ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 8/8 ojú ìwé 19-24
  • Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Lù Ọ́ Ní Jìbìtì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Lù Ọ́ Ní Jìbìtì
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Tọ́jú Àkọsílẹ̀ Nípa Ara Ẹ Dáadáa
  • Máa Lo Làákàyè
  • Àwọn Ẹni Táráyé Ti Mọ̀ Bí Olóòótọ́ Ni Kó o Bá Dòwò Pọ̀
  • Jẹ́ Kí Gbogbo Ohun Tó So Mọ́ Ọn Wà Lákọọ́lẹ̀
  • Dídájúsọ Àwọn Arúgbó
    Jí!—1997
  • Ṣọ́ra! Ọwọ́ Àwọn Gbájú-Ẹ̀ Kò Dilẹ̀
    Jí!—1997
  • Bó O Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Ọ̀daràn
    Jí!—2013
  • Wọ́n Lè Jí Ohun Ìdánimọ̀ Rẹ Lọ!
    Jí!—2001
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 8/8 ojú ìwé 19-24

Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Lù Ọ́ Ní Jìbìtì

Ó ṢEÉ ṣe kó o ti gbọ́ òwe èdè Gẹ̀ẹ́sì yìí rí pé, “Olóòótọ́ kankan ò lè kó sọ́wọ́ oníjìbìtì.” Ara àwọn àṣìpa òwe nìyẹn. Lójoojúmọ́, làwọn olóòótọ́ èèyàn ń kó sọ́wọ́ oníjìbìtì; òótọ́ inú wọn nìkan ò ní kí wọ́n má lù wọ́n ní jìbìtì. Àwọn tí ọgbọ́n yí nínú po ń pa oríṣiríṣi ète àti ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí wọ́n á fi gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Ní nǹkan tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ báyìí, òǹkọ̀wé kan kọ̀wé pé: “Àwọn ọgbọ́n jìbìtì kan wà tó jẹ́ pé àfi àwọn dìndìnrìn nìkan ni ọgbọ́n yẹn kò ní jẹ.”

Ẹ̀tàn ti dáyé ọjọ́ pẹ́, ó ti wà láti inú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Oríṣiríṣi ọgbọ́n ni wọ́n fi ń lu jìbìtì látọjọ́ tó ti pẹ́, ojoojúmọ́ sì làwọn oníjìbìtì tún ń gbọ̀nà míì yọ. Nítorí náà, báwo lo ṣe lè ṣe é tí wọn ò fi ní rí ọ gbá ? Kò dìgbà tó o bá tó kọ́ gbogbo ọ̀nà táwọn ọ̀daràn ń gbà lu àwọn èèyàn ní jìbìtì. Àwọn ìṣọ́ra bíi mélòó kan ti tó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o má bàa kó sí wọn lọ́wọ́.

Tọ́jú Àkọsílẹ̀ Nípa Ara Ẹ Dáadáa

Bí ẹnì kan bá jí ìwé sọ̀wédowó rẹ tàbí káàdì ìrajà láwìn rẹ, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n rajà. Tó bá jí àwọn ìsọfúnni tó o sọ fún báńkì rẹ wò tó bá sì ti mọ ohun púpọ̀ nípa ẹ, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé gbowó bí ẹni pé òun ló ń jẹ́ orúkọ rẹ. Tọ́rọ̀ bá ti rí báyìí, ọ̀daràn yìí lè gbowó nínú àkáǹtì rẹ ní báńkì, ó lè fi káàdì ìrajà láwìn rẹ rajà, ó sì lè forúkọ ẹ yáwó.a Wọ́n tiẹ̀ lè wá mú ọ lórí ọ̀ràn tó ò mọwọ́ mẹsẹ̀ nípa ẹ̀!

Kó o má bàa kó sọ́wọ́ irú àwọn oníjìbìtì yìí, tọ́jú gbogbo ìwé tí ìsọfúnni nípa rẹ wà nínú wọn dáadáa, títí kan ìwé tí wọ́n kọ iye tó wà nínú àkáǹtì rẹ ní báńkì sí, ìwé sọ̀wédowó rẹ, ìwé àṣẹ ìwakọ̀ rẹ àti káàdì ìdánimọ̀ tí ìjọba àpapọ̀ ṣe. Kọ̀ láti sọ àṣírí rẹ tàbí ọ̀rọ̀ nípa ìṣúnná owó rẹ fáwọn ẹlòmíràn àyàfi tí òfin bá fún wọn láṣẹ láti mọ̀ ọ́n. Èyí ṣe pàtàkì pàápàá tó bá jẹ́ nọ́ńbà káàdì ìrajà láwìn rẹ tàbí ìsọfúnni nípa àkáǹtì rẹ ní báńkì ni wọ́n ń béèrè. Ìgbà kan ṣoṣo tó yẹ kó o fún ẹnikẹ́ni ní nọ́ńbà káàdì ìrajà láwìn rẹ ni ìgbà tó o bá fẹ́ fi ra nǹkan.

Àwọn gbájúẹ̀ kan wà tí wọ́n máa ń tú inú ibi tí wọ́n ń da pàǹtírí sí láti lè rí irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀. Dípò tí wàá kàn fi ju bébà tí ọ̀rọ̀ àṣírí ẹ wà nínú rẹ̀ dànù, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o sun ún níná tàbí kó o yà á wẹ́lẹwẹ̀lẹ. Ara irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ìwé sọ̀wédowó tó ò lò mọ́, àkọsílẹ̀ iye owó ẹ tó wà ní báńkì àti ti ìpín ìdókòwò tó o rà sí ilé iṣẹ́ kan; ó tún kan àwọn bíi káàdì ìrajà láwìn, ìwé àṣẹ ìwakọ̀ àti ìwé ìrìnnà tó ò lò mọ́. Ó bọ́gbọ́n mu pẹ̀lú pé kó o máà tọ́jú àwọn ìwé ìbéèrè fún káàdì ìrajà láwìn tí wọ́n bá fi ránṣẹ́ sí ọ láìṣe pé o béèrè fún un, nítorí pé àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè láwọn ìsọfúnni nípa ẹ nínú èyí tí ẹlòmíràn lè lọ lò.

Máa Lo Làákàyè

Ohun tó sábà máa ń wà nídìí ọ̀pọ̀ jìbìtì tí wọ́n ti lù ni ìlérí táwọn gbájúẹ̀ máa ń ṣe pé téèyàn bá ti kówó lé okòwò tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ báyìí, èrè gọbọi tírú ẹ̀ ṣọ̀wọ́n ló máa mú wá. Ọgbọ́n jìbìtì tó ń sọni di ọlọ́rọ̀ òjijì kan ni èyí tó jẹ́ pé bí wọ́n bá ṣe rí èèyàn mú wọnú ẹ̀ tó lowó tí wọ́n á rí ṣe máa pọ̀ tó, ìyẹn okòwò pírámíìdì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi irú ẹ̀ ló wà, bí wọ́n ṣe sábà máa ń ṣe gbogbo wọn ni pé wọ́n á ní káwọn tó kọ́kọ́ wọ̀ ọ́ máa mú àwọn ẹlòmíì wọ̀ ọ́, bí wọ́n bá sì ṣe rí ẹni mú wọ̀ ọ́ tó ni wọ́n á ṣe rówó lórí ẹ̀ tó.b Bákan kan náà ni wọ́n ṣe ń ṣe ti àwọn lẹ́tà tí wọ́n máa ń pín fáwọn èèyàn káàkiri, wọ́n á ní káwọn wọ̀nyí fi lẹ́tà yìí ránṣẹ́ sí ọ kó o sì fowó ránṣẹ́ sí ẹni tí orúkọ rẹ̀ ti dé òkè pátápátá. Wọ́n á fi dá ọ lójú pé bí orúkọ rẹ bá ti dé òkè téńté, ẹgbẹẹgbẹ̀rún owó dọ́là ló máa wọlé fún ọ.

Okòwò pírámíìdì sábà máa ń forí ṣánpọ́n ni nítorí ó máa ń débì kan tí wọn kì í ti í ráwọn ẹni tuntun mú wọnú ẹ̀ mọ́. Jẹ́ ká gbé ìṣirò lé e wò. Táwọn márùn-ún bá dá okòwò pírámíìdì sílẹ̀, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan sì mú ẹni márùn-ún márùn-ún wọnú ẹ̀, iye àwọn tí wọ́n mú wọnú rẹ̀ á di márùndínlọ́gbọ̀n. Tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn náà bá mú ẹni márùn-ún wá, àwọn tá kún wọn á jẹ́ márùndínláàádóje. Nígbà tó bá fi máa di ìpele kẹsàn-án tí wọ́n ti ń mú èèyàn wọlé, wọ́n á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjì èèyàn tó gbọ́dọ̀ mú mílíọ̀nù mẹ́sàn-án èèyàn wọlé kí wọ́n tó lè rówó gbà! Àwọn tó dá okòwò yìí sílẹ̀ mọ̀ pé á dé ibì kan tí wọn ò ti ní réèyàn mú wọnú ẹ̀ mọ́. Tí wọ́n bá ti fura pé ó ti fẹ́ dà bẹ́ẹ̀, wọ́n á kówó tó wà nílẹ̀ wọ́n á sì na pápá bora. Ó ṣeé ṣe kówó ẹ gbé sínú ẹ̀, àwọn tó o sì mú wọbẹ̀ á wá so mọ́ ẹ láti gba owó tiwọn tó ti gbé. Rántí o, kó o tó lè rówó nínú okòwò pírámíìdì, àfi kí ẹlòmíì pàdánù owó tiẹ̀.

Ṣé ẹnì kan ń fi iṣẹ́ kékeré owó ńlá lọ̀ ọ́, tàbí ó ń sọ fún ọ pé tó o bá kówó lé òwò kan, èrè jaburata ni wà á rí níbẹ̀? Ohun kan tó lè kì ọ́ nílọ̀ nìyí: Bó bá dà bíi pé ohun tí wọ́n ń fi lọ̀ ẹ́ ti dára ju bó ṣe yẹ lọ, irọ́ ló sábà máa ń wà nídìí ẹ̀. Má tètè máa gba ìpolówó ọjà tàbí ohun tẹ́nì kan sọ nípa ẹ̀ gbọ́ tí wà á fi máa rò pé, “Ti eléyìí yàtọ̀.” Rántí pé àwọn tó dá okòwò sílẹ̀ ò wá fowó wọn ṣe sàráà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò wá fàṣírí ọlà hàn ọ́. Tí ẹnì kan bá sọ pé òun mọ nǹkan tá á jẹ́ kó o rí já jẹ, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Kí ló dé tí ò fi ṣe nǹkan náà kóun fúnra ẹ̀ lè dọlọ́rọ̀? Kí ló dé tó fi ń fàkókò ṣòfò láti fi lọ̀ mí?’

Kí ló yẹ kó o ṣe bí wọ́n bá sọ fún ọ pé o ti fakọyọ nínú ìdíje kan tàbí pé o ti jẹ ẹ̀bùn kan? Máà tíì jẹ́ kí inú ẹ dùn, ó lè jẹ́ ọgbọ́n jìbìtì nìyẹn, ó ti jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gba lẹ́tà kan láti orílẹ̀-èdè Kánádà, wọ́n sọ fún un nínú lẹ́tà náà pé ó ti jẹ ẹ̀bùn ṣùgbọ́n ó ní láti fi dọ́là mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ránṣẹ́ kí wọ́n lè fi bá a ṣètò àtirí i gbà. Lẹ́yìn tó ti fowó náà ránṣẹ́, wọ́n tẹ̀ ẹ́ láago láti Kánádà pé nígbà tí wọ́n yí koto oríire òun ló ṣe ipò kẹta, ẹ̀bùn ẹgbẹ̀rún lọ́nà òjì lé rúgba àti márùn-ún dọ́là [$245,000] sì ni iye owó tó jẹ ṣùgbọ́n ó ní láti san ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún iye yẹn tí wọ́n á fi bá a ṣètò yòókù láti rí i gbà. Ó fi egbèjìlá lé àádọ́ta dọ́là [$2,450] ránṣẹ́, kò sì rí kọ́bọ̀ gbà padà. Bí wọ́n bá ní kó o wá sanwó fún “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́” tàbí ẹ̀bùn kan tó o jẹ, jìbìtì nìyẹn. Bi ara rẹ léèrè pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè jẹ ẹ̀bùn ìdíje tí mi ò bá wọn lọ́wọ́ nínú ẹ̀?’

Àwọn Ẹni Táráyé Ti Mọ̀ Bí Olóòótọ́ Ni Kó o Bá Dòwò Pọ̀

Ṣé o rò pé o lè mọ̀ tó bá jẹ́ pé irọ́ lẹnì kan ń pa fún ọ? Ṣọ́ra! Àwọn gbájúẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe ń mú káwọn èèyàn fọkàn tán wọn. Wọ́n ní ọgbọ́n oríṣiríṣi lágbárí tí wọ́n ń ta láti wọlé sáwọn èèyàn lára kí wọ́n tó gbá wọn. Àtẹni tó ń ta irọ́ àtẹni tó ń ta òótọ́ ló mọ̀ pé kó o tó lè rí ọjà ẹ tà ẹnu ẹ ní láti dùn. Ìyẹn ò wá sọ pé kó o má gba ẹnikẹ́ni gbọ́ o, àmọ́ kó o má bàa kó sọ́wọ́ oníjìbìtì, ó yẹ kó o ní ìfura dé ìwọ̀n àyè kan. Dípò kó o kàn máa gbìyànjú láti fi àtinúdá tìẹ mọ̀ bóyá olóòótọ́ ni ẹnì kan, wò ó dáadáa bóyá wàá rí àmì méjì tá a fi máa ń dá jìbìtì mọ̀: Àkọ́kọ́, ṣé ohun tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ yìí dà bíi pé ó ti dáa ju bó ṣe yẹ lọ, èkejì ni pé, ṣé ẹni tó fẹ́ tajà fún ọ ń gbìyànjú láti tì ọ́ lọ́pọnpọ̀n-ọ́n kó o bàa lè kánjú ṣèpinnu?

Àwọn okòwò tó dùn kọjá kó lè jẹ́ òótọ́ yamùrá sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn lè rí nǹkan rà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó tún máa ń mú káwọn gbájúẹ̀ tètè rẹni gbá tí wọn ò sì ní mọ ẹni tó gbá àwọn. Ṣé o ní àdírẹ́sì E-mail [àpótí ìgbalẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì]? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè rí i pé wọ́n á máa gbé ìpolówó tó ò béèrè fún dé ọ̀dọ̀ rẹ. Lóòótọ́ irú ìpolówó ọjà yìí lè fún ọ láǹfààní láti rí oríṣiríṣi nǹkan rà, àmọ́ jìbìtì ló pọ̀ jù nínú wọn. Tó o bá fowó ránṣẹ́ láti ra ọjà kan tí wọ́n polówó ẹ̀ fún ọ látorí E-mail, ó ṣeé ṣe kó o máà rí nǹkan kan gbà fún owó tó o san. Bó o bá jàjà rí nǹkan gbà, ó dájú pé kò ní pójú owó tó o ti kó lé e lórí. Ìmọ̀ràn tó dáa jù ni pé, Má ṣe ra nǹkan kan lọ́wọ́ ẹni tó ń fi ìpolówó ọjà tó ò béèrè fún ránṣẹ́ sí ọ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Ìmọ̀ràn yìí á tún wúlò bí àwọn kan bá tẹ̀ ọ́ láago pé àwọn fẹ́ ta ọjà fún ọ. Lóòótọ́, àwọn olókòwò gidi sábà máa ń tẹ àwọn èèyàn láago láti tajà fún wọn o, ṣùgbọ́n àwọn tó máa ń fi ọjà títà lórí tẹlifóònù lu jìbìtì máa ń gba ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là lọ́wọ́ àwọn èèyàn lọ́dọọdún. Kò sí bó o ṣe lè tara ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan ń bá ọ sọ lórí tẹlifóònù mọ̀ bóyá òótọ́ ló ń sọ tàbí ó fẹ́ lu jìbìtì ni bó ṣe ń dánnu mọ́ ohun tó fẹ́ tà fún ọ. Gbájúẹ̀ kan tiẹ̀ lè díbọ́n ṣe bí aṣojú báńkì kan tàbí ti ilé iṣẹ́ tó ń báni dáàbò bo káàdì ìrajà láwìn. Ó yẹ kó o fura tẹ́nì kan tó sọ fún ọ pé báńkì tàbí ilé iṣẹ́ tó o ní àkáǹtì sí lòun ti wá, bá ń béèrè ìsọfúnni tó yẹ kí wọ́n ti mọ̀ lọ́wọ́ rẹ. Tírú ẹ̀ bá wáyé, o lè béèrè nọ́ńbà tẹlifóònù onítọ̀hùn. O wá lè padà tẹ onítọ̀hùn láago lẹ́yìn tó o bá ti rí i dájú pé ilé iṣẹ́ tàbí báńkì náà ló ni nọ́ńbà tẹlifóònù yẹn.

Àṣà kan tó dáa ni pé kó o má sọ nọ́ńbà káàdì ìrajà láwìn rẹ tàbí àṣírí ẹ mìíràn fún àjèjì tó ké sí ọ. Tẹ́nì kan bá tẹ̀ ọ́ láago tó sì lóun fẹ́ ta ohun kan tó ò nílò fún ọ, o lè sọ fún un lóhùn pẹ̀lẹ́ pé, “O ṣeun, èmi kì í bá ẹni tí mi ò mọ̀ ṣòwò lórí tẹlifóònù.” Lẹ́yìn náà gbé ọwọ́ tẹlifóònù lé e padà. Kò sídìí fún ọ láti máa bá àjèjì tó lè fẹ́ lù ọ́ ní jìbìtì sọ nǹkan tó ò nífẹ̀ẹ́ sí.

Kìkì àwọn ilé iṣẹ́ tàbí àwọn èèyàn táráyé mọ̀ bí olóòótọ́ ni kó o máa bá ṣòwò. Àwọn ilé iṣẹ́ pọ̀ tó o lè bá ṣòwò látorí tẹlifóònù tàbí látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì tówó ẹ ò sì ní há. Tó bá ṣeé ṣe, wádìí òǹtajà náà, ilé iṣẹ́ náà àti okòwò náà lọ́dọ̀ àwọn àjọ tó lè sọ fún ọ. Béèrè ìsọfúnni nípa okòwò náà, kó o sì fara balẹ̀ ka ìwé tí wọ́n bá fún ọ kó o lè rí i dájú pé kò sí má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ kankan níbẹ̀. Máà jẹ́ kí wọ́n tì ọ́ lọ́pọnpọ̀n-ọ́n tàbí kí wọ́n kán ọ lójú débi tí wà á fi fi wàdùwàdù ṣèpinnu.

Jẹ́ Kí Gbogbo Ohun Tó So Mọ́ Ọn Wà Lákọọ́lẹ̀

Gbogbo jìbìtì kọ́ ló máa ń bẹ̀rẹ̀ bíi jìbìtì. Okòwò kan tí ò ní èrú nínú lè dojú dé. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn tó wà nídìí okòwò yẹn lè bẹ̀rù kí wọ́n sì ki jìbìtì bọ̀ ọ́ kí wọ́n bàa lè rówó wọn tó wọgbó padà. Kò sí iyè méjì pé wàá ti gbọ́ nípa àwọn oníléeṣẹ́ tó ń parọ́ nípa owó tó ń wọlé fún wọn àti èrè tí wọ́n ń jẹ, tó bá sì wá di pé òwò ọ̀hún dojú dé báyìí, wọ́n á kó ìwọ̀nba owó tó kù sílẹ̀ wọ́n á sì fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ.

Kó o tó kówó lé okòwò ńlá èyíkéyìí, ó yẹ kó o ní àkọọ́lẹ̀ nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́, kó má bàa di pé jìbìtì tàbí àìgbọ́ra-ẹni yé wọ̀ ọ́. Kó o tó kọwọ́ bọ̀wé àdéhùn èyíkéyìí, rí i dájú pé ẹ kọ gbogbo ohun tó so mọ́ ìlérí tẹ́ ẹ ṣe sínú ẹ̀. Mọ̀ dájú pé bó ti wù kí òwò kan dá bíi pé ó fìdí múlẹ̀ tó, kò sí ẹni tó lè fọwọ́ ẹ̀ sọ̀yà pé ibí tẹ́ ẹ fojú sí lọ̀nà máa gbà lọ o. (Oníwàásù 9:11) Ó ṣe tán, kò sí òwò kan tí ò ní ewu tiẹ̀. Nítorí náà, ó yẹ kí iṣẹ́ olúkúlùkù àti ohun tá á fara gbá tó bá di pé òwò náà dojú dé lè wà lákọọ́lẹ̀ nínú àdéhùn tẹ́ ẹ ṣe.

Tó o bá fi àwọn ìlànà tá a jíròrò ní ṣókí yìí sọ́kàn tó o sì ń tẹ̀ lé wọn, á ṣòro díẹ̀ kó o tó lè kó sọ́wọ́ oníjìbìtì. Òwe ìgbà láéláé kan tó wà nínú Bíbélì fún wa nímọ̀ràn tó ṣeyebíye. Ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Ẹni tí gbájúẹ̀ máa ń fẹ́ gbá lẹni tó dùn-ún tàn jẹ, ẹni tá á gba gbogbo ohun tó bá sọ fún un gbọ́. Ó mà ṣe o, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í ṣe nǹkan tí ò ní jẹ́ kí wọ́n lù wọ́n ní jìbìtì.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí! April 8, 2001, ojú ìwé 26 sí 28.

b Wọ́n ṣàpèjúwe okòwò pírámíìdì bí “ètò okòwò kan nínú èyí tí àwọn èèyàn yóò ti sanwó tí wọ́n á fi dara pọ̀ mọ́ wọn kí wọ́n bàa lè láǹfààní láti mú àwọn mìíràn táwọn náà yóò sanwó wọbẹ̀.” Nínú irú okòwò bẹ́ẹ̀, kò sí ọjà tí wọ́n ń tà, kò sì sí iṣẹ́ pàtó tí wọ́n ń ṣe fáwọn èèyàn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

Bó bá dà bíi pé ohun tí wọ́n ń fi lọ̀ ẹ́ ti dára ju bó ṣe yẹ lọ, irọ́ ló sábà máa ń wà nídìí ẹ̀

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ìmọ̀ràn fún Àwọn Tó Bọ́ Sọ́wọ́ Oníjìbìtì

Ìtìjú sábà máa ń bo àwọn tí wọ́n bọ́ sọ́wọ́ oníjìbìtì, wọ́n á máa dára wọn lẹ́bi, ara á máa tì wọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n á máa bínú síra wọn. Máà dára ẹ lẹ́bi. Wọ́n gbá ẹ ni; ẹni tó gbá ẹ ló jẹ̀bi, kì í ṣe ìwọ. Tó bá jẹ́ pé o ṣàṣìṣe ni, fi ìyẹn para, kó o sì máa bá ìgbésí ayé rẹ lọ. Má ṣe rò pé nítorí pé o gọ̀ ni wọ́n fi rí ẹ gbá. Rántí pé àwọn gbájúẹ̀ ti gbá àwọn tó gbọ́n nínú, gbọ́n lẹ́yìn rí, àwọn bí olórí Orílẹ̀-èdè, àwọn ọ̀gá báńkì, àwọn ọ̀gá àgbà, àwọn ọ̀gá tó ń bójú tó ìnáwó nílé iṣẹ́, àwọn agbẹjọ́rò àtàwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn míì.

Owó tàbí nǹkan ìní nìkan kọ́ làwọn gbájúẹ̀ gbà lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n gbá, wọ́n tún gba ìdára-ẹni lójú àti iyì ara ẹni lọ́wọ́ wọn. Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan tó o pè ní “ọ̀rẹ́” ló wá lù ọ́ ní jìbìtì, ìwà ọ̀dàlẹ̀ gbáà nìyẹn. Ó máa ń dun èèyàn gan-an bí wọ́n bá gbá a. Jẹ́ kó dùn ẹ́ bó bá máa dùn ẹ̀. Ó sábà máa ń ṣèrànwọ́ téèyàn bá sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnì kan tó lè finú hàn. Àdúrà pẹ̀lú lè ṣèrànwọ́. (Fílípì 4:6-8) Mọ̀ pé bópẹ́ bóyá, wà á ní láti gbàgbé ọ̀rọ̀ àná náà ni. Kí ló dé tí wà á fi máa dára ẹ lọ́kàn rú nítorí ohun tó ti kọjá? Gbé nǹkan tó dáa síwájú ara ẹ, kó o sì ṣiṣẹ́ lórí bọ́wọ́ ẹ á ṣe tẹ̀ ẹ́.

Ṣọ́ra fún jìbìtì látọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n lè sọ pé àwọn fẹ́ bá ọ gba owó tí gbájúẹ̀ gbà lọ́wọ́ ẹ padà. Àwọn oníjìbìtì á tẹ ẹni tí wọ́n lù ní jìbìtì láago láti sọ fún un pé àwọn lè bá a ṣe é tá á fi rí owó tó pàdánù gbà padà. Wọ́n tún fẹ́ gbá onítọ̀hún lẹ́ẹ̀kan sí i ni.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]

Ọ̀nà Mẹ́fà Tí Wọ́n Gbà Ń fi Lẹ́tà Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì Lu Jìbìtì Nípa Ìpolówó Ọjà

1. Àwọn okòwò pírámíìdì: Àwọn okòwò yìí máa ń fara hàn bí àǹfààní láti rí owó rẹpẹtẹ láìlàágùn púpọ̀, nípa fífi owó táṣẹ́rẹ́ wá owó ńlá. Nínú ọ̀kan lára àwọn okòwò wọ̀nyí, wọ́n á ṣèlérí pé àwọn á fún ọ ní kọ̀ǹpútà tàbí àwọn nǹkan abánáṣiṣẹ́ mìíràn bó o bá ti lè sanwó láti dára pọ̀ mọ́ wọn tó o sì mú àwọn ẹlòmíràn wọ̀ ọ́. Irú míì tún ni ti èyí tí wọ́n ti máa ń pín lẹ́tà kiri. Ó dà bíi pé àwọn lẹ́tà tí wọ́n máa ń pín kiri kì í sábà bófin mu. Ọ̀pọ̀ àwọn tó kówó lé wọn lórí ló ti pàdánù owó wọn.

2. Okòwò àgbéléṣe: Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fi irú okòwò yìí lu jìbìtì, wọ́n á sọ fún ọ pé àwọn á fún ọ láǹfààní pé kó o máa to àwọn ẹ̀yà ara nǹkan pa pọ̀, irú bí ohun ọ̀ṣọ́ ara, àwọn nǹkan ìṣeré ọmọdé tàbí àwọn nǹkan míì tí wọn ò tíì tò. Wàá ti kówó lé àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, wàá sì tún ti fi àkókò rẹ tò wọ́n jọ kó o tó rí i pé nǹkan tó o tò pọ̀ kò ṣeé tà fáwọn tó fi iṣẹ́ náà lọ̀ ẹ́ nítorí pé kò dáa tó irú èyí tí wọ́n ń fẹ́.

3. Fífi ìlera àti oúnjẹ lu jìbìtì: Wọ́n ń polówó àwọn oògùn kan báyìí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n sọ pé wọ́n lè mú kó o fọn láìṣe pé ò ń ṣeré ìmárale tàbí pé ò ń jẹ oúnjẹ àkànṣe. Òmíràn tún wà tí wọ́n ló lè wo òkóbó, wọ́n sì tún ní àwọn nǹkan ìparun tí kì í jẹ́ kí irun já. Nígbà tí wọ́n bá ń polówó àwọn ọjà wọ̀nyí, wọ́n sábà máa ń fi ọ̀rọ̀ táwọn tó ti lò ó tó sì gbádùn rẹ̀ sọ kún ìpolówó ọjà wọn. Àwọn gbólóhùn bí “ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti jágbọ́n ẹ̀,” “ajẹ́bíidán ni,” “èròjà táyé ò mọ̀” àti “èròjà àtijọ́” sábà máa ń wà nínú ìpolówó ọjà àwọn oògùn wọ̀nyí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọjà wọ̀nyí ni kì í ṣiṣẹ́.

4. Àǹfààní láti ṣòwò: Nínú irú àwọn okòwò yìí, wọ́n sábà máa ń sọ pé owó tabua lá máa wọlé fún èèyàn lọ́dọọdún téèyàn bá ti dáwọ́ lé e, kò sì sí ewu kankan nídìí ẹ̀, bó bá tiẹ̀ wà, kò lè pọ̀. Irú okòwò báyìí ni ti ríra ìpín ìdókòwò sáwọn báńkì tó wà nílẹ̀ òkèèrè. Ohun tí wọ́n fi máa ń tan àwọn tó bá kówó lé e ni ìlérí tí wọ́n máa ń ṣe pé àwọn tó mọ àpadéludé nípa òwò ló ń bójú tó òwò tí wọ́n fowó wọn ṣe, àti pé ojú wọn tó ilé ó tó oko ọ̀ràn lórí òwò.

5. Pípa gbèsè rẹ́: Àwọn tó ń lu jìbìtì yìí á ṣèlérí pé àwọn á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pa ìsọfúnni burúkú tó wà nínú àkọsílẹ̀ rẹ rẹ́ kó o bàa lè láwọn àǹfààní bíi níní káàdì ìrajà láwìn, ẹ̀yáwó ra mọ́tò tàbí rírí iṣẹ́ ṣe. Láìka gbogbo bí wọ́n ṣe lérí léka sí, àwọn tó wà nídìí ẹ̀ ò lè ṣe ohun tí wọ́n láwọn á ṣe.

6. Ẹ̀bùn àǹfààní lílo àkókò ìsinmi: Wọ́n lè kọ lẹ́tà E-mail sí ọ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti fi kí ọ kú oríire ti àǹfààní tó tọ́ sí ọ láti lọ fi owó ìdákọmu lo àkókò ìsinmi rẹ. Àwọn kan lè sọ pé ìwọ ni wọ́n dìídì mú. Fi sọ́kàn pé wọ́n lè ti sọ nǹkan kan náà fún ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì, ibi tí wọ́n sì máa fi ọ́ sí ò ní dáa tó ibi tí wọ́n polówó ẹ̀ fún ọ.

[Credit Line]

Orísun ìsọfúnni: Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìṣòwò Nílẹ̀ Amẹ́ríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwọn okòwò pírámíìdì máa ń pàpà forí ṣánpọ́n ni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kó o tó kọwọ́ bọ̀wé àdéhùn èyíkéyìí, rí i dájú pé ẹ kọ gbogbo ohun tó so mọ́ ìlérí tẹ́ ẹ ṣe sínú ẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́