ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb16 October ojú ìwé 8
  • Ṣé O Máa Ń Lo Káàdì Ìkànnì JW.ORG?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé O Máa Ń Lo Káàdì Ìkànnì JW.ORG?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Káàdì Ìrajà Àwìn—Wọn Óò Ṣiṣẹ́ fún Ọ Ni Tàbí Wọn Óò Mú Ọ Lẹ́rú?
    Jí!—1996
  • Máa Lo Abala Ìbẹ̀rẹ̀ Orí Ìkànnì JW.ORG Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àwọn Ìpèsè Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Yẹra fún Ẹ̀jẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
mwb16 October ojú ìwé 8

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Máa Ń Lo Káàdì Ìkànnì JW.ORG?

Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ẹnì kan ní káàdì ìkànnì jw.org

Iṣẹ́ ìwàásù ti wá di kánjúkánjú gan-an báyìí, torí pé ìpọ́njú ńlá ti sún mọ́lé. (Owe 24:11, 12, 20) Ká báa lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, a lè lo káàdì ìkànnì JW.ORG láti darí wọn sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí sí ìkànnì wa. Káàdì náà ní àmì ìlujá tó máa darí wọn sí fídíò kan tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? àti apá tó máa jẹ́ kí wọ́n lè béèrè ìsọfúnni púpọ̀ sí i tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìkànnì wa. Kì í yá àwọn kan lára láti gba àwọn ìwé wa, àmọ́ ó lè wù wọ́n láti lọ sí ìkànnì wa. O lè fún wọn ní káàdì náà. Àmọ́ ṣá o, má ṣe fi káàdì náà sílẹ̀ fún àwọn tí kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa.

Tó o bá fẹ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ nígbà tí o kò sí lóde ẹ̀rí, o lè sọ pé: “Mo ní ohun kan tí mo fẹ́ fún un yín. Káàdì yìí máa darí yín sí ìkànnì kan tó láwọn ìsọfúnni lóríṣiríṣi àtàwọn fídíò tó dá lórí onírúurú nǹkan.” (Jo 4:⁠7) Pélébé la ṣe káàdì náà, èyí sì máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti mú mélòó kan dání nígbà tó o bá ń jáde, kó o lè lò ó nígbàkigbà tí àyè rẹ̀ bá yọ.

FÚNNI NÍ KÁÀDÌ YÌÍ . . .

  • tó o bá ń wàásù láìjẹ́-bí-àṣà

  • tó o bá ń wàásù ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ajé

  • tẹ́nì kan bá tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ wa àmọ́ tí kò wù ú láti gbàwé

⁠

Àwòrán Bíbélì tó wà ní ṣíṣí sílẹ̀ wà lórí Káàdì ìkànnì jw.org
Ẹ̀yìn káàdì ìkànnì jw.org
Àwòrán Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ìdílé kan wà lórí káàdì ìkànnì jw.org
Ẹ̀yìn káàdì ìkànnì jw.org

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́