ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 9/22 ojú ìwé 9-10
  • Fífi Ìsìn Ṣe Gbájú-Ẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ìsìn Ṣe Gbájú-Ẹ̀
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀pọ̀ Ìhà Tí Fífi Ìsìn Ṣe Gbájú-Ẹ̀ Ní
  • Dídájúsọ Àwọn Arúgbó
    Jí!—1997
  • Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Lù Ọ́ Ní Jìbìtì
    Jí!—2004
  • Ṣọ́ra! Ọwọ́ Àwọn Gbájú-Ẹ̀ Kò Dilẹ̀
    Jí!—1997
  • Àwọn Ẹgbẹ́ Awo—Kí Ni Wọ́n Jẹ́?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 9/22 ojú ìwé 9-10

Fífi Ìsìn Ṣe Gbájú-Ẹ̀

BÍ Ọ̀RỌ̀ nípa ìṣe gbájú-ẹ̀ tí a ti ń sọ bọ̀ bá bà ọ́ lẹ́rù, tí ó sì bà ọ́ nínú jẹ́, ìwọ nìkan kọ́. Ṣùgbọ́n àwọn ìṣe gbájú-ẹ̀ kan wà tí wọ́n tilẹ̀ burú jù—lórúkọ ìsìn. Ọ̀kan lára àwọn tó wọ́pọ̀ jù lọ ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé ọkàn ń wà láàyè lọ lẹ́yìn ikú àti pé àwọn alààyè lè ṣàǹfààní fún òkú. Wọ́n ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn aláìlábòsí ọkàn káàkiri ayé gbà gbọ́ pé nípa sísan owó gọbọi, wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn olólùfẹ́ wọn tó ti kú tàbí kí wọ́n tù wọ́n lójú.

Lónìí, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ìṣe gbájú-ẹ̀ àtayébáyé yìí ti ní apá tuntun kan. Fún àpẹẹrẹ, láìpẹ́ yìí ní Japan, wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn àlùfáà Búdà lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n sọ pé àwọn ní agbára ẹ̀mí látàrí fífura sí wọn pé wọ́n ti fi gbájú-ẹ̀ gba àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún owó yen lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ. Àwọn tí a fàṣẹ ọba mú ti polówó ìwòsàn àti iṣẹ́ àlàyé nípa ìtọ́jú. Lára àwọn tó wá wọn lọ ni àwọn ìyàwó ilé mẹ́rin kan tí wọ́n sọ fún pé àwọn ẹ̀mí àwọn ọmọ wọn tó ti kú ló ń dọdẹ wọn kiri. Ìwé agbéròyìnjáde Mainichi Daily News sọ pé: “Wọ́n wá ní kí àwọn obìnrin náà san mílíọ̀nù 10 owó yen lápapọ̀ [80,000 dọ́là ti U.S.] fún àwọn ìsìn ìrántí.” Obìnrin ọlọ́dún 64 kan kó iye tí ó lé mílíọ̀nù 6.65 yen (nǹkan bí 53,000 dọ́là) fún wọn. Obìnrin náà ti bá àwọn àlùfáà náà sọ̀rọ̀ nípa ìlera ọmọ rẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde The Daily Yomiuri sọ pé: “A gbọ́ pé wọ́n sọ fún obìnrin náà pé nǹkan burúkú yóò ṣẹlẹ̀ sí i àyàfi bí ó bá ṣe ìsìn àkànṣe kan láti ṣèrántí ọkàn àwọn babańlá rẹ̀ àti láti ṣíjú àwọn ẹ̀mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.”

Ìmọ̀ pípé nípa Bíbélì ì bá ti gba àwọn ènìyàn tí kò fura wọ̀nyí lọ́wọ́ dídi ẹni tí wọ́n lo gbájú-ẹ̀ fún. Ó fi hàn kedere pé ọkàn kì í ṣe aláìlèkú. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4) Oníwàásù 9:5 sọ pé, àwọn òkú “kò mọ ohun kan.” Nítorí náà, òkú kò lè pa alààyè lára. Bẹ́ẹ̀ sì ni alààyè kò lè ṣàǹfààní fún òkú.

Ọ̀pọ̀ Ìhà Tí Fífi Ìsìn Ṣe Gbájú-Ẹ̀ Ní

Nítorí ìwọra tí àwọn kan ní, wọ́n ń kó sọ́wọ́ àwọn tí ń fi ìsìn ṣe gbájú-ẹ̀. Ní Australia, ọkùnrin kan tí ó fẹ́ kí owó rẹ̀ pọ̀ sí i gbé 100,000 dọ́là fún tọkọtaya kan tí wọ́n sọ pé àwọn ní agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ pẹ̀lú agbára láti súre sórí owó, kí ó sì sọ ọ́ di púpọ̀. Wọ́n ní kí ó kó owó náà sínú àpótí kan, kí ó sì gbé e fún àwọn láti “yà á sí mímọ́.” Tọkọtaya náà gbé owó wọ iyàrá kejì láti lọ súre sí i, òun sì dúró dè wọ́n. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n gbé àpótí náà pa dà fún un, wọ́n sì kìlọ̀ fún un pé ohunkóhun kò gbọ́dọ̀ sún un láti ṣí àpótí náà títí di ọdún 2000. Bí ó bá ṣí i ńkọ́? Wọ́n wí fún un pé, “yóò ba idán náà jẹ́, ojú rẹ̀ yóò fọ́, irun rẹ̀ yóò re, yóò ní àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ẹ̀gbà yóò sì pa á.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, ara bẹ̀rẹ̀ sí í fu ọkùnrin náà, ó sì ṣí àpótí náà. Págà! Bébà tí wọ́n gé wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ló kún inú rẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde tó ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà sọ pé, ó dá ara rẹ̀ lẹ́bi, ohun tó tún ṣàjèjì níbẹ̀ ni pé, “orí rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í pá.”

Ní Ítálì, fífi ìsìn ṣe gbájú-ẹ̀ ní apá tuntun kan: Àwọn gbájú-ẹ̀ kan tí ń ṣe bíi Kátólíìkì olùfọkànsìn ti lo gbájú-ẹ̀ fún àwọn àlùfáà kan. Àwọn gbájú-ẹ̀ náà lo àṣà Kátólíìkì ti sísanwó fún ìsìn Máàsì òkú fún àwọn kan tí wọ́n ti kú. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Ìwé ìròyìn Kátólíìkì náà, Famiglia Cristiana, ṣàlàyé pé, àwọn ẹlẹ́tàn náà sọ pé àwọn óò sanwó sílẹ̀ fún ìsìn Máàsì òkú ẹni méjìlá ní lílo ayédèrú ìwé sọ̀wédowó tí wọ́n kọ owó tí ó pọ̀ gan-an ju iye tí a béèrè fún lọ sí. Wọ́n tan ṣùẹ̀gbẹ̀ àlùfáà kan jẹ láti fi owó gidi san iye tí ó lé lórí owó náà fún wọn. Àwọn gbájú-ẹ̀ náà gba owó náà, àlùfáà náà sì gba ìwé sọ̀wédowó tí báńkì kọ̀!

Ní United States, àwọn ayédèrú ìsìn tí ń wá àwọn ẹni tuntun tí yóò dáwó tí wọn óò pa sínú àpò ìṣúra wọn sábà máa ń sàga ti àwọn arúgbó níhà gbogbo. Ìwé ìròyìn Modern Maturity kọ̀wé pé: “Jákèjádò orílẹ̀-èdè, àwọn ayédèrú ìsìn ń ṣègbọràn sí ìlànà pàtàkì náà nípa gbogbo ìṣe jìbìtì lílù pé: Tọpa ibi tí owó wà. Ní pàṣípààrọ̀, wọ́n ń fi ohun gbogbo láti orí ìlera sí ìyípadà ìṣèlú sí ìjọba ọ̀run lọni.” A fa ọ̀rọ̀ ẹnì kan tí ń yí ìrònú àwọn mẹ́ńbà ayédèrú ìsìn tẹ́lẹ̀ rí pa dà yọ tí ó sọ pé: “Àwọn arúgbó ni ohun ìṣararindin fún àwọn ayédèrú ìsìn.”

Iye tí ń lọ sórí rẹ̀ pọ̀ gan-an. Agbẹjọ́rò kan ní New York, tí ó ti bójú tó ọ̀pọ̀ ọ̀ràn ayédèrú ìsìn sọ pé: “Mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀ràn nínú èyí tí àwọn ènìyàn ti sọ ara wọn di tálákà. Ọ̀wọ́ irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ pọ̀ jaburata láti orí àwọn ènìyàn tí a rọ̀ gidigidi láti ṣe ìtọrẹ, ó kéré tán, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún dọ́là sí àwọn tí wọn kò ní nǹkan kan àyàfi àwọn ìwé sọ̀wédowó Ìṣètò Ìfẹ́dàáfẹ́re wọn láti fi sílẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Ó ń fa ìbànújẹ́—fún àwọn ẹni náà fúnra wọn àti fún àwọn ìdílé wọn.”

Nítorí náà, ṣọ́ra! Ọwọ́ àwọn gbájú-ẹ̀ kò dilẹ̀. Àwọn ìṣe gbájú-ẹ̀ nínú ìṣàtúnṣe ilé, jìbìtì ìtajà lórí tẹlifóònù, àti fífi ìsìn ṣe gbájú-ẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́. Kò ṣeé ṣe láti tọ́ka sí gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n ń lò ní pàtó, nítorí pé lọ́tunlọ́tun ni wọ́n ń gbé àwọn ìṣe gbájú-ẹ̀ jáde. Ṣùgbọ́n láìsíyèméjì, ohun tí a kọ síhìn-ín yóò kìlọ̀ fún ọ pé o ní láti ṣọ́ra, ó sì lè jẹ́ pé ìyẹn ni ohun ìgbèjà rẹ tí ó dára jù lọ. (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 8 náà, “Bí O Ṣe Lè Yẹra fún Dídi Ẹni Tí Wọ́n Lo Gbájú-Ẹ̀ Fún.”) Ìkìlọ̀ òwe Bíbélì ìgbàanì kan bá a mu wẹ́kú pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15, NW.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn gbà gbọ́ pé nípa sísan owó, àwọn lè ṣèrànwọ́ fún àwọn olólùfẹ́ àwọn tó ti kú tàbí kí àwọn tù wọ́n lójú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́