ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 September ojú ìwé 16
  • Máa Lo Abala Ìbẹ̀rẹ̀ Orí Ìkànnì JW.ORG Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Lo Abala Ìbẹ̀rẹ̀ Orí Ìkànnì JW.ORG Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Lo Ìkànnì Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Kí Lèrò Rẹ?
    Jí!—2019
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • “Èyí Mà Rọrùn Gan-an O!”
    Jí!—2016
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 September ojú ìwé 16
Àwòrán àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lónírúurú èdè ní abala ìbẹ̀rẹ̀ orí jw.org.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Lo Abala Ìbẹ̀rẹ̀ Orí Ìkànnì JW.ORG Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

Ní abala ìbẹ̀rẹ̀ tó wà lórí ìkànnì jw.org, wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn fídíò tá a dìídì ṣe láti fa àwọn olóòótọ́ ọkàn mọ́ra. (Iṣe 13:48) Ó sábà máa ń dá lórí àwọn ohun tó ń jáde nínú ìròyìn tàbí ohun tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn lákòókò wa yìí.

Báwo lo ṣe lè lo abala yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

  • Máa wo ohun tó wà lórí ìkànnì yìí déédéé. Máa kíyè sí àwọn ohun tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé sórí ìkànnì, kó o sì máa ronú lórí àwọn tó o lè fi ràn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Láti rí àwọn ohun míì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé síbẹ̀, tẹ ìlujá tá a pè ní “Wo Àwọn Míì.”) Tó o bá ń lọ sórí ìkànnì yìí déédéé, wàá túbọ̀ rí àwọn ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

  • Máa lo àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn fídíò tó wà ní abala ìbẹ̀rẹ̀ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Àwọn ohun tó wà lórí ìkànnì yìí lè jẹ́ káwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.

  • Máa fi abala náà han àwọn èèyàn. Ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀, kó o sì kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè wá àwọn ìsọfúnni lórí ẹ̀.

  • Fi ìlujá ránṣẹ́. Àwọn kan kì í fẹ́ bá wa sọ̀rọ̀ lójúkojú, àmọ́ wọ́n máa ń gbà láti lọ sorí ìkànnì wa. Torí náà, fi ìlujá tó máa gbé wọn lọ sí abala ìbẹ̀rẹ̀ tàbí èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n lè rí àpilẹ̀kọ tàbí fídíò tó wà ìkànnì náà ránṣẹ́ sí wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́