣe máa dín kù lóṣooṣù hàn, mo sì gbé pátákó náà kọ́ sínú iyàrá wa, níbi tí a ti lè máa rí i láràárọ̀. Èyí ń fún wa ní ìṣírí lójoojúmọ́.” Nígbà tí ọdún máa fi parí, ẹ wo bí inú wọ́n ṣe dùn tó láti bọ́ lọ́wọ́ gbèsè tí ó lé ní 6,000 dọ́là nínú káàdì ìrajà àwìn wọn!

Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, kódà ìfidúkìá-dúró kì í ṣe ìdókòwò tí ó fi bẹ́ẹ̀ dára bí i ti ìgbà kan. Ríra ilé kan sì lè jálẹ̀ sí níná ọ ní owó púpọ̀ ní ti èlé. Kí ni o lè ṣe láti dín iye tí ìfidúkìá-dúró ń náni kù? Ìwé ìròyìn Newsweek dámọ̀ràn pé: “Bóyá kí o san owó tí ó pọ̀ ju iye tí báńkì náà béèrè lọ́wọ́ rẹ sílẹ̀ tàbí kí o ra ilé tí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́n. Bí o bá ti ní ilé kan, dènà ìrọni láti ra èyí tí ó tóbi jù ú lọ.”

O lè dín iye tí ẹ̀yáwó fún ríra ọkọ̀ yóò ná ọ kù ní ìwọ̀n tí ó pọ̀ díẹ̀ nípa sísan àsan-ánlẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ti máa tọ́jú owó pamọ́ fún èyí láti ìgbà pípẹ́ nípa fífi sábẹ́ ìsọ̀rí kan nínú ìwéwèé ìnáwó ìdílé rẹ. Ti yíyan àlòkù ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ńkọ́?b Owó tí wọ́n kọ́kọ́ rà á tí kò pọ̀ lè túmọ̀ sí ìdáwóléni tí kò pọ̀. Ó tilẹ̀ lè ṣeé ṣe fún ọ láti ra ọ̀kan láìní láti wọ gbèsè nítorí rẹ̀.

Ìwọ Yóò Ha Ṣàṣeyọrí Bí?

Yálà o ṣe àṣeyọrí láti mú kí ìwéwèé ìnáwó rẹ gbéṣẹ́ sinmi gan-an lórí bí ó bá ṣe jẹ́ gidi tó. Àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí nípa lílo ìwéwèé ìnáwó kan sọ pé: “Ìlànà náà kò ní ṣiṣẹ́ bí iye owó tí a yà sọ́tọ̀ fún àbójútó agboolé bá kéré gan-an débi ti kò ní fi tó yín lóṣù.”

Kókó abájọ pàtàkì míràn nínú mímú kí ìwéwèé ìnáwó gbéṣẹ́ ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó gbá múṣé láàárín àwọn mẹ́ḿbà ìdílé. Àwọn tí ìwéwèé ìnáwó náà kàn gbọ́dọ̀ ní àǹfààní láti ṣàlàyé ojú ìwòye àti èrò wọn láìsí pé a fi wọ́n ṣẹlẹ́yà. Bí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí ọ̀ràn kàn bá lóyé àwọn ohun kòṣeémánìí àti ohun tí ẹnìkíní kejì wọn ń fẹ́, tí wọ́n sì mọ bí ipò ọ̀ràn ìnáwó ìdílé wọ́n ṣe wà ní gidi, ó ṣeé ṣe kí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí ó sàn jù àti àǹfààní tí ó sàn jù wà pé ìwéwèé ìnáwó ìdílé náà yóò kẹ́sẹ járí.

Ní àwọn àkókò líle koko yìí, bí ipò ayé ti ń yí padà ni pákáǹleke lórí ọ̀ràn ìnáwó ìdílé ń pọ̀ sí i. (Tímótì Kejì 3:1; Kọ́ríńtì Kìíní 7:31) A ní láti lo “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́” ní kíkojú àwọn ìpèníjà ìgbésí ayé òde òní. (Òwe 2:7, NW) Níní ìwéwèé ìnáwó kan lè jẹ́ ohun náà gan-an tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìyẹn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àwọn èrò lórí dídín àwọn ìnáwó ojoojúmọ́ kù, wo Jí!, ti October 22, 1986, ojú ewé 26 àti 27, àti September 22, 1985, ojú ewé 24.

b Wo Jí!, April 8, 1996, ojú ìwé 16 sí 19.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Yẹ ohun kọ̀ọ̀kan tí a kọ wo láti mọ̀ bí ìnáwó náà bá yẹ fún ìgbádùn tí ó mú wá

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

Ṣọ́ra fún àwọn èlé orí káàdì ìrajà àwìn!

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 9]

ÌLAPA ÌNÁWÓ ÀTI ÌDÍYELÉ OṢOOṢÙ Oṣù

ÀWỌN ÌNÁWÓ Ìnáwó Gidi Ó Ha Pọn Dandan? Iye Tí A Wéwèé

Oúnjẹ:

Awóróbo

Jíjẹun nílé àrójẹ

Aájò àlejò

Ilé:

Ìfidúkìá-dúró tàbí ìháyà

Ìpèsè ohun èèlò

Aṣọ

Owó ìwọkọ̀

Àwọn ẹ̀bùn

●

●

●

Owó àfipamọ́

Owó orí

Ìbánigbófò

Ọ̀kan-ò-jọ̀kan

ÀRÒPỌ̀ (fi wé owó tí ń wọlé)

OWÓ TÍ Ń WỌLÉ LÓṢOOṢÙ

Owó oṣù

Ohun ìní tí a háyà (bí ó bá wà)

Èlé orí owó àfipamọ́

ÀRÒPỌ̀ (fi wé ìnáwó)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó gbámúṣé nínú ìdílé ṣe pàtàkì nínú mímú kí ìwéwèé ìnáwó gbéṣẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́