ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 3/22 ojú ìwé 3-4
  • Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan—Ìṣòro Gbogbo Àgbáyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan—Ìṣòro Gbogbo Àgbáyé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan Di Ìrọ̀rùn
  • Ìwé Ìrajà Àwìn Àti Sọ̀wédowó—Ayédèrú Tàbí Ojúlówó?
    Jí!—1996
  • Ẹ Fura O, Ẹ̀yin Òǹrajà! Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan Lè Gbẹ̀mí
    Jí!—1996
  • Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Yúróòpù—Ṣe Nǹkan Pàtàkì Ni?
    Jí!—2000
Jí!—1996
g96 3/22 ojú ìwé 3-4

Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan—Ìṣòro Gbogbo Àgbáyé

Títí fi di òpin ọ̀rúndún kejìdínlógún, wọ́n máa ń se àwọn ènìyàn tí wọ́n bá ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ yẹn láàyè ní ilẹ̀ Faransé. Ìwà ọ̀daràn tí wọ́n máa ń pani nítorí rẹ̀ ni ó jẹ́ ní ilẹ̀ England láti ọdún 1697 sí 1832, wọ́n sì ka ìwà náà sí ẹ̀ṣẹ̀ dídojú ìjọba dé. Ó lé ní 300 ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n yẹgi fún nítorí rẹ̀, nígbà tí ó sì jẹ́ pé àìmọye ni wọ́n kó nígbèkùn lọ sí àwọn agbègbè ìfìyàjẹni ní Australia láti lọ ṣiṣẹ́ àṣekára gẹ́gẹ́ bí ìjìyà fún ohun tí wọ́n ṣe.

FÚN ohun tí ó ju 130 ọdún lọ, ìjọba United States ti ń fi imú àwọn tí wọ́n bá jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí dánrin fún ohun tí ó tó ọdún 15 nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n àpapọ̀. Síwájú sí i, ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là owó ìtanràn ni wọ́n ti fi kún ìjìyà náà. Àní lónìí pàápàá, wọ́n lè pa ènìyàn nítorí rẹ̀ ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti China.

Láìka bí ìjìyà tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè gbé kà á ti pọ̀ sí, ìwà ọ̀daràn náà ń bá a lọ. Àní ìbẹ̀rù ikú pàápàá kò tí ì tó láti paná ète dídolówó-òjijì ti àwọn wọnnì tí wọ́n bá ní òye iṣẹ́ ẹ̀rọ tí wọ́n nílò. Ẹ̀mí àwọn ìjòyè òṣìṣẹ́ ìjọba ti pin. Wọ́n sọ pé: “Ohun ìdíwọ́ tí ó gbéṣẹ́ yóò ṣòro láti rí, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣòró fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.”

Ṣíṣe ayédèrú nǹkan! Ọ̀kan nínú àwọn ìwà ọ̀daràn tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ nínú ìtàn. Ní apá ìparí ọ̀rúndún ogún yìí, ó ti di ìṣòro gbogbo àgbáyé, ó sì ń gogò sí i. Robert H. Jackson, olóyè adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ United States, sọ nípa rẹ̀ pé: “Ṣíṣe ayédèrú nǹkan kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn ń ṣèèṣì dá, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa àìmọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìmọ̀lára òjijì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nínú ipò òṣì paraku. Ó jẹ́ ìwà ọ̀daràn kan tí ẹnì kan tí ó ní òye iṣẹ́ ẹ̀rọ fi ọgbọ́n wéwèé, tí ó sì ná an ní owó tabua láti ra irin iṣẹ́ rẹ̀.”

Fún àpẹẹrẹ, àwọn ènìyàn ń ṣẹ̀dà owó America láìbófin mu káàkiri àgbáyé, wọ́n sì ń ṣe é lọ́pọ̀ yanturu ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Agbẹnusọ kan fún Ẹ̀ka Ìṣètò Owó sọ pé: “Kì í ṣe kìkì pé owó United States jẹ́ owó tí àwọn ènìyàn ń fẹ́ jù lọ lágbàáyé nìkan ni. Ó tún jẹ́ èyí tí àwọn ènìyàn tètè máa ń ṣe ayédèrú rẹ̀ jù lọ.” Ohun tí ó kó ìdààmú ọkàn bá àwọn ìjọba America ni pé ọ̀pọ̀ nínú owó páńda náà ni wọ́n ń ṣe lẹ́yìn òde United States.

Gbé èyí yẹ̀ wò: Ní 1992, ayédèrú owó dọ́là tí ó tó 30 mílíọ̀nù ni wọ́n fàṣẹ gbà ní àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ òkèèrè, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé ìròyìn Time sọ. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ní ọdún tí ó kọjá, àròpọ̀ gbogbo rẹ̀ dé 120 mílíọ̀nù dọ́là, a sì retí pé kí ó ré kọjá iye yẹn ní ọdún 1994. Ohun tí ó pọ̀ fíìfíì ju iye yẹn lọ ní ń lọ láti ọwọ́ kan sí òmíràn tí wọn kò sì rí i.” Díẹ̀ ni ìṣirò náà lè sọ nípa ọ̀ràn náà. Àwọn ọ̀mọ̀ràn nípa ṣíṣe ayédèrú nǹkan gbà gbọ́ pé, tí a bá ní kí a sọ ọ́ ní ti gidi, iye dọ́là bàrúùfù tí ń lọ láti ọwọ́ kan sí òmíràn lẹ́yìn òde United States lè pọ̀ tó bílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là.

Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní ń fẹ́ owó America—àní ju owó tiwọn lọ pàápàá—tí kò sì ṣòro púpọ̀ láti ṣẹ̀dà, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ẹlẹ́gírí ń ṣe ayédèrú rẹ̀. Ní Gúúsù America, àwọn àjọ oògùn líle ti Colombia ti ń ṣe ayédèrú owó America fún ọ̀pọ̀ ọdún, láti fi kín owó tí kò bófin mu tí ń wọlé fún wọn lẹ́yìn. Nísinsìnyí, àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Àárín Gbùngbùn Ìhà Ìlà Oòrùn ti ń kópa nínú òwò ṣíṣe nǹkan ayédèrú tí ó wà káàkiri àgbáyé náà, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ. Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn “ni a sọ pé ó ń lo àwọn ọ̀nà ìtẹ̀wé tí ó lágbára, tí ó jọ irú èyí tí wọ́n ń lò ní Ẹ̀ka Ìṣètò Owó ní United States. Nítorí èyí, [ó] lè ṣe owó onípépà tí ó jẹ́ 100 dọ́là, tí ènìyàn lè fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè dá mọ̀, tí wọ́n mọ̀ sí ‘àpèkánukò owó onípépà.’”

Àwọn ènìyàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà, China, àti àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Asia míràn pẹ̀lú ti bẹ̀rẹ̀ sí í wọnú iṣẹ́ ṣíṣe owó páńda—ọ̀pọ̀ jù lọ rẹ̀ sì jẹ́ owó United States. Wọ́n fura sí i pé ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún owó United States tí ń lọ láti ọwọ́ dé ọwọ́ ní Moscow lónìí jẹ́ ayédèrú.

Ìwé ìròyìn Reader’s Digest sọ pé, lẹ́yìn Ogun Gulf, ní 1991, nígbà tí wọ́n mú kí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ owó dọ́là United States máa lọ láti ọwọ́ dé ọwọ́, “ó ya àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìfowópamọ́ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lẹ́nu láti rí i pé nǹkan bí ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn owó onípépà tí ó jẹ́ 100 dọ́là ló jẹ́ ayédèrú.”

Ilẹ̀ Faransé ní ìṣòro ayédèrú owó tirẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí pẹ̀lú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Europe míràn. Ṣíṣe ayédèrú owó kì í ṣe ìṣòro America nìkan, gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè míràn káàkiri àgbáyé ṣe lè jẹ́rìí sí i.

Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan Di Ìrọ̀rùn

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ṣaájú ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, ó gba àwọn òṣìṣẹ́ abẹ́lẹ̀—àwọn ayàwòrán, aṣọnà ìwé títẹ̀, afikẹ́míkà-tẹ̀wé, àti àwọn atẹ̀wé—ní ọ̀pọ̀ wákàtí, pẹ̀lú iṣẹ́ àṣelàágùn láti lè ṣẹ̀dà owó orílẹ̀-èdè èyíkéyìí, kò sì sí bí wọ́n ṣe lè ṣe é kí ó dára tó, ó máa ń jẹ́ ẹ̀dà tí kò dára tó ti owó gidi náà. Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí, pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ aṣẹ̀dà aláwọ̀ mèremère, àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé atẹnútẹ̀yìn, àti ẹ̀rọ aṣẹ̀dà àwòrán tí wọ́n jẹ́ ti ọlọ́gbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga, tí ó wà káàkiri àwọn ilé iṣẹ́ àti nínú ilé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ẹ̀rọ́ mú kí ó ṣeé ṣe fún láti ṣẹ̀dà owó tí ó bá wù ú.

Sànmánì wíwá tábìlì kan láti ṣe ayédèrú nǹkan fàlàlà la wà yìí! Ohun tí ń gba òye iṣẹ́ àwọn amọṣẹ́dunjú aṣọnà ìwé títẹ̀ àti àwọn atẹ̀wé tẹ́lẹ̀ ti di ohun tí ó ṣeé ṣe fún àwọn òṣìṣẹ́ ọ́fíìsì àti àwọn tí ń lo ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà nínú ilé. Àwọn nǹkan ìtẹ̀wé tí ń lo kọ̀m̀pútà kékeré tí owó rẹ̀ kò ju nǹkan bí 5,000 dọ́là lọ lè ṣe ayédèrú owó tí ó lè ṣòro fún àwọn ọ̀jáfáfá ògbógi pàápàá láti dá mọ̀. Èyí lè túmọ̀ sí pé ẹnì kan tí ó nílò owó lè gbàgbé lílọ sídìí ẹ̀rọ aṣètò owó nípa títẹ owó tirẹ̀—lọ́nà tí ó pọ̀ tó láti tẹ́ àìní ara rẹ̀ lọ́rùn! Ní báyìí ná, ohun èèlò kì-í-bà-á-tì yìí ni àwọn tí ń ṣe ayédèrú nǹkan ń lò lónìí. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn ọ̀daràn ọlọ́gbọ́n féfé yìí ń borí àwọn aláṣẹ ìjọba, wọ́n sì lè jẹ́ ewu fún àwọn lájorí owó gbogbo àgbáyé lọ́jọ́ kan.”

Fún àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Faransé, ìpín 18 nínú ọgọ́rùn-ún lára 30 mílíọ̀nù owó ilẹ̀ Faransé (mílíọ̀nù 5 dọ́là, United States) tí ó jẹ́ owó ayédèrú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ní ọdún 1992 ni wọ́n fi àwọn ẹ̀rọ tí ó máa ń wà ní ọ́fíìsì ṣe. Òṣìṣẹ́ olóyè kan ní Banque de France wo èyí gẹ́gẹ́ bí ewu, kì í ṣe sí ètò ọrọ̀ ajé nìkan, ṣùgbọ́n, sí ìgbẹ́kẹ̀lé tí àwọn ènìyàn ní nínú ìjọba pẹ̀lú. Ó fi ìbànújẹ́ sọ pé: “Nígbà tí àwọn ènìyàn bá mọ̀ pé o lè ṣe ẹ̀dà owó onípépà pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ọ̀pọ̀ ènìyàn, ìgbọ́kànlé tí wọ́n ní lè pòórá.”

Gẹ́gẹ́ bí ìsapá tí wọ́n ń ṣe láti dẹ́kun pípọ̀ tí àwọn ayédèrú owó ń pọ̀ sí i ní ilẹ̀ America àti àwọn orílẹ̀-èdè míràn, wọ́n wà lẹ́nu ṣíṣe àwọn ọnà tuntun sí àwọn owó pépà, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan sì nìyí, owó tuntun tilẹ̀ ti jáde sọ́wọ́ àwọn ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, ní ti ọ̀ràn owó ilẹ̀ America, àwòrán Benjamin Franklin tí ó wà lára owó pépà tí ó jẹ́ 100 dọ́là ni wọn yóò jẹ́ kí ó tóbi sí i ní ìlọ́po méjì, wọn yóò sì sún un sí apá òsì ní nǹkan bí ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin sẹ̀ǹtímítà 19. Ìwé ìròyìn Reader’s Digest sọ pé: “Wọn yóò tún ṣe ìyípadà 14 mìíràn níbi ọnà ìtẹ̀wé owó náà, àti àwọn nǹkan ààbò míràn tí ènìyàn kò lè tètè rí.” Wọ́n tún ń ronú nípa ọ̀pọ̀ ìyípadà míràn, irú bí àwọn àmì bí owó náà ṣe nípọn tàbí fẹ́lẹ́ sí, àti àwọn íǹkì tí ó máa ń yí àwọ̀ padà nígbà tí ènìyàn bá wò ó láti ìhà tí ó yàtọ̀ síra.

Ó ti tó ọdún bíi mélòó kan nísinsìnyí tí ilẹ̀ Faransé ti ń lo àwọn ìdènà ayédèrú tuntun nínú ọnà tí ó wà lára àwọn owó rẹ̀, èyí tí a nírètí pé yóò bẹ́gi dínà àwọn aṣayédèrú dé ìwọ̀n àyè kan. Bí ó ti wù kí ó rí, agbẹnusọ kan fún ilé ìfowópamọ́ Banque de France sọ pé: “Kò tí ì sí ọ̀nà ọgbọ́n ẹ̀rọ pípé pérépéré síbẹ̀ láti fi bẹ́gi dínà àwọn tí ó bá fẹ́ di aṣayédèrú owó, àmọ́,” ó fi kún un pé, “ó ti ṣeé ṣe fún wa nísinsìnyí láti pa ọ̀pọ̀ ìdènà ṣíṣe ayédèrú pọ̀ sára àwọn owó náà gan-an, tí ó fi jẹ́ pé yóò jẹ́ iṣẹ́ tí ó [ṣòro], tí ó sì ń náni lówó tabua.” Ó ṣàpèjúwe àwọn ìdènà ṣíṣe ayédèrú yìí gẹ́gẹ́ bíi “lájorí ìgbésẹ̀ ààbò tí a gbé kí àwọn ènìyàn má baà máa ṣe ayédèrú nǹkan.”

Germany àti Great Britain ti ń ṣe àwọn ìyípadà tí ó wà fún ààbò lára owó wọn fún ọdún bíi mélòó kan nísinsìnyí nípa fífi okùn ààbò sí i, èyí tí ó máa ń mú kí ṣíṣẹ̀dà owó wọn ṣòro. Owó onípépà Canada tí ó jẹ́ 20 dọ́là ní ìdànǹdán onígun mẹ́rin kékeré kan tí wọ́n ń pè ní ọgbọ́n ààbò atànyanranyanran, èyí tí ènìyàn kò lè ṣẹ̀dà rẹ̀ lórí ẹ̀rọ aṣẹ̀dà ìwé. Australia bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn owó oníke fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ jáde ní ọdún 1988 láti lè lo àwọn ọgbọ́n ààbò kan tí kò ṣeé lò sára pépà. Finland àti Austria ń lo irin fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan tí ń ṣe ìmúùnmúná sórí owó onípépà wọn. Àwọn wọ̀nyí máa ń tàn yòò, wọ́n sì máa ń yí àwọ̀ padà bíi bátànì tí a máa ń ṣe sára fíìmù fọ́tò ṣe máa ń ṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn aláṣẹ ìjọba ń bẹ̀rù pé kò ní pẹ́ tí àwọn aṣayédèrú yóò fi ṣe àtúnṣebọ̀sípò tí ó pọn dandan láti lè máa bá ìgbòkègbodò oníwà ọ̀daràn wọn nìṣó—àti pé, láìka àwọn ọ̀na àtúnṣe tí a lè ṣe sí, gbogbo ìsapá tuntun wọn kò ran nǹkankan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ní ìgbà tí ó kọjá. Òṣìṣẹ́ olóyè kan ní Ẹ̀ka Ìṣètò Owó sọ pé: “Ńṣe ló dà bí òwe àtijọ́ náà pé, “bí o bá mọ ògiri tí ó ga ní ẹsẹ̀ bàtà 8, àwọn ẹlẹ́gírí a sì kan àkàbà tí ó ga ní ẹsẹ̀ bàtà 10.”

Títẹ owó páńda jẹ́ apá kan lára iṣẹ́ ọwọ́ àwọn aṣayédèrú nǹkan, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò ti fi hàn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Àwọn nǹkan ìtẹ̀wé tí ń lo kọ̀m̀pútà kékeré tí owó rẹ̀ kò ju nǹkan bí 5,000 dọ́là lọ lè ṣe ayédèrú owó tí ó lè ṣòro fún àwọn ọ̀jáfáfá ògbógi pàápàá láti dá mọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́