Máa Fi Ìmọrírì Àtọkànwá Hàn fún Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa
1 Àwọn èèyàn máa ń fojú ribiribi wo dáyámọ́ńdì àtàwọn òkúta iyebíye mìíràn torí pé wọ́n lẹ́wà, àti pé owó gegere àti ọ̀pọ̀ wàhálà ló ń náni láti wá wọn rí àti láti wà wọ́n jáde látinú ilẹ̀. (Òwe 2:4) Ìmọ̀ nípa Jèhófà àti Jésù Kristi ṣeyebíye gan-an jùyẹn lọ. Nínú gbogbo ìwé tó wà lágbàáyé, àwọn ìtẹ̀jáde wa nìkan ló ń ṣàlàyé àwọn ọrọ̀ tẹ̀mí wọ̀nyí kúnnákúnná pẹ̀lú ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Róòmù 11:33; Fílí. 3:8) Báwo la ṣe lè fi hàn látọkànwá pé a mọrírì àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa?
2 Ọ̀pọ̀ àwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àtàwọn ìdílé lódindi ṣètò láti máa ya iye owó kan sọ́tọ̀ déédéé, èyí tí wọ́n á mú lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, tí wọ́n á sì fi sínú ọ̀kan lára àwọn àpótí ọrẹ tá a kọ “Contributions for the Society’s Worldwide Work [Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Yíká Ayé]—Mátíù 24:14,” sí lára. Àwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tún máa ń ṣe ìtọrẹ fún iṣẹ́ kárí ayé láfikún sí i, nígbà tí wọ́n bá gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí ìwé ìròyìn, àti nígbà tí wọ́n bá fi àwọn ọrẹ tí wọ́n gbà nínú iṣẹ́ ìsìn pápá sínú àpótí.
3 Ọ̀nà mìíràn láti gbà fi ìmọrírì hàn ni nípa rírí i pé a ṣàṣàyàn irú àwọn èèyàn tá a máa fún ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. A ò jẹ́ ronú pé ká fún ọmọ ìkókó ní dáyámọ́ńdì kan tó gbówó lórí, torí kò lè mọ bó ṣe ṣeyebíye tó. Bákan náà ni kò yẹ ká mú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó níye lórí fáwọn èèyàn tí kò mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí. (Fi wé Hébérù 12:16.) A ní láti jẹ́ olóye bá a ṣe ń fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ lo ara wa tí ẹ̀mí yìí kan náà sì ń sún wa láti fún àwọn èèyàn láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Ǹjẹ́ onílé náà múra tán láti bá wa fọ̀rọ̀ wérọ̀? Ṣé ó fetí sílẹ̀ nígbà tá à ń sọ̀rọ̀, ṣé ó ń dáhùn ìbéèrè tá a béèrè, ṣé ó sì ń fọkàn bá a lọ bá a ṣe ń ka Bíbélì? Bí onítọ̀hún bá fi irú ìfẹ́ báyìí hàn sí ọ̀rọ̀ wa, inú wa á dùn láti fún un ní ìtẹ̀jáde tó bá yẹ. Bá a bá fi àwọn ìtẹ̀jáde wa darí ìkẹ́kọ̀ọ́, èyí á ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, á sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti lè ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà. Bá a bá ṣe lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ló máa pinnu báwọn èèyàn ṣe máa jàǹfààní látinú wọn.
4 A tún lè fi ìmọrírì hàn nípa fífi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní rẹ̀ bá ṣí sílẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn ilé-dé-ilé, àti nígbà ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó yẹ kí akéde kọ̀ọ̀kan sapá láti dojúlùmọ̀ ìwé tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tá a bá ń fi lọni ní oṣù kan pàtó. Fífi àwọn ìgbékalẹ̀ tá a pinnu láti lò dánra wò ní ṣókí lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa fi ìtara gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀. Fara balẹ̀ ronú nípa àwọn ìtẹ̀jáde pàtó tó o mọ̀ pé ó gbéṣẹ́ jù lọ ní ìpínlẹ̀ yín. Irú àwọn ìtẹ̀jáde bí ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè ṣì ń bá a lọ ní ṣíṣèrànwọ́ lọ́nà àgbàyanu fáwọn onílé. Àwọn ìwé ìléwọ́ náà tún wúlò gan an.
5 Máa ronú dáadáa lórí iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó o máa nílò láti pín fáwọn èèyàn. Ó pọn dandan pé ká lo òye. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì láti gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ tó, àgàgà bó o bá ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, kò sídìí láti máa kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹpẹtẹ jọ, níwọ̀n bí a ti lè gba púpọ̀ sí i ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣáájú kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ tàbí lẹ́yìn ìpàdé. Gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ tó láti lò ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù, kó o sì máa gbà sí i bí èyí tó o gbà bá ti ń tán lọ.
6 Ọ̀nà táwọn ìtẹ̀jáde wa fi lè níye lórí jù lọ ni tá a bá mú wọn fún àwọn èèyàn tó mọrírì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó jẹ́ òtítọ́. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye bá a ṣe ń lo àwọn ohun tá a pèsè wọ̀nyí, a ó lè tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a mọyì àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa gidigidi.