Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 22
Orin 85 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 8 ìpínrọ̀ 8 sí 13 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Lúùkù 18-21 (10 min.)
No. 1: Lúùkù 18:18-34 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Ọlọ́run àti Kristi Ṣe Jẹ́ Ọ̀kan?—td 36D (5 min.)
No. 3: Kí Ni Ọkàn Tútù, Báwo La Ṣe Lè Jẹ́ Ọlọ́kàn Tútù, Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì?—Sef. 2:2, 3 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bí Ẹnì Kan Bá Sọ Pé, ‘Ẹ Kọ́kọ́ Gbàdúrà Fún Mi Kẹ́ Ẹ Tó Wàásù.’ Ìjíròrò tá a gbé ka àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí: (1) Irú ojú wo ni Jésù fi ń wo àdúrà téèyàn bá gbà ní gbangba torí kí àwọn èèyàn bàa lè rí i? (Mát. 6:5) (2) Ìtọ́ni wo ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lórí bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù? (Mát. 10:12, 13) (3) Kí ni Jésù ní kí wọ́n wàásù nípa rẹ̀? (Mát. 10:7) (4) Báwo la ṣe lè mú ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run wọnú ìjíròrò náà? (Mát. 6:9, 10; Ìṣí. 21:4) Ṣe àṣefihàn kan ní ṣókí, tó dá lórí ohun tá a lè sọ bí ẹnì kan bá sọ pé, ‘Kí ló dé tẹ́yin Ajẹ́rìí kì í gbàdúrà?’
20 min: Bá A Ṣe Lè Kíyè Sára, Ká Má Bàa Kó Sọ́wọ́ Àwọn Ajínigbé. Ìjíròrò tó dá lórí lẹ́tà October 28, 2010, tá a kọ sí gbogbo ìjọ. Rí i dájú pé o ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ “ka” sí nínú lẹ́tà náà, kó o sì ní kí àwọn ará sọ bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe wúlò fún wa.
Orin 70 àti Àdúrà