APÁ 2
Láti Ìgbà Ìkún-Omi Títí Dé Ìgbà Ìdáǹdè Kúrò ní Íjíbítì
Ẹni mẹ́jọ péré ló la Ìkún-omi já, ṣùgbọ́n nígbà tó ṣe, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i títí iye wọn fi tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́ta àti méjì [352] ọdún lẹ́yìn Ìkún-omi ni wọ́n bí Ábúráhámù. A óò kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe pa ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù mọ́ nípa fífún un ní ọmọ kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákì. Ísákì pẹ̀lú bí ọmọ méjì. Nínú ọmọ méjì tí Ísákì bí yìí, èyí tó ń jẹ́ Jékọ́bù ni Ọlọ́run yàn.
Jékọ́bù ní ìdílé ńlá, ó bí ọmọkùnrin méjìlá àti àwọn ọmọbìnrin mélòó kan. Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù mẹ́wàá kórìíra Jósẹ́fù àbúrò wọn, wọ́n sì tà á lẹ́rú sí Íjíbítì. Nígbẹ̀yìn, Jósẹ́fù di alákòóso ńlá ní Íjíbítì. Nígbà tí ìyàn líle kan mú, Jósẹ́fù dán àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá ọkàn wọn ti yí padà. Níkẹyìn, Jékọ́bù àti gbogbo ìdílé rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣí lọ sí Íjíbítì. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta dín mẹ́wàá [290] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Ábúráhámù.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ní Íjíbítì fún igba ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [215] tó tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn tí Jósẹ́fù kú, wọ́n di ẹrú níbẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n bí Mósè, Ọlọ́run sì lo Mósè láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là kúrò ní Íjíbítì. Tá a bá ro gbogbo rẹ̀ pọ̀, ìtàn ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [857] ọdún la óò sọ ní Apá KEJÌ yìí.