Àpótí Ìbéèrè
◼ Ta ló yẹ kó gba káàdì ìlẹ̀máyà táa ń lò nígbà ìpàdé àgbègbè?
Káàdì ìlẹ̀máyà táa ń lò nígbà ìpàdé àgbègbè lè jẹ́ ká dá àwọn ará mọ̀ dáadáa, ó sì máa ń polongo ìpàdé náà. Ṣùgbọ́n, káàdì yìí kì í ṣe fún irú-wá ògìrì-wá. Ṣe ni wọ́n ń fi ẹni tó lẹ̀ ẹ́ máyà hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní ìdúró rere nínú ìjọ kan ní pàtó, tó jẹ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Káàdì náà máa ń ní àlàfo fún orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti orúkọ ìjọ. Nítorí náà, ẹni náà ti gbọ́dọ̀ máa dara pọ̀ dáadáa mọ́ ìjọ tórúkọ rẹ̀ wà lára káàdì náà. Society máa ń kó àwọn káàdì yìí ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Yóò bá a mu ká fún àwọn akéde tí wọ́n ti ṣe batisí àti àwọn akéde tí kò tíì ṣe batisí ní káàdì kọ̀ọ̀kan. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ọmọdé àti àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n máa ń wá sí ìpàdé déédéé, tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú síhà kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lè gba ọ̀kan. Kò ní bá a mu pé ká fún ẹni táa ti yọ lẹ́gbẹ́ ní káàdì àpéjọpọ̀ táa ń lẹ̀ máyà.
Bí káàdì wọ̀nyí bá ti dé, kí àwọn alàgbà rí i pé ṣe la pín wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà wọ̀nyí.