ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 8/8 ojú ìwé 24-25
  • Ibo Lo Ti Lè Rí Ìwà Ọmọlúwàbí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Lo Ti Lè Rí Ìwà Ọmọlúwàbí?
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Lù Ọ́ Ní Jìbìtì
    Jí!—2004
  • Dídájúsọ Àwọn Arúgbó
    Jí!—1997
  • Kí Ni Òwò Rẹ Yóò Ná Ọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jìbìtì Gbayé Kan
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 8/8 ojú ìwé 24-25

Ibo Lo Ti Lè Rí Ìwà Ọmọlúwàbí?

À Ń GBÉ nínú ayé tí olúkúlùkù àwọn èèyàn ti ń hùwà bó ṣe wù wọ́n. Àwọn ìwà àìṣòótọ́ táráyé kórìíra nígbà kan rí ti wá di ohun tí wọ́n ń wò láwòmọ́jú báyìí. Aráyé ń wárí fún àwọn olè àtàwọn gbájúẹ̀, àwọn oníròyìn sì máa ń pè wọ́n ní bọ̀rọ̀kìnní. Nípa báyìí, àpèjúwe kan tó wà nínú Bíbélì bá ọ̀pọ̀ èèyàn mu pé: “Nígbàkigbà tí o bá rí olè, inú rẹ tilẹ̀ ń dùn sí i.”—Sáàmù 50:18.

Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn gbájúẹ̀ kì í ṣe ẹni tó yẹ ká máa gbé gẹ̀gẹ̀. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Ohun tá a fi ń dá àwọn gbájúẹ̀ mọ̀ ni pé o máa ń rọrùn fún wọn láti lo agbárí fáwọn èèyàn tó wà ní tòsí wọn, àtikékeré ló sì ti máa ń bá wọn lọ. Yàtọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ alágbárí, bí wọ́n bá lo agbárí fáwọn èèyàn tán, wọn kì í rò ó pé àwọn ṣe nǹkan tó burú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló tún máa ń dá wọn nínú dùn, ìtẹ́lọ́rùn tí wọ́n ń rí nídìí ẹ̀ yẹn ló máa ń mú kí wọ́n fi agbárí gba gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ń fẹ́, láìka ohun tíyẹn ì báà dà fún ẹni tí wọ́n gba nǹkan ọ̀hún lọ́wọ́ ẹ̀.”

Tí Gbájúẹ̀ bá gba gbogbo nǹkan tí opó kan ti ń fi ìgbésí ayé ẹ̀ tò jọ lọ́wọ́ ẹ̀, gbogbo èèyàn ló máa bá a kẹ́dùn, àmọ́ àwọn díẹ̀ ló máa ń ká lára tẹ́nì kan bá kówó ilé iṣẹ́ ńlá jẹ tàbí tó lu ilé iṣẹ́ ìbánigbófò kan ní jìbìtì. Ohun táwọn èèyàn máa ń rò ni pé ṣebí àwọn ilé iṣẹ́ kúkú lówó. Ṣùgbọ́n àwọn ilé iṣẹ́ tí wọ́n lù ní jìbìtì nìkan kọ́ ló máa forí fá a; àwọn òǹrajà náà máa jẹ̀rán ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìdílé kọ̀ọ̀kan ń san iye tó ju ẹgbẹ̀rún kan dọ́là lọ́dún láfikún sí owó ìbánigbófò tí wọ́n ń san torí òfò tó bá tibi jìbìtì wá.

Bákan náà, kíá ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń bẹ́ mọ́ àwọn ọjà gbàrọgùdù táwọn kan jí ṣe tí wọ́n kọ orúkọ ilé iṣẹ́ kan sára ẹ̀ nítorí pé ó gbọ̀pọ̀, ara àwọn ọjà bẹ́ẹ̀ ni aṣọ, aago ọwọ́, tàbí lọ́fíńdà, àwọn ohun ìṣaralóge, àtàwọn báàgì àgbéròde. Wọ́n lè mọ̀ pé àwọn ọjà gbàrọgùdù wọ̀nyí ń mú káwọn ilé iṣẹ́ pàdánù ọgọ́rọ̀ọ̀rún bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún, ṣùgbọ́n wọ́n rò pé kò kàn wọ́n. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn òǹrajà pàpà máa san ju iye tó yẹ kí wọ́n san lọ lórí ojúlówó ọjà tí wọ́n bá rà. Yàtọ̀ síyẹn, kíkówó lórí ọjà kọ̀ǹdẹ̀ ń mú kówó bọ́ sápò àwọn ọ̀daràn ni.

Òǹkọ̀wé kan tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ mọ́ gbígbógun ti jìbìtì kọ̀wé pé: “Ó dá mi lójú pé ìdí tí àwọn oníjìbìtì fi pọ̀ tó báyìí lóde ni pé àwọn èèyàn tó wà lóde òní ò lẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Ìwà ọmọlúàbí ti jó rẹ̀yìn gan-an débi pé gbogbo èèyàn ló ti níwà jìbìtì lọ́wọ́. . . . Àwọn èèyàn ò kọ́mọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ilé mọ́. Wọn ò kọ́ àwọn ọmọ níwà ọmọlúwàbí mọ́ nílé ìwé, nítorí pé ńṣe ní wọ́n á fẹ̀sùn kan àwọn olùkọ́ pé wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ ní ìwà ọmọlúwàbí.”

Ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ pátápátá, nítorí pé wọ́n ń sapá láti máa lo ìlànà ìwà rere tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ìlànà Bíbélì bí irú àwọn tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ló ń darí wọn:

● “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—Mátíù 22:39.

● “Má lu jìbìtì.”—Máàkù 10:19.

● “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere, kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.”—Éfésù 4:28.

● “A . . . dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí kì í ṣe ajọra-ẹni-lójú tàbí olódodo lójú ara ẹni, wọ́n gbà gbọ́ pé bí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà wọ̀nyí, ayé yìí á dùn á sì lárinrin. Wọ́n tún ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run pé ọjọ́ ọjọ́ kan ń bọ̀ tí ayé yóò dà bẹ́ẹ̀.—2 Pétérù 3:13.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]

Bí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ayé yìí á dùn á sì lárinrin

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, irú bíi “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́