ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 3/22 ojú ìwé 8-10
  • Ẹ Fura O, Ẹ̀yin Òǹrajà! Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan Lè Gbẹ̀mí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Fura O, Ẹ̀yin Òǹrajà! Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan Lè Gbẹ̀mí
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣe Nǹkan Ayédèrú Tí Ó Lè Pa Ènìyàn
  • Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan—Ìṣòro Gbogbo Àgbáyé
    Jí!—1996
  • Ìwé Ìrajà Àwìn Àti Sọ̀wédowó—Ayédèrú Tàbí Ojúlówó?
    Jí!—1996
  • Ṣọ́ra! Ọwọ́ Àwọn Gbájú-Ẹ̀ Kò Dilẹ̀
    Jí!—1997
  • Bó o Ṣe Lè Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ọ̀ràn Ààbò
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 3/22 ojú ìwé 8-10

Ẹ Fura O, Ẹ̀yin Òǹrajà! Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan Lè Gbẹ̀mí

WỌ́N lè tan ẹni tí kò bá lóye, tí kò sì lákìíyèsí jẹ. Wo aago ọwọ́ tí ó dà bí èyí tí ó gbówó lórí tí òǹtajà ojú pópó yẹn fi lọ̀ ọ́ ní iye owó tí ó lọ sílẹ̀ gan-an—ṣé gidi ni tàbí bàrúùfù? Ìwọ yóò ha rà á bí? Wo aṣọ òtútù jíjojúnígbèsè tí wọ́n nà sí ọ láti inú fèrèsé ọkọ̀ lójú pópó yẹn—òǹtajà náà fọwọ́ sọ̀yà pé àgbà ló jẹ́. Ṣe fífà tí ó fà ọ́ mọ́ra àti owó rẹ̀ tí ó lọ sílẹ̀ yóò pa ọ́ lọ́kàn dà? Wo òrùka onídíámọ́ǹdì tí ó wà níka ìyàwó tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ yẹn—kò lówó lọ́wọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì rílé gbé mọ́ báyìí, ó ń dúró de ọkọ̀ rélùwéè ní ibùdókọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀ kan ní New York—òrùka náà lè jẹ́ tìrẹ fún owó táṣẹ́rẹ́. Ìwọ yóò ha rò pé ó ti ya ọ̀pọ̀ ju ohun tí o lè jẹ́ kí ó fò ọ́ ru bí? Nítorí pé nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ń sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe ayédèrú nǹkan yìí ni a ti béèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, àti nítorí àwọn ipò tí a sọ nípa rẹ̀, ó ṣeé ṣe kí o dáhùn pé “RÁRÁ!”

Ìyẹ́n mà dára o, àmọ́, jẹ́ kí a yí ibi tí nǹkan ti ṣẹlẹ̀ àti àwọn ipò tí ó yí i ká padà, kí a wá wo ohun tí ìdáhùn rẹ yóò jẹ́. Àpò àpamọ́wọ́ tí àwọn olùṣe ọjà lílókìkí ṣe, tí ó wọ́n gógó tí wọ́n ń tà ní ilé ìtajà ẹlẹ́dìn-ínwó ní owó pọ́ọ́kú ńkọ́? Ọtí líle kan tí ó gbajúmọ̀ tí wọ́n ń tà ní ilé ọtí kan tí ó wà ní pàlàpálá kan ńkọ́? Ó dájú pé èyí kò fa ìṣòro kankan. Tún ro fíìmù fọ́tò tí ó ní orúkọ tí gbogbo ènìyàn mọ̀ dunjú lára, tí wọ́n ń tà ní ilé oògùn tàbí ní ìsọ̀ kámẹ́rà. Lọ́tẹ̀ yìí, aago ọwọ́ gbígbówó lórí kan tí ó jẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là ni wọ́n nà sí ọ, kì í ṣe òǹtajà ojú pópó ló nà án sí ọ, ṣùgbọ́n láti ilé ìtajà kan tí ó gbajúmọ̀. Wọ́n ti dín owó rẹ̀ kù pátápátá. Bí ó bá jẹ́ pé nítorí irú aago ọwọ́ tí ó wọ́n gógó bẹ́ẹ̀ ló ṣe lọ sọ́jà, ìwọ yóò ha rà á bí? Lẹ́yìn ìyẹn lo rí i pé irú àwọn bàtà kan tí ó gbajúmọ̀ wà ní ìsọ̀ kan báyìí báyìí tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ júwe fún ọ ní owó pọ́ọ́kú. Ó ha dá ọ lójú pé wọn kì í ṣe ayédèrú lásánlàsàn?

Lágbo àwọn oníṣẹ́ ọnà, ní àwọn gbọ̀ngàn ìṣàṣehàn àwòrán yíyà, ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan ló wà láti tà fún àwọn tí wọ́n bá ń ṣàkójọ àwọn iṣẹ́ ọnà gbígbówó lórí, tí wọ́n bá lè san iye owó tí ó ga jù lọ. Ògbógi kan nínú iṣẹ́ ọnà kìlọ̀ pé: “Ṣọ́ra. Wọ́n ń tan àwọn ọ̀mọ̀ràn tí wọ́n ti ní ìrírí fún ọ̀pọ̀ ọdún jẹ. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sì ń tan àwọn oníṣòwò nǹkan ọnà jẹ pẹ̀lú. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń tan àwọn alábòójútó gbọ̀ngàn nǹkan ìṣẹ̀m̀báyé jẹ.” Ìwọ́ ha lóye iye tí ó tó bí, tí o fi lè jágbọ́n àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ aṣayédèrú nǹkan? Fura o! Gbogbo nǹkan tí a kà sókè yìí lè jẹ́ ayédèrú. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì máa ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. Rántí pé, bí ohun kan bá wọ́n lóde, tí ó sì níye lórí, ẹnì kan tí ó wà níbì kan yóò gbìyànjú láti ṣe ayédèrú rẹ̀.

Òwo ṣíṣe ayédèrú nǹkan jẹ́ okòwò tí ń mú 200 bílíọ̀nù dọ́là wọlé káàkiri àgbáyé, ó sì “ń lọ sókè fẹ̀rẹ̀fẹ̀rẹ̀ ju ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé iṣẹ́ tí ó ń jẹ lára wọn lọ,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Forbes ṣe kọ̀wé. Àwọn ayédèrú ohun èèlò ara ọkọ̀ ń ná àwọn tí ń ṣe ọkọ̀ ní America àti àwọn tí ń kó o tà ní bílíọ̀nù 12 dọ́là lọ́dún, níbi owó tí ń wọlé tí wọ́n ń pàdánù káàkiri àgbáyé. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ilé iṣẹ́ tí ń ṣe ọkọ̀ ní United States sọ pé àwọn yóò gba àwọn ènìyàn 210,000 míràn sí i bí àwọ́n bá lè rọ́nà bẹ́gi dínà àwọn tí ń ta ohun èèlò ara ọkọ̀ tí ó jẹ́ ayédèrú.” Wọ́n sọ pé nǹkan bí ìdajì lára àwọn ilé iṣẹ́ tí ń ṣe nǹkan ayédèrú ló wà ní ẹ̀yìn òde United States—ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ níbi gbogbo ni wọ́n wà.

Ṣíṣe Nǹkan Ayédèrú Tí Ó Lè Pa Ènìyàn

Àwọn nǹkan ayédèrú kan wà tí ó jẹ́ pé wọn kò léwu pẹ́ẹ̀pẹ́ẹ̀. Àwọn ìkànnì ìdeǹkan, bóòtù, àti àwọn ìṣó ìdeǹkan tí ó wá láti ilẹ̀ òkèèrè, ló para pọ̀ jẹ́ ìpín 87 nínú ọgọ́rùn-ún lára owó ọjà bílíọ̀nù mẹ́fà dọ́là tí United States ń rí. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ̀rí fi hàn títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ lónìí pé, ìpín 62 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo àwọn ohun èèlò ìdeǹkan wọ̀nyí ní àwọn orúkọ arúmọjẹ tàbí pépà ọjà tí kò bófin mu. Ìwé ìròyìn Forbes sọ pé, ìròyìn ọdún 1990 ti Ẹ̀ka Ìṣèṣirò Ìjọba Àpapọ̀ (GAO) ṣàwárí pé, ó kéré tán, 72 lára “àwọn ilé iṣẹ́ ohun ìjà ogun” America “ló ti lo àwọn ohun èèlò ìdeǹkan tí ó jẹ́ páńda, wọ́n ti lo àwọn kan sára àwọn ìṣètò ẹ̀rọ tí ó yẹ kí ó paná ẹ̀rọ atú-ohun-ìjà olóró jáde tí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àṣìṣe ohun ìjà olóró kan ṣẹlẹ̀. Ẹ̀ka GAO sọ pé ìṣòro náà ń burú sí i. . . . A kò mọ bí ìṣòro náà, iye tí ó ń ná àwọn tí ń san owó orí tàbí ewu tí ó lè tìdi lílo irú àwọn ohun èèlò [páńda] bẹ́ẹ̀ jáde ti tóbi tó.”

Àwọn bóòtù onírin, tí agbára wọn kò gbé àwọn nǹkan tí à ń lò wọ́n fún, jẹ́ àwọn tí a ṣe ayédèrú wọn, tí àwọn alárèékérekè oníṣòwò kàǹkàkàǹkà sì ṣe fàyàwọ́ wọn lọ sí United States. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn American Way ṣe sọ: “Wọ́n lè wu ààbò ọ́fíìsì, ilé iṣẹ́ iná, afárá àti àwọn ohun èèlò ológun léwu.”

Àwọn ayédèrú ìjánu ọkọ̀ ni a sọ pé ó fa jàm̀bá ọkọ̀ akérò kan tí ó gba ẹ̀mí àwọn ènìyàn 15 ní Kánádà ní ọdún bíi mélòó kan ṣẹ́yìn. Wọ́n ròyìn pé àwọn ohun èèlò ara ọkọ̀ tí ó jẹ́ páńda ni wọ́n ti rí ní àwọn ibi tí ó léwu bí ara ọkọ̀ òfuurufú àwọn ológun àti lára àwọn ọkọ̀ agbénilọgbénibọ̀ nínú òfuurufú United States. Gbajúgbajà kan tí ń ṣèwádìí lórí ọ̀ràn ṣíṣe ayédèrú nǹkan sọ pé: “Kì í jọ ọ̀pọ̀ lára àwọn òǹrajà lójú nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa aago Cartier tàbí Rolex tí ó jẹ́ arúmọjẹ, ṣùgbọ́n nígbà tí ìlera àti ààbò ènìyàn bá wà nínú ewu, ọ̀ràn náà máa ń mú wọn lára.”

Lára àwọn nǹkan tí ó lè di ayédèrú tí ó léwu ni àwọn ẹ̀rọ ọkàn àtọwọ́dá, tí à ń tà fún àwọn ilé ìwòsàn 266 ní United States; àwọn ayédèrú oògùn fètòsọ́mọbíbí, tí ó dórí igbá ní America ní ọdún 1984; àti àwọn oògùn apakòkòrò, tí ó jẹ́ pé kìkì ẹfun ni wọ́n jẹ́, èyí tí ó pa oko kọfí Kenya run ní ọdún 1979. Àwọn ayédèrú oògùn tí ó lè fi ẹ̀mí ènìyàn sínú ewu ṣáà ń pọ̀ sí i ni. Iye ènìyàn tí ń kú nítorí àwọn ayédèrú oògùn káàkiri àgbáyé kọ sísọ.

Àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i tilẹ̀ wá ń ṣàníyàn nípa àwọn ayédèrú ohun èèlò abánáṣiṣẹ́ kéékèèké, tí à ń lò nínú ilé. Ìwé ìròyìn American Way ròyìn pé: “Àwọn kan lára àwọn ohun èèlò yìí ní orúkọ tàbí ìfọwọ́sí ayédèrú, irú bíi ti Àjọ Afọwọ́sọ́jà.” Onímọ̀ nípa ẹ̀rọ nípa ààbò kan sọ pé: “Ṣùgbọ́n ìdíwọ̀n ààbò tí wọ́n ní kò tó èyí tí wọ́n nílò, nítorí náà, wọ́n máa ń bú gbàù, wọ́n máa ń mú kí ilé jó, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí gbogbo ohun èèlò tí ń báná ṣiṣẹ́ wà láìláàbò.”

Ní United States àti ní Europe, ojora ń mú agbo àwọn òṣìṣẹ́ nípa ìrìn àjò ọkọ̀ òfuurufú. Fún àpẹẹrẹ, ní Germany, àwọn ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ti rí ẹ́ńjìnnì àti àwọn ohun èèlò ìjánu ọkọ̀ tí ó jẹ́ páńda nínú àkọsílẹ̀ ẹrù wọn. Àwọn òṣìṣẹ́ ìrìnnà sọ pé ìwádìí “ni wọ́n ń ṣe ní Europe, Kánádà àti United Kingdom, níbi tí a ti sọ pé àwọn ohun èèlò ara ọkọ̀ (àwọn ìkànnì ìdeǹkan ibi ẹ̀rọ ayíbírí ìrù ọkọ̀) tí a kò fọwọ́ sí ló fa jàm̀bá ọkọ̀ òfuurufú hẹlikópítà kan tí ó la ikú lọ, láìpẹ́ yìí.” Ìwé ìròyìn Flight Safety Digest sọ pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ ti gbẹ́sẹ̀ lé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èròjà ẹ́ńjìnnì àti èròjà ìjánu ọkọ̀ òfuurufú tí ó jẹ́ páńda, àwọn ẹ̀ya bíréèkì tí a tò pọ̀, àwọn bóòtù àti ohun èèlò ìdeǹkan tí kò dára tó, èròjà epo àti èròjà fífò ọkọ̀ tí kò dára tó, àwọn ohun èèlò ibi tí awakọ̀ òfuurufú ń jókòó sí tí a kò fọwọ́ sí àti àwọn èròjà ìdarí ọkọ̀ tí kò dára fún ààbò ọkọ̀ òfuurufú.”

Ní ọdún 1989, ọkọ̀ òfuurufú kan tí wọ́n háyà, tí ń fò lọ sí Germany láti Norway kàn já ṣòòròṣò lọ sílẹ̀ lójijì láti òkè tí ó ti ń fò ní nǹkan bí 6,600 mítà sílẹ̀. Ìrù rẹ̀ fò lọ, èyí sì mú kí ọkọ̀ òfuurufú náà mórí lọ sílẹ̀ tagbáratagbára, tí ó fi jẹ́ pé apá rẹ̀ méjèèjì ló kán dànù. Gbogbo ọkàn 55 tó wà nínú ọkọ̀ náà ló kú. Lẹ́yìn ìwádìí ọdún mẹ́ta tí wọ́n ṣe, àwọn ògbógi nípa ìrìn àjò ọkọ̀ òfuurufú ti Norway ṣàwárí pé àwọn bóòtù kan tí à ń pè ní ìṣó aláfidè, tí ó lábùkù, tí ó so ìrù náà mọ ara ọkọ̀, ló fa jàm̀bá náà. Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe nípa ipá tí ọkọ̀ náà mú lọ sílẹ̀ fi hàn pé mẹ́táàlì tí kò rára gba agbára ìfòfẹ̀rẹ̀ ọkọ̀ náà sí, ni wọ́n fi ṣe àwọn bóòtù náà. Àwọn ìṣó aláfidè tí ó lábùkù náà jẹ́ ayédèrú—ọ̀rọ̀ kan tí gbogbo àwọn ògbógi nípa ààbò ìrìn àjò ọkọ̀ òfuurufú níbi gbogbo mọ̀ dunjúdunjú, nítorí pé ṣíṣe ayédèrú nǹkan ti di ìṣòro tí ń fi ìwàláàyè àwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ òfuurufú àti àwọn èrò sínú ewu.

Nígbà tí ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ti orílẹ̀-èdè fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀gá àgbà Ẹ̀ka Ìrìnnà ní United States lẹ́nu wò, ó sọ pé: “Gbogbo ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ló ti gba àwọn ohun èèlò ara ọkọ̀ tí ó jẹ́ páńda. Gbogbo wọn ló ní in. Gbogbo wọn ló ní ìṣòro.” Ó fi kún un pé ilé iṣẹ́ náà jẹ́wọ́ pé, “àwọ́n ní ohun tí àwọ́n fojú díwọ̀n sí pé ó ṣeé ṣe kí ó tó bílíọ̀nù méjì tàbí mẹ́ta dọ́là àpapọ̀ àwọn ohun èèlò tí kò ṣeé lò.”

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan náà, ògbógi kan nípa ààbò ìrìn àjò ọkọ̀ òfuurufú, tí ó gba ilé iṣẹ́ FBI nímọ̀ràn lórí oríṣiríṣi àwọn iṣẹ́ bòńkẹ́lẹ́ tí wọ́n ń ṣe lórí àwọn ohun èèlò ara ọkọ̀ tí ó jẹ́ páńda, kìlọ̀ pé ṣíṣe ayédèrú àwọn ohun èèlò ara ọkọ̀ jẹ́ ewu ní tòótọ́. Ó sọ pé: “Mo ronú pé à ń fojú sọ́nà fún ìjábá ọkọ̀ òfuurufú pípabambarì kan ní àkókò kan ní ọjọ́ ọ̀la, gẹ́gẹ́ bí àbájáde rẹ̀.”

Ọjọ́ ìjíhìn ti sún mọ́lé fún àwọn tí ìwọra wọn ti jẹ́ kí wọ́n fi ìfẹ́ ọkàn onímọtara-ẹni-nìkan wọn ṣíwájú ìwàláàyè àwọn ẹlòmíràn. Ọ̀rọ̀ onímìísí Ọlọrun sọ ní pàtó pé àwọn oníwọra ènìyàn kò ní jogún Ìjọba Ọlọrun.—1 Korinti 6:9, 10.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Aṣọ, ohun ọ̀ṣọ́, àwọn àwòrán, oògùn, àwọn ẹ̀ya ara ọkọ̀ òfuurufú—gbogbo ohun tí ó bá ṣáà ti níye lórí ni ẹ̀rọ àwọn aṣayédèrú máa ń ṣíná fún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn àtọwọ́dá èròjà ẹ́ńjìnnì, àwọn bóòtù, àwọn ohun èèlò ibi tí awakọ̀ òfuurufú ń jókòó sí, àwọn èròjà kọ̀m̀pútà, àti àwọn nǹkan ayédèrú mìíràn tí fa ìjálulẹ̀ ọkọ̀ òfuurufú tí ó sì gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́