Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 6
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 6
Orin 26 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 9 ìpínrọ̀ 1 sí 7 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jòhánù 1-4 (10 min.)
No. 1: Jòhánù 3:22-36 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Ló Túmọ̀ sí Láti “Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí”?—Gál. 5:16 (5 min.)
No. 3: Ẹ̀mí Mímọ́ Kì Í Ṣe Ẹnì Kan—td 36E (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù May. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ May, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! May–June 2013. Bí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
5 min: “Ǹjẹ́ O Máa Ń Wo Ojú Pátákó Ìsọfúnni?” Ìjíròrò.
15 min: Rí i Pé O Ka Ìwé Ọdọọdún 2013. Ìjíròrò. Sọ̀rọ̀ lórí “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí,” èyí tó wà nínú ìwé náà. Ní kí àwọn kan, tó o ti sọ fún tẹ́lẹ̀, sọ àwọn ìrírí tó fúnni níṣìírí látinú ìwé náà. Kí àwọn ará sì sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tó gbàfiyèsí nínú ìròyìn ọdún iṣẹ́ ìsìn 2012. Parí ìjíròrò náà nípa gbígba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n ka ìwé náà tán. Àmọ́, bí ẹ kò bá tí ì rí Ìwé Ọdọọdún 2013 gbà, kí ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ. Kí ẹ sì fi apá yìí rọ́pò ọ̀rọ̀ tó ń fẹ́ àbójútó ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 3, 2013.
Orin 47 àti Àdúrà