Ìwé Ìrajà Àwìn Àti Sọ̀wédowó—Ayédèrú Tàbí Ojúlówó?
WỌ́N mà kúkú rọrùn o! Wọ́n kéré, wọ́n sì rọrùn láti mú kiri. Ṣọ́kí ni wọ́n má ń wọnú àpamọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tàbí ti àwọn obìnrin. Láìsí kọ́bọ̀ kan lápò rẹ, o lè ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan. Àwọn ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú, ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi, àwọn hòtẹ́ẹ̀lì, àti àwọn ilé àrójẹ káàkiri àgbáyé ń fún àwọn ènìyàn ní ìṣírí láti ní ìwé ìrajà àwìn, wọ́n sì ń polówó rẹ̀. Wọ́n ń rọ àwọn ènìyàn pé: “Má ṣe jáde nílé láìmú un lọ́wọ́.” Àwọn ilé iṣẹ́ kan wà tí wọn kì í gba owó gidi lọ́wọ́ ènìyàn, àyàfi ìwé ìrajà àwìn. Kò dà bí owó gidi, bí olè bá jí i tàbí tí ó bá sọnù, ènìyàn lè rí òmíràn gbà. Owó tìrẹ nìkan ló jẹ́, pẹ̀lú orúkọ àti nọ́ḿbà ìwé owó tí ó jẹ́ ti ìwọ nìkan tí a tẹ̀ gbọọrọ síwájú rẹ̀.
Ohun tí ẹ̀yin ènìyàn mọ̀ ọ́n sí ni owó oníke—ìwé ìrajà àwìn àti ìwé owó ọjà. Ní ọdún 1985, àwọn ilé ìfowópamọ́ kan gbé àwọn bátànì tí a máa ń ṣe sára fíìmù fọ́tò, tí ó lágbára, tí wọ́n ń fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ṣe, tí ó dà bí alápá mẹ́ta, jáde, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀nà ààbò míràn, tí ó bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn nọ́ḿbà àrà ọ̀tọ̀ kan lórí ìlà tẹ́ẹ́rẹ́ ẹlẹ́mọ̀ọ́ tí ó ṣe gbọọrọ lẹ́yìn rẹ̀, dé orí ìlà tí ojú lásán kò lè rí tí ó máa ń hàn nínú iná onítànṣán gíga. Gbogbo èyí jẹ́ láti dènà ṣíṣe ayédèrú rẹ̀! Wọ́n ṣírò rẹ̀ pé ohun tí ó lé ní 600 mílíọ̀nù àwọn ìwé ìrajà àwìn ní ń lọ láti ọwọ́ sí ọwọ́ káàkiri àgbáyé.
Wọ́n ronú pé iye tí wọ́n pàdánù káàkiri àgbáyé nítorí onírúurú àwọn ìwé ìrajà àwìn tí à ń ṣe arúmọjẹ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990 jẹ́, ó kéré tán, bílíọ̀nù kan dọ́là. Nínú gbogbo ìṣe arúmọjẹ náà, ṣíṣe ayédèrú rẹ̀ ni wọ́n ròyìn pé ó ń lọ sókè jù lọ—ó kéré tán, pẹ̀lú ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ìṣirò iye tí wọ́n pàdánù.
Fún àpẹẹrẹ, ní ọdún 1993, ṣíṣe ayédèrú nǹkan ná àwọn ilé ìfowópamọ́ tí ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ ìwé ìrajà àwìn tí ó tóbi jù lọ ní mílíọ̀nù 133.8 dọ́là, tí ó fi ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún kọjá ti ọdún tí ó ṣaájú. Ilé iṣẹ́ ìwé ìrajà àwìn gbígbajúmọ̀ míràn, tí ń ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, tún ròyìn pé àwọ́n pòfo rẹpẹtẹ nítorí ṣíṣe ayédèrú nǹkan. Ìwé agbéròyìnjáde New Zealand kan kọ ọ́ pé: “Èyí mú kí ṣíṣe ayédèrú ìwé ìrajà àwìn di ìṣòro ńlá kan, kì í ṣe kìkì fún àwọn ilé ìfowópamọ́, àwọn ilé iṣẹ́ ìwé ìrajà àwìn, àti àwọn oníṣòwò bàǹtàbanta, tí wọ́n máa ń gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí owó ọjà nìkan ni, ṣùgbọ́n fún àwọn òǹrajà káàkiri àgbáyé pẹ̀lú.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfò náà kì í ṣe ẹ̀bi àwọn tí wọ́n ni ìwé ìrajà àwìn, dídi ẹrù náà rù wọ́n kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.
Àwọn ọgbọ́n ààbò tí wọ́n ti ṣe mọ́ ọn lára tí ó dà bí ìdènà fún àwọn aṣayédèrú nǹkan ńkọ́—irú bí àwọn àmì tí a máa ń ṣe sára fíìmù fọ́tò àti àwọn ìlà ẹlẹ́mọ̀ọ́ tí ó ní nọ́ḿbà àrà ọ̀tọ̀? Kò pé ọdún kan lẹ́yìn tí wọ́n dá irú àwọn ọgbọ́n yìí sí i lára tán, tí àwọn tí ó jẹ́ arúmọjẹ jákujàku kan fi jáde. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ọgbọ́n ààbò ni wọ́n ṣẹ̀dà, tàbí tí wọ́n sọ di òtúbáńtẹ́. Òṣìṣẹ́ olóyè ilé ìfowópamọ́ Hong Kong kan sọ pé: “Àfi kí ènìyàn ṣáà máa tún àwọn ọgbọ́n ààbò ṣe sí i. Àwọn ẹlẹ́gírí máa ń gbìyànjú nígbà gbogbo láti gba ọ̀nà ẹ̀bùrú yọ sí àwọn ènìyàn.”
Ó ń pe àfiyèsí ẹni láti mọ̀ pé, ìdajì lára òfò tí wọ́n pa nítorí bí àwọn ènìyàn ti ń ṣe ayédèrú ìwé ìrajà àwìn ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990 ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Asia, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àwọn ògbógi sọ, ìdajì lára ìwọ̀nyí ni a sì tọpasẹ̀ dé Hong Kong. Ògbógi kan sọ pé: “Bí Paris ṣe jẹ́ sí àwọn nǹkan ìṣaralóge, bẹ́ẹ̀ ní Hong Kong ṣe jẹ́ sí ṣíṣe ayédèrú àwọn ìwé ìrajà àwìn.” Àwọn mìíràn tí fi ẹ̀sùn kan Hong Kong pé òun ni òléwájú ìlú tí ń ṣe ayédèrú àwọn ìwé ìrajà àwìn—“ọ̀nà ‘orita mẹ́ta’ tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ arúmọjẹ àwọn ìwé ìrajà àwìn, èyí tí ó ní Thailand, Malaysia àti, ní báyìí, gúúsù China, nínú.” Ìwé agbéròyìnjáde kan ní New Zealand sọ pé: “Àwọn ọlọ́pàá Hong Kong sọ pé àwọn ìgbìmọ̀ àdúgbò kan sọ pé àwọn ará China ní àwọn agbo ọ̀daràn abẹ́lẹ̀ tí ń tẹ àwọn ìwé ìrajà àwìn arúmọjẹ, tí ń kọ nǹkan sí i lára, tí wọ́n sì ń kọ nọ́ḿbà sí i, nípa lílo àwọn nọ́ḿbà tí àwọn òǹtajà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ń fún wọn. Ohun tí wọn yóò kàn ṣe ni kí wọ́n fi ayédèrú àwọn ìwé ìrajà àwìn náà ránṣẹ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ òkèèrè.”
Ìwé agbéròyìnjáde Globe & Mail ti Kánádà ròyìn pé: “Ẹ̀rọ tí ń tẹ ìwé ìrajà àwìn, tí àwọn onípàǹpá ilẹ̀ Asia rà [ní Kánádà] ni wọ́n ń lò nísinsìnyí láti ṣe àwọn ìwé ìrajà àwìn tí ó jẹ́ arúmọjẹ. Ẹ̀rọ náà ń tẹ 250 ìwé ìrajà àwìn ní wákàtí kan, àwọn ọlọ́pàá sì gbà gbọ́ pé wọ́n ti fi lu jìbìtì ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là.” Ní àwọn ọdún bíi mélòó kan tí ó kọjá, àwọn ará China tí ń gbé ní Hong Kong ni a ti fàṣẹ ọba mú nítorí lílo ayédèrú ìwé ìrajà àwìn, ó kéré tán, ní orílẹ̀-èdè 22 láti Austria títí dé Australia, títí kan Guam, Malaysia, àti Switzerland. Àwọn ìwé ìrajà àwìn ilẹ̀ Japan ni wọ́n tilẹ̀ ń fẹ́ jù, níwọ̀n bí wọ́n ti máa ń fún ẹni tí ń lò ó ní àǹfààní láti ra ọ̀pọ̀ nǹkan.
Òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ Kánádà kan sọ pé, ìlọsókè iṣẹ́ màdàrú àti ṣíṣe ayédèrú ìwé ìrajà àwìn ti “fi agbára mú àwọn tí ń fún àwọn ènìyàn ní ìwé ìrajà àwìn láti sọ pé àwọn tí ń lo ìwé ìrajà àwìn ni yóò máa pín iye tí ń ga sí i tí iṣẹ́ arúmọjẹ ń ná àwọn.” Bí a ti rí i nìyẹn. Òtítọ́ ni pé ìwé ìrajà àwìn lè jẹ́ ohun tí ó rọrùn, tí ó sì ń gba ẹ̀mí là nígbà tí ẹni tí ń lò ó kò bá ní owó gidi tí ó tó lọ́wọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, rántí pé gbogbo ohun tí aṣayédèrú nílò ni nọ́ḿbà ìṣètò owó rẹ, àti ọjọ́ tí ìwé rẹ̀ yóò parí iṣẹ́, tí wọ́n bá ti rí gbogbo èyí, iṣẹ́ ti yá. Ìjòyè òṣìṣẹ́ aláàbò kan fún ilé iṣẹ́ ìwé ìrajà àwìn American Express International kìlọ̀ pé: “Owó oníke ni, àmọ́ àwọn ènìyàn kì í tọ́jú rẹ̀ pẹ̀lú làákàyè tí wọ́n fi ń tọ́jú owó gidi.”
Ọ̀gá ọlọ́pàá kan sọ pé: “Àbùkù kún gbogbo inú ètò ìwé ìrajà àwìn bámúbámú. Gbogbo rẹ̀ ni àwọn erìkìnà sì ti rí.” Ó sì sọ nípa àwọn aṣayédèrú owó pé: “Ó gbèlé ò, gbogbo àbùkù náà ni wọ́n sì fi ṣèjẹ pẹ̀lú ìmójúkuku.”
Ṣíṣe Ayédèrú Sọ̀wédowó
Pẹ̀lú ìwọlédé ètò ìtẹ̀wé tí a lè ṣe fàlàlà lórí tábìlì, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí owó onípépà tí kò lè ṣẹ̀dà lọ́nà pípé, ohun tí yóò tẹ̀ lé e kò ní ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Ní báyìí, àwọn olùṣarúmọjẹ lè ṣẹ̀dà àìmọye ìwé àkọsílẹ̀: ìwé ìrìnnà, ìwé ọjọ́ ìbí, ìwé àṣẹ ìwọ̀lú, ìwé ẹ̀rí ìjólóhun, àwọn ìwé ìbéèrè ọjà, ìwé ìsọfúnni nípa oògùn, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn. Ṣùgbọ́n ibi tí èrè tí ó pọ̀ jù lọ yóò ti jáde wá ní ibi ṣíṣẹ̀dà sọ̀wédowó.
Ọ̀nà tí wọ́n ń lò kò le. Gbàrà tí sọ̀wédowó kan láti ilé iṣẹ́ ńlá kan pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là tí wọ́n lọ kó pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́ àdúgbò, tàbí ti ìpínlẹ̀, bá ti dé ọwọ́ aṣayédèrú kan, iṣẹ́ ti dé nìyẹn. Pẹ̀lú ẹ̀rọ ìtẹ̀wé rẹ̀ lórí tábìlì, ẹ̀rọ aṣẹ̀dà àwòrán oníná, àti àwọn ohun èèlò oníná mìíràn tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ̀, ó lè yí sọ̀wédowó náà padà láti bá ète rẹ̀ mu—kí ó yí déètì rẹ̀ padà, kí ó pa orúkọ ẹni tí ó ni ín rẹ́, kí ó sì fi tirẹ̀ sí i, kí ó kọ àwọn oódo kún iye dọ́là tí ó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ni yóò tẹ sọ̀wédowó tí ó ti yí padà náà pẹ̀lú ẹ̀rọ ìtẹ̀wé oníná rẹ̀, nípa lílo pépà tí ó rà ni ilé ìtaǹkan ìkọ̀wé tí ó wà nítòsí, èyí tí ó jẹ́ àwọ̀ kan náà pẹ̀lú ti sọ̀wédowó náà. Ó lè tẹ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ sọ̀wédowó ayédèrú, ó sì lè sọ wọ́n dowó ní èyíkéyìí lára àwọn ilé ìfowópamọ́ tí ó bá wà ní ìlú èyíkéyìí.
Ọ̀nà tí ṣíṣe ayédèrú sọ̀wédowó gbà ń lọ sókè pẹ̀lú ọgbọ́n tí kò ṣòro, tí kì í sì í náni lówó púpọ̀ yìí ga, débi tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ àti àwọn agbófinró fi sọ pé, òfò tí ọrọ̀ ajé ń pa nínú rẹ̀ tó bílíọ̀nù kan dọ́là. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn ọ̀ràn tí wọ́n ti lo ìgbójúgbóyà, tí agbo àwọn onípàǹpá kan tí ó fìdí kalẹ̀ sí Los Angeles ti lọ káàkiri orílẹ̀-èdè United States, tí wọ́n sì ń sọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún sọ̀wédowó arúmọjẹ dowó ní àwọn ilé ìfowópamọ́, èyí tí ìṣirò gbogbo rẹ̀ ju mílíọ̀nù méjì dọ́là lọ. Àwọn ògbógi nínú ọ̀ràn ilé iṣẹ́ ṣírò rẹ̀ pé àpapọ̀ iye òfò tí sọ̀wédowó arúmọjẹ ń fà lọ́dún jẹ́ bílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là ní United States nìkan báyìí. Òṣìṣẹ́ àjọ ìṣèwádìí FBI kan sọ pé: “Ògúnná gbòǹgbò ìṣòro ìwà ọ̀daràn fún àwọn ilé iṣẹ́ ètò owó ni àwọn ohun èèlò ayédèrú tí ó lè lọ láti ọwọ́ ẹnì kan sí òmíràn, irú bí arúmọjẹ sọ̀wédowó àti ìwé ẹ̀rí ìgbowó.”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
Èrè tí ó pọ̀ jù lọ ń wá láti inú ṣíṣẹ̀dà àwọn sọ̀wédowó