Jìbìtì Gbayé Kan
WAYNE wuyì lọ́kùnrin, kò lè sọ̀rọ̀ ẹnu ẹ̀ tán, ó jọ irú ẹni tó wu Karen láti fi ṣọkọ. Karen sọ pé: “Irú ẹni tí mo ti ń gbàdúrà pé kí n rí fẹ́ gan-an nìyí. Gbogbo àwọn tó ń rí wa ló sọ pé gẹ́gẹ́ wa ṣe gẹ́gẹ́. Ó ń fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ mi torítọrùn.”
Àmọ́, ìṣòro kan wà o. Wayne sọ fún Karen pé ipò kẹta lòun wà sí ọ̀gá àgbà Àjọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Ó lóun fẹ́ fiṣẹ́ yẹn sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ náà ò gbà. Wọ́n ló ti mọ àṣírí àwọn jù. Wọ́n láwọn á pa á ni! Tọkọtaya yìí bá gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dọ́gbọ́n kan. Wọ́n láwọn á ṣègbéyàwó, àwọn á pa gbogbo owó àwọn pọ̀, àwọn á sá kúrò ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, àwọn á sì sá lọ sí orílẹ̀-èdè Kánádà. Karen ta ilé ẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní pátá, ó sì kó owó tó gbà lórí ẹ̀ lé Wayne lọ́wọ́.
Wọ́n ṣègbéyàwó bí wọ́n ṣe sọ. Wayne sá kúrò lórílẹ̀-èdè náà, àmọ́ kò mú Karen dání, bó ṣe já a jù sílẹ̀ nìyẹn, gbogbo owó tó sì kù tí Karen ní sí báńkì ò tó dọ́là mẹ́fà. Ìgbà náà ló tó yé e pé irọ́ gbuu ni gbogbo nǹkan tí ọkùnrin yẹn ń sọ fún òun, kó bàa lè rí òun gbá ló ṣe ń pa adúrú irọ́ yẹn. Àfi bí òṣèré orí ìtàgé, Wayne ṣe bí èèyàn gidi, ó ń hu irú ìwà tí inú Karen á dùn sí. Òjé ni gbogbo ohun tó sọ fún ún nípa irú ẹni tó lóun jẹ́, ohun tó lóun fẹ́ ṣe, ìwà tó ń hù àti ìfẹ́ tó lóun ní sí i, ọgbọ́n kó bà á lè gbọ́kàn lé e ni, nígbà tó sì gbọ́kàn lé e tán, ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba dọ́là ló fi gbára. Ọlọ́pàá kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà dà á lọ́kàn rú pátápátá. Ká tiẹ̀ pa ti owó tó gbà lọ́wọ́ ẹ̀ tì, ìdààmú ọkàn tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń kó bá èèyàn kò ṣeé fẹnu sọ rárá.”
Karen sọ pé: “Gbogbo nǹkan polúkúrúmuṣu mọ́ mi lọ́kàn. Àṣé kì í ṣe irú ẹni tó lóun jẹ́ ló jẹ́.”
Àìmọye èèyàn káàkiri ayé bíi ti Karen ni wọ́n ń lù ní jìbìtì. Kò sí ẹni tó mọ iye owó táwọn gbájúẹ̀ ti gbà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn, àmọ́ wọ́n ṣírò ẹ̀ pé á tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún bílíọ̀nù dọ́là, iye owó yìí sì ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún ni. Yàtọ̀ sí ti olówó dé, ó máa ń dá ọgbẹ́ sáwọn èèyàn lọ́kàn tí wọ́n bá rí i pé ẹni kan gbá àwọn, kó tún wá lọ jẹ́ ẹnì kan táwọn gbọ́kàn lé ló ṣe irú ẹ̀.
Kó O Má Ti Jẹ́ Kí Wọ́n Rí Ẹ Gbá Ló Dáa Jù
Ohun tó ń jẹ́ jìbìtì ni “ọgbọ́n àrékendá tàbí ẹ̀tàn láti rówó nípa dídíbọ́n, píparọ́ gbowó tàbí ṣíṣèlérí.” Ó máa ń dunni pé kì í sábà sí nǹkan tí wọ́n lè fi ẹni tó lu jìbìtì ṣe nítorí pé ó máa ń sábà ṣòro láti fẹ̀rí ẹ̀ hàn pé ẹni tó lu jìbìtì mọ̀ọ́mọ̀ tan ẹni tó lù ní jìbìtì ni. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn gbájúẹ̀ mọ òfin wọ́n sì mọ ibi táwọn lè rí sá sí lábẹ́ òfin, ìyẹn ni pé wọ́n mọ báwọn ṣe lè lu jìbìtì tí ẹjọ́ ẹ̀ á ṣòro láti dá ní kóòtù tàbí tí ò tiẹ̀ ní lẹ́jọ́ nínú. Síwájú sí i, béèyàn bá tiẹ̀ fẹ̀sùn ọ̀daràn kan gbájúẹ̀, owó lá jẹ kò ní jẹ àgbàdo, àkókò díẹ̀ kọ́ ló sì máa gbà. Àwọn tí wọ́n sábà máa ń jù sẹ́wọ̀n nítorí nǹkan tí wọ́n ṣe sábà máa ń jẹ́ àwọn tó jí ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó dọ́là tàbí àwọn tó ṣe nǹkan tó burú débi tí gbogbo èèyàn á fi mọ̀ sí i. Bọ́wọ́ bá tiẹ̀ tẹ gbájúẹ̀ tí wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́, o ṣeé ṣe kó ti náwó tó gbà tàbí kó ti fi pamọ́. Ìdí rèé táwọn tí wọ́n bá lù ní jìbìtì kì í fi í rówó wọn gbà padà mọ́.
Lọ́rọ̀ kan ṣà, bí gbájúẹ̀ bá ti gbá ọ, ó lè máà sí nǹkan tó o lè ṣe láti rí owó ẹ gbà padà mọ́. Ó dáa kó o má ti kó sọ́wọ́ àwọn gbájúẹ̀ ju kó o ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá bó o ṣe máa rówó ẹ gbà padà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbá ọ. Ọkùnrin ọlọgbọ́n kan sọ lọ́jọ́ tó ti pẹ́ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Àpilẹ̀kọ tó kàn lẹ́yìn eléyìí á fi ọ̀nà tí wàá gbé e gbà tí wọn ò fi ní rí ọ gbá hàn ọ́.