Àwọn Ìpèsè Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Yẹra fún Ẹ̀jẹ̀
Kí àwọn akéde tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n ti kọ́kọ́ kọ ọ̀rọ̀ sínú káàdì Advance Medical Directive/Release tàbí Identity Card [Káàdì Ìdánimọ̀] tí kò ní déètì kankan lára tàbí tó ní déètì 3/99 lára, má wulẹ̀ kọ òmíràn lọ́dún yìí. Ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ December 29, kí akọ̀wé rí i pé káàdì tó pọ̀ tó wà lọ́wọ́ fún àwọn akéde tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi, àwọn ọmọ wọn àtàwọn tó nílò láti pààrọ̀ tiwọn. A ti kó àwọn káàdì wọ̀nyí ránṣẹ́ sí ìjọ. Bí ìjọ ò bá ní èyí tó pọ̀ tó lọ́wọ́, akọ̀wé lè béèrè lọ́wọ́ àwọn ìjọ tó wà nítòsí tàbí kó béèrè fún àwọn káàdì náà nígbà tí ìjọ bá tún ń kọ̀wé béèrè fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́.
Kí a rí i pé a fara balẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ sínú àwọn káàdì náà láti ilé àmọ́ kí a MÁ ṢE buwọ́ lù ú. Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tó ń bọ̀, kí a buwọ́ lu àwọn káàdì náà, kí àwọn ẹlẹ́rìí náà buwọ́ lù ú, kí a kọ déètì sí i, kí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ sì ṣèrànwọ́ bó bá pọn dandan. Kí àwọn tó ń buwọ́ lu káàdì náà gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí rí i pé ẹni tó ni káàdì náà buwọ́ lù ú níṣojú wọn.
Àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi lè ṣe káàdì àti fọ́ọ̀mù tiwọn, tí àwọn àtàwọn ọmọ wọn yóò máa lò, nípa títún àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú káàdì Advance Medical Directive/Release àti Identity Card kọ láti bá ipò wọn àti ìgbàgbọ́ wọn mu.