ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 3/1 ojú ìwé 3-5
  • Ariyanjiyan Nla naa Ki ni O Jẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ariyanjiyan Nla naa Ki ni O Jẹ?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ariyanjiyan Nla Naa
  • Ipilẹṣẹ Agbaye
  • Ipilẹṣẹ Iwalaaye
  • Yiyanju Ariyanjiyan Naa
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ogun Tí Wọ́n Á Fi Bọ́ǹbù Átọ́míìkì Jà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àwọn Wo Ló Ń Gbára Dì fún Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé?
    Jí!—2004
  • Ẹlẹ́dàá Lè Mú Kí Ayé Rẹ Nítumọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ó Dájú Pé Ewu Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Kò Tíì Kásẹ̀ Nílẹ̀
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 3/1 ojú ìwé 3-5

Ariyanjiyan Nla naa Ki ni O Jẹ?

KI NI ariyanjiyan nla naa ti o dojukọ ẹnikọọkan wa? O ha jẹ omi òkun ti kíkún rẹ̀ nga sii ati oju ọjọ alaibarade tí ìmóoru yika ile-aye ńfà ni bi? O ha jẹ ìmúpòórá ibori afẹfẹ ozone, ti o nṣamọna si fifi ara sabẹ itanṣan ultraviolet ti oorun lọna ti o kun fun ewu ni bi? O ha jẹ iye eniyan pupọ rekọja aala, eyi ti o mu awọn iṣoro miiran yika ilẹ-aye di pupọ, iru bii òṣì ati iwa-ọdaran ni bi? Tabi o ha jẹ ifojusọna fun iparun yán-ányán-án ti araadọta ọkẹ alainiye ninu ogun atọmiki, ninu eyi ti awọn ti wọn la iparun nla naa já yoo maa ku ninu ìjẹ̀rora lati ọwọ otútù, airi ounjẹ jẹ, tabi ooru atọmiki ni bi?

Lẹhin jijiroro iwọnyi ati awọn ariyanjiyan miiran, ni 1989 iwe irohin naa Scientific American pari-ero pe: “Laiṣe aniani ṣiṣeeṣe ogun atọmiki duro fun ewu ririnlẹ julọ ti o le ṣẹlẹ sí . . . lilaaja.” Nigba naa, ogun atọmiki ha ni ariyanjiyan naa ti o dojukọ wa bi?

Ariyanjiyan Nla Naa

Pẹlu iyipada ninu ipo oṣelu lati 1989, ogun atọmiki le jọ bii ẹni pe ko ni waye. Ani bi o tilẹ jẹ bẹẹ, niwọnbi awọn ohun ija atọmiki ba ṣì wà, wọn yoo gbe ihalẹmọni elewu ka iwaju araye. Bi o ti wu ki o ri, isọfunni ninu 1990 Britannica Book of the Year tọkasi ọran lilekoko miiran. Gẹgẹ bi itọkasi yii ti wi, awọn olugbe ilẹ-aye ti wọn ju 230 million jẹ alaigbọlọrungbọ. Awọn orisun miiran fihan pe afikun araadọta ọkẹ ni ọgbọn-imọ-ọran Ila-oorun ti o yọọda fun oju iwoye pe ko si Ẹlẹdaa kankan lo agbara idari le lori. Ju bẹẹ lọ, nigba ti o jẹ pe ọgọrọọrun lọna araadọta ọkẹ gbagbọ ninu Ẹlẹdaa kan, ero wọn nipa rẹ̀ yàtọ̀síra patapata. Ati ninu ọpọlọpọ ọran, iwa wọn nmu ẹ̀gàn nlanla wa sori Ẹni naa ti wọn sọ pe wọn njọsin.—2 Peteru 2:1, 2.

Bi Ọlọrun ba wà—ti oun sì wà dajudaju han-unhan-un—nigba naa ariyanjiyan ṣiṣekoko julọ lonii dajudaju gbọdọ niiṣe pẹlu rẹ. Eeṣe ti oun fi da araye? Ki ni ẹru-iṣẹ wa si i? Bawo ni oun yoo ṣe huwapada si ọna ti eniyan ngba pa ilẹ-aye run? Bawo ni oun yoo si ṣe dahunpada si ipenija ti kíkọ̀ ọpọlọpọ eniyan tobẹẹ lati nigbagbọ ninu rẹ̀ tabi lati tẹriba fun ifẹ-inu rẹ̀ tumọsi? Niti tootọ, ariyanjiyan nla naa ti o dojukọ ẹnikọọkan wa ni yala lati tẹwọgba tabi kọ̀ ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun silẹ, “ẹni kanṣoṣo ti njẹ JEHOFA.”—Saamu 83:18.

Ipilẹṣẹ Agbaye

Dajudaju, fun awọn wọnni ti wọn kò ni igbagbọ ninu Ọlọrun, ẹru iṣẹ wa siha ọdọ rẹ̀ kii ṣe ohun ariyanjiyan. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi otitọ inu wo iṣẹ-ọna ati ẹwà ilẹ aye ti o jẹ ibugbe wa ni a fi agbara sún lati gbà pe Olùpète nla kan gbọdọ wà. Otitọ ni pe ni gbigbiyanju lati ṣalaye awọn ohun iyanu adanida ti o yi wa ka, ọpọ julọ awọn onimọ ijinlẹ ni wọn ko ka Ọlọrun si ẹni ti o wà ni ipò lati mọ gbogbo otitọ naa. Fun apẹẹrẹ, ọpọlọpọ wipe agbaye tobi de iwọn rẹ̀ ti isinsinyi lati ìwọ̀n bín-íntín kan ti o kere ju ori abẹ́rẹ́ lọ, pe gbogbo rẹ̀ ṣẹlẹ “lọna adanida,” nipa èèṣì, láìnílò Ẹlẹdaa kan. Bi o ti wu ki o ri, lẹhin ṣiṣe alaye àbá èrò-orí titun ti o wọpọ lori bi agbaye ṣe bẹrẹ, onimọ ijinlẹ physics naa Hanbury Brown, ninu iwe rẹ The Wisdom of Science, jẹwọ pe: “Mo rò pe, fun ọpọjulọ awọn eniyan, iyẹn yoo jọ bi ẹni pe o jẹ àgálámàṣà dipo alaye.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Brown pari ọ̀rọ̀ pe “ipilẹṣẹ ati ète aye” jẹ “awọn ohun ijinlẹ nlanla” tí imọ ijinlẹ jọ bi ẹni pe ko le yanju.

Awọn onimọ ijinlẹ ti ṣaṣefihan pe awọn ohun eelo ti o di gbogbo agbaye ati awọn ohun àmúṣagbára tanmọra pẹkipẹki ati pe awọn ohun eelo ti o di gbogbo agbaye ni a le yipada si ohun àmúṣagbára a sì lè yi ohun àmúṣagbára pada si awọn ohun eelo ti o di gbogbo agbaye. Gẹgẹ bi a ti rii ninu awọn ìbúgbàù atọmiki, iye kekere kan lara awọn ohun eelo ti o di gbogbo agbaye duro fun iye agbara nla kan. Nigba naa, nibo ni orisun gbogbo agbara tí awọn irawọ 100,000 million ninu iṣupọ irawọ wa duro fun, ati pẹlu 1,000 million iṣupọ irawọ ti o parapọ jẹ agbaye ti a lè fojuri wà?

Bibeli wipe: “Gbe oju yin soke si ibi giga, ki ẹ sì wò, ta ni o da nnkan wọnyi, ti nmu ogun wọn jade wá ni iye: o npe gbogbo wọn ni orukọ nipa titobi ipá rẹ̀, nitori pe oun le ni ipá; kò si ọkan ti o kù.” Ta ni Ẹni yẹn? Akọsilẹ Bibeli naa dahun pe: “Emi ni Jehofa. Eyiini ni orukọ mi; ògo mi ni emi ki yoo sì fi fun ẹlomiran kankan.”—Aisaya 40:26; 42:5, 8, New World Translation.

Imefo pe ilẹ-aye papọ pẹlu iyoku agbaye pilẹṣẹ nipa èèṣì mu ogo ti o yẹ Ẹlẹdaa naa, Jehofa Ọlọrun kuro. (Iṣipaya 4:11) O tun mu isunniṣe alagbara lati huwa si ilẹ-aye gẹgẹ bi ẹni ti yoo jihin kuro. Bi awọn ẹda eniyan ba mọ pe awọn yoo jihin fun Ọlọrun ohun ti wọn ṣe si iṣẹda rẹ̀, boya wọn yoo tubọ jẹ oniṣọọra ninu iru awọn ọran bii biba ayika jẹ, iparun ìbòrí afẹfẹ ozone, ati imooru yika ile aye.

Ipilẹṣẹ Iwalaaye

Tun gbe ibeere naa yẹwo: Bawo ni iwalaaye ṣe bẹrẹ? Awọn eniyan ni a ti kọ́ pe iwalaaye ṣẹlẹ laisi ilọwọsi eyikeyii lati ọdọ Ọlọrun. Ṣugbọn eyi lodisi ilana tí imọ ijinlẹ ti fìdí rẹ̀ mulẹ daradara. Ni igba kan a gbà á gbọ́ pe awọn yímíyímí wá lati inu ẹlẹ́bọ́tọ, aràn lati inu ẹran-ara jíjẹrà, ati èkúté lati inu ẹrọ̀fọ̀. Ani laaarin ọrundun ti o kọja paapaa, awọn onimọ ijinlẹ kọni pe awọn ohun alaaye ti ko ṣeefojuri wá lati inu awọn nnkan aláìlẹ́mìí. Ṣugbọn awọn èrò bii iwọnyi ni a jadii eke wọn lati ọwọ́ Redi, Pasteur ati awọn onimọ ijinlẹ miiran. The World Book Encyclopedia (itẹjade 1990) wipe: “Lẹhin awọn iwadiiyẹwo Pasteur, ọpọ julọ awọn onimọ ijinlẹ nipa ẹ̀dá alaaye tẹwọgba ero naa pe gbogbo iwalaaye wá lati inu iwalaaye ti o ti wà ṣaaju.”

Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn onimọ ijinlẹ dabaa ero ori pe ni igba jijinna réré sẹhin, awọn nǹkan yatọ. Wọn sọ pe awọn ohun alaaye akọkọ onísẹ́ẹ̀lì kanṣoṣo dide nipa eeṣi lati inu apopọ alailẹmii kan ti wọn npe ni ọbẹ̀ àtayébáyé, eyi ti o ni awọn egboogi ti a nilo fun iwalaaye ninu. “Èèṣì, ani èèṣì nikanṣoṣo, ni o ṣe gbogbo rẹ̀, lati inu ọbẹ̀ àtayébáyé si eniyan,” ni Christian de Duve polongo ninu A Guided Tour of the Living Cell.

Ni sisọrọ nipa Ọlọrun, Bibeli wipe: “Pẹlu rẹ ni orisun iye wà.” (Saamu 36:9) Gbolohun ọ̀rọ̀ yii wà ni ibaramuṣọkan nitootọ pẹlu ohun ti a ti ṣakiyesi—pe iwalaaye lè wá kiki lati inu iwalaaye ti o ti wà ṣaaju. Bi o ti wu ki o ri, niwọnbi ọna ironu imọ ijinlẹ ti o wọpọ ti fẹ lati wo ọkan lara awọn ẹbun ṣiṣeyebiye julọ ti Ọlọrun, iwalaaye, gẹgẹ bi ohun kan ti o ṣàdédé ṣẹlẹ, ọpọlọpọ eniyan ko nimọlara bi ẹni ti yoo jihin fun Ọlọrun nipa bi wọn ṣe lo igbesi-aye wọn. Nipa bayii, wọn ńrú awọn ofin Ọlọrun, wọn ńpọ́n araawọn ẹnikinni keji loju, wọn nja araawọn lólè, wọn nṣikapa araawọn, wọn sì ńná ọpọlọpọ owó, akoko, ati ọgbọn inu ninu pipete awọn ohun ija aṣekupani ti npani ti o si nṣeparun yán-ányán-án pẹlu ijafafa akó jinnijinni bani.

Yiyanju Ariyanjiyan Naa

Yatọ si awọn alaigbọlọrungbọ ati awọn elero igbalode, ailonka awọn miiran sẹ́ ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun. Ọpọlọpọ iye eniyan lonii sọ pe wọn gbagbọ ninu Ọlọrun, ohun ti o sì ju 1,700 million pe araawọn ni Kristian. Fun ọpọ ọ̀rúndún ṣọọṣi Kristẹndọm ti yin Ọlọrun logo ni gbangba ninu awọn isin wọn. Ṣugbọn nibo ni ọpọ julọ lara 1,700 million eniyan wọnni duro si niti gidi lori ọran ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun?

Awọn ẹnikọọkan ati orilẹ-ede ti ṣaṣefihan ainaani rẹ̀ nipa titako awọn aṣẹ pato ti Ọlọrun. Awọn orilẹ-ede ti wọn sọ pe awọn jẹ Kristian ti fi aiwa bi Ọlọrun hù iwa ipa, ti o ni awọn ogun biburu julọ meji ninu itan ẹda eniyan ninu—awọn alufaa niha mejeeji ti wọn jẹ “Kristian” si gbadura fun awọn ogun wọnni! Nipa iru agabagebe bẹẹ, wọn ti ṣoju fun Ọlọrun lọna èké lọpọlọpọ. Gẹgẹ bi Bibeli ti wi: “Wọn jẹwọ pe wọn mọ Ọlọrun; ṣugbọn nipa iṣẹ wọn ńsẹ́ ẹ.”—Titu 1:16.

Bi o tilẹ ri bẹẹ, Ọlọrun “kò lè sẹ́ araarẹ.” (2 Timoti 2:13) Akoko naa gbọdọ de nigba ti oun yoo yanju gbogbo apa iha ariyanjiyan ipo ọba-alaṣẹ yii ni ibamu pẹlu ète rẹ tí oun funraarẹ sọ: “Wọn yoo sì mọ̀ pe emi ni Jehofa.” (Esekiẹli 38:23, NW) Ṣugbọn eeṣe ti o fi gba akoko pipẹ tobẹẹ? Bawo ni a o ṣe yanju ariyanjiyan yii nikẹhin? Bawo sì ni iwọ yoo ṣe ṣe awọn ipinnu titọna ninu ọran pataki julọ yii?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Àwòrán àfitẹ́lẹ̀ Ẹ̀yìn Ìwé: Fọto U.S. Naval Observatory

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Aworan àfitẹ́lẹ̀: Fọto U.S. Naval Observatory

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́