ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g01 6/8 ojú ìwé 4-9
  • Ìṣègùn Òde Òní—Ibo Lagbára Rẹ̀ mọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣègùn Òde Òní—Ibo Lagbára Rẹ̀ mọ?
  • Jí!—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Ìpìlẹ̀ Lélẹ̀
  • Gẹrungẹrun Tó Tún Ń Ṣiṣẹ́ Abẹ
  • Kíkápá Àwọn Àrùn
  • Ìmọ̀ Ìṣègùn ní Ọ̀rúndún Ogún
  • Ṣé Àlá Tí Kò Lè Ṣẹ Ni?
  • Ṣé Fífi Àbùdá Ṣe Ìtọ́jú ni Ojútùú Rẹ̀?
  • Ijakadi Lodi Si Aisan ati Iku A Ha Nja Ajaṣẹgun Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Á Gba Aráyé Lọ́wọ́ Àìsàn?
    Jí!—2007
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
  • Ọjọ́ Pẹ́ Táráyé Ti Ń Gbógun Ti Àrùn
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2001
g01 6/8 ojú ìwé 4-9

Ìṣègùn Òde Òní—Ibo Lagbára Rẹ̀ mọ?

LÁTI kékeré làwọn ọmọdé ti ń mọ̀ pé ńṣe làwọn máa gun èjìká ẹlẹgbẹ́ wọn bí wọ́n bá fẹ́ ká ọsàn tọ́wọ́ wọn kò tó. Ohun kan náà ti ṣẹlẹ̀ lágbo ìṣègùn. Iwájú lọ̀pá ẹ̀bìtì àwọn olùṣèwádìí ìṣègùn ń ré sí nítorí pé wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ògbóǹkangí oníṣègùn tó wà nígbà kan rí.

Lára àwọn oníwòsàn ọjọ́un làwọn gbajúmọ̀ ọkùnrin bíi Hippocrates àti Pasteur, àtàwọn bíi Vesalius àti William Morton wà—àwọn orúkọ tí ọ̀pọ̀ kò gbọ́ rí. Ọ̀nà wo làwọn wọ̀nyí gbà gbọnwọ́ sáwo àṣeyọrí ìṣègùn lóde òní?

Láyé àtijọ́, ọ̀rọ̀ ìwòsàn kì í la ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ bí kò ṣe ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àtàwọn ààtò ìsìn. Ìwé The Epic of Medicine, látọwọ́ Dókítà Felix Marti-Ibañez, sọ pé: “Láti kápá àìsàn . . . , ńṣe làwọn ará Mesopotámíà bẹ̀rẹ̀ sí lo ìsìn àti ìṣègùn pa pọ̀, nítorí wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn òrìṣà wọn ló ń fi àìsàn jẹ wọ́n níyà.” Orí ìsìn ni wọ́n tún gbé ìṣègùn tàwọn ará Íjíbítì tó dé lẹ́yìn náà kà. Èyí fi hàn pé látọdún gbọ́nhan ni wọ́n ti ń fojú onísìn wo oníṣègùn.

Dókítà Thomas A. Preston sọ nínú ìwé rẹ̀ The Clay Pedestal, pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ àtayébáyé ṣì ń fara hàn nínú iṣẹ́ ìṣègùn tó ń bá a lọ dòní olónìí. Ọ̀kan lára ìgbàgbọ́ ọ̀hún ni pé bí àìsàn bá kọlu ẹnì kan kò sọ́gbọ́n tí onítọ̀hún lè ta sí i, agbára idán oníṣègùn nìkan ló lè mú un lára dá.”

Fífi Ìpìlẹ̀ Lélẹ̀

Bó ti wù kó rí, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bẹ̀rẹ̀ sí wọ iṣẹ́ ìṣègùn lọ́nà tó kọyọyọ láti wo èèyàn sàn. Òléwájú oníṣègùn òyìnbó ayé ọjọ́un ni Hippocrates. Nǹkan bí ọdún 460 ṣáájú Sànmánì Tiwa ni wọ́n bí i ní erékùṣù Gíríìkì ti Kos, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ ọ́n bí olùdásílẹ̀ ìṣègùn Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Hippocrates fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún fífi ojú tó tọ́ wo ìṣègùn. Kò fara mọ́ èrò náà pé àwọn òrìṣà ló ń fi àìsàn jẹ èèyàn níyà, ó sì fi yé wọn pé ohun kan ló ń fà á. Fún àpẹẹrẹ, ó ti pẹ́ tí wọ́n ti sọ pé àìsàn ẹ̀sìn ni wárápá, nítorí wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn òrìṣà nìkan ló lè wo àìsàn yìí. Ṣùgbọ́n Hippocrates kọ ọ́ pé: “Ní ti àìsàn tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ Mímọ́ yìí: lójú tèmi, kì í ṣe ọlọ́run kankan ló ń fà á, kò sì jẹ́ mímọ́ ju àwọn àìsàn mìíràn lọ, ó ń dìídì ṣẹlẹ̀ ni.” Hippocrates tún ni oníṣègùn àkọ́kọ́ tó ṣàwárí àwọn àmì oríṣiríṣi àrùn tó sì kọ wọ́n sílẹ̀ káwọn èèyàn lè rí wọn lò lọ́jọ́ iwájú.

Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, Galen, oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tí a bí lọ́dún 129 Sànmánì Tiwa náà tún ṣe àwọn ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Galen ṣe ìwé kan jáde tó dá lórí ìwádìí kínníkínní tó ṣe nípa èèyàn àti ẹranko, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn dókítà sì fi lo ìwé ọ̀hún! Andreas Vesalius tí wọ́n bí ní Brussels lọ́dún 1514 kọ ìwé kan lórí bí ara ẹ̀dá enìyàn ṣe rí, èyí tó pè ní On the Structure of the Human Body. Àwọn èèyàn ta ko ìwé náà, torí pé kò bá ọ̀pọ̀ ohun tí Galen sọ mu, àmọ́ ó fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìwádìí òde òní nípa bí ara ènìyàn ṣe rí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Die Grossen (Àwọn Ẹni Ńlá) ti sọ, Vesalius tipa bẹ́ẹ̀ di “ọ̀kan lára àwọn olùṣèwádìí ìṣègùn tó ṣe pàtàkì jù lọ láàárín gbogbo èèyàn àti fún gbogbo ìgbà.”

Nígbà tó yá, àbá èrò orí Galen nípa bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń káàkiri ara tún di èyí tí kò bóde mu mọ́.a Ọ̀pọ̀ ọdún ni oníṣègùn ọmọ ilẹ́ Gẹ̀ẹ́sì náà William Harvey fi tú ẹ̀yà ara àwọn ẹranko àti ẹyẹ wò fínnífínní. Ó ṣàyẹ̀wò nípa iṣẹ́ táwọn ihò inú ọkàn máa ń ṣe, ó díwọ̀n iye ẹ̀jẹ̀ tó wà nínú ọkàn ó sì wá fojú bu iye ẹ̀jẹ̀ tó wà nínú ara. Harvey tẹ ohun tó rí nínú ìwádìí rẹ̀ jáde lọ́dún 1628 nínú ìwé tó pè ní On the Motion of the Heart and Blood in Animals. Wọ́n ṣe lámèyítọ́ rẹ̀, wọ́n takò ó, wọ́n gbógun tì í, wọ́n sì bú u. Àmọ́ ìyípadà ńláǹlà lohun tó ṣe jẹ́ lágbo ìṣègùn—ó ti ṣàwárí bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń káàkiri inú ara!

Gẹrungẹrun Tó Tún Ń Ṣiṣẹ́ Abẹ

Ìtẹ̀síwájú ribiribi tún wáyé lágbo ìṣègùn iṣẹ́ abẹ. Láàárín Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, àwọn gẹrungẹrun ló sábàá máa ń ṣiṣẹ́ abẹ féèyàn. Kò yani lẹ́nu láti gbọ́ táwọn kan sọ pé ọ̀gbẹ́ni ará Faransé kan ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún tó ń jẹ́ Ambroise Paré ló dá ìṣègùn iṣẹ́ abẹ òde òní sílẹ̀. Aṣáájú onímọ̀ iṣẹ́ abẹ ni, ọba ilẹ̀ Faransé mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sì sìn. Paré tún ṣe àwọn ohun èèlò bíi mélòó kan tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ abẹ.

Ọ̀kan lára àwọn ìṣòro ńláǹlà tí oníṣègùn iṣẹ́ abẹ yìí ṣì ní ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ni àìṣeé ṣe fún un láti mú ìrora iṣẹ́ abẹ kúrò. Àmọ́ nígbà tó di 1846, oníṣẹ́ abẹ eyín kan tó ń jẹ́ William Morton ló kọ́kọ́ lo oògùn apàmọ̀lára tí wọ́n ń lò níbi gbogbo báyìí nínú iṣẹ́ abẹ.b

Nígbà tí Wilhelm Röntgen, onímọ̀ físíìsì ń fi iná mànàmáná ṣe àyẹ̀wò kan ní 1895, ó rí i pé àwọn ìtànṣán ń gba inú ẹran ara kọjá àmọ́ kò gba inú egungun. Ìgbà tí kò kúkú mọ ibi tí àwọn ìtànṣán náà ti wá, kò mọ bó ṣe máa ṣàlàyé àwárí tó ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Die Großen Deutschen (Àwọn Èèyàn Ńlá Ilẹ̀ Jámánì) ṣe sọ, Röntgen sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Àwọn èèyàn á sọ pé: ‘orí Röntgen ti dàrú.’” Àwọn kan kúkú sọ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ àwárí rẹ̀ mú ìyípadà bá ìṣègùn iṣẹ́ abẹ. Ó ti ṣeé ṣe báyìí fáwọn oníṣẹ́ abẹ láti rí inú ara láìjẹ́ pé wọ́n là á.

Kíkápá Àwọn Àrùn

Tipẹ́tipẹ́ làwọn àrùn tó ń ran èèyàn, irú bí ìgbóná, ti ń gbèèràn bí iná ọyẹ́, ti ń kó ìpayà báni, ọ̀pọ̀ ló sì ti pa. Ar-Rāzī, ará Páṣíà kan tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹsàn-án, táwọn kan pè ní oníṣègùn tó dáńgájíá jù lọ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí lákòókò yẹn, ló kọ́kọ́ ṣàlàyé tó pé pérépéré nípa ìgbóná. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà ni oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Edward Jenner tóó ṣàwárí ọ̀nà àtiwo àrùn yìí. Jenner kíyè sí i pé béèyàn bá ti lè kó àrùn àléfọ́ ara màlúù—àrùn kan tí kì í ṣèèyàn ní jàǹbá—ìgbóná ò lè mú ẹni yẹn mọ́. Pẹ̀lú àkíyèsí tó ṣe yìí, Jenner wá ha èépá ara ẹni tí àléfọ́ ara màlúù mú, ló bá fi ṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára àrùn ìgbóná. Ìyẹn jẹ́ lọ́dún 1796. Wọn kò ṣàì bẹnu àtẹ́ lu Jenner tí wọ́n sì tún ta kò ó gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣe sáwọn olùṣàwárí tó ṣáájú rẹ̀. Àmọ́ àwárí tó ṣe nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí ló mú kó ṣeé ṣe láti kápá àrùn yìí níkẹyìn, ó sì fún ìmọ̀ ìṣègùn ní ọ̀nà tuntun láti gbéjà ko àrùn.

Abẹ́rẹ́ àjẹsára ni ọmọ ilẹ̀ Faransé náà Louis Pasteur fi gbógun ti àìsàn dìgbòlugi àti àrun anthrax. Ó tún sọ pé àwọn kòkòrò àrùn wà lára ọ̀dádá tó ń dá àìsàn sílẹ̀. Ní 1882, Robert Koch ṣàwárí kòkòrò àrùn tó ń fa ikọ́ ẹ̀gbẹ tí òpìtàn kan pè ní “àrùn panipani tó burú jù lọ ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún.” Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, Koch ṣàwárí kòkòrò tó ń fa àrùn onígbá méjì. Ìwé ìròyìn Life sọ pé: “Akitiyan Pasteur àti Koch ló gbé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè tíntìntín dé, èyí sì ti jẹ́ kí ìlọsíwájú bá ìmọ̀ nípa ìdènà àrùn, àti ìmọ́tótó, àwọn ohun wọ̀nyí ti ṣe bẹbẹ láti mú kéèyàn túbọ̀ pẹ́ láyé sí i ju ohun èyíkéyìí mìíràn tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tíì ṣe fún ẹgbẹ̀rún ọdún tó kọjá lọ.”

Ìmọ̀ Ìṣègùn ní Ọ̀rúndún Ogún

Níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, ńṣe ni ìmọ̀ ìṣègùn gun èjìká àwọn oníṣègùn yìí àtàwọn mìíràn tó tún ní ìmọ̀ gidi gan an. Látìgbà náà ni ìdàgbàsókè ti ń dé lọ́kan-ò-jọ̀kan lọ́nà tó yára kánkán—wọ́n ń lo insulin fún àrùn àtọ̀gbẹ, ìtọ́jú oníkẹ́míkà fún àrùn jẹjẹrẹ, fífi omi ìsúnniṣe tọ́jú ẹṣẹ́, oògùn agbógunti kòkòrò àrùn fún ikọ́ ẹ̀gbẹ, chloroquine fún oríṣi àwọn ibà kan, àti ìtọ́jú fífọ ìdọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò fún àrùn kíndìnrín, bákan náà ni iṣẹ́ abẹ ọkàn àti pípààrọ̀ ẹ̀yà ara àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àmọ́ ní báyìí tí a ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí, báwo ni ìmọ̀ ìṣègùn ti sún mọ́ ète rẹ̀ tó, ìyẹn “fífún gbogbo èèyàn lágbàáyé ní ìlera tó jọjú”?

Ṣé Àlá Tí Kò Lè Ṣẹ Ni?

Àwọn ọmọdé mọ̀ pé gígun èjìká àwọn ẹlẹgbẹ́ àwọn ò sọ pé kọ́wọ́ àwọn tó gbogbo ọsàn tó wà lórí igi kan. Lára àwọn ọsàn tó lómi jù lọ ṣì wà lókè igi lọ́hùn ún, ọwọ́ wọn ò sì lè tó o. Lọ́nà kan náà, onírúurú àṣeyọrí ni ìmọ̀ ìṣègùn ti ṣe, òkè-òkè ló sì ń lọ. Àmọ́ góńgó tó jẹ ẹ́ lọ́kàn jù, ìyẹn ìlera fún gbogbo ènìyàn ṣì wà lókè fíofío níbi tọ́wọ́ ò lè tó.

Abájọ tó jẹ́ pé, lẹ́yìn tí Àjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ní ọdún 1998 sọ pé “àwọn ará Yúróòpù kò tíì gbádùn irú ẹ̀mí gígùn àti ìgbésí ayé tó lárinrin bẹ́ẹ̀ rí,” ó tún fi kún un pé: “Ẹnì kan nínú márùn-ún ni yóò máa kú kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún márùnlélọ́gọ́ta. Àrùn jẹjẹrẹ ló máa pa ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn wọ̀nyí, àrùn òpójẹ̀ máa pa ìdá ọgbọ̀n . . . Ìdáàbòbò tó péye sì gbọ́dọ̀ wà nítorí àwọn àrùn tí á tún yọjú.”

Ní November 1998, ìwé ìròyìn ìlera ilẹ̀ Jámánì náà Gesundheit sọ pé àwọn àrùn tó ń ran èèyàn irú bí onígbá méjì àti ikọ́ ẹ̀gbẹ ti bẹ̀rẹ̀ síí dúnkookò mọ́ èèyàn. Kí ló fà á? Àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn “kò gbéṣẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ńṣe làwọn kòkòrò àrùn ń ya bóorán kalẹ̀; àní oríṣi oògùn kan ò ran púpọ̀ wọn mọ́.” Kì í ṣe pé àwọn àìsàn tá ò gbúròó mọ́ tún ń padà wá nìkan ni, àmọ́ àwọn àrùn tuntun bí Éèdì tún ti dé. Ìwé egbòogi ti ilẹ̀ Jámánì náà Statistics ‘97 sọ pé: “Ìdá méjì nínú mẹ́ta onírúurú àìsàn táa mọ̀ la ò tíì rí ọ̀nà láti wò, ìyẹn sì ń lọ sí bí ọ̀kẹ́ kan àìsàn.”

Ṣé Fífi Àbùdá Ṣe Ìtọ́jú ni Ojútùú Rẹ̀?

Lóòótọ́, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ṣàwárí ìtọ́jú lọ́tun-lọ́tun. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ló rò pé yíyí àbùdá padà lè mú kéèyàn ní ìlera tó jí pépé. Lẹ́yìn ìwádìí táwọn oníṣègùn bíi Dókítà W. French Anderson ṣe láwọn ọdún 1990, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sọ pé fífi àbùdá ṣètọ́jú èèyàn lohun tuntun tó ń “mórí ẹni yá jù lọ tó sì gbajúmọ̀ jù lọ nínú ìwádìí ìmọ̀ ìṣègùn.” Ìwé Heilen mit Genen (Fífi Àbùdá Ṣe Ìtọ́jú) sọ pé fífi àbùdá ṣe ìtọ́jú lè mú kí “ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣègùn sún mọ́ dídi aṣáájú nídìí ìtẹ̀síwájú. Èyí ò sì lè ṣe kó má rí bẹ́ẹ̀ torí àwọn àìsàn tí kò gbóògùn tẹ́lẹ̀ ló ti lóògùn báyìí.”

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ronú pé bí àkókò ti ń lọ á ṣeé ṣe fáwọn láti wo àwọn àrùn tó jẹ́ àjogúnbá nípa fífa àwọn àbùdá tó lè wo àrùn náà sàn sára aláìsàn. Kódà, àwọn kòkòrò tín-tìn-tín inú ara tó lè pa ni lára, irú bí èyí tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ ni wọ́n á mú kí wọ́n máa pa ara wọn. Ó ti ṣeé ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́ láti wo àbùdá èèyàn láti mọ irú àwọn àrùn tó lè kọlu irú ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn kan sọ pé mímú àwọn ohun ìtọ́jú bá àbùdá aláìsàn kan mu tún ni nǹkan mìíràn tí wọ́n máa ṣàwárí. Gbajúgbajà olùwádìí kan sọ pé ọjọ́ kan á jọ́kan táwọn dókítà á lè “ṣàwárí àrùn tó ń ṣe àwọn èèyàn tí wọ́n á sì fún wọn ní ásíìdì DNA kín-ún láti wò wọ́n sàn.”

Bó ti wù kó rí, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà pé fífi àbùdá ṣe ìtọ́jú ló máa jẹ́ ìtọ́jú “ajẹ́bíidán” ní ọjọ́ ọ̀la. Kódà, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ti fi hàn, àwọn èèyàn tiẹ̀ lè máà fẹ́ kí wọ́n yẹ àbùdá wọn wò pàápàá. Ọ̀pọ̀ ló tún ń bẹ̀rù pé ó ṣeé ṣe kí fífi àbùdá ṣe ìtọ́jú ṣàkóbá fún ọ̀nà táa gbà ṣẹ̀dá èèyàn.

Àkókò ló máa fi hàn bóyá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àbùdá tàbí àwọn ọ̀nà ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga mìíràn nípa iṣẹ́ ìṣègùn á lè mú ìlérí kàǹkà-kanka yìí ṣẹ. Àmọ́ ṣá, ó yẹ ká ṣọ́ra ká má ṣe fọkàn wa balẹ̀ sórí òfo. Ìwé The Clay Pedestal, ṣàpèjúwe ohun kan tí a mọ̀ tó máa ń ṣẹlẹ̀ léraléra báyìí: “Wọ́n ṣàwárí ọ̀nà ìṣètọ́jú tuntun, wọ́n polówó rẹ̀ ní ìpàdé àwọn oníṣègùn àti nínú ìwé ìròyìn. Àwọn tó ṣàwárí rẹ̀ á wá di gbajúgbajà nídìí iṣẹ́ ọ̀hún, àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde á sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe sàdáńkátà fún àwárí náà. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti dáwọ̀ọ́ ìdùnnú fún sáà kan tí ẹ̀rí sì ti wà lákọọ́lẹ̀ pé ajẹ́bíidán ni ìtọ́jú náà, làwọn èèyàn ò bá tún ní gba tiẹ̀ mọ́, wọ́n á sì gbàgbé rẹ̀ tó bá fi máa di oṣù tàbí ẹ̀wádún díẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni wọ́n á tún ṣàwárí ìtọ́jú mìíràn, lójú ẹsẹ̀ ni wọ́n á pa ti tẹ́lẹ̀ tì, wọ́n á ní kò wúlò mọ́.” Kẹ́ẹ sì máa wò ó, ọ̀pọ̀ ìtọ́jú tí ọ̀pọ̀ dókítà sọ pé kò gbéṣẹ́ mọ́ ló jẹ́ èyí tí wọ́n ni ó pójú owó léyìí tí kò pẹ́ sẹ́yìn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í fojú ẹlẹ́sìn tí wọ́n fi ń wo àwọn oníwòsàn láyé ọjọ́un wo àwọn dókítà òde òní, àwọn kan ṣì lè sọ pé agbára tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bí ti òrìṣà làwọn oníṣègùn ń lò kí wọ́n sì máa ronú pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì á wo gbogbo àrùn aráyé sàn. Àmọ́ ṣá, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fi hàn pé èrò yìí ò tọ̀nà rárá àti rárá. Dókítà Leonard Hayflick sọ nínú ìwé rẹ̀, How and Why We Age, pé: “Lọ́dún 1900, ìpín márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn ní United States ló ń kú kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún márùnlélọ́gọ́ta. Lónìí, ọ̀rọ̀ ti yí padà: nǹkan bí ìpín àádọ́rin èèyàn ló ń lé lọ́mọ ọdún márùnlélọ́gọ́ta kí wọ́n tó kú.” Kí ló mú kí ẹ̀mí èèyàn wá gùn lọ́nà tó jọni lójú bẹ́ẹ̀? Hayflick ṣàlàyé pé “ògidì ohun tó fà á ni bí àwọn ọmọ ọwọ́ ò ṣe ń kú bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.” Ó dáa, ká wá sọ pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣègùn lè mú àwọn ohun tó sábàá ń fa ikú àwọn àgbàlagbà, bí àrùn ọkàn, àrùn jẹjẹrẹ, àti àrùn ẹ̀gbà kúrò. Ṣé ìyẹn á wá túmọ̀ sí pé èèyàn ò ní kú mọ́? Kò rí bẹ́ẹ̀. Dókítà Hayflick sọ pé bó bá tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, “ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ̀mí wọn ò ní gùn ju nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lọ.” Ó fi kún un pé: “Àwọn tọ́jọ́ orí wọn bá pé ọgọ́rùn-ún ọdún á ṣì kú. Àmọ́ kí ló máa pa wọn? Ńṣe ni wọ́n á kàn bẹ̀rẹ̀ sí di ahẹrẹpẹ títí wọ́n á fi kú.”

Láìfi akitiyan tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣègùn ń ṣe pè, mímú ikú kúrò ṣì kọjá agbára ìmọ̀ ìṣègùn. Èé ṣe tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ṣé àlá tí ò lè ṣẹ wá ni lílépa ìlera fún gbogbo èèyàn jẹ́?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣe sọ, Galen ronú pé ńṣe ni ẹ̀dọ̀ máa ń yí oúnjẹ tó bá ti dà padà sí ẹ̀jẹ̀, táá wá ṣàn lọ sáwọn ibi tó kù nínú ara.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, “From Agony to Anesthesia,” tí ó fara hàn nínú Jí! Gẹ̀ẹ́sì ìtẹ̀jáde November 22, 2000.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ àtayébáyé ṣì ń fara hàn nínú iṣẹ́ ìṣègùn tó ń bá a lọ títí dòní olónìí.”—The Clay Pedestal

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Hippocrates, Galen, àti Vesalius ló fi ìpìlẹ̀ ìṣègùn òde òní lélẹ̀

[Àwọn Credit Line]

Erékùṣù Kos, Gíríìsì

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda National Library of Medicine

Woodcut látọwọ́ Jan Steven von Kalkar ti A. Vesalius, táa mú jáde látinú Meyer’s Encyclopedic Lexicon

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Aṣáájú onímọ̀ iṣẹ́ abẹ ni Ambroise Paré, ó sì sin ọba ilẹ̀ Faransé mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Ar-Rāzī oníṣègùn ará Páṣíà (lápá òsì), àti oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà Edward Jenner (lápá ọ̀tún)

[Àwọn Credit Line]

Paré àti Ar-Rāzī: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda National Library of Medicine

Látinú ìwé Great Men and Famous Women

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Louis Pasteur ará Faransé fẹ̀rí hàn pé àwọn kòkòrò tín-tìn-tín máa ń fa àrùn

[Credit Line]

© Institut Pasteur

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ká tiẹ̀ sọ pé àwọn lájorí ohun tó ń fa ikú kò sí mọ́, ọjọ́ ogbó á ṣì máa jẹ́ kéèyàn kú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́