ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 12/8 ojú ìwé 24-27
  • Louis Pasteur—Ohun Tí Iṣẹ́ Rẹ̀ Ṣí Payá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Louis Pasteur—Ohun Tí Iṣẹ́ Rẹ̀ Ṣí Payá
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwádìí Tí Ó Ṣe Níbẹ̀rẹ̀
  • Ìsọdaláìníkòkòrò Lọ́nà ti Pasteur
  • Ìwàláàyè Wá Láti Inú Ìwàláàyè
  • Gbígbógunti Àrùn Àkóràn
  • Iṣẹ́ Tí Ó Níye Lórí
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Ìṣègùn Òde Òní—Ibo Lagbára Rẹ̀ mọ?
    Jí!—2001
  • Ariyanjiyan Nla naa Ki ni O Jẹ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ohun Tó Rúni Lójú Nípa Àìlera
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 12/8 ojú ìwé 24-27

Louis Pasteur—Ohun Tí Iṣẹ́ Rẹ̀ Ṣí Payá

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ

ÌWÀLÁÀYÈ ha lè wá láti inú ohun aláìlẹ́mìí bí? Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan rò pé ó lè ṣeé ṣe. Wọ́n lérò pé ìwàláàyè lè wá fúnra rẹ̀ láti inú ohun aláìlẹ́mìí, láìjẹ́ pé ẹlẹ́dàá kan lọ́wọ́ nínú rẹ̀.

Ṣùgbọ́n ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan nígbà ìrúwé April 1864, àwùjọ kan tí ó wà ní gbọ̀ngàn ìpàdé kan ní Yunifásítì Sorbonne ní Paris gbọ́ ohun tí ó yàtọ̀. Nínú ìgbékalẹ̀ kan tí ó fakọ yọ níwájú ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan, Louis Pasteur fi ẹ̀rí hàn lẹ́sẹẹsẹ pé àbá-èrò-orí ìmújáde láti inú ohun aláìlẹ́mìí kò tọ̀nà.

Gẹ́gẹ́ bí The World Book Encyclopedia ti sọ, ọ̀rọ̀ àpilẹ̀sọ yìí àti àwọn àwárí mìíràn lẹ́yìn náà ló sọ ọ́ di “ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ títayọ jù lọ lágbàáyé.” Ṣùgbọ́n kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi irú èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn yìí sọ́kàn àwọn ènìyàn lákòókò rẹ̀, báwo ni ó sì ṣe di ẹni tí a mọ̀ jákèjádò ayé? Lọ́nà wo ni a ń gbà jàǹfààní láti inú díẹ̀ lára àwọn àwárí rẹ̀?

Ìwádìí Tí Ó Ṣe Níbẹ̀rẹ̀

Wọ́n bí Louis Pasteur ní 1822 ní ìlú kékeré Dôle, ní ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé. Bàbá rẹ̀, tí ó jẹ́ oníṣẹ́ awọ, ní àwọn góńgó kan fún ọmọkùnrin rẹ̀. Láìka pé ó ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ ọnà, ó sì ní ẹ̀bùn iṣẹ́ ọnà sí, Louis nawọ́ gán ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Ó gba oyè dókítà nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ní ẹni ọdún 25.

Àwọn ìwádìí tí ó ṣe níbẹ̀rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ásíìdì tartaric, àpòpọ̀ kan tí ń wà nínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí a fi sílẹ̀ sínú àgbá wáìnì. Àwọn aṣèwádìí mìíràn lo àbájáde ìwádìí yẹn ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà láti fi ìdí ìpìlẹ̀ ìṣiṣẹ́ àpòpọ̀ carbon ti òde òní múlẹ̀. Pasteur wá tẹ̀ síwájú lọ sórí ẹ̀kọ́ nípa àwọn èròjà tí ń mú nǹkan bà.

A kò mọ àwọn èròjà tí ń mú nǹkan bà bí ìwúkàrà kí Pasteur tó ṣe ìwádìí rẹ̀. Ṣùgbọ́n a ronú pé wọ́n jẹ́ ìyọrísí bíbà. Bí ó ti wù kí ó rí, Pasteur fẹ̀rí hàn pé àwọn èròjà tí ń mú nǹkan bà wọ̀nyí kì í ṣe ìyọrísí bíbà, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ní ń fa bíbà. Ó fi hàn pé irú èròjà kọ̀ọ̀kan tí ń mú nǹkan bà ń ṣokùnfà irú bíbà tí ó yàtọ̀. Àkọsílẹ̀ tí ó tẹ̀ jáde nípa rẹ̀ ní 1857 ni a wò lónìí gẹ́gẹ́ bí “ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nipa ohun alààyè tíntìntín.”

Láti ìgbà yẹn wá, àwọn iṣẹ́ àti àwárí rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Nítorí orúkọ rere tí ó ní, àwọn tí ń ṣe ọtí kíkan ní Orléans ké sí i láti yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro tí wọ́n ń ní lẹ́nu iṣẹ́ wọn. Pasteur fẹ̀rí hàn pé èròjà tí ń mú kí wáìnì yí padà sí ọtí kíkan ni ohun tí a ń pè nísinsìnyí ní ohun alààyè tíntìntín, tí ó wà lójú ohun olómi náà. Lópin ìwádìí rẹ̀, ó jíròrò “Ẹ̀kọ́ Lórí Ọtí Wáìnì Kíkan” rẹ̀ lílókìkí náà níwájú àwọn tí ń ṣe ọtí kíkan àti àwọn sàràkísàràkí ní ìlú náà.

Ìsọdaláìníkòkòrò Lọ́nà ti Pasteur

Ìwádìí tí Pasteur ṣe nípa bíbà jẹ́ kí ó lè parí ọ̀rọ̀ sí pé àwọn kòkòrò tíntìntín ló ń fa ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìṣòro ìsọdeléèérí ní ilé iṣẹ́ oúnjẹ. Àwọn kòkòrò tíntìntín wà nínú afẹ́fẹ́ tàbí àwọn ohun ìkóǹkansí tí a kò fọ̀ dáradára. Pasteur dámọ̀ràn pé a lè ṣèdíwọ́ fún bíbà tí bakitéríà ń ba àwọn ìṣejáde oúnjẹ jẹ́ nípa mímú ìmọ́tótó sunwọ̀n sí i àti pé a lè ṣèdíwọ́ fún bíba ohun olómi jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ó wà láàárín ìwọ̀n 50 sí 60 lórí òṣùwọ̀n Celsius fún ìṣẹ́jú mélòó kan. Orí wáìnì ni a ti kọ́kọ́ lo ìlànà yìí láti ṣèdíwọ́ fún bíbà lọ́nà ṣíṣàjèjì. Àwọn lájorí kòkòrò tíntìntín ni a pa láìfa ìyípadà púpọ̀ nínú ìtọ́wò tàbí òórùn rẹ̀.

Ìlànà yìí, tí a ń pè ní pasteurization [ìsọdaláìníkòkòrò lọ́nà ti Pasteur], tí Pasteur ní ẹ̀tọ́ oníǹkan lé lórí, mú ìyípadà tegbòtigaga bá ilé iṣẹ́ oúnjẹ. Lọ́jọ́ òní, wọn kò lo ọgbọ́n ìṣe yìí fún wáìnì mọ́ ṣùgbọ́n ó ṣì ṣeé lò nínú ṣíṣe oríṣiríṣi ohun àṣejáde bíi wàrà tàbí omi èso. Bí ó ti wù kí ó rí, a lè lo àwọn ìlànà míràn, bí ìsọdaláìníkòkòrò tíntìntín ní ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù tí ó túbọ̀ ga.

Ilé iṣẹ́ ńlá mìíràn tí ó tún jàǹfààní láti inú ìwádìí Pasteur ni àwọn ilé iṣẹ́ ìpọntí. Nígbà yẹn, àwọn ará Faransé ní ọ̀pọ̀ ìṣòro ìṣèmújáde àti ti ìbánidíje lílágbára láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Germany. Pasteur bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lákọ̀tun, ó sì gba àwọn apọntí nímọ̀ràn púpọ̀. Ó dámọ̀ràn pé kí wọ́n fún ìmọ́tónítóní ọtí òjò àwọn apọntí láfiyèsí títí kan ìmọ́tótó afẹ́fẹ́ àyíká. Àṣeyọrí náà yá kánkán, ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀tọ́ oníǹkan lẹ́yìn náà.

Ìwàláàyè Wá Láti Inú Ìwàláàyè

Láti ìgbà láéláé, a ti dábàá àwọn èrò bíbójúmu jù lọ láti ṣàlàyé bí àwọn kòkòrò, ìdin, tàbí àwọn ẹ̀dá mìíràn ṣe ń dé inú ohun tí ń jẹrà. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kẹ̀tàdínlógún, onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ chemistry kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Belgium yangàn pé òún ti mú kí èkúté fara hàn nípa kíki aṣọ dídọ̀tí kan bọnú agbada bàbà kan!

Nígbà ayé Pasteur, àríyànjiyàn tí ó wà ní àwùjọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbóná jọjọ. Láti kojú àwọn tí wọ́n ti ìmújáde láti inú ohun aláìlẹ́mìí lẹ́yìn jẹ́ ìpèníjà gidi. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ohun tí ó ti kọ́ nínú ìwádìí rẹ̀ nípa bíbà, Pasteur ní ìdánilójú. Nítorí náà, ó ṣe àwọn àṣeyẹ̀wò tí a pète láti fòpin sí èrò ìmújáde láti inú ohun aláìlẹ́mìí títí ayérayé.

Àṣeyẹ̀wò rẹ̀ nínú èyí tí ó ti lo àwọn ṣágo amúǹkangbóná ọlọ́rùn tín-ínrín jẹ́ ọ̀kan lára èyí tí ó lókìkí jù lọ. Àwọn kòkòrò tètè sọ èròjà olómi kan tí a ṣí sílẹ̀ sínú afẹ́fẹ́ nínú ṣágo amúǹkangbóná tí kò nídèérí di eléèérí. Bí ó ti wù kí ó rí, tí a bá dà á sínú ṣágo amúǹkangbóná ọlọ́rùn tín-ínrín, èròjà yìí kan náà kò ní di eléèérí. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Àlàyé tí Pasteur ṣe rọrùn: Nígbà tí àwọn bakitéríà tí ó wà nínú afẹ́fẹ́ bá kọjá nínú ọrùn tín-ínrín náà, wọ́n óò tẹ́ sójú gíláàsì náà, afẹ́fẹ́ náà kì yóò ní àwọn kòkòrò tíntìntín nínú nígbà tí ó bá dé ibi tí omi náà wà. Àwọn èròjà olómi kọ́ ni ó ṣèmújáde àwọn kòkòrò tí ó yọ nínú ṣágo amúǹkangbóná tí kò nídèérí náà láìròtẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ló gbé wọn wá.

Láti fi ìjẹ́pàtàkì afẹ́fẹ́ hàn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń gbé àwọn kòkòrò tíntìntín kiri, Pasteur lọ sí Mer de Glace, ìṣàn òkìtì yìnyín kan ní òkè ńlá Alps ilẹ̀ Faransé. Ní ibi gíga tó 1,829 mítà, ó ṣí ìdérí àwọn ṣágo amúǹkangbóná rẹ̀, ó sì gbé wọn sínú afẹ́fẹ́. Ẹyọ kan péré lára 20 ṣágo amúǹkangbóná náà ló di eléèérí. Ó wá lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn Òkè Ńlá Jura, ó sì ṣe àṣeyẹ̀wò kan náà. Níbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ ga yìí, ṣágo kékeré amúǹkangbóná mẹ́jọ ló di eléèérí. Ó wá fẹ̀rí hàn pé nítorí afẹ́fẹ́ tí ó túbọ̀ mọ́ tónítóní ní àwọn ibi tí ó ga jù, ewu ìsọdeléèérí kò pọ̀.

Nípasẹ̀ irú àwọn àṣeyẹ̀wò bẹ́ẹ̀, Pasteur fi hàn kedere pẹ̀lú ìdánilójú pé ìwàláàyè wá kìkì láti inú ìwàláàyè tí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Kò wá fúnra rẹ̀ láti inú ohun tí kò lẹ́mìí.

Gbígbógunti Àrùn Àkóràn

Níwọ̀n bí ó ti béèrè pé kí àwọn kòkòrò tíntìntín wà kí nǹkan tó bà, Pasteur ronú pé ohun kan náà ní láti ṣẹlẹ̀ nípa àwọn àrùn àkóràn. Ìwádìí tí ó ṣe nípa àrùn kòkòrò ṣẹ́dà, ìṣòro ọrọ̀ ajé tí ó le koko fún àwọn tí ń ṣe aṣọ ṣẹ́dà ní gúúsù Faransé, fi hàn pé èrò rẹ̀ tọ̀nà. Láàárín ọdún bíi mélòó kan, ó ṣàwárí àwọn okùnfà àrùn méjì, ó sì dábàá àwọn ìlànà àmúlógìírí fún yíyan àwọn kòkòrò ṣẹ́dà tí ó lera, tí yóò ṣèdíwọ́ fún ìrànkálẹ̀.

Nígbà tí ó ń ṣàyẹ̀wò nípa àrùn onígbáméjì adìyẹ, Pasteur ṣàkíyèsí pé níní ẹ̀yà kòkòrò tíntìntín tí kò lọ́jọ́ lórí ju oṣù mélòó kan péré lọ kì í sọ àwọn adìyẹ náà di alárùn ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àrùn. Ní àbájáde rẹ̀, ó ṣàwárí pé òún lè fún wọn lábẹ́rẹ́ àjẹsára pẹ̀lú irú kòkòrò tíntìntín aláìlágbára kan, tàbí èyí tí a rẹ agbára rẹ̀ sílẹ̀.

Kì í ṣe Pasteur ló kọ́kọ́ lo abẹ́rẹ́ àjẹsára. Ọmọ ilẹ̀ England náà, Edward Jenner, ti lò ó ṣáájú rẹ̀. Ṣùgbọ́n Pasteur ló kọ́kọ́ lo èròjà aṣokùnfà àrùn gidi náà lọ́nà tí a rẹ agbára rẹ̀ sílẹ̀ dípò lílo kòkòrò tín-ń-tín kan tí ó tan mọ́ ọn. Ó tún kẹ́sẹ járí pẹ̀lú abẹ́rẹ́ àjẹsára kan ní ìgbógunti àrùn anthrax, àrùn àkóràn tí ń wá láti ara àwọn ẹranko ẹlẹ́jẹ̀ lílọ́wọ́ọ́wọ́ bíi màlúù àti àgùntàn.

Lẹ́yìn èyí, ó gbé ogun rẹ̀ tí ó kẹ́yìn tí ó sì lókìkí jù lọ, dìde sí àrùn dìgbòlugi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀, nígbà tí ó ń ko àrùn dìgbòlugi lójú, Pasteur ń kojú ohun kan tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ti bakitéríà. Ó ń kojú àwọn fáírọ́ọ̀sì, àwọn ohun tí kò lè fi awò asọhun-kékeré-di-ńlá wò.

Ní July 6, 1885, ìyá kan gbé ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́sàn-án lọ sí ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ Pasteur. Ajá kan tí ó lárùn dìgbòlugi ló bù ú jẹ. Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀bẹ̀ tí ìyá ọmọ náà bẹ̀, Pasteur lọ́ra láti ran ọmọdékùnrin náà lọ́wọ́. Òun kì í ṣe oníṣègùn, wọ́n sì lè fẹ̀sùn kàn án pé ó ṣiṣẹ́ ìṣègùn láìbófin mu. Àti pé kò tí ì dán àwọn ìlànà rẹ̀ wò lára ẹ̀dá ènìyàn. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ní kí alájọṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, Dókítà Grancher, fún ọ̀dọ́mọdékùnrin náà ní abẹ́rẹ́ àjẹsára. Ó ṣe bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìyọrísí rere. Lára 350 ènìyàn tí wọ́n tọ́jú láàárín àkókò tí kò pé ọdún kan, ẹyọ kan péré—tí wọn kò tètè gbé wá—ni kò là á já.

Bí àkókò ti ń lọ, Pasteur ń ronú nípa ipò ìmọ́tótó ilé ìwòsàn. Ibà puerperal ń fa ikú ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin lọ́dọọdún ní ilé ìgbẹ̀bí ti Paris. Pasteur dámọ̀ràn ìlànà ìṣèdènà àkóràn àti ìmọ́tótó tí a mú lógìírí, ní pàtàkì fún ọwọ́. Ìwádìí tí oníṣẹ́ abẹ ọmọ ilẹ̀ England náà, Joseph Lister àti àwọn mìíràn, ṣe lẹ́yìn náà fi ìpépérépéré àbájáde Pasteur hàn.

Iṣẹ́ Tí Ó Níye Lórí

Pasteur kú ní 1895. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ rẹ̀ níye lórí, a sì ń jàǹfààní lára àwọn kan nínú rẹ̀ lónìí pàápàá. Ìdí nìyẹn tí a fi pè é ní “aṣàǹfààní fún ẹ̀dá ènìyàn.” Orúkọ rẹ̀ ṣì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú abẹ́rẹ́ àjẹsára àti àwọn ìlànà ìṣe tí a mọ̀ níbi gbogbo pé òun ló ṣàwárí rẹ̀.

L’Institut Pasteur, ibùdó ìwádìí kan tí a dá sílẹ̀ ní Paris nígbà ayé Pasteur fún ṣíṣètọ́jú àrùn dìgbòlugi, jẹ́ ibùdó tí a mọ̀ gan-an fún àyẹ̀wò àwọn àrùn àkóràn lónìí. A mọ̀ ibùdó náà ní pàtàkì fún iṣẹ́ rẹ̀ nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára àti ìṣègùn—ní pàtàkì láti 1983, nígbà tí àwùjọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ láti ibẹ̀, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Luc Montagnier ṣíwájú wọ́n, kọ́kọ́ ṣàwárí fáírọ́ọ̀sì àrùn AIDS.

Àríyànjiyàn lórí ìmújáde ìwàláàyè láti inú ohun aláìlẹ́mìí, èyí tí Pasteur kópa nínú rẹ̀, tí ó sì borí, kì í ṣe ẹjọ́ wẹ́wẹ́ lásán nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Ó ju kókó ọ̀rọ̀ fífani mọ́ra tí ó wà fún ìwọ̀nba àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tàbí àwọn onílàákàyè kéréje láti jíròrò láàárín ara wọn lọ. Ó ní ìjẹ́pàtàkì tí ó tóbi jọjọ—ó kan ẹ̀rí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú wíwà Ọlọ́run.

François Dagognet, ọ̀mọ̀ràn kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé tí ó jẹ́ ògbóǹtagí nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, sọ pé “àwọn elénìní” Pasteur, “àwọn onígbàgbọ́ nínú ohun àfojúrí àti àwọn aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọ́run, gbà gbọ́ pé àwọ́n lè fi ẹ̀rí hàn pé ẹ̀dá alààyè kan lè jáde láti ara àwọn èérún tí ń jẹrà. Èyí jẹ́ kí wọ́n kọ wíwà Ọlọ́run. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ti Pasteur, kò sí ọ̀nà àbákọjá kan tí ó ṣeé gbà láti inú ikú sí ìwàláàyè.”

Títí di òní yìí, gbogbo ẹ̀rí láti inú ìṣàyẹ̀wò, ìtàn, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìwalẹ̀pìtàn, àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn ń bá a lọ láti fi ohun tí Pasteur ṣàṣefihàn rẹ̀ hàn—pé ìwàláàyè lè wá láti inú ìwàláàyè tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ nìkan, kì í ṣe láti inú ohun tí kò lẹ́mìí. Ẹ̀rí náà tún fi hàn kedere pé ìwàláàyè ń mú nǹkan jáde “ní irú tirẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Bíbélì ti sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì. Àwọn ọmọ sábà máa ń jẹ́ “irú” tàbí ẹ̀dà kan náà bí àwọn òbí.—Jẹ́nẹ́sísì 1:11, 12, 20-25.

Nípa bẹ́ẹ̀, yálà Louis Pasteur mọ̀ tàbí kò mọ̀, iṣẹ́ àti ẹ̀rí rẹ̀ pèsè ẹ̀rí tí ó lágbára lòdì sí àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n, ó sì tún pèsè ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ẹ̀rí pé ẹlẹ́dàá kan gbọ́dọ̀ wà kí ìwàláàyè tó lè fara hàn lórí ilẹ̀ ayé. Iṣẹ́ rẹ̀ ṣàgbéyọ ohun tí onírẹ̀lẹ̀, onísáàmù náà sọ pé: “Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé Olúwa, òun ni Ọlọ́run: òun ni ó dá wa, tirẹ̀ ni àwa.”—Orin Dáfídì 100:3.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Irin iṣẹ́ tí ó wà lókè yìí ni a lò láti sọ wáìnì di aláìníkòkòrò, ní pípa àwọn kòkòrò tíntìntín tí a kò fẹ́; a gbé e yọ dáradára nínú àwòrán ìsàlẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn àṣeyẹ̀wò Pasteur fagi lé àbá-èrò-orí ìmújáde láti inú ohun aláìlẹ́mìí

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Gbogbo fọ́tò lójú ìwé 24 sí 26: © Institut Pasteur

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́