Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Ọmọ ọdún 16 ni mí, mo sì fẹ́ẹ́ dúpẹ́ ní ọwọ́ yín fún àpilẹ̀kọ náà nípa Àǹtí Louie, tí ó ní àkọlé “Ọ̀rẹ́ Mi Ọ̀wọ́n.” (February 22, 1996) Fọ́tò náà fà mí mọ́ra, mo sì ka àpilẹ̀kọ náà lọ́gán. Mo ní ìjákulẹ̀ díẹ̀ nítorí pé púpọ̀ jù lọ àwọn ọ̀rẹ́ mi ni kì í ṣe ojúlówó ọ̀rẹ́. Ní ti gidi, àpilẹ̀kọ náà fún mi ní ìṣírí láti bá àwọn ènìyàn tí ó dàgbà jù mí lọ dọ́rẹ̀ẹ́.
L. N., Ítálì
Eré Ìdárayá ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Àwọn Eré Ìdárayá Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́—Wọ́n Ha Dára fún Mi Bí?” (February 22, 1996) Ó jọ pé èmi gan-an ni ẹ kọ ọ́ fún. Ó mú kí n mọ̀ pé, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé mo ti ń jọ́sìn àwọn eléré ìdárayá títí di ìsinsìnyí. Àpilẹ̀kọ náà tún ràn mí lọ́wọ́ láti mọrírì rẹ̀ pé “ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti ara ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀.”—Tímótì Kìíní 4:8.
Y. T., Japan
Ṣèbé Mo máa ń rò pé àwọn ṣèbé jẹ́ olubi ẹ̀dá afàyàfà tí ó yẹ kí a pa run. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo ka àpilẹ̀kọ náà, “Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Láti Wo Ṣèbé?” (March 22, 1996), mo wáá ní ojú ìwòye tí ó yàtọ̀ nípa wọn nísinsìnyí. Ẹ ṣeun fún dídá àwọn ènìyàn bíi tèmi ní ìdè ní ọwọ́ àwọn èrò òdì nípa àwọn ẹ̀dá afàyàfà tí ó fani mọ́ra wọ̀nyí.
P. E., Nàìjíríà
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé agbègbè àrọko kan, ní ibi tí àwọn ejò gbé pọ̀ gan-an ni a ti tọ́ mi dàgbà, n kò mọ nǹkan púpọ̀ nípa wọn ní ti gidi. Kíkà nípa bí ṣèbé ṣe ń lo ìṣọ́ra ní yíyẹra fún ìkòlójú ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ Jésù ní Mátíù 10:16 pé: “Ẹ jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò.”
J. F. S., Brazil
Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan Ẹ ṣeun fún ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà “Ṣíṣe Ayédèrú Nǹkan—Ìṣòro Gbogbo Àgbáyé.” (March 22, 1996) Mo ń ṣiṣẹ́ ní báńkì kan, mo sì parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan nípa dídènà jìbìtì. Ìsọfúnni tí ẹ pèsè ni ó bá àkókò mu jù lọ. Ẹ ṣeun fún gbogbo àpilẹ̀kọ yín tí ó ṣeé gbára lé, tí ó sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.
B. P., United States
Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ kaṣíà ní báńkì kan, mo mọrírì àwọn àpilẹ̀kọ náà. Ní ìyàtọ̀ sí àwọn ìwé àtìgbàdégbà kan tí ń tẹ àwọn ìsọfúnni èké jáde láti ru ìmọ̀lára sókè, ẹ tẹ ojú ìwòye tí kò fì sí ibì kan jáde. Báńkì tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ń fún àwọn òǹtajà nímọ̀ràn yìí: ‘Tọ́jú agánrán ẹ̀dà owó kọ̀ọ̀kan. Bí o bá ń ṣe iyè méjì, fi èyí tí ń ṣe ọ́ ní iyè méjì (bébà, òǹtẹ̀, àti àwọ̀) wé èyí tí ó jẹ́ ojúlówó.’
L. G., ilẹ̀ Faransé
Ìmúwàdéédéé Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ̀bùn Ìmúwàdéédéé Tí Ọlọrun Fún Wa.” (March 22, 1996) Ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, mo ní àrùn vertigo fún ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ. Ní àkọ́kọ́, mo rò pé èmi ni ẹni tí àrùn yìí kọ́kọ́ ṣe, nítorí pé n kò gbọ́ nípa rẹ̀ rí. Àpilẹ̀kọ yín tù mí nínú, ní fífi hàn pé àwọn ẹlòmíràn ti ní ìṣòro yìí rí, wọ́n sì ti borí rẹ̀.
D. P., Jàmáíkà
Àwọn Eṣinṣin Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ tí ó wọni lọ́kàn jù lọ náà, “Àwọn Eṣinṣin Akóninírìíra Wọ̀nyẹn—Wọ́n Ha Wúlò Ju Bí O Ti Lérò Lọ Bí?” (March 22, 1996) Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó kọjá, mo lo àkókò díẹ̀ ní ṣíṣe ìwádìí nípa eṣinṣin, ṣùgbọ́n n kò rí ìsọfúnni tí ń tẹ́ni lọ́rùn kankan. Mo rò pé wọ́n máa ń dani láàmú tàbí pé wọ́n ya ọ̀bùn, bí àpilẹ̀kọ náà ṣe sọ. Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo mọ̀ pé wọ́n ń ṣe ohun kan tí ó wúlò—bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Ẹlẹ́dàá wa kì bá tí dá wọn. Mo mọrírì àwọn àpilẹ̀kọ tí ẹ ń tẹ̀ jáde gidigidi.
T. G., Ítálì
Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka àpilẹ̀kọ nípa àwọn eṣinṣin náà tán ni, mo sì ní láti kọ̀wé. Ní ìgbà púpọ̀ ni mo ti fi bá àwọn ènìyàn ṣe àwàdà pé èmi yóò fẹ́ láti mọ ohun tí Jèhófà ń rò lọ́kàn nígbà tí ó ń dá ẹ̀dá oníwàhálà yìí. Ní báyìí, mo wáá mọ̀ pé a kò fi eṣinṣin sí ilẹ̀ ayé láti wulẹ̀ máa dà wá láàmú ṣáá!
P. P., United States