ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 12/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkédàárò Nítorí Àdánù Ìwà Rere
  • Ewu Tẹlifóònù Alágbèéká
  • Àwọn Obìnrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Anìkàngbé Kọ́ Ìjà Karate
  • Oòrùn Ń Sọ Omi Di Mímọ́ Tónítóní
  • Àwọn Ọmọdé Tí Másùnmáwo Kì Mọ́lẹ̀
  • Wíwà Ní Ipò Ọ̀jáfáfá fún Ìgbà Pípẹ́
  • Àrùn Buffalo Pox Kọ Lu Íńdíà
  • Ariwo Ìdáníjì Èké Mìíràn
  • Ọ̀nà Omi Tuntun
  • Ìdíyelé Pi
  • Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1999
Jí!—1996
g96 12/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Kíkédàárò Nítorí Àdánù Ìwà Rere

Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé: ‘Ìwà àìlẹ́kọ̀ọ́, ìwà àìlọ́wọ̀, ìmúra jákujàku tàbí lọ́nà àìbìkítà, bíbúra, ìyannijẹ, àti lílo ipá ẹhànnà ti sọ ìgbésí ayé di èyí tí kò dáni lójú, tí kò rọrùn, tí kò tuni lára.’ Èyí tí ó wọ́pọ̀ jù lọ nínú ìwà àìlẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilẹ̀ kan ni mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàìka ìrísí ara ẹni sí. Athena Leoussi, ti Yunifásítì Reading sọ pé: “Àwọn jákẹ́ẹ̀tì aláwọ, ìwérí àwọn agbábẹ́lẹ̀ jagun, imú lílu, bàtà gìrìwò aláwọ tí ó lónìíní ìdè àti ìfínra jákujàku jẹ́ ìpolongo ogun.” Gẹ́gẹ́ bí Leoussi ti sọ, irú àwọn aṣọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àmì híhàn kedere ti rírí àwọn ẹlòmíràn fín. Ìwé ìròyìn The Times sọ pé, ‘ẹ̀kọ́ ilé, ìkálọ́wọ́kò, àti àṣẹ ìtọ́ni tí ń dín kù ń halẹ̀ mọ́ àwùjọ bóyá ju bí ìwà ọ̀daràn ti ṣe lọ pàápàá.’ Nígbà náà, kí ni ojútùú rẹ̀? Ìwé ìròyìn náà sọ pé, ìwà rere ni a gbọ́dọ̀ “gbé kalẹ̀ láàárín ìdílé. A kò lè ṣàlàyé wọn lásán fún àwọn ọmọ, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ kọ́ wọn pẹ̀lú àpẹẹrẹ.”

Ewu Tẹlifóònù Alágbèéká

Ìwádìí àìpẹ́ kan ní Japan ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìgbì rédíò tí ń jáde láti inú tẹlifóònù alágbèéká náà lè fa ìṣòro líle koko fún àwọn irin iṣẹ́ ìṣègùn ilé ìwòsàn. Ìwé agbéròyìnjáde Asahi Evening News sọ pé: “Nínú àyẹ̀wò kan, ẹ̀rọ aṣàkóso ìgbékiri ẹ̀jẹ̀ nígbà iṣẹ́ abẹ ọkàn-àyà kan dáwọ́ iṣẹ́ dúró nígbà tí wọ́n lo tẹlifóònù alágbèéká kan ní sẹ̀ǹtímítà 45 [íǹṣì 18] sí ibẹ̀.” Àwọn olùṣèwádìí tún ṣàwárí pé àwọn àmì ìdáníjì dún lára àwọn ẹ̀rọ ìfamisínilára àti àwọn ẹ̀rọ tí ń pèsè oògùn adènà àrùn jẹjẹrẹ nígbà tí wọ́n lo tẹlifóònù alágbèéká kan ní ibi tí ó fi sẹ̀ǹtímítà 76 jìnnà sí ẹ̀rọ náà. Ó nípa lórí àwọn ẹ̀rọ X ray àti àwọn ẹ̀rọ adíwọ̀n ìgalára pẹ̀lú. Lójú àwọn àwárí yìí, Ilé Iṣẹ́ Ìfìwéránṣẹ́ àti Ìfìsọfúnniránṣẹ́ dámọ̀ràn pé kí a má ṣe máa mú tẹlifóònù alágbèéká wọ iyàrá iṣẹ́ abẹ àti ti ẹ̀ka ìtọ́jú lójú méjèèjì. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti fi hàn, nǹkan bí ilé ìwòsàn 25 ní Tokyo ti ṣòfin lórí lílo àwọn tẹlifóònù alágbèéká, tí 12 lára wọ́n sì fòfin de àwọn tẹlifóònù alágbèéká pátápátá.

Àwọn Obìnrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Anìkàngbé Kọ́ Ìjà Karate

Nítorí pé àwọn obìnrin ń kojú ewu ìwà ipá tí ń pọ̀ sí i, àwùjọ àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé kan ní Ibùjókòó Àlùfáà ti Anne Mímọ́ ní Madhavaram, Ìpínlẹ̀ Tamil Nadu, Gúúsù Íńdíà, ti bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìjà karate. Shihan Hussaini, ààrẹ Ẹgbẹ́ Karate Isshinryu Àpapọ̀ Íńdíà, sọ pé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé náà ṣe dáradára ju àwọn obìnrin mìíràn tí òún ti dá lẹ́kọ̀ọ́ láàárín ọdún 24 tí òún ti ń ṣe olùdánilẹ́kọ̀ọ́ ìjà karate lọ. Ó sọ pé: ‘Mo lérò pé ó ní nǹkan láti ṣe pẹ̀lú agbára fífara sin àti ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ní.’ Ohun èèlò kan tí wọ́n kọ́ àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé náà láti máa lò ń jẹ́ sein ko. Wọ́n ṣe é bí àgbélébùú, Hussaini sì sọ pé, nípa “lílo ohun èèlò yìí, ó tilẹ̀ ṣeé ṣe láti pa afipákọluni kan.”

Oòrùn Ń Sọ Omi Di Mímọ́ Tónítóní

Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail, ti Toronto sọ pé: “Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ará Kánádà ti ṣàwárí pé oòrùn lásán ń sọ àwọn èròjà mẹ́kúrì tí ó lè ṣèpalára nínú omi di aláìlágbára.” Àwọn olùṣèwádìí láti Yunifásítì Manitoba àti Àjọ Freshwater ti Winnipeg ṣàwárí pé gbígbé omi adágún tí èròjà olóró methylmercury ti sọ di eléèérí sínú oòrùn fún ọ̀sẹ̀ kan péré yọrí sí dídín ìpele èròjà olóró methylmercury kù ní ìwọ̀n ìpín 40 sí 66 nínú ọgọ́rùn-ún. Ìwé agbéròyìnjáde Globe sọ pé: “Kí ó tó di pé wọ́n ṣe àṣeyẹ̀wò yìí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà gbọ́ pé àwọn kòkòrò àrùn nìkan ní ń sọ èròjà olóró methylmercury di aláìlágbára nínú omi adágún. Ìròyìn náà tún ṣàkíyèsí pé ó jọ pé oòrùn ń “fi ìgbà 350 yára ṣiṣẹ́ ju àwọn ọ̀nà tí àwọn kòkòrò àrùn tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí ń gbà ṣiṣẹ́.”

Àwọn Ọmọdé Tí Másùnmáwo Kì Mọ́lẹ̀

Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Brazil náà, O Estado de S. Paulo, ròyìn pé iye àwọn ọmọdé tí wọ́n ní àrùn ọgbẹ́ inú àti àrùn ìwúlé awọfẹ́lẹ́ inú àpòlúkù ti di ìlọ́po méjì láàárín ọdún mẹ́wàá. Àwọn àwárí tí a gbé karí ìwádìí kan tí Yunifásítì São Paulo ṣe, tọ́ka sí másùnmáwo èrò ìmọ̀lára gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn lájorí okùnfà rẹ̀. Onímọ̀ àrùn inú àti ìfun Dorina Barbieri sọ pé: “Àwọn ìkìmọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà fara hàn nínú bí èrò ìmọ̀lára ọmọ náà ṣe rí, . . . débi pé ó ṣokùnfà àrùn.” Ìwé agbéròyìnjáde náà to àwọn okùnfà bíi mélòó kan tí ó pa kún másùnmáwo ìgbà ọmọdé, tí ó ní nínú, ìjà, ìjàm̀bá tàbí ikú nínú ìdílé, ìrinkinkin mọ́ ìjẹ́pípé, oúnjẹ tí èròjà rẹ̀ kò pé, ẹ̀mí ìbánidíje, àti àìní àkókò ìgbafẹ́.

Wíwà Ní Ipò Ọ̀jáfáfá fún Ìgbà Pípẹ́

Ṣe o fẹ́ kí agbára ìrònú rẹ jí pépé títí di ọjọ́ ogbó rẹ? Ìwé ìròyìn American Health sọ pé: “Má ṣe pa ẹ̀kọ́ ìwé rẹ tì, ṣe ṣámúṣámú, kí o sì dáàbò bo ẹ̀dọ̀fóró rẹ.” Marilyn Albert, afìgbékalẹ̀ ètò iṣan ara mọ̀rònú ẹ̀dá ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìkọ́ṣẹ́ Ìṣègùn ti Harvard sọ pé: “Àwọn ohun tí a lè ṣe wà làti mú kí ìṣeéṣe ṣíṣàkóso agbára èrò orí wa pọ̀ sí i.” Dókítà Albert sàsọtẹ́lẹ̀ pé lọ́nà kan, ẹ̀kọ́ ìwé “ń yí ìgbékalẹ̀ ọpọlọ dà” láti má ṣe jẹ́ kí òye èrò orí dín kù bí a ti ń darúgbó. Ní àfikún, a ronú pé ìgbòkègbodò àfaraṣe lè mú kí ìgbékiri ẹ̀jẹ̀ lọ sínú ọpọlọ sunwọ̀n sí i, kí ó sì fún un ní afẹ́fẹ́ oxygen sí i. Albert wá dámọ̀ràn pé: “Rìn kiri lóòjọ́, ó kéré tán, ka ìwé tuntun kan lóṣù, bí o bá sì jẹ́ amusìgá, fún ẹ̀dọ̀fóró (àti ọpọlọ) rẹ ní ìsinmi, nípa jíjáwọ́.”

Àrùn Buffalo Pox Kọ Lu Íńdíà

Ìwé agbéròyìnjáde The Times of India sọ pé wọ́n ti ṣàwárí àrùn buffalo pox, tí ‘fáírọ́ọ̀sì kan tí ó jẹ́ ìsọ̀wọ́ kan náà pẹ̀lú fáírọ́ọ̀sì ìgbóná’ ṣokùnfà ní agbègbè Beed ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Íńdíà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fáírọ́ọ̀sì pox náà kò légbá kan tó ìgbóná, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń ṣàníyàn nípa ìrànkálẹ̀ rẹ̀. Dókítà Kalyan Banerjee, olùdarí Àjọ Ìṣàkóso Fáírọ́ọ̀sì ti Àpapọ̀ Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “A gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ àwọn fáírọ́ọ̀sì náà tìṣọ́ratìṣọ́ra. A kò lè sọ bí ó ṣe burú tó.” Ohun tí a ṣàníyàn nípa rẹ̀ jù lọ ni pé ó ṣeé ṣe kí fáírọ́ọ̀sì pox náà ràn kálẹ̀ ní àwọn agbègbè jíjìnnà réré níbi tí àwọn ohun èèlò ìṣègùn kò ti tó nǹkan. Àrùn buffalo pox lára ènìyàn máa ń ṣokùnfà akọ ibà, ìwúlé ìṣù omira lymph, kókó ọlọ́yún rẹpẹtẹ lára, àti àárẹ̀ ní gbogbo ara.

Ariwo Ìdáníjì Èké Mìíràn

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Ìwákiri àwọn olùwà lẹ́yìn òde ilẹ̀ ayé ṣàṣeyọrí pàtàkì kan ní èṣí.” Àwọn olùṣèwádìí tí ń ṣiṣẹ́ fún Àjọ SETI, tí wọ́n wà ní Mountain View, California, “rí àwọn àmì ìsọfúnni tí ó pèsè ẹ̀rí aláìṣeéjáníkoro nípa ìwàláàyè ọlọ́gbọ́nlóye.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn ìwádìí síwájú sí i, ẹgbẹ́ náà rí i pé àwọn àmì ìsọfúnni rédíò náà “kò wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ET [àwọn olùwà lẹ́yìn òde ilẹ̀ ayé] ṣùgbọ́n láti inú ààrò microwave ìseúnjẹ nísàlẹ̀ ilé náà.” Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Àjọ SETI yóò rí ìjákulẹ̀. Àwọn olùṣèwádìí tí ń wá inú òfuurufú ní Australia rí i pé “ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìdániníjì èké náà jẹ́ àmì ìsọfúnni láti inú àwọn sátẹ́láìtì.” Agbẹnusọ kan fún Àjọ SETI jẹ́wọ́ fún Ẹgbẹ́ Àwọn Onímọ̀ Ìjìnlẹ̀ Sánmà ti America lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé gbogbo àmì ìsọfúnni rédíò tí àjọ SETI rí ní 1995 “wá láti inú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tiwa fúnra wa.”

Ọ̀nà Omi Tuntun

Wọ́n ti ṣàgbékalẹ̀ ìwéwèé ọ̀nà omi tuntun kan tí ó gùn tó kìlómítà 3,450 gba ìhà gúúsù láti ìlú ńlá Brazil náà, Cáceres, lọ dé Ìpele Omi Odò Argentina. Yóò so àwọn odò Paraná àti Paraguay pọ̀. Ọ̀nà omi náà, tàbí hidrovia, yóò gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà àwọn ọ̀nà tí kò dára kọjá, ní mímú kí ó túbọ̀ rọrùn láti gbé ẹ̀wá sóyà, òwú, ọkà, irin àìpò tútù, òroǹbó wẹẹrẹ, manganese, àti àwọn ẹrù míràn lọ sí ọjà òkèèrè. Hidrovia náà jẹ́ iṣẹ́ ìdáwọ́lé àjùmọ̀ṣe tí ó pa Argentina, Brazil, Paraguay, Uruguay, àti Bolivia tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ yí po pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Economist ti sọ, “àwọn kọ́lékọ́lé rí èyí gẹ́gẹ́ bí odò Mississippi ti Gúúsù America, tí a ń kó ẹrù lọ kó ẹrù bọ̀ gba orí rẹ̀ dé àárín gbùngbùn kọ́ńtínẹ́ǹtì tí ó jẹ́ ara rẹ̀ lápá kan, tí ó múra tán láti kún ní kíákíá.”

Ìdíyelé Pi

Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe kọ́ ọ ní ilé ẹ̀kọ́, pi jẹ́ ìṣirò ìfiwéra àyípo ohun roboto kan pẹ̀lú ìwọ̀n ìdábùú òbírí rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyàn lè lo ìdíyelé pi tí ó sún mọ́ 3.14159 láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, ṣùgbọ́n pi kì í ṣe odindi nọ́ḿbà, nítorí náà, ìdíyelé ìpín nọ́ḿbà pi náà kò lópin. Ní ọ̀rúndún kejìndínlógún, a rí ìdíyelé kan tí ó jẹ́ ìpín nọ́ḿbà ìwọ̀n 100 gẹ́lẹ́, àti ní 1973, àwọn ọmọ Faransé méjì tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìṣirò dé orí ìpín nọ́ḿbà ìwọ̀n mílíọ̀nù. Ní báyìí, Yasumasa Kanada, ti Yunifásítì Tokyo ní Japan, ti lo kọ̀m̀pútà láti ṣírò ìdíyelé náà sí iye tí ó lé ní ìpín nọ́ḿbà ìwọ̀n bílíọ̀nù mẹ́fà. Ìwé agbéròyìnjáde The Times, ti London sọ pé, fígọ̀ náà kò ní ìlò kan tí a lè finú wòye, níwọ̀n bí “ìpín nọ́ḿbà ìwọ̀n 39 péré ti tó láti ṣírò àyípo ohun roboto tí ó yí àgbáálá ayé tí a mọ̀ ká sí àárín ìlàjì átọ̀mù hydrogen.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Kanada sọ pé òún gbádùn ṣíṣírò pi “nítorí pé òún gbádùn ìpèníjà ṣíṣírò rẹ̀.” Ṣùgbọ́n má ṣe gbìyànjú láti ṣàtúnwí àbájáde tí ó rí. Ìwé agbéròyìnjáde The Times sọ pé: “Ní ìwọ̀n òǹkà kan láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan, láìdáwọ́ dúró, yóò gba 200 ọdún.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́