ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kc orí 6 ojú ìwé 46-55
  • Nínàgà fun Ijọba Naa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nínàgà fun Ijọba Naa
  • “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌLÀ ÌDÍLÉ KAN TÍ Ó PẸTẸRÍ
  • ILU-NLA TÍ ỌLỌRUN KỌ́
  • ỌBA NAA TÍ Ó NÍ “Ẹ̀TỌ́ OFIN”
  • Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá
    Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá
  • Ábúráhámù àti Sárà—O Lè Fara Wé Ìgbàgbọ́ Wọn!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ta Ni Ábúráhámù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì—Apá Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
“Kí Ijọba Rẹ Dé”
kc orí 6 ojú ìwé 46-55

Ori 6

Nínàgà fun Ijọba Naa

1. (a) Niti ijọba, ki ni Jehofa nawọ́ rẹ̀ jade ní ìfiwéra sí ohun tí awọn eniyan ti pese? (b) Eeṣe tí awa fi lè kọ́ igbesi-aye wa yika Ọ̀rọ̀ Ọlọrun láìséwu?

NIGBA tí a bá fi ohun ti o fanimọ́ra kan lọ ọ, bawo ni iwọ ṣe maa ń dahunpada? Iwọ kò ha ń nàgà fun un bi? Ó dara, Jehofa Ọlọrun ń fi anfaani ìyè ainipẹkun labẹ ijọba pípé kan si iwaju rẹ. Ootọ ni pe, ninu ijọba lonii, ọpọlọpọ awọn oloṣelu jẹ́ oníwà-ìbàjẹ́ tí awọn ileri wọn kò si múnádóko. Àní bi wọn ba tilẹ ní ìpètepèrò dídára, awọn eniyan ti fihan pe wọn kò lagbara pipese ijọba rere kan tí ó wà ní ìdádúró lómìnira si ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun. (Owe 20:24) Ṣugbọn jálẹ̀ gbogbo itan, Ọlọrun ti ń gbé awọn ìgbésẹ̀ onitẹsiwaju tí ń yọrisi ìfìdímúlẹ̀ akoso Ijọba pípé rẹ̀, o sì késí awọn olufẹ ododo lati janfaani ninu rẹ̀. Ète rẹ̀ ṣeégbẹkẹle ó sì jẹ́ otitọ. Oun kò lè ṣèké. Awa lè kọ́ igbesi-aye wa yika Ọ̀rọ̀ rẹ̀ laisewu.​—⁠Ìfihàn 21:​1-⁠5; Titu 1:⁠2.

2. (a) Nigba wo ati bawo ni Ọlọrun ṣe sọ ète rẹ̀ jade nipa gbígbé ijọba ododo kan kalẹ? (b) Ki ni Heberu 11:​4-⁠7 ṣipaya niti awọn wọnni tí wọn nàgà fun ireti Ijọba naa?

2 Ète Ọlọrun lati fìdí ijọba ododo kan múlẹ̀ kìí ṣe titun. Ní Edeni, nigba tí a kọ́kọ́ pe ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun níjà, Ọlọrun sọ ete rẹ̀ lati mú “irú-ọmọ” kan jade eyi tí yoo “tẹ̀” Satani ati irú-ọmọ rẹ̀ “pa.” (Genesisi 3:15; Romu 16:20) Laaarin ìwà-ipá ayé igbaani, Abeli, Enoku ati Noa fi igbagbọ hàn ninu ileri Jehofa. Pẹlu igbẹkẹle pe Ọlọrun yoo san èrè-ẹ̀san fun “awọn tí ó fi ara balẹ wá a,” wọn farada ẹ̀gàn, wọn sì yàn lati ‘rìn pẹlu Ọlọrun’ ati lati waasu ododo. (Heberu 11:​4-⁠7) Apẹẹrẹ rere wo ni wọn jẹ́ fun gbogbo eniyan lonii tí wọn ń lò igbagbọ ninu ‘dídé’ Ijọba Ọlọrun!

ÌLÀ ÌDÍLÉ KAN TÍ Ó PẸTẸRÍ

3. Gẹgẹ bi Genesisi 12:​1-⁠7 ti wí, bawo ni Abrahamu ṣe jẹ́ àwòṣe ológo fun wa?

3 Ní eyi tí ó jù 400 ọdun lọ lẹhin Ikun omi, Ọlọrun mú un ṣe kedere pe “irú-ọmọ” ọlọ́ba tí a ṣeleri naa yoo wá lati ìlà idile Abrahamu. Ṣugbọn ó ṣe jẹ́ Abrahamu? Nitori pe Ọlọrun rí igbagbọ titayọ ninu rẹ̀. Ó pè Abrahamu jade lati inu ilu ibilẹ rẹ̀, Uri, ti ilẹ Kaldea, ó sì rán an lọ si ilẹ ajeji naa, Kenaani, ni sisọ pe:

“Ninu rẹ ni a o ti bukun fun gbogbo idile ayé. . . . Irú-ọmọ rẹ ni emi o fi ilẹ yii fun.” (Genesisi 12:​3, 7; Iṣe 7:⁠4)

Dipo rírọ̀mọ́ orilẹ-ede ìbí rẹ̀, Abrahamu fi i silẹ, kò sì tún pada sibẹ mọ́ lae. Ó ṣetan lati ṣe iyipada kíkún ninu ọ̀nà igbesi-aye rẹ̀, ki ó baa lè fi igbọran pípé pérépéré hàn fun Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ. Àwòṣe ológo kan ni, nitootọ, fun gbogbo ẹni tí yoo lepa igbesi-aye iyasimimọ fun Jehofa lonii!

4. Bawo ni a ṣe bukun Sara nitori igbagbọ rẹ̀? (Heberu 11:​11, 12)

4 Bi ó tilẹ jẹ́ pe aya rẹ̀, Sara, wà ní àgàn titi di ọjọ́ ogbó rẹ̀, Jehofa tún mú un dá Abrahamu lójú lẹhin naa, ní sisọ fun un pe: “Emi yoo sì busii fun un, oun yoo sì ṣe ìyá ọpọ orilẹ-ede; awọn ọba eniyan ni yoo ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.” (Genesisi 17:16) Ní ẹni 90 ọdun, Sara olùṣòtítọ́ ni a bukun nipa bíbí ọmọkunrin kan lọna iṣẹ́-ìyanu fun Abrahamu, Isaaki, baba-nla ọpọlọpọ awọn ọba.​—⁠Matteu 1:​2, 6-11, 16; Ìfihàn 17:⁠14.

5. Bawo ni a ṣe san èrè-ẹ̀san fun igbọran Abrahamu ati ti Isaaki?

5 Nigba tí ó ṣe, Jehofa fi Abrahamu ati Isaaki sinu ìdánwò tí ń wádìírí ọkàn-àyà. Ó fun Abrahamu ni ìtọ́ni lati mú ọmọkunrin rẹ̀ kanṣoṣo tí Sara bí fun un lọ fun irin-ajo ọlọ́jọ́ mẹta kan si ori Oke Moria, lati fi i rú ẹbọ sisun nibẹ. Nisinsinyi laisi àníànì Isaaki yoo ti tó ẹni 25 ọdun ti ó sì lagbara tó lati gbé ẹrù igi ìdáná wiwuwo lọ sori òkè-ńlá naa; ó sì lágbára tó lati ranrí mọ́ baba rẹ̀ ẹni 125 ọdun lọwọ, bi oun bá fẹ́ lati ṣe bẹẹ. Ṣugbọn baba ati ọmọ fi igbọran ṣe ipa tiwọn ninu àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí ń runisoke yii, titi di igba tí angẹli Jehofa fi dáwọ́ Abrahamu duro bi oun ti gbé ọ̀bẹ ìdúḿbú naa soke. Àgbò kan sì rọ́pò Isaaki gẹgẹ bi ohun irubọ naa.​—⁠Genesisi 22:​1-⁠14.

6. (a) Àwòkọ́ṣe alasọtẹlẹ wo ni a mu ṣe nibẹ? (b) Eeṣe tí ó fi yẹ ki o ni akanṣe ifẹ si ileri tí ó wà ninu Genesisi 22:18?

6 Níhìn-ín Ọlọrun fi awokọṣe alasọtẹlẹ kan lelẹ nipa bi oun yoo ṣe fi Ọmọkunrin ti araarẹ̀ rubọ, ki ó baa lè kó ẹ̀ṣẹ̀ araye lọ. (Johannu 1:29; Galatia 3:16) Nitori pe Ọlọrun wa sọ fun Abrahamu lẹhin naa pe:

“Ati ninu irú-ọmọ rẹ ni a o bukun fun gbogbo orilẹ-ede ayé: nitori ti iwọ gba ohùn mi gbọ́.”​—⁠Genesisi 22:​15-⁠18.

7. Ipa ọ̀nà wo níhà ọ̀dọ̀ tiwa ni Jehofa yoo san èrè-ẹ̀san fun?

7 Ẹ wo apẹẹrẹ igbọran titayọ ti Abrahamu ati Isaaki jẹ́! A lè má kesi wa láé lati ṣe iru irubọ tiwọn, ṣugbọn ó ṣe pataki pe ki a jọwọ araawa fun Jehofa bi wọn ti ṣe, lati inu ojulowo ifẹ fun un. (Jakọbu 4:7; 2 Korinti 9:13) Ìmúratán lati fi ara-ẹni ati anfaani onímọ̀tara ẹni-nìkan rubọ, lati lè nàgà fun ‘dídé Ijọba naa,’ jẹ́ ipa-ọ̀nà kan ti Jehofa maa ń tẹwọgba tí ó sì maa ń san èrè-ẹ̀san fun nigba gbogbo.​—⁠Matteu 6:⁠33.

8. (a) Bawo ni ipa ọ̀nà Jakobu ṣe rí ní ìfiwéra pẹlu ti Esau? (b) Ibukun wo ni Isaaki fi jíǹkí Jakobu?

8 Jakobu ọmọkunrin Isaaki jẹ́ ẹlomiran tí ó nàgà fun Ijọba naa. Ṣugbọn Esau ìbéjì rẹ̀ tẹ́ḿbẹ́lú awọn ohun mímọ́-ọlọ́wọ̀, ó ní ifẹ si awọn obinrin ará Kenaani ati si ifẹ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì onímọ̀tara ẹni-nìkan. Oun sì ta ogún ìbí rẹ̀ tí ó ṣeyebíye fun Jakobu nitori abọ́ ìpẹ̀tẹ̀ lasan! (Heberu 12:16) Jakobu tí ohun tẹmi jẹlọ́kàn ronu lọna giga nipa ogún ìbí naa, Jehofa sì dari awọn ọ̀ràn kí o baa lè pa ẹ̀bùn naa mọ́, koda ni rírí ibukun gbà lati ọ̀dọ̀ Isaaki arugbo naa paapaa. Esau ti gbé awọn obinrin olujọsin ẹ̀mí-èṣù níyàwó, ṣugbọn ní ìfiwéra, Jakobu rìn irin-ajo jijinna lọ si Mesopotamia lati wá aya laaarin awọn olujọsin Jehofa. Ní akoko naa Isaaki tún mú un dá Jakobu lójú pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi:

“Ki Ọlọrun Olodumare ki o gbè ọ, ki o sì mú ọ bísíi, ki o sì mu ọ́ rẹ̀ sii, ki iwọ ki o le di ọpọlọpọ eniyan.”​—⁠Genesisi 25:27-⁠34; 26:34, 35; 27:1-⁠23; 28:1-⁠4.

9. (a) Eeṣe tí a fi yí orukọ Jakobu pada si Israeli? (b) Bawo ni awa ṣe lè janfaani lati inu apẹẹrẹ rẹ̀?

9 Lẹhin akoko naa, nigba tí ó sunmọ ẹni 100 ọdun, Jakobu fihan lẹẹkan sii bi oun ṣe mọriri ohun tẹmi lọna giga. Ó bá angẹli kan jijakadi ní gbogbo òru fun ibukun kan. Gẹgẹ bi àmì ojurere Rẹ̀, nibẹ Jehofa yí orukọ Jakobu pada si Israeli, tí ó tumọsi “Oluforiti pẹlu Ọlọrun.” (Genesisi 32:​24-⁠30) A ó san ère-ẹ̀san fun wa lonii, pẹlu, bi a bá foriti i ní nínàgà fun ọrọ̀ tẹmi, bi a tí ń yẹra fun ẹmi ayé buruku tí ó yí wa ká.​—⁠Matteu 6:​19-⁠21.

10. (a) Bawo ni a ṣe mú asọtẹlẹ tí ó wà ninu Genesisi 28:3 ṣẹ? (b) Niti iṣotitọ ẹnikọọkan, ki ni diẹ lara awọn apẹẹrẹ wiwọnilọkan tí ó wà ninu Heberu 11:1–12:⁠1?

10 Jehofa nitootọ ṣeto awọn ìran ọmọ Jakobu bi “ijọ awọn eniyan” kan, ati nipasẹ Mose alárinà Rẹ̀, ẹni tí Oun lò pẹlu lati bẹrẹ ṣiṣakọsilẹ Bibeli, Ọlọrun kesi orilẹ-ede Israeli, wi pe:

“Bi ẹyin yoo bá ṣegbọran sí ohun mi láìyẹhùn . . . ẹyin fúnraayín yoo di ijọba awọn alufaa ati orilẹ-ede mímọ́ kan fun mi.” (Eksodu 19:​5, 6, NW)

Ó banininujẹ pe, nitori pe wọn kò ṣegbọran si ohùn Ọlọrun, Israeli nipa ti ara kuna lati di ijọba tẹmi yẹn. Ṣugbọn ní ibakẹgbẹpọ pẹlu orilẹ-ede yẹn, ọpọlọpọ eniyan lẹnikọọkan fi ìwàtítọ́ wọn hàn si Ọlọrun​—⁠iru bi awọn onidaajọ ní Israeli, awọn wolii ani panṣaga kan tẹlẹri pàápàá, Rahabu. Awa lè kà nipa “awọn ẹlẹ́rìí ” olùṣòtítọ́ wọnni ninu Heberu 11:1–12:1, ìṣírí ọlọ́yàyà wo ni wọn sì ti pèsè fun awọn eniyan tí ń fojusọna, lode-oni, fun ‘dídé Ijọba Ọlọrun’!

11. Bawo ni iwọ ṣe lè dabi awọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ wọnni?

11 Iwọ ha fẹ́ di alagbara ni igbagbọ bi? Iwọ ha fẹ́ lati dabi awọn ọkunrin ati obinrin igbagbọ wọnni nisinsinyi ní “nínàgà wò ibi kan ti o dara jù, eyiini ni, ibi kan tii ṣe ti ọrun,” bẹẹni, nínàgà wò “ilu-nla tí ó ní awọn ipilẹ gidi, ilu-nla tí akọ́lé ati olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọrun”? (Heberu 11:​10, 16, NW) ‘Ṣugbọn, ki ni “ilu-nla” naa?’ ni iwọ le beere.

ILU-NLA TÍ ỌLỌRUN KỌ́

12. Fun “ilu-nla” wo ni awọn iranṣẹ Ọlọrun igbaani ń nàgà fun? (Tún wò Heberu 11:​22-⁠32; Rutu 1:​8, 16, 17 pẹlu.)

12 “Ilu-nla” naa ni Ijọba Ọlọrun tí a ṣeleri. Eeṣe tí a fi wí bẹẹ? Ó dara, nigba laelae o saba maa ń jẹ́ ootọ pe ilu-nla kan jẹ́ ijọba kan, tí ọba kan ń ṣakoso lélórí. Ọba kìn-ín-ní tí a sọrọ rẹ̀ pẹlu ìtẹ́wọ́gbà ninu Bibeli ni “Melkisedeki, ọba [ilu-nla] Salemu, alufaa Ọlọrun Ọga-ogo.” Ní ọpọ ọ̀rúndún lẹhin naa, a kọ́ ilu-nla Jerusalemu sori àyè ilẹ̀ kan-naa, ati, gẹgẹ bi Salemu, ó wá duro fun Ijọba ọrun lọwọ Ọba nla ati Alufaa Agba naa, Jesu Kristi. (Genesisi 14:​1-⁠20; Heberu 7:1, 2, 15-⁠17; 12:22, 28) Bi ó tilẹ jẹ́ pe wọn kò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ nigba naa, Abrahamu ati Sara, ati Isaaki pẹlu Jakobu, fi titaratitara wa “ilu-nla” naa kiri eyi tí Messia yoo ṣakoso lélórí bi ọba. Abrahamu “yọ̀ gidigidi ninu ifojusọna naa.” Iwọ, pẹlu, lè rí ayọ bi o ti ń nàgà ninu igbagbọ fun àyè kan ninu iṣeto Ijọba naa.​—⁠Heberu 11:​14-⁠16; Johannu 8:⁠56.

13, 14. Bawo ni asọtẹlẹ tí Jakobu sọ lori ibusun iku rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ síi ní imuṣẹ?

13 Jakobu bí ọmọkunrin 12, awọn ẹni tí ó di olórí ẹ̀yà Israeli 12 nigba tí ó yá. Lori ibusun iku rẹ̀, Jakobu sọ asọtẹlẹ nipa èwo ninu awọn ẹ̀yà 12 naa ni yoo pese oluṣakoso tí Ọlọrun yàn pẹlu ọla-aṣẹ Ijọba naa, ní wiwi pe:

“Ọmọ kinniun ni Juda. . . . Ọ̀pá-alade kì yoo ti ọwọ́ Juda kuro . . . títí Ṣiloh [tí ó tumọsi, Ẹni naa Tí Ó Ni Ín] yoo fi dé; oun ni awọn eniyan yoo gbọ́ tirẹ̀.” (Genesisi 49:​9, 10)

Ṣiloh ha wá lati Juda bi? Họ́wù, bẹẹni!

14 Imuṣẹ asọtẹlẹ Jakobu bẹrẹ sii farahan ní eyi tí ó jù 600 ọdun lọ lẹhin naa. Igba naa ni Jehofa yàn “ọkunrin kan tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀” lati inu ẹ̀yà Juda. Orukọ rẹ̀ ni Dafidi. Ọlọrun sọ ‘kinniun ẹya Juda’ onigboya yii di aṣaaju ati ọba lori awọn eniyan Rẹ̀ Israeli. (1 Samueli 13:14; 16:7, 12, 13; 1 Kronika 14:17) Fun Ọba Dafidi, Jehofa ṣeleri ijọba ainipẹkun kan.​—⁠Orin Dafidi 89:​20, 27-⁠29.

15. Eeṣe tí Jehofa fi dojú ijọba Juda bolẹ̀, bawo ni ó sì ti pẹ́ tó?

15 Dafidi, ẹni tí ó bẹrẹ iṣakoso rẹ̀ ní 1077 B.C.E., jẹ́ èkínní ninu ìlà awọn ọba Juda tí wọn ṣakoso ní ilu Jerusalemu. Orilẹ-ede naa láásìkí nigbakuugba tí ọba rẹ̀ bá fi tinútinú ṣegbọran si Jehofa. Ṣugbọn nigba tí ọba kan bá di eniyan buruku tí ó sì ṣọ̀tẹ̀ si awọn ofin ododo Jehofa, awọn eniyan naa maa ń jìyà. (Owe 29:⁠2) Sedekiah, ọba tí ó jẹ kẹ́hìn ní Juda, buru pupọpupọ. Wolii Ọlọrun sọ fun un pe: “Ṣí adé kuro. . . . Emi o bì ṣubu, emi o bì ṣubu, emi o bì í ṣubu, . . . titi igba tí ẹni tí ó ni i [“ní ẹ̀tọ́ ofin,” NW] ba de; emi o sì fi fun un.” Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ dojú ijọba yẹn bolẹ̀, titi igba tí ọba tí ó “ní ẹ̀tọ́ ofin” yoo fi farahàn.​—⁠Esekieli 21:​26, 27.

ỌBA NAA TÍ Ó NÍ “Ẹ̀TỌ́ OFIN”

16. Bawo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi ajogún pipẹtiti fun Ijọba naa hàn?

16 Ta ni yoo jogún “ẹ̀tọ́ ofin” si ijọba Dafidi? Awọn ẹsẹ 17 akọkọ ninu iwe Matteu ninu Bibeli pese idahun naa. Awọn ẹsẹ naa tọpasẹ̀ ìlà “iru-ọmọ” tí a ṣeleri naa lati ọ̀dọ̀ Abrahamu titi dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ati lati ibẹ lọ sọdọ Josefu, ẹni tí ó di ọkọ Maria nigba tí ó yá. Nipa bayii àkọ́bí Maria yoo ní “ẹ̀tọ́ ofin” si Ijọba naa. Ní ibẹrẹ ọdun 2 B.C.E., angẹli Gabrieli lè tipa bẹẹ kede nipa ọmọkunrin naa tí oun yoo loyun rẹ̀ lọna iṣẹ́-ìyanu pe:

“Iwọ o sì pè orukọ rẹ̀ ní Jesu. Oun o pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo julọ ni a ó sì maa pè é; Oluwa Ọlọrun yoo sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fun un. Yoo sì jọba ni ilé Jakobu títí ayé, ijọba rẹ̀ kì yoo sì ní ipẹkun.” (Luku 1:​26-⁠33)

Lọna titobilọla là awọn ọ̀rúndún já ni Jehofa ti ń ṣiṣẹ fun aṣeyọri ete rẹ̀ lati mú àjògún pipẹtiti yii fun ijọba Dafidi jade wa. Bi a ti ń ṣe atunyẹwo awọn nǹkan wọnyi, wọn kò ha fun igbagbọ wa lókun ninu ileri Ọlọrun nipa ‘dídé ijọba rẹ̀’ bi?

17, 18. (a) Kìkì awọn wo ni yoo jogún Ijọba ọrun? (b) Awọn wo ni diẹ lara awọn olùṣòtítọ́ eniyan tí a ó jí dìde sori ilẹ̀-ayé? (c) Ki ni imuṣẹ eyi gbọdọ fun wa ní iṣiri lati ṣe?

17 Kii ṣe pe gbogbo wa lè reti lati wà ninu Ijọba ọrun pẹlu Jesu, nitori pe anfaani yẹn ni a pamọ fun kiki “agbo kekere” kan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. (Luku 12:32) Àní Ọba Dafidi paapaa kò ní irúfẹ́ ireti bẹẹ. A sọ fun wa pe: “Dafidi kò sáà goke lọ si ọrun.” (Iṣe 2:34) Bẹẹ ni Johannu Arinibọmi ati awọn ọkunrin ati obinrin olùṣòtítọ́ igbaani kò wọ̀ inu “Ijọba ọrun.”​—⁠Matteu 11:11; Heberu 11:​39, 40.

18 Bi o ti wu ki o ri, irúfẹ́ awọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́ bẹẹ ni a ó jí dide síhìn-ín gan-an lori ilẹ̀-ayé, tí pupọ ninu wọn yoo di “awọn ọmọ-aládé” ninu iṣeto Ijọba Ọlọrun. (Orin Dafidi 45:⁠16, NW) Iwọ ki yoo ha fẹ́ lati kí wọn kaabọ lati inu ibojì ati lati gbadun ibakẹgbẹpọ ọlọ́ràá pẹlu wọn bi? Dajudaju iwọ yoo fẹ́ bẹẹ! Nigba naa pinnu, pẹlu, lati nàgà fun “ilu-nla” naa nipa didi ‘alabaaṣiṣẹpọ fun ijọba Ọlọrun’ pẹlu gbogbo awọn miiran lonii tí wọn mọriri anfaani titobilọla naa.​—⁠Kolosse 4:⁠11.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 52, 53]

WỌN NÀGÀ FUN IJỌBA ỌLỌRUN

ABELI ni nǹkan bi 3900 B.C.E.

NOA 2970-2020 B.C.E.

ABRAHAMU, SARA, ISAAKI, JAKOBU 2018-1711 B.C.E.

JOSEFU 1767-1657 B.C.E.

MOSE 1593- 1473 B.C.E.

RAHABU 1473 B.C.E.

AWỌN ONIDAJỌ 1473-1117 B.C.E.

RUTU, NAOMI ni nǹkan bi 1300 B.C.E.

DAFIDI 1107-1037 B.C.E.

AWỌN WOLII 1117-442 B.C.E.

JOHANNU ARINIBỌMI 2 B.C.E.-31 C.E.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́