ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 11/8 ojú ìwé 3
  • Àrùn Aids—Àjàkálẹ̀ Náà Ń Jà Nìṣó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àrùn Aids—Àjàkálẹ̀ Náà Ń Jà Nìṣó
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ìrètí Ọjọ́ Iwájú Nípa Àrùn Aids?
    Jí!—1998
  • “Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Burú Jù Lọ Táráyé Ò Rírú Ẹ̀ Rí”
    Jí!—2002
  • Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Àrùn Aids
    Jí!—1998
  • Wọn Kò Bẹ̀rù Òpin Ayé Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 11/8 ojú ìwé 3

Àrùn Aids—Àjàkálẹ̀ Náà Ń Jà Nìṣó

KAREN gbé ìhà ìwọ̀ oòrùn United States dàgbà.a Bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere nígbà èwe rẹ̀. Ní 1984, nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún 23, òun àti Bill, tó ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún ọdún méjì péré, ṣègbéyàwó. Wọ́n bí ọmọ méjì, ọkùnrin kan àti obìnrin kan.

Nígbà tó fi di 1991, wọ́n ti nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an, wọ́n sì ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀. Nígbà tí ọdún yẹn ń parí lọ, àmì funfun kan yọ ní ahọ́n Bill, kò sì pa rẹ́. Ó lọ rí dókítà.

Láìpẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, Karen àti àwọn ọmọ ń gbá ìràwé jọ níta. Bill jókòó lórí àtẹ̀gùn àbáwọlé, ó sì pe Karen pé kó wá jókòó ti òun. Ó fi ọwọ́ rẹ̀ kọ́ Karen níbàdí, ó sì wí fún un pẹ̀lú omi lójú pé, òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, òun sì fẹ́ láti máa bá a gbé títí láé. Kí ló wá fa omi lójú? Dókítà lérò pé Bill ní fáírọ́ọ̀sì HIV tí ń di àrùn AIDS.

Wọ́n ṣe àyẹ̀wò fún ìdílé náà. Bill àti Karen sì ní fáírọ́ọ̀sì náà. Bill ti ní in kí ó tó di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà; òun ló kó o ran Karen. Àwọn ọmọ kò ní fáírọ́ọ̀sì náà lára. Láàárín ọdún mẹ́ta, Bill kú. Karen wí pé: “N ò mọ bí mo ṣe lè ṣàlàyé bó ti rí lára, pé kí ènìyàn máa wo ẹni tó nífẹ̀ẹ́, tó sì fẹ́ máa bá gbé títí ayé, tó rẹwà nígbà kan rí, bí ó ti ń daláàárẹ̀ díẹ̀díẹ̀, tó sì rù kan egungun. Lórulóru ni mo ń sunkún. Ó ku oṣù mẹ́ta kí ó pé ọdún mẹ́wàá tí a ṣègbéyàwó ló kú. Baba dáadáa ni, ọkọ rere sì ni pẹ̀lú.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, dókítà kan ti sọ pé Karen yóò kú tẹ̀ lé ọkọ rẹ̀ láìpẹ́, ó ṣì wà láàyè síbẹ̀. Àrùn náà ti dé ìpele ìbẹ̀rẹ̀ àrùn AIDS.

Karen wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú nǹkan bí 30 mílíọ̀nù ènìyàn tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV òun àrùn AIDS ní báyìí ni, iye kan tó pọ̀ ju àpapọ̀ àwọn ará orílẹ̀-èdè Ireland, Ọsirélíà, àti Paraguay. Ìfojúdíwọ̀n fi hàn pé mílíọ̀nù 21 nínú wọn ló wà ní Áfíríkà. Bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe wí, nígbà tí ọ̀rúndún tí ń bọ̀ bá fi bẹ̀rẹ̀, iye náà lè ti pọ̀ tó 40 mílíọ̀nù. Ìròyìn àjọ UN kan sọ pé àrùn náà ti ń ta àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tó le jù lọ nínú ìtàn yọ. Lára àwọn àgbàlagbà ọlọ́dún 15 sí 49 tí ń ní ìbálòpọ̀ lágbàáyé, ìpín kan nínú 100 wọn ti ní fáírọ́ọ̀sì HIV ní báyìí. Ìpín kan péré nínú 10 lára wọn ló mọ̀ pé àwọ́n ti kó àrùn. Ní àwọn àgbègbè kan ní Áfíríkà, ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà ló ti kó o.

Láti ìgbà tí àjàkálẹ̀ àrùn AIDS ti bẹ̀rẹ̀ ní 1981, a fojú díwọ̀n pé mílíọ̀nù 11.7 ènìyàn ló ti pa. A ti fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ní 1997 nìkan, nǹkan bí mílíọ̀nù 2.3 ló pa. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ohun tuntun ń ṣẹlẹ̀ tí ń mú kí àwọn ènìyàn gbà pé, a óò ṣẹ́gun àrùn AIDS. Láàárín àwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, iye àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kó àrùn AIDS dín kù ní àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀. Láfikún sí i, àwọn egbòogi tó ṣeé ṣe kó ṣàṣeyọrí ń fún àwọn tó ti ní fáírọ́ọ̀sì HIV nírètí ìlera àti ẹ̀mí gígùn.

Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrùn AIDS? Àwọn ohun tuntun wo ló wà fún ìṣètọ́jú àti àjẹsára? Ǹjẹ́ a óò rẹ́yìn àrùn náà? A óò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́