ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 11/8 ojú ìwé 8-9
  • Kí Ni Ìrètí Ọjọ́ Iwájú Nípa Àrùn Aids?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ìrètí Ọjọ́ Iwájú Nípa Àrùn Aids?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojútùú Kan Yóò Wà
  • Akitiyan Tí Wọ́n Ti Ṣe Láti Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì
    Jí!—2004
  • Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Àrùn Aids
    Jí!—1998
  • Aráyé Nílò Oògùn Éèdì Báyìíbáyìí!
    Jí!—2004
  • Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 11/8 ojú ìwé 8-9

Kí Ni Ìrètí Ọjọ́ Iwájú Nípa Àrùn Aids?

YÀTỌ̀ sí àìsí egbòogi fún ìwòsàn tàbí ìdènà fáírọ́ọ̀sì HIV, àwọn kókó mìíràn ń ṣèdíwọ́ fún kíkápá àrùn náà. Ọ̀kan nínú wọn ni pé, ó tẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí kò ti fẹ́ yí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn padà lọ́rùn láti fara wewu kíkó àrùn. Bí àpẹẹrẹ, ní United States, iye àwọn tí ń kó àrùn náà kò lé, kò dín, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn tó ti ní àrùn AIDS tó hàn gbangba dín kù. Bí àjọ akóròyìnjọ Associated Press ṣe sọ, ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn kò tẹ̀ lé ìkìlọ̀ tí a ń ṣe láti dènà rẹ̀.”

Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lágbàáyé, tí a ròyìn pé nǹkan bí ìpín 93 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV wà, àwọn ìṣòro mìíràn wà tí ń gbógun ti bíbá àrùn náà jà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè náà ló tálákà jù láti fún àwọn ènìyàn ní ìwọ̀n àbójútó ìlera ṣíṣekókó. Ká tilẹ̀ wá ní àwọn egbòogi tuntun náà wà ní àwọn ilẹ̀ náà—tí wọn kò sì sí níbi púpọ̀ jù—owó tí wọn yóò fi rà wọ́n lọ́dún ju iye owó tó lè wọlé fún ọ̀pọ̀ ènìyàn ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn lọ!

Síbẹ̀, ẹ jẹ́ ká gbà pé a tilẹ̀ ṣe egbòogi tuntun kan, tí owó rẹ̀ kò pọ̀, tí yóò sì wo àrùn náà sàn ní gidi. Ǹjẹ́ irú egbòogi náà yóò dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó nílò rẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó máà rí bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ètò-Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ṣe sọ, nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́rin ni àwọn ọmọdé tí àwọn àrùn márùn-ún tó ṣeé dènà nípa gbígba àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára olówó pọ́ọ́kú, tó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ń pa lọ́dọọdún.

Àwọn tó wá ní àrùn, tí wọ́n ń gbé ní orílẹ̀-èdè tí wọn kò ti lè rí oògùn ńkọ́? Ruth Mota, láti Àjọ Ètò Ìlera Àgbáyé ní Santa Cruz, California, ti ṣètò ìpolongo ìdènà àti ìtọ́jú fáírọ́ọ̀sì HIV ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ó wí pé: “Láti inú ìrírí mi, bí níní egbòogi lárọ̀ọ́wọ́tó ṣe ṣe pàtàkì tó ni níní ẹ̀mí nǹkan yóò dára náà ṣe ṣe pàtàkì tó. Mo mọ àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ní fáírọ́ọ̀sì HIV láàárín ọdún 10 sí 15, síbẹ̀, tí wọn kò lo egbòogi kankan. Lílo egbòogi ṣàǹfààní, àmọ́ ìwòsàn ju kíkó oògùn mì lásán lọ. Ó kan ìrònú ẹni, ìtìlẹ́yìn àwùjọ ènìyàn, ipò tẹ̀mí, àti oúnjẹ jíjẹ.”

Ojútùú Kan Yóò Wà

Ǹjẹ́ ìdí kankan wà láti gbà pé a óò ṣẹ́gun àrùn AIDS lọ́jọ́ kan ṣáá? Dájúdájú, ó wà. Ìrètí dídára jù wà nínú ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń pè ní Àdúrà Olúwa tàbí Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run (Paternoster). Nínú àdúrà yẹn tí a kọ sínú ìwé Mátíù nínú Bíbélì, a ń bẹ Ọlọ́run pé kí ìfẹ́ rẹ̀ di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé bí ó ti jẹ́ nínú ọ̀run. (Mátíù 6:9, 10) Kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pé kí àìsàn máa bá ènìyàn jà títí láé. Ọlọ́run yóò dáhùn àdúrà yẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, yóò mú òpin bá àrùn AIDS àti gbogbo àrùn mìíràn tí ń bá ènìyàn fínra. Nígbà náà, “kò [ní] . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

Ní báyìí ná, ọ̀nà dídára jù ni dídènà àrùn. Ní ti ọ̀pọ̀ àrùn, ọ̀nà méjì ló wà: O lè dènà wọn tàbí bó bá ṣeé ṣe, o lè wò wọ́n sàn. Ní ti fáírọ́ọ̀sì HIV, kò rí bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé dènà, àmọ́ ní báyìí ná, kò ṣeé wò sàn. Ǹjẹ́ ìdí kankan wà fún ọ láti máa fi ìwàláàyè rẹ wewu? Ó dájú pé ìdènà sàn ju àìsí ìwòsàn lọ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

“Ìwòsàn ju kíkó oògùn mì lásán lọ. Ó kan ìrònú ẹni, ìtìlẹ́yìn àwùjọ ènìyàn, ipò tẹ̀mí, àti oúnjẹ jíjẹ.” —Ruth Mota

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

“Ìjọ Náà Ṣe Dáradára Lọ́nà Àrà Ọ̀tọ̀”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Ìyá Karen tí a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ bí ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò ṣe hùwà nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Karen àti Bill ní fáírọ́ọ̀sì HIV. Ó wí pé: “Ìjọ náà ṣe dáradára lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Nígbà tí òtútù àyà mú Bill, ara Karen fúnra rẹ̀ kò yá, ó sì tún ń gbìyànjú láti bójú tó òun àti àwọn ọmọ. Àwọn ará bá wọn tún ilé ṣe, wọ́n tún ọkọ̀ wọn ṣe, wọ́n sì bá wọn fọ àwọn aṣọ wọn. Wọ́n bá wọn bójú tó àwọn ọ̀ràn òfin àti kíkó lọ sí ilé mìíràn. Wọ́n bá wọn ra oúnjẹ, wọ́n sì gbọ́únjẹ fún wọn. Wọ́n ṣàfihàn ojúlówó ìtìlẹ́yìn ti ìmọ̀lára, ti ẹ̀mí, àti ti ohun ìní.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ìṣòtítọ́ nínú ipò ìgbéyàwó lè dènà kíkó fáírọ́ọ̀sì HIV

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́