Àpótí Ìbéèrè
◼ Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nígbà tá a bá ń lo cellular phone [tẹlifóònù alágbèérìn] àti electronic pager [ohun èlò atanilólobó]?
Irú àwọn ohun èlò bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti kàn sí àwọn ẹlòmíràn láti ibikíbi tá a bá wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí wúlò gan-an, a ní láti ṣọ́ra kí lílò tá à ń lo tẹlifóònù alágbèérìn àti ohun èlò atanilólobó lásìkò tí kò yẹ má bàa tàbùkù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tàbí àwọn ìpàdé Kristẹni wa. Báwo lèyí ṣe lè ṣẹlẹ̀?
Ronú lórí ohun tó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ bí tẹlifóònù alágbèérìn wa bá dún ganran-un ganran-un tàbí tí ohun èlò wa tó ń tani lólobó bá han gooro nígbà tá à ń jẹ́rìí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Kí lohun tí onílé máa rò? Kí lèrò tá a máa gbìn sọ́kàn onílé bá a bá dánu dúró láti dáhùn ìpè náà? Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa ṣèdíwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn láti fetí sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. (2 Kọ́r. 6:3) Nítorí náà, bá a bá mú tẹlifóònù alágbèérìn tàbí ohun èlò atanilólobó dání, ńṣe ló yẹ ká yí i wálẹ̀ kí ó má bàa pín ọkàn wa níyà tàbí kó dí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
Ká ní ńṣe là ń dúró de àwọn tó ń jẹ́rìí lọ́wọ́ ńkọ́? Bá a bá ti ya àkókò pàtó kan sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ǹjẹ́ kì í ṣe orí rẹ̀ ló yẹ ká pọkàn pọ̀ sí? Láti fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa, ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ ká fi bíbójú tó àwọn ohun tí kò pọn dandan, èyí tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ara ẹni tàbí àwọn ohun tó da àwa àtàwọn ẹlòmíràn pọ̀ sí àkókò mìíràn. (Róòmù 12:7) Àmọ́ ṣá o, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé a ò lè fi tẹlifóònù jẹ́rìí síwájú sí i tàbí ká lò ó fún ṣíṣe àdéhùn láti wá jẹ́rìí síwájú sí i.
Ó tún yẹ ká ṣọ́ra gidigidi nípa lílo tẹlifóònù alágbèérìn nígbà tá a bá ń wakọ̀, nítorí pé àwọn ìwádìí kan fi hàn pé ṣíṣe èyí lè mú kí ewu ìjàǹbá ọkọ̀ pọ̀ sí i. A ní láti pa òfin èyíkéyìí tí kò bá fàyè gba lílo tẹlifóònù alágbèérìn nígbà téèyàn bá ń wakọ̀ mọ́.
Ìdí tá a fi ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, àpéjọ àyíká, àti àpéjọ àgbègbè ni láti lọ jọ́sìn Jèhófà ká sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìmọrírì tá a ní fún jíjẹ́ tí àwọn ìpàdé wa jẹ́ ohun ọ̀wọ̀ sún wa láti yí tẹlifóònù alágbèérìn àti ohun èlò wa tó ń tani lólobó wálẹ̀, kí wọ́n má bàa fa ìpínyà ọkàn fún wa tàbí fún àwọn ẹlòmíràn? Bí ọ̀ràn kánjúkánjú kan bá wà tó pọn dandan pé ká bójú tó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìta gbọ̀ngàn ìpàdé ló yẹ ká ti ṣe èyí. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó yẹ ká ṣètò láti bójú tó àwọn ọ̀ràn tó jẹ́ ti ara ẹni àtàwọn tí kò jẹ mọ́ ìjọsìn láwọn àkókò mìíràn tó yàtọ̀ sáwọn àkókò tá a yà sọ́tọ̀ fún ìjọsìn.—1 Kọ́r. 10:24.
Ẹ jẹ́ kí ọ̀nà tá a gbà ń lo tẹlifóònù alágbèérìn tàbí àwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ mìíràn fi hàn pé a ní ìgbatẹnirò fáwọn ẹlòmíràn, pé a sì ní ìmọrírì àtọkànwá fáwọn nǹkan tẹ̀mí.