ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 6/15 ojú ìwé 3-5
  • Ijakadi Lodi Si Aisan ati Iku A Ha Nja Ajaṣẹgun Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ijakadi Lodi Si Aisan ati Iku A Ha Nja Ajaṣẹgun Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Arun “Titun”
  • Kò Sí Ẹ̀rí Pé Ìwòsàn Ńbọ̀ Lọ́nà
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
  • Ìṣègùn Òde Òní—Ibo Lagbára Rẹ̀ mọ?
    Jí!—2001
  • Ọjọ́ Pẹ́ Táráyé Ti Ń Gbógun Ti Àrùn
    Jí!—2004
  • Ibi Táráyé Ṣẹ́gun Àrùn Dé àti Ibi Tó Kù Sí
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 6/15 ojú ìwé 3-5

Ijakadi Lodi Si Aisan ati Iku A Ha Nja Ajaṣẹgun Bi?

KÒ SÍ aisan mọ, kò sí iku mọ! Fun ọpọlọpọ eniyan eyi le dún bii ohun ti o fẹrẹẹ ma ju igbagbọ ninu ohun ti ẹnikan fẹ ki o ṣẹlẹ lọ. O ṣetan, gẹgẹ bi dokita iṣegun ati ọjọgbọn ninu imọ ijinlẹ kokoro bacteria Wade W. Oliver ti kọwe: “Lati igba akọsilẹ itan ijimiji julọ, arun ti nipa lori kadara araye lọna àìlóǹkà . . . Ajakalẹ arun ńláǹlà ti rọ́ lu eniyan lojiji pẹlu ìyára kánkán ti ńdáyà já ni . . . Okunrun ti figba gbogbo tẹle awọn ipasẹ rẹ̀.”

Idi kankan ha wa lati gbagbọ pe iyipada ojiji ti sunmọle bi? Imọ ijinlẹ iṣegun ha ti sunmọ tosi mimu gbogbo aisan ati boya iku funraarẹ paapaa kuro bi?

Láìsí iyèméjì, awọn oniṣegun ati olùwádìí ti ṣe iṣẹ pipẹtẹri ninu jijagun lodi si arun. Ọmọwe eniyan wo ni o le kuna lati kún fun imoore fun aṣeyọri si rere ọna iwosan arun kọ́lẹ́rà, ti o di ṣiṣẹ ni ìgbẹ̀hìngbẹ́hín ni òpin ọrundun kọkandinlogun, tabi fun imujade àjẹsára lodi si arun ṣànpọ̀nná adáyà fo ni? Àjẹsára yẹn ni a mu jade ni 1796 nipasẹ Edward Jenner lati inu egbò arun ṣànpọ̀nná maluu ti kii yara ṣekú pa ni. Ni 1806, ààrẹ Thomas Jefferson ti United States sọ imọlara ọpọlọpọ awọn miiran jade nigba ti o kọwe si Jenner pe: “Tirẹ ni iranti atuni lara tí araye ko le gbagbe lae pe o ti gbé rí; awọn orilẹ-ede ẹhin ọla yoo mọ kiki nipasẹ itan pe arun ṣànpọ̀nná asúnni fún ìríra wà rí.”

Jù bẹ́ẹ̀ lọ, awọn àṣeyọrí sí rere iwadii iṣegun ni isopọ pẹlu awọn arun iru bii diphtheria [arun ti o le ranni ti o maa ńmúni ní ihò imú, ọna ọfun, ti o mu ki o ṣoro lati mí] ati poliomyelitis [arun àkóràn ti ńmú eegun ẹhin ti o saba maa nsọni di arọ] ni a tun gbọdọ mẹnukan lọna rere ati pẹlu imoore. Iwọnba awọn eniyan diẹ lonii ni wọn ko si fiyin fun itẹsiwaju pupọ sii ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ninu ọna iwosan arun ọkan-aya ati káńsà. Laika eyiini si, awọn eniyan ṣì ńkú lati inu arun ọkan-aya ati káńsà. Góńgó mímú gbogbo arun ati aisan kuro ti fi ẹri han pe àléèba ni.

Awọn Arun “Titun”

Ni odikeji sii, sanmani ode oni ti o ti ri dide iṣẹ abẹ ti a fi ńtún awọn ẹ̀yà ara rọ [CAT scans and reconstructive surgery] ti tun ri ibẹrẹ ọgọọrọ awọn arun “titun,” iru bii Legionnaires [arun àkóràn ẹdọ fóró ti a saba maa ńko nibi ti ọpọlọpọ eniyan ba péjọ sí], toxic shock syndrome, ati arun apani ti a kede rẹ lọna gbigbooro naa ti njẹ AIDS.

A gbà pe, ọpọlọpọ gbé ibeere dide si bi awọn arun titun wọnyi ṣe jẹ titun tó. Ọrọ-ẹkọ kan ninu U.S.News and World Report sọ pe, ninu awọn ọran diẹ, awọn arun ti wọn ti wà yika fun igba pipẹ ni a wulẹ ti wá dámọ̀ lọna yiyẹrẹgi ti a si fun wọn ni awọn orukọ titun. Fun apẹẹrẹ, arun Legionnaires ni a kọkọ mọ ni 1976, ṣugbọn a le ti ṣii mọ ni iṣaaju gẹgẹ bi viral pneumonia [arun otutu àyà ti kokoro fáírọ́sì ńfà]. Lọna ti o fara jọra, toxic shock syndrome ni a ti le ṣì mú fun scarlet fever.

Laika eyi ni si, iye awọn òkùnrùn meloo kan ni o jọ bii pe wọn jẹ titun láìṣiyèmeji. Ko si iyèmeji pe AIDS ni a mọ̀ julọ lara awọn wọnyi. Arun asọni dalaiwulo ti o si nyọri si iku yii ni a kọkọ dá mọ̀ ti a si fun ni orukọ ni 1981. Arun “titun” ti a kò mọ̀ tó bẹ́ẹ̀ miiran ni Brazilian purpuric fever. A dá a mọ̀yàtọ̀ ni Brazil ni 1984 o si ti ṣokunfa iye iku ti o tó ipin 50 ninu ọgọrun un.

Kò Sí Ẹ̀rí Pé Ìwòsàn Ńbọ̀ Lọ́nà

Nitori naa, laika awọn isapa didara julọ ti eniyan sí, iwosan kikun ti o sì wà titilọ fun ailera eniyan ni ko si ẹri pe o nbọ lọna. Otitọ ni pe ipindọgba iye ọdun ti ẹnikan le gbé láyé gẹgẹ bi eniyan ti ga sii ni nǹkan bi 25 ọdun lati ọdun 1900. Ṣugbọn iyipada yii ni o ti jẹ́ ni pataki nitori awọn ọna ọgbọn iwosan ti o ti din ewu kíkú nigba ọmọ-ọwọ tabi ni ọmọde kù. Niti gidi, gigun iwalaaye eniyan wà lẹbaa “aadọrin ọdun” ti Bibeli.—Saamu 90:10.

O tipa bayi di koko irohin nigba ti Anna Williams ku ni December 1987 ni ẹni ọdun 114. Ni sisọrọ lori iku Omidan Williams, akọrohin kan kọwe pe: “Awọn onimọ ijinlẹ ronu pe 115 si 120 ọdun ni o ṣeeṣe ki o jẹ opin giga julọ ti gigun iwalaaye eniyan. Ṣugbọn eeṣe ti iyẹn fi nilati jẹ́ bẹ́ẹ̀? Eeṣe ti ara eniyan fi nwa sopin lẹhin 70, 80, tabi 115 ọdun paapaa?”

Ni awọn ọdun 1960, awọn onimọ ijinlẹ iṣegun ṣawari pe awọn sẹ́ẹ̀lì eniyan jọ bi eyi ti o ni agbara lati pín kiki ni nǹkan bi 50 igba. Gbara ti a ba ti dori góńgó yii, o jọ pe a kò le ṣe ohunkohun lati mu ki awọn sẹ́ẹ̀lì maa walaaye lọ. Eyi ni o dabi pe o lodi si aba ero-ori ti imọ ijinlẹ ti iṣaaju pe awọn sẹ́ẹ̀lì eniyan le maa walaaye niṣo lailopin bi a ba fi si awọn ipo ti o yẹ.

Pa iyẹn pọ̀ pẹlu mímọ̀ dájú pe pupọ ninu ijiya eniyan jẹ afọwọfa eniyan. Gẹgẹ bi oluwadii kan ti fi ironu jinlẹ pari ero: “Awọn arun ni a ko tii ṣẹgun nipasẹ iwosan elegboogi nikan. Itan arun ni a so pọ timọtimọ pẹlu awọn okunfa ẹgbẹ-oun-ọgba ati iwa rere.”

Eto-ajọ Ilera Agbaye ṣakiyesi pe: “A ti pa ara wa lara, ninu igbagbọ naa pe imọ ijinlẹ, awọn dokita ati ile-iwosan yoo ri iwosan kan, dipo didena awọn okunfa òkùnrùn naa gan an lakọọkọ. Dajudaju a ko le ṣai nilo awọn ipese itọju iṣegun ti ngba ẹmi là niti tootọ, ṣugbọn ẹ jẹ ki o yé wa pe wọn ko fikun ‘ilera’ wa—wọn kò wulẹ jẹki a kú ni. . . . Òòfà lilagbara apara-ẹni run ti ẹni tí ńmu siga ati ẹni tí ńmu ọti, awọn iyọrisi lori ero inu ati ara ti airiṣẹ ṣe—awọn wọnyi ni diẹ lara awọn ‘aisan titun naa.’ Eeṣe ti a fi yọnda fun ‘ọ̀pọ̀ jaburata ijamba oju popo,’ eyi ti o ngba awọn ẹmi ti o si nfa orisun inawo wa gbẹ?”

Arun, aisan, ijiya, ati iku nipa bayii ṣi wà pẹlu wa pupọpupọ. Laika eyiini sí, awa ni idi lati foju sọna pẹlu igbọkanle si akoko kan nigba ti ki yoo sí aisan mọ ti ki yoo sì sí iku mọ. Ju gbogbo rẹ lọ, gbogbo idi ni o wà lati gbagbọ pe akoko yẹn ti sunmọ etile.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

“AWỌN ARUN IJIBITI”

Pé eniyan ti bá òkùnrùn jà laisi aṣeyọri si rere lati igba ijimiji ni a ṣakiyesi ani ninu Bibeli paapaa. Fun apẹẹrẹ, Mose ṣe itọkasi ti o fani lọkan mọran kan si “arun buburu Ijibiti.”—Deutaronomi 7:15.

Lọna ti o hàn gbangba awọn wọnyi ní jàkùtẹ̀, ìgbẹ́ ọ̀rìn, ṣànpọ̀nná, bubonic plague, ati ophthalmia ninu. Awọn eniyan Mose bọ́ lọwọ iru awọn ailera bẹẹ ni pataki nitori itẹsiwaju awọn aṣa ilera ti a Ofin majẹmu gbé kari wọn.

Bi o ti wu ki o ri, iṣayẹwo kínníkínní ara oku awọn ara Ijibiti, ti yọrisi dida ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ “awọn arun Ijibiti” miiran mọ. Awọn wọnyi ni ninu oríkèé wiwu, spondylitis, akokoro ati yọ̀rọ̀, appendicitis, ati gout. Ikọwe iṣegun aye ti ijimiji kan, ti a mọ si Ebers Papyrus, tilẹ mẹnukan awọn arun iru bii kókó ara, irora inu ati ẹdọ, àtọ̀gbẹ, ẹ̀tẹ̀, oju pipọn, ati ìyadi.

Awọn oniṣegun Ijibiti igbaani ṣe ohun ti wọn le ṣe lati jà lodi si awọn òkùnrùn wọnyi, awọn kan di ogbogi gan an ninu papa iṣegun wọn. Opitan Giriiki Herodotus kọwe pe: “Ilẹ orilẹ-ede [Ijibiti] kun fun awọn oniṣegun; ọkan nwo kiki awọn arun oju; awọn miiran ti ori, ehin, ati ikun, tabi awọn ẹya inu.” Bi o ti wu ki o ri, ọpọjulọ ninu “oogun” awọn ara Ijibiti jẹ idibọn onisin ti o si jinna si imọ ijinlẹ.

Awọn oniṣegun ode oni ti gbadun aṣeyọri si rere pupọ sii ninu ijakadi wọn lodi si arun. Sibẹ, oluwadii iṣegun Jessie Dobson fa ipari ero agberonu dide yii yọ pe: “Nigba naa, ki ni a lè mọ lati inu ikẹkọọ awọn arun igba laelae? Ipari ero gbogbogboo lati inu iwadii kiri ẹri naa jọ bi pe awọn arun ati inira ti igba jíjìnà réré sẹhin ko yatọ ni kedere si awọn ti isinsinyi . . . Lọna ti o hàn gbangba gbogbo awọn òye ati isapa ti iwadii alaisan ko tii ṣe eyi ti o pọ tó lati mu arun kuro.” —Disease in Ancient Man.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́