Ṣọ́ra! Ọwọ́ Àwọn Gbájú-Ẹ̀ Kò Dilẹ̀
FINÚ wòye ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ìjì líle kan ti jà. Ẹ̀fúùfù líle kan ti ṣíwọ́ bíba nǹkan jẹ́, àkúnya omi kì í sì í ṣe ewu mọ́. Àwọn olùlàájá tí ẹ̀rù ń bà ń jáde láti ibùgbé wọn, láti ọ̀nà jíjìn, àwọn ẹni tí a kó jáde, tí pákáǹleke òun ìbẹ̀rù mú ń pa dà wá wo ìjàǹbá tí ìjì líle náà ṣe. Àwọn òrùlé ti ṣí kúrò lórí ilé; àwọn igi ti hú jáde, wọ́n sì ti ṣubú sínú àwọn iyàrá ṣíṣísílẹ̀ tí òjò ti rin ẹrù inú wọn. Àwọn wáyà iná mànàmáná ti ṣubú, tí èyí sì mú kí ìpè fún ìrànwọ́ àti ìsọfúnni ní pàjáwìrì má ṣeé ṣe. Àwọn ilé kan, tí wọ́n jẹ́ ibùjókòó àwọn ìdílé aláyọ̀ nígbà kan rí, kò sí mọ́—wọ́n ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Ohun tí ó fìgbà kan jẹ́ àdúgbò dídákẹ́rọ́rọ́, tí ó sì lálàáfíà, ti wá di ibi ìṣẹ̀lẹ̀ ìparun àti àìsírètí.
Àwọn ará àdúgbò náà kojú ìpèníjà náà—wọ́n múra tán láti ṣe àtúnkọ́. Àwọn aládùúgbò ń ran ara wọn lọ́wọ́; àwọn kan kò tilẹ̀ mọ orúkọ ara wọn títí di ìgbà náà. Àwọn ọkùnrin ń ṣàjọpín ohun èlò ìṣiṣẹ́ àti òye iṣẹ́. Àwọn obìnrin ń gbọ́únjẹ fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ tí wọ́n ti dàgbà díẹ̀ sì ń tọ́jú àwọn àbúrò wọn. Ọ̀wọ́ àwọn ọkọ̀ tí ń rìnrìn àjò pọ̀ tí wọ́n kó àwọn agbo òṣìṣẹ́ tí ń fínnúfíndọ̀ láti ṣèrànwọ́ ń dé láti àdúgbò míràn—àwọn akanlé, àwọn akógi, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn akunlé. Síbẹ̀, àwọn gbájú-ẹ̀ pẹ̀lú wà lára wọn, tí wọ́n ṣe tán láti kó àwọn olùlàájá náà nífà.
Wọ́n ń béèrè fún púpọ̀ nínú àsansílẹ̀ owó iṣẹ́ àtúnṣe náà. Àwọn onílé tí àìnírètí ti bò mọ́lẹ̀ ń kó owó fún wọn, kìkì láti wá mọ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ náà ti kó o sá lọ, wọn kò sì ní rí wọn mọ́. Àwọn akanlé tí wọ́n “fọwọ́ sọ̀yà” lórí iṣẹ́ wọn, ṣiṣẹ́ àjàǹbàkù sí àwọn ojúkò páànù tí ó ṣí, ńṣe ni wọ́n sì ń jò gan-an nígbà tí òjò àkọ́kọ́ rọ̀. Ní dídíbọ́n pé àwọn fẹ́ háyà àwọn ẹ̀rọ ìṣiṣẹ́ ńláńlá fún iṣẹ́ ọjọ́ kejì, àwọn akógi fi gbájú-ẹ̀ gba àsansílẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là lọ́wọ́ àwọn tí ìjàǹbá ṣe náà. Wọn kò rí wọn mọ́.
Owó gọbọi tí àwọn onílé san fún àwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò tí wọn kò kúnjú ìwọ̀n tàbí tí wọ́n jẹ́ ayédèrú tí wọ́n wá kọ̀ láti san owó ìbánigbófò lórí àwọn ohun tó bà jẹ́ tàbí tí wọ́n ti àwọn ọ́fíìsì wọn pa, tí àwọn tó ni wọ́n náà ti sá lọ, dá kún ìbàjẹ́ àti àdánù náà. Àwọn tí wọ́n rìnnà kore tí wọ́n rí owó ìbánigbófò gbà lórí ohun tó bà jẹ́ wá rí i pé lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn agbaṣẹ́ṣe oníṣẹ́kíṣẹ́, tí wọn kò sì tóótun, ló wà nídìí iṣẹ́ náà, nígbà tí ìwọ̀nba àwọn tí wọ́n tóótun kò lè ṣe gbogbo iṣẹ́ náà. Ní àbájáde rẹ̀, iṣẹ́ àjàǹbàkù ni wọ́n ṣe, tí ó túbọ̀ ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn onílé tí ìpayà ti bá tẹ́lẹ̀.
Wọ́n ń lo gbájú-ẹ̀ fún àwọn tí ìjàǹbá ṣẹlẹ̀ sí léraléra. Ohun tó bẹ̀rẹ̀ bí àdúgbò kan tí ó dahoro tí a wá ń kó jọ pọ̀ fún ire gbogbogbòò, wá yọrí sí ẹ̀tàn tí ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn kan.
Lẹ́yìn ìjì líle kan, ní àdúgbò kan, ó yani lẹ́nu pé owó ìdì mindin-mín-ìndìn kan lọ sókè sí dọ́là 4, àwọn ìyá ọlọ́mọ sì ra agolo oúnjẹ ọmọdé ní dọ́là 6. Ní ilé ìtajà kan, wọn kò ní ta bátìrì fúnni bí a kò bá kọ́kọ́ ra tẹlifíṣọ̀n tàbí rédíò kan. Àpò owó àwọn tí ń ta ohun èlò ìkọ́lé kún dẹ́nu látàrí gbígbówó lé ọjà jù. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, àwọn tí wọ́n ní ilé alágbèéká, tí a bá wọ́ ilé wọn lọ sí ibi tí ó túbọ̀ ga nígbà ìkún omi, rí i pé owó tí àwọn san fi ìpín 600 lórí ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀ kan, obìnrin ọlọ́dún 84 kan tí ibùgbé rẹ̀ bà jẹ́ gba ìkésíni orí tẹlifóònù láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan tí ó pe ara rẹ̀ ní òṣìṣẹ́ ìjọba. Obìnrin náà rò pé àwọn ìwé tí òun fọwọ́ sí lẹ́yìn náà jẹ́ ìwé ìbéèrè fún ìrànlọ́wọ́ ìjọba àti ìwé àsansílẹ̀ owó láti rí oúnjẹ gbà. Ní gidi, wọ́n jẹ́ fún fífi ilé rẹ̀ dúró fún 18,000 dọ́là láti fi pèsè owó fún àtúnṣe kan tí iye rẹ̀ wá jẹ́ nǹkan bí 5,000 dọ́là péré.
Jìbìtì Títajà Lórí Tẹlifóònù
‘Mo bá ọ yọ̀, Ìyáàfin S——! O ti ṣoríire lónìí.’ Ìwọ̀nyí lè jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan fi bẹ̀rẹ̀ ìkésíni àìròtẹ́lẹ̀ kan lórí tẹlifóònù. ‘Ìwọ lo jẹ nínú ìdíje wa . . . ’ Ọ̀pọ̀ ènìyàn ti gba irú ìtẹniláago tí ń wí pé wọ́n “ti jẹ,” pé àwọn ẹ̀bùn náà “dájú.” “Ẹ̀bùn” tí a jẹ náà lè jẹ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun kan, ìtòjọ àwọn ohun èlò ìgbafàájì nínú ilé, tàbí bóyá òrùka dáyámọ́ńdì kan.
O ha ti gba irú ìtẹniláago tí ń kéde pé ìwọ ni yóò gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan bí? Inú rẹ ha dùn bí? Ó ha ṣòro fún ọ láti gbà gbọ́ bí? Bí o bá ti dáhùn irú ìtẹniláago bẹ́ẹ̀ rí, o ha rí ẹ̀bùn rẹ gbà bí? Tàbí o ti kó sọ́wọ́ àwọn oníjìbìtì tí ń tajà lórí tẹlifóònù ni? Bí ìyẹn bá ti ṣẹlẹ̀ sí ọ, ìwọ nìkan kọ́ ló ṣẹlẹ̀ sí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Consumers’ Research ti sọ, ní United States nìkan, àwọn ayédèrú olùtajà-lórí-tẹlifóònù ń lu nǹkan bí ẹni mẹ́wàá ní jìbìtì ní ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan. Lọ́dọọdún, àwọn gbájú-ẹ̀ oníṣẹ́kíṣẹ́ ń fi gbájú-ẹ̀ gba bílíọ̀nù 10 sí 40 bílíọ̀nù dọ́là lọ́wọ́ àwọn aláràjẹ, nǹkan bí 7,500 dọ́là ní ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan.
Ìwé ìròyìn Reader’s Digest sọ pé: “Lọ́dọọdún, ó lé ní 150,000 ènìyàn tí ń dáhùn ìtẹniláago tí ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ń tajà lórí tẹlifóònù jákèjádò Kánádà, tí ń wí fún wọn pé wọ́n ti ‘jẹ’ tàbí ‘a ti mú wọn’ fún jíjẹ ẹ̀bùn kan. Àti pé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Kánádà ni a ń fi àwọn ìtẹniláago wọ̀nyí lù ní jìbìtì lọ́dọọdún, tí wọ́n sì ń ná ìpíndọ́gba 2,000 dọ́là kí wọ́n lè rí ẹ̀bùn wọn gbà.” Ọ̀gá Ọlọ́pàá kan ní Ìpínlẹ̀ Ontario sọ pé: “Fífi tẹlifóònù ṣe gbájú-ẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn jìbìtì títóbijùlọ nínú ìtàn ilẹ̀ Kánádà.” Ó fi kún un pé: “A mọ̀ pé ó ń ná àwọn ará Kánádà ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là lọ́dún.” Fígọ̀ náà jẹ́ kìkì àwọn tí a ròyìn fún àwọn ọlọ́pàá. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí a ti fojú díwọ̀n pé kìkì ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ó ṣẹlẹ̀ sí ni wọ́n sọ ohun tí wọ́n pàdánù, kò ṣeé ṣe láti mọ bí ìṣòro náà ṣe tó gẹ́lẹ́.
Gbájú-ẹ̀ kan sọ pé: “A ń wí fún àwọn ènìyàn pé wọ́n ti jẹ kí wọ́n má baà lè ronú lọ́nà ṣíṣekedere mọ́.” Ó fi kún un pé: “Lẹ́yìn náà, a ń yọ wọ́n lẹ́nu láti fi owó ránṣẹ́, a kì í sì í fi wọ́n sílẹ̀ bọ̀rọ̀ bí wọ́n bá kọ̀.” Gbàrà tí wọ́n bá ti lo gbájú-ẹ̀ fún ẹnì kan, wọ́n lè ta orúkọ rẹ̀ fún àwọn ilé iṣẹ́ mìíràn tí ń tajà lórí tẹlifóònù, wọ́n óò sì kọrúkọ rẹ̀ sínú àkọsílẹ̀ àwọn “sùẹ̀gbẹ̀.” Wọ́n lè ta orúkọ wọn fún àwọn ẹlòmíràn tí àwọn pẹ̀lú yóò máa tẹ̀ wọ́n láago léraléra. Òṣìṣẹ́ atẹniláago tẹ́lẹ̀ rí kan nílé iṣẹ́ tí ń tajà lórí tẹlifóònù ní Toronto sọ pé: “Bí a bá ń ṣiṣẹ́ lórí àkọsílẹ̀ àwọn sùẹ̀gbẹ̀, a ń rí àwọn tí ó tó ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún láti rajà nígbà ìtẹ̀láago àkọ́kọ́. Ó ń dín kù sí ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún nígbà kẹta tí a bá ṣiṣẹ́ lórí àkọsílẹ̀ náà. Àmọ́, gbàrà tí àwọn ènìyàn kan bá ti bẹ̀rẹ̀, wọn kì í bojú wẹ̀yìn mọ́; ńṣe ni wọ́n máa ń lépa owó lọ.”
Báwo ni àwọn tí àwọn òǹtajà ayédèrú lórí tẹlifóònù náà ń tàn jẹ yóò ṣe lọ jìnnà tó ní lílépa ìmúṣẹ àlá wọn láti jẹ ẹ̀bùn àgbàyanu kan? Ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan sọ pé: “A ní láti bá àwọn báńkì ṣiṣẹ́ láti fòfin de ọ̀nà tí àwọn arúgbó kan yóò gbà lo owó wọn kí wọ́n má baà gbà á tán.” A ṣàwárí pé obìnrin kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di opó ti san owó nígbà 36 fún àwọn ilé iṣẹ́ 16 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ń tajà lórí tẹlifóònù, àròpọ̀ owó náà lé ní 85,000 dọ́là. Ó rí “gbàrọgùdù gbẹ̀dẹ̀ ìṣaralọ́ṣọ̀ọ́ tí ó kún ìdajì iyàrá kan” gbà.
Lílo Gbájú-Ẹ̀ fún Àwọn Ọlọ́gbọ́n Ayé
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ń ṣe gbájú-ẹ̀ kì í dá ẹnì kan sí. Àtolówó àtòtòṣì ni wọ́n ń lo gbájú-ẹ̀ fún láwùjọ. Kódà wọ́n ti tan àwọn amọṣẹ́dunjú tí a rò pé wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n ayé jẹ. Ẹ̀tàn tí wọ́n ṣètò náà lè kún fún àrékérekè débi pé wọ́n lè lo gbájú-ẹ̀ fún aláràjẹ tí ó wà lójúfò jù lọ. Wọ́n lè polówó àwọn ìṣe gbájú-ẹ̀ olówó gọbọi tí ó jẹ́ nítorí àwọn òǹrajà ọlọ́gbọ́n ayé lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí a fi ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́. Wọ́n lè ní nínú, ìdókòwò tí ó ṣèlérí mímú èrè gọbọi wá—ìdókòwò lórí àwọn ilé sinimá, góòlù àti ibi ìwakùsà góòlù, àwọn kòtò ìwapo bẹtiróòlù. Ó jọ pé àkọsílẹ̀ náà kò lópin. Bí ó ti wù kí ó rí, àbáyọrí rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan náà—àdánù pátápátá.
Obìnrin kan tí ó kàwé, tí wọ́n lo gbájú-ẹ̀ fún, sọ pé: “Bí wọ́n ṣe ń tanni jẹ tó ń yani lẹ́nu. Èmi bí olùkọ́ kan lérò pé mo jẹ́ onílàákàyè ènìyàn. . . . Àwọn ìlérí náà kò lópin.” Ilé iṣẹ́ sinimá kan fi gbájú-ẹ̀ gba 20,000 dọ́là lọ́wọ́ rẹ̀.
Jìbìtì títajà lórí tẹlifóònù jẹ́ ìṣòro tó kárí ayé. Àwọn olùṣèwádìí sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò “burú sí i ní ẹ̀wádún yìí.” Àmọ́, ṣọ́ra! Irú gbájú-ẹ̀ míràn wà, àwọn gbájú-ẹ̀ kan sì ní àwọn tí wọ́n dájú sọ ní pàtàkì—àwọn arúgbó.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ṣọ́ra fún àwọn gbájú-ẹ̀ tí ń wá lẹ́yìn ìjì líle kan!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
“O ti jẹ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan!”—àbí ṣé o ti jẹ?