Ẹranko Kudu Yìí Rántí
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ
ARẸWÀ akọ ẹranko kudu, oríṣi àgbọ̀nrín kan tí ó ní ìwo lílọ́ àti etí gbògàgboga, máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó 150 sẹ̀ǹtímítà láti èjìká rẹ̀ nígbà tí ó bá dàgbà tán. Etí rẹ̀ títóbi ni a fi máa ń dá abo rẹ̀ mọ̀, níwọ̀n bí kò ti sábà máa ń ní ìwo. Ẹranko onítìjú ni kudu, ó sábà máa ń wà lójúfò, ó sì máa ń múra tán láti sá lọ fara pamọ́. Nítorí èyí, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Karen ní Zimbabwe gbàfiyèsí.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn African Wildlife ṣe sọ, a dá abo ọmọ kudu kékeré kan, tí a rí níbi tí ó ti lọ́ mọ́ ọgbà oníwáyà kan, sílẹ̀, a sì fi fún Karen, tí ó fi oúnjẹ inú ìgò bọ́ ọ fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan. Ó dàgbà dáadáa, ó sì wà ní sàkáání oko ìpèsè oúnjẹ tí ń ti ara ẹran jáde tí Karen àti ìdílé rẹ̀ ń gbé, ó sì máa ń bá àwọn ọmọdé àti àwọn ajá ṣeré. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ń sú wọgbó lọ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ títí di ìgbà tí a kò fi rí i nítòsí oko náà mọ́, nígbà tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dàgbà tán.
Nígbà tí Karen ń wakọ̀ lọ ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn náà, ó yà á lẹ́nu láti rí aboyún kudu kan tí kò sá wọgbó lọ nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ ń bọ̀. Nígbà tí ó sì tilẹ̀ ń rìn sún mọ́ ọn, kò sá lọ. Nígbà yẹn, ó mọ̀ pé, ó ní láti jẹ́ ẹranko kan náà tí òún ti fi oúnjẹ inú ìgò bọ́ nìyí, nítorí náà ó ń sọ̀rọ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ bí ó ti rọra ń sún mọ́ ọn. Ẹranko náà mọ̀ ọ́n pẹ̀lú, nítorí pé ó dorí kodò, o sí fimú rò ó lára, nígbà tí ó gbà á láyè láti fọwọ́ gbá òun mọ́ra!
Ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, ẹranko náà tún wà lẹ́bàá ọ̀nà—lọ́tẹ̀ yìí, pẹ̀lú ọmọ kékeré kan. Karen rò pé, ó ní láti jẹ́ pé ẹranko náà, tí ó gba òun láyè láti bá a ṣeré, wáá fi ọmọ rẹ̀ kékeré hàn ni. Irú ohun kan náà ṣẹlẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà tí ó jọ pé ẹranko náà pilẹ̀ wáá dúró de Karen ni.
Oṣù bíi mélòó kan tún kọjá, àwọn alágbàṣe kán sì ròyìn pé àwọ́n rí kudu kan náà yìí pẹ̀lú okùn lọ́rùn. Wọ́n ti gbìyànjú láti sún mọ́ ọn, kí wọ́n sì bá a mú okùn ọrùn rẹ̀ kúrò, ṣùgbọ́n ó sá lọ. Nítorí náà, Karen lọ wá a nínú igbó, ó sì ń pè é bí ó ti ń lọ. Láìpẹ́, gannboro ló yọ síwájú rẹ̀. Pẹ̀lú ìrònú pípéye, Karen ti mú búrẹ́dì díẹ̀ dání, èyí tí ẹranko náà fẹ́ràn gan-an tẹ́lẹ̀, nígbà tí ó sì ń fún un ní oúnjẹ àdídùn yìí, ọkọ Karen gé okùn ọrùn ẹranko náà kúrò.
Ìdè híhàn gbangba tí ó wà pẹ́ bẹ́ẹ̀ láàárín ènìyàn àti ẹranko ìgbẹ́ mú ìdùnnú púpọ̀ wá fún ìdílé yìí.