ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 47
  • Olè Kan Ní Ísírẹ́lì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Olè Kan Ní Ísírẹ́lì
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóṣúà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ohun Tí Jóṣúà Rántí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Jóṣúà 1:9—“Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Má Ṣe Di Olè!
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 47
Ákáánì fi odindi wúrà, owó fàdákà àti aṣọ dáradára tó jí pa mọ́ sínú àgọ́ rẹ̀

ÌTÀN 47

Olè Kan Ní Ísírẹ́lì

WO NǸKAN tí ọ̀gbẹ́ni yìí ń rì mọ́lẹ̀ nínú àgọ́ rẹ̀! Aṣọ dáradára kan, àti odindi wúrà kan àtàwọn owó fàdákà wẹ́wẹ́ mélòó kan. Ìlú Jẹ́ríkò ló ti kó wọn. Ṣùgbọ́n kí ló yẹ kí wọ́n ṣe sí àwọn nǹkan inú ìlú Jẹ́ríkò? Ṣó o rántí?

Ṣe ló yẹ kí wọ́n run wọ́n, kí wọ́n sì kó wúrà àti fàdákà lọ sí ilé ìṣúra àgọ́ Jèhófà. Nítorí náà àwọn èèyàn wọ̀nyí ti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Wọ́n ti ja Ọlọ́run lólè. Orúkọ ọkùnrin náà ni Ákáánì, ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ ló sì wà pẹ̀lú rẹ̀ yẹn. Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀.

Lẹ́yìn tí Ákáánì ti jí àwọn nǹkan wọ̀nyí, Jóṣúà rán àwọn kan jáde láti bá ìlú Áì jà. Ṣùgbọ́n àwọn ará Áì lù wọ́n ní àlùbolẹ̀ lójú ogun. Wọ́n pa àwọn kan lára wọn, àwọn yòókù sì sá. Inú Jóṣúà bà jẹ́ gidigidi. Ó dojú bolẹ̀ ó sì gbàdúrà sí Jèhófà pé: ‘Kí ló dé tó o fi jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ sí wa?’

Jèhófà dáhùn pé: ‘Dìde ńlẹ̀! Ísírẹ́lì ti dẹ́ṣẹ̀. Wọ́n ti mú lára ohun tó yẹ kí wọ́n pa run tàbí tó yẹ kí wọ́n mú lọ sínú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà. Wọ́n jí aṣọ dáradára kan wọ́n sì fi í pa mọ́. Mi ò ní fi ojú rere hàn sí yín títí tẹ́ ẹ fi máa pa nǹkan náà run tẹ́ ẹ sì fi máa pa ẹni tó jí àwọn nǹkan wọ̀nyí run.’ Jèhófà sọ pé òun máa fi ẹni búburú náà han Jóṣúà.

Nítorí náà Jóṣúà kó gbogbo àwọn èèyàn náà jọ, Jèhófà sì mú Ákáánì tó jẹ́ ẹni búburú náà jáde. Ákáánì wí pé: ‘Èmi ti ṣẹ̀. Mo rí aṣọ dáradára kan, àti odindi wúrà kan àtàwọn owó fàdákà díẹ̀. Àwọn nǹkan wọ̀nyí wọ̀ mí lójú tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi mú wọn. Inú àgọ́ mi ni mo rì wọ́n mọ́lẹ̀ sí.’

Nígbà tí wọ́n rí àwọn nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n sì kó wọn tọ Jóṣúà wá, ó wí fún Ákáánì pé: ‘Kí ló dé tó o fi kó wa sínú ìyọnu? Wàyí o, Jèhófà yóò mú ìyọnu wá sórí rẹ!’ Bí àwọn èèyàn ṣe gbọ́ èyí, gbogbo wọn sọ Ákáánì àti ìdílé rẹ̀ ní òkúta pa. Ǹjẹ́ èyí ò ha fi hàn pé a kò gbọ́dọ̀ mú nǹkan tí kì í bá ṣe tiwa?

Lẹ́yìn èyí, Ísírẹ́lì lọ sí ogun láti bá Áì jà lẹ́ẹ̀kan sí i. Lọ́tẹ̀ yìí Jèhófà ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹ́gun.

Jóṣúà 7:1-26; 8:1-29.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́