ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 2/15 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Ẹgbẹ́ Awo—Kí Ni Wọ́n Jẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹgbẹ́ Awo—Kí Ni Wọ́n Jẹ́?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ẹgbẹ́ Awo kan Jẹ́?
  • Ẹgbẹ́ Awo Ha Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ṣíṣe Nǹkan Ní Bòókẹ́lẹ́ ní Orúkọ Olúwa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ipò Wúńdíá—Èé Ṣe?
    Jí!—1996
  • Fífi Ìsìn Ṣe Gbájú-Ẹ̀
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 2/15 ojú ìwé 3-4

Àwọn Ẹgbẹ́ Awo​—⁠Kí Ni Wọ́n Jẹ́?

NÍ FEBRUARY 28, 1993​—⁠iye tí ó ju ọgọ́rùn-⁠ún kan àwọn agbófinró dàbo agboolé tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé ń gbé. Góńgó náà ni láti ṣàwárí àwọn ohun-ìjà tí kò bófinmu kí wọ́n sì fàṣẹ ọba mú ẹnìkan tí wọ́n bá fura sí gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún àwọn aṣojú náà, nígbà tí òjò ọta ìbọn bẹ̀rẹ̀ síí rọ̀ jáde wá sí ìhà ọ̀dọ̀ wọn láti inú àwọn ilé náà. Àwọn náà yìnbọn padà.

Ìgbéjàkoni yìí ṣekúpa ẹni mẹ́wàá tí àwọn mélòókan sì farapa. Ní 50 ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn aṣojú ìjọba sàga ti agboolé náà pẹ̀lú ìbọn tí ó pọ̀ tó láti gbógun kékeré kan tì wọ́n. Ìdótì náà jálẹ̀ sí ìjà àjàmọ̀gá tí ó ṣekúpa ènìyàn 86, ó kérétán àwọn ọmọdé 17 ni ó ní nínú.

Ṣùgbọ́n ta ni ọ̀tá náà? Agbo àwọn àjọ-ìpàǹpá tí ń ṣòwò oògùn ha ni bí? Ẹ̀yà-ẹgbẹ́ ọ̀jagun abẹ́lẹ̀ ha ni bí? Rárá. Gẹ́gẹ́ bí o ti lè mọ̀, “ọ̀tá” náà jẹ́ agbo àwọn olùfarajìn fún ìsìn, àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ awo kan. Ọ̀ràn ìbìnújẹ́ wọn sọ ẹgbẹ́-àwùjọ fífarasin kan ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àárín-gbùngbùn Texas, U.S.A., di ibi tí àfiyèsí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè darí sí. Àwọn àjọ oníròyìn gbé ọ̀pọ̀ àwọn ìròyìn, ìfọ́síwẹ́wẹ́ ìròyìn, àti àlàyé lórí ewu àwọn ẹgbẹ́ awo agbawèrè-mẹ́sìn jáde lórí afẹ́fẹ́ àti lójú-ewé àwọn ìwé ìròyìn.

Gbogbo ènìyàn ni a ránléti nípa àwọn àpẹẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti wà ṣáájú nínú èyí tí àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ awo ti sin àwọn mẹ́ḿbà wọn lọ sẹ́nu ikú: ìṣìkàpànìyàn láti ọwọ́ Manson ti California ní 1969; ìpara-ẹni tìrìgàngàn ti àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ awo ní Jonestown, Guyana ní ọdún 1978; àdéhùn-ìmùlẹ̀ ìṣìkàpànìyàn-òun-ìpara-ẹni ti ọdún 1987 tí aṣáájú ẹgbẹ́ awo náà Park Soon-ja ti Korea dọ́gbọ́nhùmọ̀, èyí tí ó yọrí sí ikú àwọn mẹ́ḿbà 32. Lọ́nà ṣíṣepàtàkì, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ pé àwọn jẹ́ Kristian wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Bibeli.

Lọ́nà tí ó ṣeélóye, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún Bibeli gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni àṣìlò Ìwé Mímọ́ lọ́nà ọ̀dájú nípasẹ̀ àwọn ẹgbẹ́ awo wọ̀nyí kónírìíra. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde, láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ètò-àjọ ni a ti fìdí wọn múlẹ̀ fún ète ṣíṣọ́ àwọn ẹgbẹ́ awo tọwọ́tẹsẹ̀ àti títú àwọn àṣà wọn tí ó léwu fó. Àwọn ògbógi onímọ̀ nípa ẹgbẹ́ awo sọtẹ́lẹ̀ pé ẹgbẹ̀rúndún titun tí yóò dé ní ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ síi lè ṣokùnfà ìgbèrú àwọn ẹgbẹ́ awo. Ìwé-ìròyìn kan ṣàlàyé pé gẹ́gẹ́ bí àwùjọ àwọn aṣòdì sẹ́gbẹ́ awo ti sọ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹgbẹ́ awo ní ń bẹ “níta tí wọ́n múratán láti mú ara rẹ wá sábẹ́ ìdarí wọn, darí ọkàn rẹ, sọ ọkàn rẹ dìbàjẹ́. . . . Ìwọ̀nba díẹ̀ dìhámọ́ra ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jùlọ ni a kà sí eléwu. Wọn yóò tàn ọ́ jẹ wọn yóò lù ọ́ ní jìbìtì, wọn yóò ṣètò ìgbéyàwó rẹ wọ́n yóò sì ṣètò ìsìnkú rẹ.”

Kí Ni Ẹgbẹ́ Awo kan Jẹ́?

Ọ̀rọ̀ náà “ẹgbẹ́ awo” ni ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n lè má mọ èrò tí ó ń gbìn síni lọ́kàn ní kíkún ń lò bí wọ́n ti fẹ́. Láti ṣèdíwọ́ fún ìdàrúdàpọ̀, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn kan ti yẹra fún lílo èdè ìsọ̀rọ̀ náà níti gidi.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣàlàyé pé “lọ́nà ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́, ọ̀rọ̀ náà ẹgbẹ́ awo tọ́ka sí irú ìjọsìn tàbí pípa ìlànà ìsìn èyíkéyìí mọ́.” Pẹ̀lú ìlànà ìpinnu yẹn, gbogbo ètò-àjọ ìsìn ni a pè ní ẹgbẹ́ awo. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọ̀nà tí a gbà ń lò ó ní gbogbogbòò lónìí, ọ̀rọ̀ náà “ẹgbẹ́ awo” ní ìtumọ̀ kan tí ó yàtọ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan-náà ṣàlàyé pé “láti agbedeméjì àwọn ọdún 1900 wá, ìpolongo ìròyìn nípa awọn ẹgbẹ́ awo ti yí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà padà. Lónìí, ọ̀rọ̀ náà ni a ń lò fún àwọn àwùjọ tí wọ́n tẹ̀lé aṣáájú tí ó wàláàyè kan tí ń ṣagbátẹrù ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ àti àṣà titun tí kò ní ìtẹ́wọ́gbà gbogbo ènìyàn.”

Ní fífọwọ́ sí ìlò ọ̀rọ̀ náà tí ó wọ́pọ̀, ìwé-ìròyìn Newsweek ṣàlàyé pé àwọn ẹgbẹ́ awo “máa ń sábà jẹ́ àwùjọ kékeré, olójú-ìwòye àṣerégèé tí àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ń rí àmì-ìdámọ̀ àti ète wọn gbà láti ọ̀dọ̀ ẹnìkanṣoṣo, tí ó ní agbára àrà-ọ̀tọ̀.” Lọ́nà kan-náà, ìwé-ìròyìn Asiaweek ṣàlàyé pé “ọ̀rọ̀ náà fúnraarẹ̀ [ẹgbẹ́ awo] kò ṣe kedere tó, ṣùgbọ́n ó sábà máa ń tọ́ka sí ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ titun kan tí a kọ́ yíká aṣáájú kan tí ó ní agbára àrà-ọ̀tọ̀, tí ó sábà máa ń polongo araarẹ̀ pé òun jẹ́ ògidi-àpẹẹrẹ Ọlọrun.”

Èdè náà tí a lò nínú ìgbèròpinnu àdáwọ́jọpọ̀ṣe kan ti Ìpéjọ Ìpínlẹ̀ Maryland, U.S.A., ọlọ́gọ́rùn-⁠ún irú rẹ̀ tún ṣe ìgbéjáde èrò tí ń tàbùkù ti ọ̀rọ̀ náà ẹgbẹ́ awo ní. Ìgbèròpinnu náà kà pé “ẹgbẹ́ awo jẹ́ àwùjọ tàbí àjọ ìgbòkègbodò kan tí ń fi ìfọkànsìn àṣerégèé hàn fún ènìyàn tàbí èrò kan tí ó sì ń lo ọgbọ́n ẹ̀tàn ti ìyíniléròpadà àti ìṣàkóso ti kò bá ètò ìlànà ìwàhíhù mu láti lè gbé góńgó ìlépa àwọn aṣáájú rẹ̀ ga síwájú.”

Lọ́nà tí ó ṣe kedere, àwọn ẹgbẹ́ awo ni a lóye ní gbogbogbòò pé wọ́n jẹ́ àwọn àwùjọ ìsìn olójú-ìwòye àti àṣà àṣerégèé tí ó forígbárí pẹ̀lú ohun tí a tẹ́wọ́gbà pé ó jẹ́ ìṣarasíhùwà ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tí ó bójúmu lónìí. Wọ́n sábà máa ń ṣe àwọn ìgbòkègbodò ìsìn wọn ní bòókẹ́lẹ́. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn àwùjọ ẹgbẹ́ awo wọ̀nyí máa ń ya araawọn sọ́tọ̀ sínú àwùjọ adánìkanwà níti gidi. Ìfọkànsìn wọn fún ènìyàn kan tí ó polongo araarẹ̀ ní aṣáájú ni ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ èyí tí a kò gbékarí ipò-àfilélẹ̀ tí ó sì jẹ́ àyàsọ́tọ̀gedegbe. Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn aṣáájú wọ̀nyí a máa fọ́nnu pé a ti yan àwọn látọ̀runwá tàbí pé àwọn fúnraawọn ní ìwà ẹ̀dá ti ọ̀run.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ètò-àjọ aṣòdìsí ẹgbẹ́ awo àti àjọ oníròyìn ti tọ́ka sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ awo kan. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ìwé-ìròyìn kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti fi àwọn Ẹlẹ́rìí kún àwọn àwùjọ ìsìn tí a mọ̀ mọ́ àwọn àṣà tí a lè gbé ìbéèrè díde sí. Ṣùgbọ́n yóò ha jẹ́ ohun tí ó yẹ láti tọ́ka sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ìsìn kékeré olójú-ìwòye àṣerégèé bí? Àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ awo máa ń sábà ya araawọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́, ìdílé, àti kódà ẹgbẹ́-àwùjọ lápapọ̀. Báyìí ha ni ọ̀ràn náà rí pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bí? Àwọn Ẹlẹ́rìí ha ń lo àwọn ọgbọ́n ẹ̀tàn àti èyí tí kò bá ètò ìlànà ìwàhíhù mu láti kó mẹ́ḿbà jọ fún araawọn bí?

Àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ awo ni a mọ̀ pé wọ́n ń lo àwọn ọgbọ́n àyínìke láti ṣàkóso ọkàn àwọn ọmọlẹ́yìn wọn. Ẹ̀rí èyíkéyìí ha wà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe èyí bí? Ìjọsìn wọn ha jẹ́ ní bòókẹ́lẹ́ bí? Wọn ha ń tẹ̀lé tí wọ́n sì ń jọ́sìn ènìyàn kan tí ó jẹ́ aṣáájú bí? Ní ṣàkó, ẹgbẹ́ awo ha ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bí?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Jerry Hoefer/Fort Worth Star Telegram/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́