Ipò Wúńdíá—Èé Ṣe?
“ẸGBẸ́ awo ipo wúńdíá”—ìyẹn ni Randall Balmer, amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ìsìn ní Kọ́lẹ́ẹ̀ji Barnard/Yunifásíti Columbia, pe ìtẹ̀sí tí ó jọ pé ó ń pọ̀ sí i láàárín àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà láti sún ìgbòkègbodò ìbálòpọ̀ takọtabo síwájú di ìgbà tí wọ́n bá túbọ̀ dàgbà sí i.
Kò yani lẹ́nu pé, ọ̀pọ̀ ìrọni láti ta kété sí ìbálòpọ̀ ń wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ètò àjọ onísìn. Ọ̀mọ̀wé Balmer tọ́ka sí i pé: “Ṣùgbọ́n ète ìsúnniṣe ẹgbẹ́ awo ipò wúńdíá kì í ṣe ti ìsìn. Ìsúnniṣe gidi láti wà ní ipò wúńdíá jẹ́ ìbẹ̀rù—kì í ṣe ìbẹ̀ru ìjìyà àtọ̀runwá, bí kò ṣe ìbẹ̀ru àrùn aṣekúpani.” Nípa bẹ́ẹ̀, ó fi ìyàtọ̀ hàn láàárín “ẹgbẹ́ awo Màríà Wúńdíá,” tí ń ṣàgbéyọ ìtakété gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé ti ìsìn, àti “ẹgbẹ́ awo ipò wúńdíá” ti òde òní, tí ń fi ìtakété hàn bí èyí tí ó túbọ̀ jẹ́ ti ọ̀ràn ìlera.
Ọ̀mọ̀wé Balmer ń bá a lọ pé: “Ó jẹ́ àpèjúwe bíbani nínú jẹ́ nípa ipò ìsìn ní àwọn ọdún 1990 pé ìbẹ̀rù àrùn ni ó ń ṣàkóso ọ̀nà ìwà híhù. Nítorí ìhára gàgà wọn láti má ṣẹni, àwọn aṣáájú ìsìn ti pèsè ọ̀nà ìwà híhù tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, tàbí kí wọ́n má tilẹ̀ pèsè ọ̀kan rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, ó wáá kù sọ́wọ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ará ìlú láti gba àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà nímọ̀ràn nípa bí ó ṣe yẹ kí wọ́n gbé ìgbésí ayé wọn lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀.”
Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀ràn kò rí báyìí láàárín àwọn ojúlówó Kristẹni. Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn Chad, ọ̀dọ́langba kan tí a tọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọmọbìnrin kan sún mọ́ Chad, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kan. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, ó ṣe kedere pé ète rẹ̀ ju ìjíròrò lásán lọ. Chad wí pé: “Nígbà náà ni èrò náà wá sọ́kàn mi. Èmi kò lè já Jèhófà kulẹ̀. Pẹ̀lú èrò títẹ́ Jèhófà lọ́rùn nígbà gbogbo nínú mi, mo dágbére fún un.”
Bíi ti Chad, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń di ìwà rere mú, kì í wulẹ̀ í ṣe nítorí ìlera ara, bí kò ṣe láti tẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn, Jèhófà Ọlọ́run, lọ́rùn lákọ̀ọ́kọ́. Ìsúnniṣe ọ̀nà ìwà rere wọn kì í ṣe ìbẹ̀rù àrùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, irú àwọn èwe bẹ́ẹ̀ ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Oníwàásù 12:1 pé: “Rántí ẹlẹ́dàá rẹ nísinsìnyí, ní ọjọ́ èwe rẹ.”