Ohun Tuntun Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Ta Kété sí Ẹ̀jẹ̀
Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti fọwọ́ sí ohun tuntun kan, ìyẹn ni pé kí a pa àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú fọ́ọ̀mù Durable Power of Attorney (DPA [Gbígbé Àṣẹ Ọ̀ràn Ìtọ́jú Ìṣègùn Lé Aṣojú Ẹni Lọ́wọ́]) àtàwọn kókó ọ̀rọ̀ inú káàdì Advance Medical Directive/Release pọ̀ sọ́nà kan láti di ìwé kan ṣoṣo tó bá òfin mu. Káàdì DPA ni a óò máa pe ìwé yìí.
Tó o bá ti kọ àwọn ohun tó yẹ sínú káàdì DPA lẹ́ẹ̀kan, títí gbére ni yóò máa báṣẹ́ lọ. Kódà, tó o bá lọ sórílẹ̀-èdè mìíràn, káàdì yìí á jẹ́ kí wọ́n mọ irú ìtọ́jú tó o fẹ́. Àmọ́ o, ó máa di dandan pé kó o gba káàdì DPA tuntun (1) bó o bá ní láti ṣe àyípadà èyíkéyìí sí káàdì DPA rẹ, bóyá o fẹ́ sọ irú ìtọ́jú mìíràn tó o fẹ́ kí àwọn oníṣègùn ṣe fún ọ, o fẹ́ yan àwọn aṣojú mìíràn lábẹ́ òfin tàbí pé o fẹ́ yí àdírẹ́sì tàbí nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ padà, tàbí (2) tí káàdì DPA rẹ bá sọ nù tàbí tí ohun kan bá bà á jẹ́.
Ó yẹ kó o gbàdúrà nípa àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe lórí káàdì DPA, kó o sì fara balẹ̀ kọ ohun tó yẹ sínú rẹ̀ ní ilé. Àmọ́ o, kó o tó buwọ́ lu káàdì yìí, ó ṣe pàtàkì pé kó o ṣe àwọn ohun tí òfin sọ. Bí àpẹẹrẹ, bó bá wà nínú káàdì rẹ pé ẹlẹ́rìí méjì gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú rẹ nígbà tó ò ń buwọ́ lù ú, wọ́n ní láti rí ọ nígbà tó o bá ń buwọ́ lù ú. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè máa béèrè nípa káàdì DPA tuntun yìí lọ́wọ́ àwọn tí kò tíì kọ nǹkan sínú tiwọn, láti mọ̀ bóyá wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.
Kó o tó ká káàdì DPA rẹ, rí i pé o lọ fi ẹ̀rọ tó ń ṣe ẹ̀dà ìwé ṣe àwọn ẹ̀dà káàdì yìí tó máa hàn ketekete, kó o sì fún aṣojú rẹ lórí ọ̀ràn ìlera, ẹlòmíràn tó tún lè ṣojú rẹ tóun ò bá sí nítòsí àti dókítà rẹ; bákan náà, ṣe àwọn ẹ̀dà tí wàá tọ́jú síbi tó ò ń fi àwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì sí. O tún lè ṣe ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan fún àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé kan náà àti ọ̀kan fún akọ̀wé ìjọ yín. Bébà tó máa lè gba káàdì DPA ni kó o lò. Má ṣe ṣe ẹ̀dà káàdì yìí ní ojú àti ẹ̀yìn, ojú ewé kọ̀ọ̀kan ni kó o ṣe ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan káàdì DPA sí, kó o sì jẹ́ kó bọ́ sáàárín láìgé ọ̀rọ̀ kankan sọnù. Káàdì DPA gan-an ni kó o máa mú kiri, kì í ṣe ẹ̀dà tó o ṣe.
Ìyípadà kò tíì dé bá káàdì Identity Card [Káàdì Ìdánimọ̀] tí a kọ 3/99 sí lára, èyí tá a ṣe fún àwọn ọmọ tí kò tíì ṣèrìbọmi tí àwọn òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Kí àwọn òbí rí i dájú pé àwọn kọ ohun tó yẹ sínú káàdì ọmọ wọn kọ̀ọ̀kan bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, àwọn sì buwọ́ lù ú. Bákan náà, kí wọ́n rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ń mú u dání ní gbogbo ìgbà tó bá ti yẹ.
Àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi lè tún àwọn ohun tó wà nínú káàdì DPA àti káàdì Identity Card kọ, láti mú un bá irú ìtọ́jú tí wọ́n ń fẹ́ fún àwọn àtàwọn ọmọ wọn mu. Kí akọ̀wé ìjọ fún gbogbo àwọn akéde tó bá ṣèrìbọmi láàárín ọdún ní káàdì DPA.