ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 9/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọkọ̀ Ayọ́kẹ́lẹ́ Tí Kì Í Lo Epo Bẹntiróòlù àti Àyíká
  • Ṣọ́ra: Àáyá Ń Ré Títì Kọjá
  • Ìkìlọ̀: Tẹlifóònù Lè Léwu
  • Ọgbọ́n Ilé Iṣẹ́ Tábà
  • Ìsínwín Ẹgbẹ̀rúndún
  • Àwọn Ìsẹ̀lẹ̀ Kò Ṣeé Sọ Tẹ́lẹ̀
  • Àwọn Ọ̀gbìn Ń Gba Agbára Àwọn Ohun Abúgbàù
  • Ijó Eléwu
  • Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ Sí Ọ?
    Jí!—2002
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
  • Ìbínú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà—Báwo Lo Ṣe Lè Kojú Rẹ̀?
    Jí!—1997
  • Àárẹ̀—Ìdẹkùn Àìrí fún Àwọn Awakọ̀ Akẹ́rù
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 9/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Àwọn Ọkọ̀ Ayọ́kẹ́lẹ́ Tí Kì Í Lo Epo Bẹntiróòlù àti Àyíká

Ilé Iṣẹ́ Aṣọkọ̀jáde Ilẹ̀ Germany ṣèwádìí kan láti mọ̀ bóyá àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí kì í lo epo bẹntiróòlù dára fún afẹ́fẹ́ àyíká ju àwọn tí ń lo epo bẹntiróòlù lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung ṣe wí, ìwádìí náà kan 100 awakọ̀ tí ó rin 1.3 mílíọ̀nù kìlómítà láàárín 1992 sí 1996. Wọ́n rí i pé àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí kì í lo epo bẹntiróòlù ṣàǹfààní púpọ̀, láìka ti pé wọn kò lè rin ọ̀nà jíjìn sí: Wọ́n ń ṣiṣẹ́ láìpariwo, wọn kì í sì í tú èéfín sáfẹ́fẹ́ níbi tí a ti lò wọ́n. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣeé ṣe kí ìṣòro pàtàkì kan tẹ̀wọ̀n ju àwọn àǹfààní wọ̀nyí lọ. Sísọ agbára bátìrì wọn dọ̀tun ń lo agbára iná mànàmáná púpọ̀ ju ti àwọn ọkọ̀ tí ń lo bẹntiróòlù lọ—láti ìlọ́po 1.5 sí ìlọ́po 4, tí ó sinmi lórí bí a bá ṣe lò wọ́n tó—agbára yẹn sì gbọ́dọ̀ wá láti ibì kan. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé, ní sísinmi lórí ibi tí a ti mú agbára yẹn wá, ó ṣeé ṣe kí “ìbàjẹ́ tí ó ń fà fún afẹ́fẹ́ àyíká ju èyí tí àwọn ọkọ̀ wíwọ́pọ̀ ń fà lọ.”

Ṣọ́ra: Àáyá Ń Ré Títì Kọjá

Igbó Diani, nítòsí etíkun ìhà gúúsù Kẹ́ńyà, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi mélòó kan péré tí àáyá ṣì gbilẹ̀ ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Ìṣòro tí àwọn ẹranko náà ní ni bí wọ́n ṣe lè ré títì etíkun tí ọkọ̀ ti ń lọ tí ó sì ń bọ̀ láìdáwọ́dúró kọjá láìfarapa. Gẹ́gẹ́ bí ìfojúdíwọ̀n kan ṣe sọ, ìwé ìròyìn Swara ti Ẹgbẹ́ Ààbò Ohun Alààyè Inú Igbó Ìlà Oòrùn Áfíríkà sọ pé, ó kéré tán, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ń pa ọ̀bọ 12 lóṣù ní títì náà. Àwùjọ àwọn olùgbé Diani kan tí ń dàníyàn pinnu láti gbégbèésẹ̀ láti dín ìpakúpa náà kù. Yàtọ̀ sí pé wọ́n ń rọ àwọn awakọ̀ láti túbọ̀ máa ṣọ́ra, wọ́n ṣe afárá olókùn àtigidégi gíga lókè títì náà. Bí rírí tí wọ́n ń rí àwọn ọ̀bọ tí ń gba orí afárá náà ti wú wọn lórí, àwọn olùgbé náà ń wéwèé láti tún ṣe afárá púpọ̀ sí i.

Ìkìlọ̀: Tẹlifóònù Lè Léwu

Bí a bá ń lò ó nígbà tí a bá ń wakọ̀ lọ́wọ́. Ìwádìí kan tí a gbé jáde nínú ìwé ìròyìn New England Journal of Medicine fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn awakọ̀ tí ń lo tẹlifóònù nígbà tí wọ́n ń wakọ̀ lọ́wọ́ ṣejàǹbá ní ìlọ́po mẹ́rin ti àwọn tí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí wíwakọ̀. Èyí lè mú kí ewu lílo tẹlifóònù nígbà tí a ń wakọ̀ lọ́wọ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ bá ewu wíwakọ̀ nígbà tí a ti mu ohun ọlọ́tí líle tí ó jẹ́ ìpín 0.1 nínú ọgọ́rùn-ún nínú ẹ̀jẹ̀ wa dọ́gba. Àwọn awakọ̀ onífóònù tí a kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbé sọ́wọ́ dojú kọ ewu lọ́nà kan náà bíi ti àwọn tí ń gbé tiwọn sọ́wọ́. Àwọn olùwádìí náà yára mẹ́nu bà á pé àwọn fóònù náà kọ́ ló lẹ̀bi àwọn ìjàǹbá náà, àmọ́ pé wọ́n wulẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjàǹbá náà ni, bí ìgbà tí àríyànjiyàn bá ṣẹlẹ̀, tí ọkàn ẹnì kan sì pín. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ìpín 39 nínú ọgọ́rùn-ún nínú àwọn awakọ̀ tí ó ṣèjàǹbá ń lo àwọn tẹlifóònù ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn láti fi wá ìrànlọ́wọ́ lẹ́yìn ìjàǹbá náà. Wọ́n dámọ̀ràn pé kí àwọn tí ó ní fóònù nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ máa yẹra fún gbogbo ìtẹniláago tí kò pọn dandan nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n má sì máa jẹ́ kí ìjíròrò wọn gùn. Àwọn orílẹ̀-èdè kan bíi Brazil, Ísírẹ́lì, àti Switzerland, ti gbé òfin kalẹ̀ tí ó ka lílo àwọn fóònù alágbèéká léèwọ̀ fún àwọn awakọ̀ kalẹ̀.

Ọgbọ́n Ilé Iṣẹ́ Tábà

Ìwé ìròyìn The Christian Century béèrè pé: “O ha fìgbà kankan ṣe kàyéfì lórí ìdí tí ilé iṣẹ́ tábà kò fi tí ì lo ẹsẹ̀ gígùn ìṣèlú rẹ̀ kíkàmàmà lórí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin láti dín ìlekoko òfin ìwé ìkìlọ̀ pélébé tí a ní kí ó máa lò nínú ìpolówó sìgá àti lára páálí sìgá [ní United States] kù tàbí láti mú òfin náà kúrò? Ìdáhùn náà rọrùn: ìkìlọ̀ yẹn nípa ewu tí sìgá mímu ní ń dáàbò bo ilé iṣẹ́ tábà lọ́wọ́ ìpenilẹ́jọ́. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá ní ọmọ ọdún 12, tí ó sì yọrí sí àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró ní ọmọ ọdún 45, tí o sì pinnu láti pe ilé iṣẹ́ tó sọ ọ́ di fìkanrànkan lẹ́jọ́, ilé iṣẹ́ náà ní ọ̀nà àbáyọ rírọrùn kan pé: ‘A ti kìlọ̀ fún ọ pé sìgá mímu léwu fún ìlera.’” Ọ̀kan lára àwọn ọgbọ́n ìtajà ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ni láti fún tábà mímu níṣìírí nípa mímú kí àwọn ẹni pàtàkì àti àwọn afìmúra-polówó-ọjà fífanimọ́ra lórí gọgọwú tẹlifíṣọ̀n fọwọ́ sí àmújáde náà. Bí ó ti wù kí ó rí, tábà túbọ̀ ń bàyíká jẹ́, ó sì ń mú ewu ìlera púpọ̀ sí i wá ju sìgá lọ. Dókítà Neil Schachter, ti Ilé Ìwòsàn Mount Sinai ní New York City, sọ pé: “Tábà mímu kò ṣe obìnrin kankan láǹfààní, kàkà bẹ́ẹ̀, yóò fi kún ewu àrùn tí ń fi ìwàláàyè sínú ewu tí obìnrin náà dojú kọ, yóò sì dù ú ní okun àti agbára tí ó nílò láti ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé.”

Ìsínwín Ẹgbẹ̀rúndún

Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Ó jọ pé ọ̀rúndún ogún tó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rúndún Ogun Àjàkáyé, tó sì tẹ̀ síwájú di Sànmánì Ohun Ìjà Átọ́míìkì, ń parí lọ gẹ́gẹ́ bíi Sànmánì Ìnàjú. A ti gba àyè àwọn hòtẹ́ẹ̀lì jákèjádò ayé” fún ayẹyẹ Àìsùn Ọdún Tuntun 1999. Bí ó ti wù kí ó rí, awuyewuye kan ti ń jà rànyìn lórí ibi tí ẹgbẹ̀rúndún náà yóò ti bẹ̀rẹ̀ gan-an. Ìwé ìròyìn U. S. News & World Report sọ pé “Wàhálà náà bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Kiribati. Ìlà ibi ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kìíní ọdún máa ń la àwọn erékùṣù tí ó fara kọ́ra já: Nígbà tí ó bá jẹ́ Sunday ní ìlà oòrùn Kiribati, ó ń jẹ́ Monday ní ìwọ̀ oòrùn Kiribati.” Orílẹ̀-èdè náà yanjú ìṣòro náà nípa sísọ pé, bẹ̀rẹ̀ láti January 1, 1995, síwájú, ìlà ibi ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kìíní ọdún yóò lọ sí erékùṣù ìhà ìlà oòrùn rẹ̀ jíjìnnà jù lọ, Caroline. Ìyẹn yóò túmọ̀ sí pé Kiribati ni yóò jẹ́ ojú ilẹ̀ àkọ́kọ́ tí ilẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan yóò mọ́ sí. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn orílẹ̀-èdè míràn, bíi Tonga àti New Zealand, ń fẹ́ ipò “kíní.” Gẹ́gẹ́ bí Ibi Ìdúrówosánmà Greenwich ti Aláyélúwà ṣe sọ, ìbéèrè náà jẹ́ ti ìdọpọlọ-láàmú lásán. Ìròyìn ìwádìí náà sọ pé: “Níwọ̀n bí oòrùn ti ń ràn ní Ìhà Gúúsù Ìlàjì Ayé láti ìgbà tí ọ̀sán àti òru ń dọ́gba ní September sí ìgbà tí ọ̀sán àti òru ń dọ́gba ní March, ọ̀yẹ̀ ẹgbẹ̀rúndún náà yóò kọ́kọ́ là níhà gúúsù pátápátá Ilẹ̀ Ayé.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ibi Ìdúrówosánmà náà fi kún un pé, ìyẹn kì yóò ṣẹlẹ̀ ṣáájú January 1, 2001—kì í ṣe lọ́dún 2000.

Àwọn Ìsẹ̀lẹ̀ Kò Ṣeé Sọ Tẹ́lẹ̀

Láìpẹ́ yìí, àwùjọ àwọn ògbóǹkangí onímọ̀ nípa ìsẹ̀lẹ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè pàdé ní London láti jíròrò lórí bí sáyẹ́ǹsì ṣe lè sọ tẹ́lẹ̀ tó nípa ìsẹ̀lẹ̀. Orí èrò wo ni wọ́n dé dúró? Ọ̀mọ̀wé Robert Geller, láti Yunifásítì Tokyo, kọ̀wé nínú ìwé agbéròyìnjáde Eos pé: “Fún èyí tí ó lé ní 100 ọdún ni ọ̀pọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa Ilẹ̀ Ayé ti rò pé àwọn atọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣeé rí, tí ó ṣeé dá mọ̀, tí a sì lè fi ṣe ìpìlẹ̀ fún pípèsè igbe ìkìlọ̀ gbọ́dọ̀ ṣáájú [àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ńláńlá] ní kedere.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a ṣe àyípadà pàtàkì kan nínú èrò yí nítorí pé “ó jọ pé ìsẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan kò ṣeé sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà àdánidá.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè pèsè àsọtẹ́lẹ̀ pàtó, wọ́n lè fojú díwọ̀n pé ó ṣeé ṣe kí ilẹ̀ sẹ̀, kí wọ́n sì fojú díwọ̀n bí ó ti ṣeé ṣe kí àwọn ìsẹ̀lẹ̀ lágbára tó ní àwọn àgbègbè tí ó ní àkọsílẹ̀ ìmìtìtì púpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwòrán ilẹ̀ kan tí Ẹ̀ka Àyẹ̀wò Ilẹ̀ àti Ohun Inú Rẹ̀ ní United States gbé jáde tọ́ka sí àwọn ibi tí ìmìtìtì lílágbára ti lè ṣẹlẹ̀ ní kọ́ńtínẹ́ǹtì United States láàárín 50 ọdún tí ń bọ̀. Ní lílo àkọsílẹ̀ oníṣirò yí, àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ìjọba tọ́ka sí i pé ó lé ní ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé California tí ń gbé àwọn àgbègbè tí ó lè léwu.

Àwọn Ọ̀gbìn Ń Gba Agbára Àwọn Ohun Abúgbàù

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé àwọn ọ̀gbìn beet oníṣúgà àti oríṣi ewéko kan tí ń hù lójú omi adágún lè yọ àwọn ohun abúgbàù láti inú ilẹ̀ àti omi tí ó bá wà níbi tí a kó ohun ìjà sí tẹ́lẹ̀, kí wọ́n sì mú kí wọ́n jẹrà láìsí ewu kankan. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní Yunifásítì Rice, ní Houston, Texas, fa èròjà TNT sínú àwọn ewéko periwinkle àti parrot feather, tó jẹ́ ewéko wíwọ́pọ̀ tí ń hù lójú omi adágún. Láàárín ọ̀sẹ̀ kan, kò sí àmì àwọn ohun abúgbàù kankan tí ó ṣẹ́ kù sínú wọn, dídáná sun àwọn ọ̀gbìn náà kò sì mú ìbúgbàù kankan wá. Nígbà kan náà, àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Maryland ṣàwárí pé ìṣùpọ̀ ọ̀gbìn beet oníṣúgà àti àwọn tí a dá yọ lẹ́yọlẹ́yọ lè fa èròjà nitroglycerin, kí wọ́n sì sọ ọ́ di aláìlágbára. Àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì méjèèjì pa àwọn ohun alààyè tíntìntín kúrò lára àwọn ọ̀gbìn náà láti fi hàn pé àwọn ohun alààyè tíntìntín kò ṣèrànwọ́ nínú ìgbésẹ̀ náà. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ní báyìí ná, ó léwu púpọ̀, ó sì gbówó lérí gidigidi láti sọ àwọn ibi tí a kó ohun ìjà olóró sí tẹ́lẹ̀ dọ̀tun kí a sì máa kọ́lé sórí wọn, àmọ́ ipò yẹn lè yí dà bí àwọn ọ̀gbìn tí kò náni lówó bá ṣeé gbìn láti fa àwọn ohun abúgbàù náà kúrò nínú ilẹ̀ àti omi, kí wọ́n sì mú kí wọ́n jẹrà láìsí ewu kankan.” Àìní kánjúkánjú wà nítorí pé “a ń kásẹ̀ àṣà dída àwọn ohun ìjà sókun tí a ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ nílẹ̀.”

Ijó Eléwu

Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé, àwọn ijó kan tí wọ́n ń jó nínú ilé ijó ti yí pa dà kúrò ní ijó fàájì “sí eré ìdíje oníwà ẹhànnà kan tí a fi ń pawó.” Ìkọlura lórí eré àti ìtàpá tí ń ṣèèṣì pa àwọn oníjó tí ń díje lára ti ń di ewu ní agbo ijó náà. Èyí tó burú jù lọ ni pé, gẹ́gẹ́ bí Harry Smith-Hampshire, aṣíwájú kan gẹ́gẹ́ bí adájọ́ níbi ijó jíjó ṣe wí, a ń mọ̀ọ́mọ̀ jó ijó eléwu lẹ́yìn “ìwéwèé àmọ̀ọ́mọ̀ṣe aláìláàánú.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Times ṣe wí, àwọn olùdíje ijó jíjó ń mú “àwọn ìṣe orí pápá ìṣeré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá àti ibi ìkànṣẹ́” wọlé wá. Bí ó ti ń jọ pé ijó inú ilé ijó yóò jèrè ìtẹ́wọ́gbà Olympic láìpẹ́, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olùdánilẹ́kọ̀ọ́ àti adájọ́ ti ṣàkójọ “àwọn òfin àti ìlànà iṣẹ́” tí a fàṣẹ sí láti máa darí eré ìdíje náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́