ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 9/22 ojú ìwé 6-8
  • Dídájúsọ Àwọn Arúgbó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dídájúsọ Àwọn Arúgbó
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wo Àwọn Gbájú-Ẹ̀ Ará Japan
  • Lílo Gbájú-Ẹ̀ fún Àwọn Arúgbó ní Ítálì
  • Fífi Ìsìn Ṣe Gbájú-Ẹ̀
    Jí!—1997
  • Ṣọ́ra! Ọwọ́ Àwọn Gbájú-Ẹ̀ Kò Dilẹ̀
    Jí!—1997
  • Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Lù Ọ́ Ní Jìbìtì
    Jí!—2004
  • Àwọn Ìdílé Kristian Ń Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 9/22 ojú ìwé 6-8

Dídájúsọ Àwọn Arúgbó

MÁ ṢE àṣìṣe. Àwọn gbájú-ẹ̀ ti múra sílẹ̀ dáradára. Wọ́n mọ àwọn òkodoro òtítọ́ tí ń mú kí àwọn arúgbó jẹ́ ohun ìdájúsọ fífanimọ́ra pàtàkì láti lo gbájú-ẹ̀ fún. Fún àpẹẹrẹ, ní United States, àwọn tí wọ́n ti lé ní ẹni ọdún 65 jẹ́ kìkì nǹkan bí ìpín 12 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn olùgbé ibẹ̀. Síbẹ̀, àpapọ̀ iye owó tí ń wọlé fún wọn lé ní 800 bílíọ̀nù dọ́là, èyí tí ó dúró fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára ọrọ̀ tó ń kù sọ́wọ́ àwọn ìdílé ní United States lẹ́yìn yíyọ onírúurú ìdáwóléni kúrò. Kò yani lẹ́nu pé irú àwọn arúgbó bẹ́ẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n ń lo gbájú-ẹ̀ fún.

Kí ló ń jẹ́ kí a lè tètè rí àwọn arúgbó mú? Ìwé ìròyìn Consumers’ Research sọ pé: “Wọ́n sábà máa ń fọkàn tán ènìyàn, wọ́n sì lè máà ní ìmọ̀ nípa ọ̀nà ìdókòwò ti lọ́wọ́lọ́wọ́.” Ọlọ́pàá kan kédàárò pé jìbìtì ìtajà lórí tẹlifóònù “ń kó àwọn tí wọ́n nìkan wà, pàápàá jù lọ, tí wọ́n sì ṣeé tètè rí mú—àwọn arúgbó—tí wọ́n máa ń lo gbájú-ẹ̀ fún jù lọ nífà. Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹni tó dàgbà ní sànmánì tí kìkì ìbọnilọ́wọ́ ẹnì kan ń fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀.” A fa ọ̀rọ̀ aṣojú Àjọ Àwọn Olùfẹ̀yìntì Lẹ́nu Iṣẹ́ kan ní America yọ tí ó wí pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà ni a máa ń sọ pé ìwọra ló kó ọ sí wàhálà. Ní ti àwọn àgbàlagbà, kì í ṣe ìwọra. Wọ́n ń bẹ̀rù kí owó máà tán lọ́wọ́ wọn. Wọn kò fẹ́ dẹrù ìnira ru àwọn ọmọ wọn. Lẹ́yìn náà, ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fẹ̀sùn [jìbìtì náà] sùn nítorí pé wọ́n ń bẹ̀rù pé àwọn ọmọ wọn yóò rò pé wọn kò lè bójú tó ara wọn.”

Kì í fìgbà gbogbo jẹ́ pé ẹ̀tàn tàbí ìṣìlọ́nà ni wọ́n fi máa ń rí àwọn arúgbó lo gbájú-ẹ̀ fún. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, wọ́n dá nìkan wà ni, bóyá tí wọ́n ní àìní kan láti “ra” ìbádọ́rẹ̀ẹ́. Ní àdúgbò kan, wọ́n rọ àwọn opó kan tí wọ́n nìkan wà láti san 20,000 dọ́là sílẹ̀ fún ohun tí ìwé agbéròyìnjáde kan pè ní, “ẹ̀kọ́ ijó tí ó wúlò fún gbogbo ìgbà ìgbésí ayé ẹni. Ara àwọn kan ṣẹlẹgẹ́ jù láti rìn. Wọ́n kì í ṣe òpè, àníyàn wulẹ̀ pò wọ́n rúurùu ni.” Ẹgbẹ́ oníjó kan ń fún àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ forúkọ sílẹ̀ láǹfààní láti rí ibì kan lọ kí wọ́n baà lè wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ní, tí wọ́n sábà máa ń jẹ́ ojúgbà wọn. Ó ṣòro láti yẹra fún olùtajà gbígbọ́nféfé kan, tí ẹnu rẹ̀ dùn, tí ó máa ń fẹ̀tàn pọ́nni, tí ó tún lè jẹ́ pé òun ní ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ ijó.

Wo Àwọn Gbájú-Ẹ̀ Ará Japan

Àwọn gbájú-ẹ̀ kan lo ipò ìdáwà àwọn arúgbó láti fi mú wọn ní àwọn ọ̀nà míràn. Ní Japan àwọn oníjìbìtì tí kò ní ìlànà ti díbọ́n pé àwọn jẹ́ aláájò, ní lílo àkókò láti fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú àwọn arúgbó tí wọ́n fẹ́ lo gbájú-ẹ̀ fún, ní fífetísílẹ̀ sí wọn. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n ń bẹ̀ wọ́n wò lemọ́lemọ́, lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti jèrè ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí wọ́n dájú sọ pátápátá, wọn óò sọ̀rọ̀ títa ọjà jìbìtì. Àpẹẹrẹ irú ìpète jìbìtì bẹ́ẹ̀ kan ni ti ìṣe gbájú-ẹ̀ ayédèrú góòlù kan tí a ròyìn pé wọ́n fi gbájú-ẹ̀ gba 200 bílíọ̀nù owó yen (1.5 bílíọ̀nù dọ́là) lọ́wọ́ nǹkan bí 30,000 ènìyàn, tí ó ní ọ̀pọ̀ àwọn olùfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ nínú. Ìwé agbéròyìnjáde Asahi Evening News ti Japan ní àkọlé ìròyìn náà, “Kò Jọ Pé A Lè Kọ́fẹ Àdánù Àwọn Tí A Lo Gbájú-Ẹ̀ fún Pa Dà.”

Ìwé agbéròyìnjáde Asahi Shimbun ti Tokyo ròyìn lórí ọ̀ràn yí pé: Obìnrin olùtajà kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ wà láàárín 40 sí 60 ọdún bẹ bàbá arúgbó kan wò, ó wí pé: “Ọ̀gbẹ́ni K., mo bìkítà nípa rẹ ju iṣẹ́ mi lọ, nítorí pé o ń dá gbé.” Ó fetí sí àwọn àlàyé rẹ̀, ó sì fi ìṣesí rẹ̀ tan bàbá náà jẹ. Nígbà tí ó ń lọ, ó béèrè fún àyè láti pa dà wá lọ́jọ́ kejì. Ìdáhùn bàbá náà ni pé: “Má ṣàìpadàwá.”

Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ wò déédéé; wọn óò jẹun alẹ́ pọ̀, ó tilẹ̀ gbé oúnjẹ wá fún Ọ̀gbẹ́ni K. Ó ṣèlérí pé: “N óò máa tọ́jú rẹ títí tí o fi máa kú.” Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó dorí ọ̀rọ̀ ìyọnilẹ́nu fún ìtajà: “N óò bá ọ bójú tó dúkìá rẹ. Àìpẹ́ yìí ni ilé iṣẹ́ tí mo ń bá ṣiṣẹ́ gbé ìlànà lílo dúkìá ẹni lọ́nà tí ń mérè wá gan-an kalẹ̀.” Ìlànà náà béèrè pé kí ó fi ilé àti ohun ìní rẹ̀ dúró, kí ó ra góòlù tútù, kí ó sì gbé e fún ilé iṣẹ́ obìnrin náà. Wọ́n ti dẹ pàkúté ná. Ọ̀gbẹ́ni K. di ọ̀kan lára àwọn púpọ̀ tí wọ́n ti lo gbájú-ẹ̀ fún. Gbàrà tí ìdúnàádúrà ti parí, obìnrin náà kò tún pa dà wá mọ́.

Ọ̀gbẹ́ni K. sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bíi sójà kan, mo wà ní bèbè ikú. Àmọ́, ó tilẹ̀ ṣòro gan-an láti kojú pé ẹnì kan tí ń fi àìlera àwa arúgbó tí ń dá gbé láìsí ẹbí kankan láti fẹ̀yìn tì dẹkùn mú wa, ti fi gbájú-ẹ̀ gba dúkìá mi. Ó jọ pé ayé ti wọnú sànmánì kan tí àwọn ènìyàn ń fẹ́ owó lọ́nà jìbìtì pàápàá.”

Lílo Gbájú-Ẹ̀ fún Àwọn Arúgbó ní Ítálì

Ìwé náà, L’Italia che truffa (Ítálì Tí Ń Lo Gbájú-Ẹ̀), ròyìn ìpète búburú dídíjú kan tí àwọn gbájú-ẹ̀ gbé kalẹ̀ ní Ítálì láti fi jìbìtì gbọ́n owó iyebíye tí àwọn arúgbó ní nípamọ́ gbẹ. Ní 1993, wọ́n dá ètò àkóso kan tí gómìnà àná ti Báńkì Ítálì jẹ́ aṣáájú rẹ̀ sílẹ̀. Dájúdájú, ìbuwọ́lùwé rẹ̀ wà lára àwọn owó oníbébà (tí ó dájú pé ó ṣì lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀) tí wọ́n ṣe jáde lákòókò tó wà lórí àléfà gẹ́gẹ́ bíi gómìnà. Lẹ́yìn tí àwọn gbájú-ẹ̀ mélòó kan tí wọ́n fi ara wọn hàn bí òṣìṣẹ́ Báńkì Ítálì, tí wọ́n sì mú ayédèrú káàdì ìdánimọ̀ dáni láti fi gbè é nídìí, bá ti dé ẹnu ọ̀nà àwọn arúgbó, wọn óò wí fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tí wọ́n lo gbájú-ẹ̀ fún pé: “O mọ̀ pé gómìnà Báńkì Ítálì ti di ààrẹ Ìgbìmọ̀ Tẹ̀ẹ́kótó Àwọn Mínísítà Ìjọba; nítorí náà, ìbuwọ́lùwé rẹ̀ tí ó wà lára àwọn owó bébà kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́. Ó jẹ́ iṣẹ́ tiwa láti gba gbogbo owó bébà àtijọ́ lọ́wọ́ ìdílé kọ̀ọ̀kan, kí a sì pààrọ̀ wọn sí tuntun tí ẹni tí ó gbapò rẹ̀ buwọ́ lù . . . Rìsíìtì nìyí. Mú ìwé yìí lọ sí báńkì rẹ ní ọ̀túnla, ìwọ yóò sì gba iye owó tí o kó fún wa nísinsìnyí.” Nípasẹ̀ ìpète búburú yìí, àwọn gbájú-ẹ̀ náà gba mílíọ̀nù 15 lire (nǹkan bí 9,000 dọ́là) lọ́jọ́ kan!

Àwọn gbájú-ẹ̀ kan ní Ítálì kàn sí àwọn tí wọn kò fura, títí kan àwọn arúgbó, lójú pópó. Wọ́n ní kí àwọn tí kò fura náà kópa nínú àyẹ̀wò kan, wọ́n sì fún wọn ní àwọn abala bébà láti buwọ́ lù, ní wíwí pé ìbuwọ́lùwé wọn wulẹ̀ jẹ́ láti fẹ̀rí hàn pé wọ́n kópa nínú àyẹ̀wò náà. Ní gidi, wọ́n ń buwọ́ lu àdéhùn kan tí ó sọ ọ́ di dandan fún wọn láti ṣe ohun kan tàbí láti ra ohun kan.

Ní àkókò kan lẹ́yìn náà, ẹni tí wọ́n lo gbájú-ẹ̀ fún náà yóò rí àpótí ẹrù kan tí ó ní àwọn ẹrù nínú gbà, bóyá pẹ̀lú ìkìlọ̀ kan tí ó hàn kedere lára ohun tí wọ́n fi wé e pé, bí ó bá kọ ẹrù náà, wọn óò fìyà jẹ ẹ́ ní àwọn ọ̀nà kan. Ẹ̀rù ba àwọn kan, pàápàá jù lọ àwọn arúgbó, tí wọ́n ń rò pé yóò sàn jù láti san ìwọ̀nba owó díẹ̀, kí àwọn sì gba ẹrù tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí náà ju kí a pe àwọn lẹ́jọ́ lọ.

Báwo ni lílo gbájú-ẹ̀ ti tàn kálẹ̀ tó ní Ítálì? Gẹ́gẹ́ bí ìwé L’Italia che truffa ti sọ, àròpọ̀ iye ìṣe gbájú-ẹ̀, tí a ròyìn jẹ́ nǹkan bí 500,000 lọ́dún kan. Ó kéré tán, ìṣe gbájú-ẹ̀ tí a kò ròyìn tó ìlọ́po mẹ́ta ìyẹn. Akọ̀ròyìn kan fún ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n sọ pé: “Àròpọ̀ náà jẹ́ nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì onírúurú ìdẹkùn lọ́dọọdún, tàbí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún sí mẹ́fà lọ́jọ́ kan.”

Ó ṣì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀. Àwọn tí ń fi gbájú-ẹ̀ gba owó àwọn ènìyàn—tí ó sì sábà máa ń jẹ́ gbogbo owó tí wọ́n ní láyé—kò yẹ àwùjọ ọjọ́ orí kankan (tàbí ẹ̀yà ìran, orílẹ̀-èdè, tàbí àwùjọ ìran, nínú ọ̀ràn yí) sílẹ̀. Ṣọ́ra! Ó lè ṣẹlẹ̀ sí ọ.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Bí O Ṣe Lè Yẹra fún Dídí Ẹni Tí Wọ́n Lo Gbájú-Ẹ̀ Fún

KÌ Í ṣe gbogbo ilé iṣẹ́ tí ń tajà lórí tẹlifóònù ló jẹ́ alábòsí. Fún àpẹẹrẹ, ní United States, 140,000 ilé iṣẹ́ ló tajà lórí tẹlifóònù ní 1994, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Àjọ Àwọn Olùfẹ̀yìntì Lẹ́nu Iṣẹ́ ní America (AARP) sọ. A fojú díwọ̀n pé ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún, tàbí 14,000 lára wọn ló jẹ́ oníjìbìtì. Nítorí náà, ó wá pọn dandan láti wà lójúfò bí wọ́n bá fi ohun kan tí ó ṣòro láti gbà gbọ́ lọ̀ ọ́. Àwọn àbá díẹ̀ kan nìyí tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún dídí ẹni tí wọ́n lo gbájú-ẹ̀ fún nípasẹ̀ ìtajà lórí tẹlifóònù.

◆ Bí ẹnì kan bá tẹ̀ ọ́ láago láti wí fún ọ pé o ti jẹ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan, ohun tí ó bọ́gbọ́n mu jù lọ tí o lè ṣe lè jẹ́ láti gbé tẹlifóònù sílẹ̀.

◆ Bí ẹni tí ń tajà lórí tẹlifóònù náà bá rin kinkin pé kí o rà á lónìí bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò ti pẹ́ jù, èyí jẹ́ àmì tó wọ́pọ̀ pé ayédèrú ni ohun tó ń fi lọ̀ ọ́.

◆ Pa nọ́ńbà káàdì ìrajà àwìn rẹ mọ́. Má ṣe sọ ọ́ fún àlejò tí ó tẹ̀ ọ́ láago láti tọrọ owó.

◆ Má ṣe ra ohunkóhun lórí tẹlifóònù àyàfi tó bá jẹ́ ìwọ lo tẹ̀ wọ́n láago, tí ó sì jẹ́ ilé iṣẹ́ tí ń lo ìwé ìbéèrè fún ọjà, tí o mọ̀ pé ó ní orúkọ rere, ni.

Àwọn tí wọ́n ní ilé tìwọn ní láti ṣọ́ra fún àwọn ìṣe gbájú-ẹ̀ nínú ìṣàtúnṣe ilé. Àwọn ìkìlọ̀ díẹ̀ kan nìyí, bí ó ṣe wà nínú ìwé Àlámọ̀rí Àwọn Aláràjẹ ti àjọ AARP:

◆ Má ṣe gbéṣẹ́ fún àjèjì kan títí o óò fi wádìí nípa àwọn tó mọ̀ ọ́n; béèrè orúkọ àti nọ́ńbà tẹlifóònù àwọn oníbàárà míràn tí ó ti ṣiṣẹ́ fún rí.

◆ Má ṣe fọwọ́ sí ohunkóhun láìjẹ́ pé o yẹ̀ ẹ́ wò kínníkínní, sì rí i dájú pé gbogbo ohun tí ó là sílẹ̀ nínú iṣẹ́ tàbí àdéhùn èyíkéyìí yé ọ, o sì fara mọ́ wọn.

◆ Má ṣe fọkàn tẹ ẹnì kan láti ṣàlàyé àdéhùn kan fún ọ àyàfi bí ó bá jẹ́ ẹni tí o mọ̀ tí o sì gbẹ́kẹ̀ lé. Ka apá tí a kọ wínníwínní, tí kò ṣe kedere nínú àdéhùn náà fúnra rẹ.

◆ Má ṣe sanwó sílẹ̀ fún àtúnṣe. Rí i dájú pé wọ́n ṣe iṣẹ́ náà tán lọ́nà tí ó tẹ́ ọ lọ́rùn kí o tó san owó tó kù.

Wà lójúfò. Lo làákàyè. Má ṣe lọ́ra láti sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́ bí o kò bá fẹ́ láti rajà náà. Sì rántí pé: Bí ohun kan tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ bá ṣòro láti gbà gbọ́, ó lè jẹ́ jìbìtì ni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn oníjìbìtì lè ṣe bí ẹni tó bìkítà, kí wọ́n baà lè lo gbájú-ẹ̀ fún àwọn arúgbó

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́