Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 29
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 29
Orin 50 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 8 ìpínrọ̀ 14 sí 20 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Lúùkù 22-24 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́. Lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù May. Gba gbogbo àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn.
10 min: Ìhìn Rere Ìjọba Yìí. Àsọyé tó ń tani jí tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 279 sí 281.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Mátíù 16:21-23 àti Lúùkù 9:22-26. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni.
Orin 117 àti Àdúrà