Àpótí Ìbéèrè
◼ Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa lílo fóònù alágbèéká ní ìpàdé àti lóde ẹ̀rí?
“Ohun Gbogbo Ni Ìgbà Tí A Yàn Kalẹ̀ Wà Fún” (Oníw. 3:1): Àwọn èèyàn sábà máa ń fi fóònù alágbèéká pe ara wọn tàbí kí wọ́n fi fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ nígbàkigbà tó bá wù wọ́n. Àmọ́, àwọn ìgbà míì wà tí àwa Kristẹni kì í fẹ́ kí fóònù wa pín ọkàn wa níyà. Bí àpẹẹrẹ, torí ká lè jọ́sìn Jèhófà, ká gba ìtọ́ni tẹ̀mí, ká sì fún ara wa níṣìírí la ṣe ń lọ sí ìpàdé. (Diu. 31:12; Sm. 22:22; Róòmù 1:11, 12) Ǹjẹ́ kò ní dáa ká pa fóònù wa, ká sì jẹ́ kí ìpàdé parí ká tó máa wo àwọn àtẹ̀jíṣẹ́ tó bá wà níbẹ̀? Tó bá pọn dandan pé ká tan fóònú wa sílẹ̀ nítorí àwọn ìpè pàjáwìrì, ó yẹ ká ṣe é lọ́nà tí kò fi ní dí àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.
“Ṣe Ohun Gbogbo Nítorí Ìhìn Rere” (1 Kọ́r. 9:23): Láwọn ìgbà míì, ó máa ń pọn dandan pé ká lo fóònù alágbèéká lóde ẹ̀rí. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin tó darí àwọn ará lọ sóde ẹ̀rí lè lò ó láti fi pe àwọn kan lára àwọn tí wọ́n jọ wá sóde. Nígbà míì, àwọn akéde máa ń lò ó láti fi pe ẹni tí wọ́n fẹ́ lọ bẹ̀ wò kí wọ́n tó lọ, pàápàá tí ibi tí onítọ̀hún ń gbé bá jìnnà díẹ̀. Bí fóònù bá wà lọ́wọ́ wa lóde ẹ̀rí, kò ní dáa ká jẹ́ kó pín ọkàn wa níyà nígbà tá a bá ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 6:3) Tá a bá ń dúró de àwọn tá a jọ wà lóde ẹ̀rí, ǹjẹ́ kò ní dáa ká fiyè sí iṣẹ́ ìwàásù wa àtàwọn tá a jọ wà lóde dípò ká máa pe àwọn èèyàn tàbí ká máa fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù wa?
Máa Gba Tàwọn Ẹlòmíì Rò (1 Kọ́r. 10:24; Fílí. 2:4): Ẹ má ṣe jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa pẹ́ dé síbi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ká wá máa ronú pé a kúkú lè pe àwọn ará lórí fóònù tàbí ká fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù wọn láti fi mọ ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́. Tí ẹnì kan bá pẹ́ dé, ó sábà máa ń gba pé kí wọ́n tún àwọn ará pín. Òótọ́ ni pé àwọn ohun kan lè jẹ́ ká pẹ́ lẹ́yìn nígbà míì. Àmọ́, tá a bá fi kọ́ra láti máa tètè dé, à ń fi hàn pé a ka Jèhófà sí pàtàkì, a sì gba ti ẹni tó darí àwọn ará lọ sóde ẹ̀rí rò títí kan àwọn akéde yòókù.