ṢÉ AYÉ YÌÍ Ò NÍ BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?
OMI TÓ MỌ́
AYÉ yìí ò ní ṣeé gbé láìsí omi, ní pàtàkì omi tó mọ́. Kódà, omi ló pọ̀ jù lára gbogbo ohun alààyè tó wà láyé yìí. A máa ń rí omi látinú àwọn adágún omi, odò, ilẹ̀ olómi àti omi tó wà lábẹ́ ilẹ̀. Àwa èèyàn àtàwọn ẹranko máa ń mu àwọn omi yìí, a sì tún máa ń lò ó láti ṣọ̀gbìn.
Omi Tó Mọ́ Ṣọ̀wọ́n
Omi ló pọ̀ jù láyé yìí. Àmọ́, àjọ tó ń rí sí bí ojú ọjọ́ ṣe rí lágbàáyé, ìyẹn World Meteorological Organization sọ pé “ìwọ̀nba díẹ̀ lára omi tó wà láyé ló mọ́ tó sì ṣeé lò.” Òótọ́ ni pé ó yẹ kí ìwọ̀nba omi yìí tó àwọn ohun alààyè lò. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lára omi yìí làwọn èèyàn ti bà jẹ́ tàbí kí ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà mú kó má ṣeé lò. Ìwádìí táwọn kan ṣe fi hàn pé tó bá fi máa tó ọgbọ̀n ọdún, ó ṣeé ṣe kó tó bílíọ̀nù márùn-ún èèyàn tí kò ní rí omi tó mọ́ lò.
Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé
Bí Ọlọ́run ṣe dá ayé yìí fi hàn pé omi ò lè tán nínú ayé láéláé. Bákan náà, iyẹ̀pẹ̀, àwọn ohun alààyè inú omi àti oòrùn máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti mú kí omi mọ́. Jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé omi ò lè tán láyé yìí àti pé omi máa ń tún ara ẹ̀ ṣe.
Ìwádìí fi hàn pé iyẹ̀pẹ̀ lè yọ àwọn ohun tó ń sọ omi di ẹlẹ́gbin kúrò nínú omi. Àwọn ewéko kan máa ń hù láwọn ilẹ̀ olómi tó máa ń dín èròjà nitrogen àti phosphorus kù nínú omi, torí tó bá pọ̀ jù, ó lè ba omi jẹ́. Bákan náà àwọn ewéko yìí máa ń yọ àwọn kẹ́míkà tó lè ba omi jẹ́ kúrò.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti rí ọ̀nà tí omi máa ń gbà tún ara ẹ̀ ṣe. Táwọn ohun tó lè ba omi jẹ́ bá bọ́ sínú omi tó ń ṣàn, àwọn ohun alààyè tín-tìn-tín kan máa fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ kó má bàa pa wá lára.
Láàárín ọjọ́ díẹ̀, àwọn ìṣáwùrú àti òkòtó òkun lè yọ àwọn kẹ́míkà tó lè pa wá lára kúrò nínú omi lọ́nà tó dáa ju bí àwọn ilé iṣẹ́ tó máa ń yọ ẹ̀gbin kúrò nínú omi ṣe máa ń ṣe é lọ.
Bí omi ṣe ń lọ sójú ọ̀run tó ń di òjò tó sì ń rọ̀ sórí ilẹ̀ ló ń jẹ́ ká ṣì máa rí omi lò. Èyí àtàwọn nǹkan míì tó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ni kò jẹ́ kí ìgbà kan wà tá ò rómi lò tàbí kí omi tiẹ̀ tán pátápátá.
Ohun Táwọn Èèyàn Ti Ṣe
Tá a bá ń dí àwọn ibi tí óìlì ti ń jò, tá a sì ń da àwọn èròjà olóró nù síbi tó yẹ, a ò ní máa sọ àwọn omi wa di ẹlẹ́gbin
Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé kò yẹ ká máa fomi ṣòfò. Wọ́n tún sọ pé tá ò bá fẹ́ kí omi lẹ́gbin, ó yẹ ká máa dí àwọn ibi tí ọ́ìlì ti ń jò nínú àwọn mọ́tò wa, ká má ṣe fọ àwọn oògùn tá ò lò mọ́ sínú ilé ìgbọ̀nsẹ̀, ká má sì fọ àwọn èròjà olóró sínú àwọn ọ̀pá tó ń gbé omi kiri.
Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ti mọ ọ̀nà míì téèyàn lè gbà fa iyọ̀ kúrò nínú omi. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè rí i pé omi tó ṣeé mu pọ̀ sí i láyé.
Àmọ́, ìṣòro kan ni pé owó tí wọ́n ń ná lórí fífa iyọ̀ kúrò nínú omi ti pọ̀ jù, bákan náà ó tún máa gba pé kí wọ́n lo iná mànàmáná tó pọ̀ jù. Lórí ọ̀rọ̀ ààbò omi, ìròyìn kan tó jáde láti Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé lọ́dún 2021 sọ pé: “Kárí ayé, a ò tíì dé ìdajì ibi tá à ń lọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.”
Bíbélì Mú Ká Nírètí
“Ọlọ́run . . . ń fa àwọn ẹ̀kán omi sókè; omi inú àwọsánmà rẹ̀ ń di òjò; àwọsánmà wá rọ òjò; ó rọ̀ sórí aráyé.”—Jóòbù 36:26-28.
Kí omi má bàa tán láyé, Ọlọ́run ṣètò pé kí omi máa lọ sójú ọ̀run, kó di òjò, ko sì máa rọ̀ sórí ilẹ̀.—Oníwàásù 1:7.
Rò ó wò ná: Torí pé Ẹlẹ́dàá wa ló ṣètò pé kí omi máa tún ara ẹ̀ ṣe kó lè ṣeé lò, ó dájú pé kò kọjá agbára ẹ̀ láti yanjú ìṣòro omi, kí omi tó dáa tún lè wà níbi gbogbo. Ka àpilẹ̀kọ náà “Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé” lójú ìwé 15.