Àwọn Káàdì Ìrajà Àwìn—Wọn Óò Ṣiṣẹ́ fún Ọ Ni Tàbí Wọn Óò Mú Ọ Lẹ́rú?
OLÙKỌ́ kan tí ń kọ́ni ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní United States sọ pé: “Tí mo bá ṣí àkọsílẹ̀ ìṣirò owó káàdì ìrajà àwìn mi wò lóṣooṣù, ń ṣe ló máa ń dà bí ọ̀rọ̀ burúkú tòun-tẹ̀rín. Mo máa ń wo iye tí ó ṣẹ́ kù tìyanutìyanu, bíi pé ẹlòmíràn tí ó jẹ́ ẹ̀dàyà mi, tí ó ti yíra rẹ̀ padà, ló ti lọ náwó nínàákúnàá ní àwọn ibi ìtajà ohun ìṣeré ọmọdé, àwọn ibi ìtajà ìhùmọ̀ abánáṣiṣẹ́, àwọn ilé ìtajà ńlá àti ní àwọn ilé epo.”
Dolores pẹ̀lú ń jẹ gbèsè lọ ràì pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Ó sọ pé: “Lílo káàdì ìrajà àwìn kò ní ìdààmú nínú. N kò jẹ́ ná owó gidi bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n rírajà pẹ̀lú káàdì ìrajà àwìn yàtọ̀. O kò lè rí owó tí o ń ná náà. Gbogbo ohun tí o máa ṣe ni pé kí o fún wọn ní káàdì rẹ, wọn óò sì dá káàdì náà padà fún ọ.”
Kò yani lẹ́nu pé àpapọ̀ gbèsè tí àwọn ènìyàn jẹ lórí káàdì ìrajà àwìn ní United States ní June 1995 jẹ́ bílíọ̀nù 195.2 dọ́là—ìpíndọ́gba iye tí ó lé ní 1,000 dọ́là fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó ní káàdì! Síbẹ̀, àwọn ilé iṣẹ́ káàdì ìrajà àwìn ń bá a lọ láti fọ̀rọ̀ dídùn fa ojú àwọn oníbàárà tuntun mọ́ra pẹ̀lú àwọn ohun ìṣírí bí èlé kékeré fún ìgbàwọlé àti àìsanwó ọlọ́dọọdún. Fífọ̀rọ̀ aájò fani mọ́ra nípa káàdì ìrajà àwìn mélòó ni o ti rí gbà ní àwọn oṣù àìpẹ́ yìí? Agboolé alábọ́ọ́dé kan ní United States ń gba nǹkan bíi 24 lọ́dọọdún! Ẹnì kan, bí àpẹẹrẹ àwọn tí wọ́n ní káàdì náà ní United States, lo káàdì ìrajà àwìn mẹ́wàá ní 1994 láti ra ọjà àwìn tí ó fi ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju èyí tí ó rà ní ọdún tí ó ṣáájú.
Ní Japan, káàdì ìrajà àwìn pọ̀ ju tẹlifóònù lọ; wọ́n ní ìpíndọ́gba káàdì méjì fún ará Japan kọ̀ọ̀kan tí ó ti lé ní ẹni 20 ọdún. Ní àwọn ibi yòó kù ní Éṣíà, wọ́n tẹ àwọn káàdì ìrajà àwìn tí ó lé ní 120 mílíọ̀nù jáde, nǹkan bí 1 fún ẹni 12 tí ń gbé ilẹ̀ náà. James Cassin, tí ń ṣiṣẹ́ ní MasterCard International, sọ pé: “Éṣíà ni agbègbè tí òwò káàdì ìrajà àwìn ti ń yára pọ̀ sí i jù lọ.” Ààrẹ ilé iṣẹ́ Visa International, Edmund P. Jensen, sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A óò jẹ́ àwùjọ tí ó ní ọ̀pọ̀ ibùdó káàdì fún ìgbà pípẹ́.”
Àwọn káàdì ìrajà àwìn yóò máa nípa lórí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn nìṣó lọ́nà gígadabú. Bí a bá lò wọ́n dáradára, wọ́n lè jẹ́ búrùjí. Síbẹ̀síbẹ̀, àṣìlò rẹ̀ lè fìyà jẹni gan-an. Níní ìmọ̀ tí ó ṣe kókó nípa káàdì ìrajà àwìn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lo ìhùmọ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ìnáwó yìí lọ́nà tí yóò ṣàǹfààní fún ọ.
Oríṣi Àwọn Káàdì
Àwọn káàdì tí a buyì fún jù lọ ni àwọn káàdì báńkì bíi Visa àti MasterCard. Àwọn ilé iṣẹ́ abójútó ọ̀ràn ìnáwó ní ń ṣe àwọn káàdì yìí jáde, wọ́n sì ń ní owó sísan ọlọ́dọọdún nínú, tí ó jẹ́ láti orí dọ́là 15 sí dọ́là 25 lọ́dún. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń yí owó náà padà, látàrí bóyá oníbàárà ní àkọsílẹ̀ rere ní ti bí ó ṣe ń san àwọn owó rẹ̀ àti bí ó ṣe ń lo káàdì náà. Ó lè máa san owó tán lóṣooṣù, lápapọ̀ láìsí èlé, tàbí kí ó máa san owó náà díẹ̀díẹ̀ lóṣooṣù, èyí sì gbé èlé gíga lórí. Wọ́n máa ń tọ́ka sí bí ó ṣe lè náwó mọ látàrí irú àkọsílẹ̀ tí oníbàárà náà ní. Wọ́n sábà máa ń mú ààlà náà ga sí i bí a bá ṣe fi ìtóótun láti san án hàn tó.
Àwọn káàdì báńkì tún ní ìṣètò fún dídáàbò bo ànáálẹ̀ owó nípa lílo àwọn ẹ̀rọ ìsanwó-gbowó adáṣiṣẹ́ tàbí ìwé sọ̀wédowó tí báńkì náà ṣe jáde. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gbígba owó lọ́nà yìí gbówólórí. Wọ́n sábà máa ń kọ láti dọ́là 2 sí dọ́là 5 lórí 100 dọ́là tí a bá yá ní gbogbogbòò. Èlé orí irú ànáálẹ̀ owó bẹ́ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́ jọ láti ọjọ́ tí a bá ti gba owó.
Yàtọ̀ sí àwọn báńkì, ọ̀pọ̀ ibi ìtajà àti ìsokọ́ra ibi ìtajà orílẹ̀-èdè ní ń ṣe káàdì ìrajà àwìn tí a tẹ́wọ́ gbà ní àwọn ilé iṣẹ́ wọn jáde. Kì í sábà sí owó sísan ọlọ́dọọdún ní ti irú àwọn káàdì bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a kò bá san iye tí ó tọ́ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, èlé náà lè ga ju èyí tí ó wà lórí káàdì báńkì lọ.
Àwọn ilé iṣẹ́ elépo pẹ̀lú ń ṣe káàdì ìrajà àwìn tí kì í ṣe olówó sísan lọ́dọọdún jáde. Ní gbogbogbòò, àwọn káàdì wọ̀nyí ṣètẹ́wọ́gbà ní ilé epo ti àwọn ilé iṣẹ́ náà nìkan àti ní àwọn hòtẹ́ẹ̀lì kan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bí àwọn káàdì tí àwọn ibi ìtajà ṣe jáde, wọ́n gbà kí a san wọ́n lódindi láìsí èlé tàbí kí a máa san wọ́n díẹ̀díẹ̀ pẹ̀lú èlé.
Àwọn káàdì ìrìn àjò òun eré ìnàjú wà pẹ̀lú, bíi Diners Club àti American Express. Irú àwọn káàdì wọ̀nyí jẹ́ ti olówó sísan lọ́dọọdún ṣùgbọ́n wọn kì í béèrè èlé, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé bí ẹnì kan ṣe ń gba àkọsílẹ̀ iye owó rẹ̀ lóṣooṣù ni ó yẹ kí ó san gbogbo owó náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn káàdì wọ̀nyí àti káàdì báńkì kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere. Fún àpẹẹrẹ, American Express pẹ̀lú ń pèsè káàdì Optima, tí ó ní èlé, ó sì rí bákan náà pẹ̀lú káàdì báńkì.
Irú káàdì míràn tí ń wọ ọjà United States ní káàdì jíjáfáfá, tí a ń pè bẹ́ẹ̀ nítorí ipa ìkójọ ìsọfúnni tí ó wà nínú rẹ̀. A lè lò ó bíi káàdì ẹ̀yáwó, níwọ̀n bí a ti lè ṣètò ìkójọ ìsọfúnni fún iye owó kan pàtó sínú rẹ̀ fún ẹni tí ń lò ó. Òǹtajà kan tí ọ̀ràn kàn lè yọ iye owó ohun tí a bá rà nínú èyí. Títí di èṣí, àwọn ará Faransé ti ń lo mílíọ̀nù 23 káàdì jíjáfáfá, àwọn ará Japan sì ń lo mílíọ̀nù 11. Wọ́n ti sàsọtẹ́lẹ̀ pé iye irú àwọn káàdì bẹ́ẹ̀ jákèjádò ayé yóò pọ̀ gan-an tó iye tí ó lé ní bílíọ̀nù kan tí ó bá fi máa di ọdún 2000.
Kí ẹnì kan tó gba káàdì kan, yóò jẹ́ ìwà ọlọ́gbọ́n fún un láti fiyè sí àwọn ipò àfilélẹ̀ inú káàdì náà. Ìwé pẹlẹbẹ kan, tí Ètò Àbójútó Ìṣúra Ìjọba Àpapọ̀ United States kọ, sọ pé: “Àwọn ipò àfilélẹ̀ ṣíṣe kókó nípa ìrajà àwìn tí a ní láti gbé yẹ̀ wò” ni “iye ọjà àwìn lórí ọgọ́rùn-ún lọ́dọọdún (APR), owó sísan lọ́dọọdún, àti àkókò ìsanwó láìsí ìdáwóléni.” Àwọn kókó abájọ mìíràn tí a tún ní láti gbé yẹ̀ wò ni iye ànáálẹ̀ owó àti owó tí a ń san fún nínáwó kọjá ààlà àti ìdáwóléni fún pípẹ́ láti sanwó.
Àwọn Ìdáwóléni—Báwo Ni Wọ́n Ṣe Pọ̀ Tó?
Àwọn ìdáwóléni tí àwọn ènìyàn wà lábẹ́ rẹ̀ nígbà tí wọn kò bá san àjẹṣẹ́yìn owó wọn olóṣooṣù tán lè pọ̀ ju bí ọ̀pọ̀ jù lọ ṣe ronú. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa APR, tí ó jẹ́ iye tí ọjà àwìn jẹ́ ní gidi. A lè ṣàpèjúwe ìbátan tí ó wà láàárín èlé ọlọ́dọọdún pẹ̀lú APR lọ́nà yìí. Kí a sọ pé o yá ọ̀rẹ́ kan ní 100 dọ́là, ó sì ń san dọ́là 108 padà fún ọ lópin ọdún náà. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ ń san èlé ìpín 8 nínú ọgọ́rùn-ún fún ọ lọ́dún. Síbẹ̀, kí a sọ pé ó ń san 100 dọ́là tí ó yá yẹn padà díẹ̀díẹ̀ ní dọ́là 9 lóṣooṣù fún oṣù 12. Àròpọ̀ iye rẹ̀ lópin ọdún náà yóò ṣì jẹ́ dọ́là 108, ṣùgbọ́n ìwọ, ayánilówó, ń rí owó náà lò bí ó ti ń san án lóṣooṣù. A ṣírò APR lórí irú ẹ̀yáwó bẹ́ẹ̀ sí ìpín 14.5 nínú ọgọ́rùn-ún!
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí Ètò Àbójútó Ìṣúra Ìjọba Àpapọ̀ United States ṣe ní èṣí ṣe rí i, APR tí ó wà lórí iye ọjà àwìn lórí káàdì ìrajà àwìn bẹ̀rẹ̀ láti orí ìpín 9.94 nínú ọgọ́rùn-ún, ó sì lọ sókè sí ìpín 19.80 nínú ọgọ́rùn-ún, pẹ̀lú ohun tí ó sábà máa ń wà láàárín ìpín 17 sí ìpín 19 nínú ọgọ́rùn-ún ní gbogbogbòò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilé iṣẹ́ abójútó ọ̀ràn ìnáwó kan máa ń pèsè ìwọ̀n owó ìgbàwọlé tí ó túbọ̀ kéré, tí ó sábà máa ń jẹ́ ìpín 5.9 nínú ọgọ́rùn-ún ní gbogbogbòò, wọ́n lè pọ̀ sí i ní gbàrà tí sáà ìgbàwọlé náà bá ti kọjá. Wọ́n tún máa ń fi kún ìwọ̀n náà bí àwọn tí ń ṣe káàdì náà jáde bá ríi pé ewu ń pọ̀. Àwọn kan tí ń ṣe káàdì jáde ń fìyà jẹ àwọn tí ń pẹ́ sanwó nípa fífi kún èlé wọn. Wọ́n tún máa ń fìyà jẹni fún ríré kọjá ààlà ìnáwó.
Ní àwọn orílẹ̀-èdè Éṣíà, ìwọ̀n ìpín ọgọ́rùn-ún ọlọ́dọọdún lórí àwọn káàdì lè ga gan-an. Fún àpẹẹrẹ, àwọn káàdì báńkì kan ń dá ìpín 24 nínú ọgọ́rùn-ún léni ní Hong Kong, ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún ní Íńdíà, ìpín 36 nínú ọgọ́rùn-ún ní Indonesia, ìpín 45 nínú ọgọ́rùn-ún ní Philippines, ìpín 24 nínú ọgọ́rùn-ún ní Singapore, àti ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún ní Taiwan.
Ní kedere, àwọn káàdì ìrajà àwìn ń jẹ́ kí a lè rajà àwìn lọ́nà rírọrùn ṣùgbọ́n ó wọ́n gan-an. Wíwọ inú ibi ìtajà kan, kí ó sì máa gba ìdáwóléni káàdì ìrajà àwìn tí o jẹ́ pé o lè san án kìkì ní díẹ̀díẹ̀ dà bíi wíwọ inú báńkì kan lọ, kí o sì lọ yá owó ní ìwọ̀n èlé tí ó ga gan-an. Síbẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ohun tí ẹni 3 lára ẹni 4 tó ní káàdì lọ́wọ́ ní United States ń ṣe gan-an nìyẹn! Wọ́n ní àkọsílẹ̀ ìṣirò owó tí wọn kò san tí wọn óò san èléwó gíga lórí rẹ̀. Ní United States, ìpíndọ́gba àròpọ̀ oṣooṣù lórí Visa àti MasterCard ní ọdún tó kọjá jẹ́ dọ́là 1,825, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọ́n sì jẹ gbèsè iye yẹn lórí àwọn káàdì ìrajà àwìn mélòó kan.
Ìdẹkùn Kan Tí Ó Lè Mú Ọ Lẹ́rú
Ruth Susswein, olùdarí àgbà Àwọn Tí Wọ́n Ní Káàdì Báńkì Lọ́wọ́ ní America, sọ pé àwọn tí ń lo káàdì kò mọ ìṣòro ọ̀ràn ìnáwó tí àwọ́n lè kó sí. Ó tọ́ka pé ẹnì kan tí ń lo káàdì tí ń san iye tí ó kéré jù lọ—dọ́là 36 lóṣù—lórí káàdì ìrajà àwìn tí àròpọ̀ rẹ̀ jẹ́ dọ́là 1,825 yóò lò lé ní ọdún 22 láti san gbèsè rẹ̀ tán.a Nítorí àwọn àfikún èlé tí a óò san, lákòókò yẹn, oníbàárà náà yóò san nǹkan bí 10,000 dọ́là fún gbèsè dọ́là 1,825 náà! Ìyẹn sì jẹ́ bí kò bá tí ì ra ohunkóhun lórí káàdì yìí! Nítorí náà, bí o bá ní ìtẹ̀sí láti náwó kọjá ààlà, káàdì ìrajà àwìn tí ó wà nínú àpò rẹ lè di ìdẹkùn kan.
Báwo ni a ṣe ń dẹkùn mú àwọn ènìyàn? Robert, tí a mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí a fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀wọ́ yìí, sọ pé: “A ra àwọn nǹkan tí a kò nílò. A dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eléré ìmárale kan tí a kò lọ rí. A ra ilé alágbèérìn kan, a sì ná ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là lórí àtúnṣe rẹ̀ láìronú nípa bóyá ó tóyeyẹ. A kò ronú rí ní gidi nípa àbájáde àwọn gbèsè wa.”
Reena, tí a sọ̀rọ̀ òun pẹ̀lú nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, ṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí òun àti ọkọ rẹ̀, Michael, pé: “A kàn kó sínú gbèsè ni. Lẹ́yìn tí a ṣègbéyàwó, a ń fi àwọn káàdì ìrajà àwìn ra gbogbo nǹkan tí a nílò. Fún àwọn owó tí a san fún ètò ìbánigbófò ìtọ́jú ìṣègùn àti àwọn ohun tí a rà tí a kò lè lo káàdì náà fún, a ṣàmúlò ìṣètò ànáálẹ̀ owó lórí àwọn káàdì ìrajà àwìn wa. Láàárín ọdún kan, gbèsè wa ti di 14,000 dọ́là. Mímọ̀ tí a mọ̀ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára owó tí a ń san lórí káàdì ìrajà àwìn wa ń tán sórí èlé nìkan ló là wá lójú.”
Ṣé Ó Yẹ Kí O Ní Àwọn Káàdì?
Lẹ́yìn ṣíṣàgbéyẹ̀wò ipò ìṣòro ọ̀ràn ìnáwó tí káàdì ìrajà àwìn ti ri àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn sí, àwọn kan lè sọ pé rárá. Daphne, ẹni ọdún 32, sọ pé: “Àwọn òbí mi kò ní káàdì ìrajà àwìn rí, wọn kò sì fẹ́ láti ní in.” Dájúdájú, ẹnì 1 nínú àwọn ẹni 4 tí wọ́n ní káàdì ní United States ní ń fọgbọ́n lo káàdì rẹ̀. Ó ń jàǹfààní rẹ̀ láìjẹ̀rora sísan èlé ìdáwóléni gọbọi. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Maria. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ràn ìrọ̀rùn ibẹ̀. N kò ní láti máa kó owó púpọ̀ kiri. Bí mo bá rí ohun tí mo nílò lórí àtẹ, mo lè rà á.”
Maria ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń rí i dájú pé mo ní owó tí ó tó láti san fún ohun tí mo rà. N kò ṣàmúlò ìṣètò ànáálẹ̀ owó rí. N kò sì san ìdáwóléni èyíkéyìí rí.” Ó rọrùn láti lo káàdì ìrajà àwìn kan nígbà tí a bá ń gba iyàrá hòtẹ́ẹ̀lì tí a fi dáni lójú, káàdì ìrajà àwìn sì pọn dandan ní United States nígbà tí o bá ń háyà ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn kan túbọ̀ máa ń ṣe nǹkan láìrò ó jinlẹ̀ tí ó bá kan ọ̀ràn ọjà rírà. Wọ́n lè sọ ọjà rírà di ìgbésẹ̀ tí ó túbọ̀ jẹni lọ́kàn nípa níná owó nìkan. Michael àti Reena kò fẹ́ láti sọ jíjẹ gbèsè di ọ̀nà ìgbésí ayé. Nítorí náà, wọ́n pinnu láti má ṣe lo káàdì kankan fún ọdún márùn-ún—àyàfi nínú ọ̀ràn pàjáwìrì.
Yíyàn láti lo àwọn káàdì ìrajà àwìn jẹ́ ìpinnu ara ẹni. Ṣùgbọ́n bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, lò wọ́n tìṣọ́ratìṣọ́ra. Lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun èèlò fún ìrọ̀rùn. Bí o bá sì ti lè ṣe tó, yẹra fún jíjẹ gbèsè jọ. Fífi lílo káàdì ìrajà àwìn sábẹ́ àkóso jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì nínú bíbójú tó ọ̀ràn ìnáwó rẹ pẹ̀lú àṣeyọrí. Gbé àwọn ohun mìíràn tí o lè ṣe yẹ̀ wò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Iye tí ó kéré jù lọ tí a san lè jẹ́ dọ́là 10 tàbí iye owó tí ó dọ́gba pẹ̀lú ìpín kékeré kan nínú ọgọ́rùn-ún lára àṣẹ́kù tuntun náà, èyíkéyìí tí ó bá pọ̀ jù.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Lílo káàdì ìrajà àwìn kò ní ìdààmú nínú—títí di ìgbà tí àkọsílẹ̀ owó bá dé