Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 29, 2013. A fi déètì tá a máa jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan síwájú àwọn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ lè ṣèwádìí wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
1. Ọ̀rọ̀ pàtàkì wo ni Jésù rán wa létí nípa ìgbéyàwó nínú ìwé Máàkù 10:6-9? [Mar. 4, w08 2/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 8]
2. Kí ló túmọ̀ sí láti sin Jèhófà tọkàntọkàn? (Máàkù 12:30) [Mar. 4, w97 10/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 4]
3. “Ìroragógó wàhálà” wo ni ìwé Máàkù 13:8 ń tọ́ka sí? [Mar. 11, w08 3/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 2]
4. Inú àwọn ìwé wo ni Lúùkù ti ṣèwádìí nígbà tó ń múra láti ṣe àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere rẹ̀? (Lúùkù 1:3) [Mar. 18, w09 3/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 4]
5. Níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé Sátánì ń wá ‘àkókò tí ó wọ̀’ láti dán ìwà títọ́ wa wò, kí ló yẹ ká ṣe? (Lúùkù 4:13) [Mar. 25, w11 1/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 10]
6. Báwo la ṣe lè fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Lúùkù 6:27, 28 sílò? [Mar. 25, w08 5/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 4]
7. Kí nìdí tí Jésù fi lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ obìnrin kan jì í ṣáájú kó tó fi ara rẹ̀ ṣe ẹbọ ìràpadà? (Lúùkù 7:37, 48) [Apr. 1, w10 8/15 ojú ìwé 6 àti 7]
8. Lọ́nà wo ni àwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ “kórìíra” àwọn ìbátan wọn? (Lúùkù 14:26) [Apr. 15, w08 3/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 1; w92 7/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 3 sí 5]
9. Ipa wo ni ‘àwọn àmì inú oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀’ yóò ní lórí àwọn èèyàn? (Lúùkù 21:25) [Apr. 22, w97 4/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 8 àti 9]
10. Tá a bá dojú kọ àdánwò tó le gan-an, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú bó ṣe máa ń gbàdúrà? (Lúùkù 22:44) [Apr. 29, w07 8/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 2]