ORi 9
Awọn Ajogún Ijọba Pa Ìwàtítọ́ Mọ́
1. (a) Eeṣe tí Jesu fi jogún orukọ kan tí ó tayọlọla? (b) Ta ni lè jèrè lati inu apẹẹrẹ rẹ̀, bawo sì ni?
NÍ JÍJẸ́ olùṣòtítọ́ titi dé oju iku, Jesu jogún orukọ kan tí ó tayọlọla ju ti awọn angẹli lọ. Ninu gbogbo awọn ẹ̀dá ọlọ́gbọ́nlóye ti Ọlọrun, oun ni Ẹni naa lati fihan pe ọmọkunrin Ọlọrun kan lè pa ìwàtítọ́ pípé mọ́ si Ọlọrun, nipa bayii ó fi Satani hàn ní elékèé. Nitori naa, aposteli Paulu kọwe pe: “Lẹhin tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹṣẹ [nipa pipese irapada], ó jokoo ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlanla ní awọn ibi giga.” Ẹ wo apẹẹrẹ titobilọla ti o fi lelẹ fun gbogbo ẹni tí ó durode ‘dídé’ Ijọba naa—ati awọn wọnni tí ó jẹ́ ti “agbo kekere” tí yoo jogún Ijọba ọrun ati awọn wọnni tí yoo jẹ́ ọmọ-abẹ Ijọba naa lori ilẹ̀-ayé! Gẹgẹ bi aposteli kan-naa ti wí lẹhin naa pe: “Ẹ sì jẹ́ kí a fi ifarada sá eré-ìje tí a gbeka iwaju wa, gẹgẹ bi a ti ń tẹjumọ Olórí Aṣoju ati Aláṣepé igbagbọ wa, Jesu. Nitori ayọ̀ tí a gbeka iwaju rẹ̀, ó farada igi oró, o tẹmbẹlu itiju, ó sì ti jokoo ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.”—Heberu 1:3, 4; 12:1, 2, NW.
2-4. (a) Bawo ni Jesu ṣe kọ́ tí ó sì ṣeto awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ jọ ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé fun igbokegbodo iwaasu? (b) Bawo ni a ṣe mọ̀ pe wọn mú “ihinrere” naa lọ si ile awọn eniyan? (c) Apẹẹrẹ iṣaaju rere wo ni igbokegbodo yii pese fun awọn iranṣẹ Ọlọrun lonii?
2 Kii ṣe kiki pe Jesu pese apẹẹrẹ ológo fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ nikan ni, ṣugbọn ó tún kọ́ wọn ó sì fun wọn ní idanilẹkọọ, ki wọn baa lè tẹsiwaju ninu iṣẹ Ọlọrun lẹhin tí ó bá ti lọ.
“Ó ń la gbogbo ilu ati ìletò lọ, ó ń waasu, ó ń ro ihin ayọ ijọba Ọlọrun: awọn mejila sì ń bẹ lọdọ rẹ̀.”—Luku 8:1.
3 Lẹhin naa, Jesu rán awọn 12 jade ní awọn nikan “lati waasu ijọba Ọlọrun, ati lati mú awọn olókùnrùn láradá.” “Wọn là ìletò lọ, wọn sì ń waasu ihinrere, wọn sì ń mú eniyan láradá nibi gbogbo.” (Luku 9:2, 6) Ninu awọn ilu-nla ati ìletò ni wọn yoo ti wá awọn ẹni yiyẹ rí, eyi ni wọn sì ṣe nipa lilọ sinu ile awọn eniyan. Ó ń beere fun fifi tigboyatigboya tọju ìwàtítọ́ deedee níhà ọ̀dọ̀ wọn, gan-an gẹgẹ bi ó ti rí pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ọpọlọpọ ìpínlẹ̀ lonii, nitori atako sí ìhìn-iṣẹ́ naa. Jesu wi pe: “Bi ile naa bá sì yẹ, kí alaafia yin kí ó bà sori rẹ̀; ṣugbọn bi kò bá yẹ, kí alaafia yin kí ó pada sọdọ yin. Ẹnikẹni tí kò bá sì gbà yin, tí kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yin, nigba tí ẹyin bá jade kuro ní ile naa tabi ilu naa, ẹ gbọ̀n eruku ẹsẹ yin silẹ.”—Matteu 10:7, 11-14.
4 Lẹhin naa, nigba tí Jesu yàn 70 ọmọ-ẹhin miiran, ó sọ fun wọn pe: “Sá wò ó, emi rán yin lọ bi ọ̀dọ́-agutan saaarin ìkookò.” Awọn wọnyi, pẹlu, nilati lọ si ile awọn eniyan, nitori Jesu ń báa lọ lati wi pe: “Ní ilékílé tí ẹyin bá wọ̀, ki ẹ kọ́ wi pe, Alaafia fun ile yii. Bi ọmọ alaafia bá sì ń bẹ nibẹ, alaafia yin yoo bà lé e: ṣugbọn bi kò bá sí, yoo tún pada sọdọ yin.” Àní bi awọn eniyan kò tilẹ fetisi “ihinrere” naa, a nilati kilọ fun wọn pe Ijọba Ọlọrun ti súnmọ́ etílé! (Luku 10:3-11) Eyi pese apẹẹrẹ iṣaaju rere fun iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii, bi awọn wọnyi ti ń lọ lati ile dé ile pẹlu ìhìn-iṣẹ́ itunu ati ikilọ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.—Isaiah 61:1, 2.
WIWAASU LAIKA INUNIBINI SÍ
5. Ní awọn ọna wo ni Jesu tí a jí dide naa gbà tẹnumọ iru iṣẹ tí ń bẹ niwaju fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀?
5 Nigba iku Jesu, a tú awọn ọmọ-ẹhin wọnyẹn ká. Ṣugbọn ní ọpọ igba lẹhin ajinde rẹ̀ ninu ẹmi ó farahan wọn ninu ara-ìyára, lati fun wọn ní idaniloju ati okun. (1 Korinti 15:3-8) Ní ọ̀kan lara awọn igba wọnyi Jesu beere lọwọ Peteru lẹẹmẹta boya nitootọ ni ó nifẹẹ oun tí ó sì ní ìfẹ́ni fun oun. Ibanujẹ-ọkan bá Peteru nitori eyi, ṣugbọn igba mẹta ni Jesu tẹnumọ ọn pe, ní ẹ̀rí ifẹ ati ifẹni, Peteru gbọdọ maa bọ́ ki ó sì maa ṣe oluṣọ-agutan “awọn ọdọ-agutan,” awọn ‘agutan keekeeke’ rẹ̀. (Johannu 21:15-17) Nigba ifarahan miiran, Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ olùṣòtítọ́ mọkanla pe:
“Gbogbo agbara ní ọrun ati ni ayé ni a ti fi fun mi. Nitori naa ẹ lọ, ẹ maa kọ́ orilẹ-ede gbogbo, ki ẹ si maa baptisi wọn ni orukọ Baba ati ni ti Ọmọ, ati ni ti ẹmi mímọ́, ki ẹ maa kọ́ wọn lati kíyèsí ohun gbogbo, ohunkohun tí mo ti pa ni àṣẹ fun yin: ẹ sì kiyesi emi wà pẹlu yin nígba gbogbo, titi o fi dé opin ayé.” (Matteu 28:18-20)
Iṣẹ́ pupọ ń bẹ niwaju fun wọn.
6. Eeṣe tí awọn ọmọ-ẹhin Jesu yoo fi ṣe ‘awọn iṣẹ tí ó tobiju’?
6 Jesu ti sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Loootọ, loootọ ni mo wi fun yin, Ẹni tí ó bá gbà mi gbọ́, iṣẹ tí emi ń ṣe ni oun naa yoo ṣe pẹlu; iṣẹ tí ó tobiju iwọnyi lọ ni yoo sì ṣe; nitori emi ń lọ sọdọ Baba.” (Johannu 14:12) Wọn yoo kárí ìpínlẹ̀ tí ó tobiju eyi tí oun ti kárí lọ, wọn yoo sì maa bá iṣẹ iwaasu Ijọba Ọlọrun nìṣó fun akoko tí ó tubọ gùn gan-an.
7. Ohun ìyanu wo ni ó yọrisi ijẹrii kínníkínní ní ọjọ Pentekosti, pẹlu iyọrisi yiyanilẹnu wo sì ni?
7 Lẹhin tí ó ti dé sí ọwọ́ ọ̀tún Baba rẹ̀ ní ọrun, Jesu ṣe ohun ìyanu kan. Ní ọjọ Pentekosti, 33 C.E., ó tú ẹmi mimọ dà sori awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tí ń fojusọna, ni fifororo yan wọn lati jẹ̀ ajogún pẹlu rẹ̀ ninu Ijọba Ọlọrun ní ọrun. Ní àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀, 144,000 ni a yàn laaarin araye lati di ọba ati alufaa ní ọrun pẹlu Kristi. Nitori ijẹrii kínníkínní tí a ṣe ní ọjọ́ yẹn kanṣoṣo péré, 3,000 awọn Ju ati awọn aláwọ̀ṣe ni wọn fi tọkàntọkàn tẹwọgba ọ̀rọ̀ naa tí a sì baptisi wọn.—Johannu 14:2, 3; Ìfihàn 14:1-5; 20:4, 6; Iṣe 2:1-4, 14, 40, 41.
8-11. (a) Ìforígbárí wo ni ó bẹsilẹ laaarin awọn aṣaaju Ju ati awọn aposteli? (b) Bawo ni awọn aposteli ṣe fi araawọn hàn gẹgẹ bi awọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́? (c) Gẹgẹ bi Iṣe 5:40-42 ti wi, apẹẹrẹ rere wo ni awọn aposteli wọnyi fi lelẹ fun awọn iranṣẹ Ọlọrun lonii?
8 Iwaasu “ihinrere” naa tànká ìpínlẹ̀ Jerusalemu bi iná oko. Bẹẹ sì ni atako si Ijọba Ọlọrun. Laipẹ laijinna a wọ́ awọn aposteli dé iwaju ile-ẹjọ awọn Ju tí a ń pè ní Sanhedrin tí a sì kà á léèwọ̀ fun wọn lati sọrọ ní orukọ Jesu. Wọn yoo ha di ìwàtítọ́ wọn mú bi? Peteru ati Johannu fesi pe: “Bi ó bá tọ́ ní oju Ọlọrun lati gbọ́ ti yin jù ti Ọlọrun lọ, ẹ gbà á rò. Awa kò sá lè ṣàìmá sọ ohun tí awa ti rí, tí a sì ti gbọ́.” Nigba iṣẹlẹ yii a tú awọn aposteli silẹ, lójú-ẹsẹ̀ awọn ati awọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn fi ọpẹ́ fun Ọlọrun, wọn sì rawọ́-ẹ̀bẹ̀ si i pe: “Ǹjẹ́ nisinsinyi, Oluwa, . . . fi fun awọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lati maa fi igboya gbogbo sọ ọ̀rọ̀ rẹ.” Nitori naa wọn tẹsiwaju lati maa waasu pẹlu iranlọwọ ẹmi Jehofa.—Iṣe 4:19, 20, 29, 31.
9 Awọn aṣaaju isin tún fàṣẹ mú awọn aposteli lẹẹkan sii, wọn sì fi wọn sinu ẹ̀wọ̀n. Ṣugbọn kii ṣe ifẹ-inu Ọlọrun pe ki wọn pẹ́ nibẹ. Ní òru angẹli Jehofa tú wọn silẹ, nitori naa ilẹ mọ́ bá wọn nibi tí wọn ti ń kọni lẹẹkan sii ninu tẹmpili ní Jerusalemu.—Iṣe 5:17-21.
10 Ki ni Sanhedrin lè ṣe lati dá ìtànkálẹ̀ “ihinrere” naa duro? Lẹẹkan sii, a mú awọn aposteli wá sinu ile-ẹjọ, alufaa agba sì fi ẹ̀sùn kàn wọn pe: “Awa kò ha ti kilọ fun yin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ [Jesu] kọni mọ́? Sì wò ó, ẹyin ti fi ẹkọ yin kún Jerusalemu, ẹ sì ń pete lati mú ẹjẹ ọkunrin yii wá sori wa.” Idahunpada alaijuwọsilẹ ti awọn aposteli wọnni dún jade, la ọ̀rúndún mọkandinlogun já pe:
“Awa kò gbọdọ má gbọ́ ti Ọlọrun jù ti eniyan lọ”!
Ki ni awọn Ju lè ṣe pẹlu awọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́ wọnyi? Gamalieli olukọ ofin naa pese àmọ̀ràn ọlọgbọn: “Ẹ gáfárà fun awọn ọkunrin wọnyi, ki ẹ sì jọwọ wọn jẹ́ẹ́: nitori bi imọ tabi iṣẹ yii bá jẹ́ ti eniyan, a ó bì í ṣubu: ṣugbọn bi ti Ọlọrun bá ni, ẹyin ki yoo lè bì í ṣubu; ki ó má baa jẹ́ pe, a rí yin, ẹ ń bá Ọlọrun jà.”—Iṣe 5:27-39.
11 Nitori naa awọn aposteli ni a nàlọ́rẹ́, tí a sì paṣẹ fun wọn lati ṣíwọ́ ọ̀rọ̀-sísọ, lẹhin naa a tú wọn silẹ. Ki ni ihuwapada wọn? Wọn yọ̀ niti pe a kà wọn yẹ lati jiya nitori orukọ Jesu.
“Ati ní ojoojumọ ní tẹmpili ati ni ilé, wọn kò dẹkun ikọni, ati lati waasu Jesu Kristi.” (Iṣe 5:40-42)
Awọn ajogún Ijọba wọnyi ti pinnu lati farada ohun tí ó pọndandan ki wọn baa lè maa tẹsiwaju ní ṣiṣe iṣẹ Ọlọrun. Wọn tipa bayii fi apẹẹrẹ rere lelẹ fun gbogbo awọn ẹlẹ́rìí Ọlọrun tootọ naa tí wọn ti ń báa nìṣó ní pipokiki Ijọba naa “ní gbangba ati lati ile dé ile” títí di òní yii.—Iṣe 20:20, 21.
“IHINRERE” IJỌBA NAA TAǸKÁLẸ̀
12. Gẹgẹ bi a ti fihan ninu Iṣe 8:1-4, bawo ni inunibini ṣe saba maa ń yọrisi ìtànkálẹ̀ “ihinrere” naa siwaju sii?
12 Inunibini naa tún gbonajanjan lẹẹkan sii, tí ó fi jẹ́ pe gbogbo wọn ni a túkáàkiri si Judea ati Samaria tí ń bẹ nítòsí ayafi awọn aposteli nikan. Ṣugbọn eyi wulẹ ṣiṣẹ lati mú ki ijẹrii naa tànkálẹ̀ ni, nitori pe “awọn tí wọn sì tuka lọ sibi gbogbo, wọn ń waasu ọ̀rọ̀ naa.” (Iṣe 8:1-4) Ó runi-lọkan-soke pe, ohun kan-naa ni ó ti ṣẹlẹ ní ode-oni. Nigba tí awọn ijọba aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀ ti gbiyanju lati pa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lẹ́numọ́ nipa títú wọn ká si awọn àgbègbè àdádó, wọn ti ń báa lọ lati maa waasu nibẹ, “ihinrere” naa sì ti tànkálẹ̀.
13, 14. (a) Nigba wo ni ọsẹ akanṣe ojurere Ọlọrun sí awọn Ju dopin, awọn wo nigba naa ni a tẹwọgba gẹgẹ bi ajogún Ijọba? (b) Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ Paulu ninu Iṣe 13 ati Romu 11 ṣe jẹrii si eyi?
13 Bi ó ti wù ki ó rí, lẹhin lọ́hùn-ún ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, ṣé kiki awọn Ju ati awọn ará Samaria aládùúgbò wọn nikan ni a mú ìhìn-iṣẹ́ Ijọba naa lọ sọdọ wọn bi? Iye pipe pérépéré mẹmba Ijọba ọrun yoo ha jẹ́ laaarin wọn nikanṣoṣo bi? Àní pẹlu ijẹrii agbayanu tí a ń fi funni, eyiini kò nilati jẹ́ bẹẹ. Ó hàn gbangba pe ní 36 C.E., gẹgẹ bi “ọsẹ” akanṣe ojurere Ọlọrun si awọn Ju ti wá si opin, Jehofa dari Peteru lati ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Korneliu, olóyè ẹgbẹ ọmọ-ogun Itali kan, ní ile rẹ̀ ní Kesaria. Bi Peteru ti ń waasu fun ẹni tí kii ṣe Ju yii ati agbo-ile rẹ̀, ẹmi mímọ́ bà lé wọn, ni fifororo yan wọn gẹgẹ bi ajogún Ijọba naa. A baptisi wọn gẹgẹ bi awọn Keferi aláìkọlà akọkọ tí a yílọ́kànpadà sí isin Kristian.—Iṣe 10:1-48.
14 Lẹhin naa, nigba tí aposteli Paulu ati awọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ bá atako oníwà-ipá pade lati ọ̀dọ̀ awọn Ju ní Antioku ti Pisidia, Paulu sọ fun awọn Ju wọnni pe: “Ẹyin ni a gbọdọ kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun fun: ṣugbọn bi ẹ ti ta á nù, ẹ sì kà araayin si aláìyẹ fun ìyè ainipẹkun, wò ó, awa yipada sọdọ awọn keferi. Bẹẹ ni Oluwa sáà ti paṣẹ fun wa pe, Mo ti gbé ọ kalẹ̀ fun imọlẹ awọn keferi, ki iwọ ki ó lè jẹ́ fun igbala titi dé opin ayé.” (Iṣe 13:46, 47) Gẹgẹ bi Paulu ti wi lẹhin naa ninu akawe kan, awọn Ju alaigbagbọ wọnni dabi awọn ẹ̀ka àdánidá tí a gé kuro lara igi olifi. Awọn Ju ìbá ti pese ẹkunrẹrẹ iye ajogún Ijọba naa. Bi ó ti wù ki ó rí, ní ipò wọn, “awọn Keferi,” gẹgẹ bi ẹ̀ka igi olifi ìgbẹ́, di eyi tí a lọ́ sinu rẹ̀, nipa bayii “a o gba gbogbo Israeli [ti ẹmi] là,” titi de iye mẹmba Ijọba naa ní kíkún.—Romu 11:13-26; Galatia 6:16.
ÌWÀTÍTỌ́ LABẸ “IPỌNJU”
15, 16. (a) Ki ni Paulu ṣe tí ó sì sọ nipa “ipọnju,” awokọṣe rere wo ni eyi sì pese fun wa? (b) Ki ni yẹ kí ó jẹ́ iṣarasihuwa wa si atako lati ọ̀dọ̀ awọn ijọba tabi awọn mẹmba idile, abajade wo ni a sì ṣeleri fun wa?
15 Labẹ inunibini siwaju sii, alaboojuto arinrin-ajo olùṣòtítọ́ yẹn, aposteli Paulu, pada si Antioku, ki ó baa lè mú awọn ọmọ-ẹhin lọ́kànle ki ó sì fun wọn ní iṣiri ati lati gbé ìṣètò ijọ ró. Nigba naa ni Paulu wi pe:
“Ninu ipọnju pupọ ni awa o fi wọ ijọba Ọlọrun.”—Iṣe 14:21-23.
16 Paulu ń báa lọ lati ní ìpín tirẹ̀ ninu awọn iṣoro ati idanwo. Ṣugbọn oun jẹ́ apẹẹrẹ titayọ ní pipa ìwàtítọ́ rẹ̀ mọ́ láìyingin. Ó pese àwòkọ́ṣe rere fun ọpọlọpọ ní ode-oni tí wọn nilati jà ija lile ti igbagbọ. Pupọ ninu awọn wọnyi ti nilati farada awọn ìluni, ifisẹwọn ati ewu si iwalaaye fúnraarẹ̀. Atako ti wá lati ọ̀dọ̀ awọn ijọba aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀, tabi lati ọ̀dọ̀ awọn ibatan tí wọn jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n paapaa. Awọn mẹmba idile ti kọ̀ awọn kan silẹ nitori titẹwọgba ati gbígbé ìgbésẹ̀ ní itilẹhin “ihinrere ijọba” naa. (Matteu 24:14) Bi ó ti wù ki ó rí, irufẹ awọn ẹni bẹẹ ni awọn ọ̀rọ̀ Jesu wọnyi ti tùnínú gidigidi: “Kò si ẹni tí ó fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi ìyá, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori mi, ati nitori ihinrere, ṣugbọn nisinsinyi ní ayé yii oun yoo sì gbà ọgọrọọrun, ile, ati arakunrin, ati arabinrin, ati ìyá, ati ọmọ, ati ilẹ, pẹlu inunibini, ati ní ayé tí ń bọ̀ ìyè ainipẹkun.” (Marku 10:29, 30) Dajudaju wọn ń ká “ọgọrọọrun” ninu ibatan timọtimọ wọn pẹlu Jehofa ati Ọmọkunrin rẹ̀ ati ninu ibakẹgbẹpọ wọn onídùnnú pẹlu idile Jehofa kárí ilẹ̀-ayé.
17. (a) Awọn ìdẹwò wo ni awọn Kristian akọkọbẹrẹ nilati jìjà lodisi? (b) Apẹẹrẹ ati àmọ̀ràn ológo wo ni Paulu pèsè fun wa?
17 Aposteli Paulu ati awọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tún nilati jìjà lodisi awọn idẹwo ayé sinu ìwà-pálapàla ati ifẹ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì. Eniyan lásán bí tiwa ni wọn jẹ́. Nigba tí a bá dojukọ irufẹ awọn ìrélọ bẹẹ a gbọdọ ṣe gẹgẹ bi Paulu, ẹni tí ó wi pe: “Emi ń pọ́n araami lójú, mo sì ń mú un wá sabẹ itẹriba: pe lẹhin tí mo ti waasu fun awọn ẹlomiran, nitori ohunkohun, ki emi tikaraami maṣe di ẹni ìtanù.” Ati gẹgẹ bi Paulu, awa, pẹlu, lè rí aabo ní sisọ fun awọn aladuugbo wa nipa Ijọba Ọlọrun. Gẹgẹ bi Paulu ti wi nipa irufẹ iṣẹ-isin mímọ́ bẹẹ: “Àní, mo gbé! bi emi kò bá waasu ihinrere.”—1 Korinti 9:16, 27.
A “JAGUNMÓLÚ PATAPATA”
18. Iṣiri wo ni Paulu fi silẹ fun gbogbo Kristian tootọ, bawo ni iwọ sì ṣe dahun si eyi?
18 Aposteli Paulu sì tún sọ fun awọn Kristian ẹni ami ororo ẹlẹgbẹ rẹ̀ pe: “Bi awa bá sì jẹ́ ọmọ [Ọlọrun], ǹjẹ́ ajogún ni wa, ajogún Ọlọrun, ati ajùmọ̀jogún pẹlu Kristi; bi ó bá ṣe pe awa bá a jìyà, ki a sì ṣe wa lógo pẹlu rẹ̀.” Ṣugbọn ohun tí ó tẹsiwaju lati sọ tún kan “ogunlọgọ nla” ti “agutan miiran” bakan naa, awọn ẹni tí ń nágà lonii fun èrè-ẹ̀san ológo ti ìyè ainipẹkun ninu paradise ilẹ̀-ayé. (Ìfihàn 7:9, NW; Johannu 10:16) Paulu fun gbogbo awọn Kristian tootọ ní iṣiri, ní wiwi pe:
“Ta ni yoo ha yà wa kuro ninu ifẹ Kristi? Ipọnju ni, tabi wahala, tabi inunibini, tabi ìyàn, tabi ìhòòhò, tabi ewu, tabi idà? . . . Ṣugbọn ninu gbogbo nǹkan wọnyi awa [ń mókè bí ẹni jagunmólú patapata, NW] nipa ẹni tí ó fẹ wa. Nitori o damiloju pe, kii ṣe iku, tabi ìyè, tabi awọn angẹli, tabi awọn ìjòyè, tabi awọn alagbara, tabi ohun igba isinsinyi, tabi ohun igba tí ń bọ̀, tabi òkè, tabi ọ̀gbun, tabi ẹ̀dá miiran kan ni yoo lè yà wa kuro ninu ifẹ Ọlọrun tí ń bẹ ninu Kristi Jesu Oluwa wa.” (Romu 8:17, 35-39; tún wò 2 Korinti 11:22-28 pẹlu.)
Iwọ ha ń mú iru ìgbọ́kànlé bẹẹ dagba ninu ifẹ Ọlọrun ati ninu ‘dídé’ Ijọba Jesu Oluwa bi? Iwọ gbọdọ ṣe bẹẹ!
19. Ikilọ wo ni Paulu funni nipa ewu panipani miiran?
19 Ewu miiran tí o gbọdọ mura araarẹ silẹ lodisi ní “awọn ọjọ ikẹhin” wọnyi ni ẹ̀kọ́ èké. Paulu kilọ lodisi eyi pẹlu. (Iṣe 20:29, 30; 2 Timoteu 3:1, 13) Lati ibo ni awọn olukọ eke ti wá, bawo ni a ṣe lè ṣọra fun wọn?