ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kc orí 10 ojú ìwé 87-95
  • Ayédèrú Ijọba kan Yọjú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayédèrú Ijọba kan Yọjú
  • “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌPẸ̀HÌNDÀ NLA NAA
  • IPILẸṢẸ ISIN KATOLIKI
  • NIPA ISIN PROTẸSTANTI Ń KỌ́?
  • “BABILONI NLA”
  • Constantine Ńlá—Ṣé Ajàjàgbara fún Ẹ̀sìn Kristẹni Ni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Bí Kristẹndọm Ṣe Di apakan Ayé Yii
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Jija Àjàbọ́ Kuro Ninu Isin Èké
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
“Kí Ijọba Rẹ Dé”
kc orí 10 ojú ìwé 87-95

Ori 10

Ayédèrú Ijọba kan Yọjú

1. Bawo ni “ihinrere” naa ti gbèrú tó nigba ijimiji?

LÓJÚ awọn inunibini tí ó rorò julọ, ijọ Kristian tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dagba naa ń báa niṣo lati gbèrú ati lati tànkálẹ̀. Otitọ ihinrere nipa Ijọba Ọlọrun lati ọwọ́ Messia naa “ń so eso pẹlu ní gbogbo ayé.” Bi awọn olùpòkìkí Ijọba naa ti ń jáwọnú awọn ìpínlẹ̀ titun ni awọn alatako ń kédàárò pe “awọn wọnyi tí ó ti yí ayé po wá síhìn-ín yii pẹlu.”​—⁠Kolosse 1:​5, 6; Iṣe 17:⁠6.

2. Awọn isapa wo ni Eṣu ṣe lati dá ìtànkálẹ̀ otitọ duro, ṣugbọn eeṣe tí ó fi kùnà?

2 Àmọ́ ṣáá o, ki ni awọn eniyan lásán-làsàn lè ṣe lati dá ìtànkálẹ̀ otitọ duro? Itan ṣe akọsilẹ pe ní ọ̀rúndún mẹta akọkọ Sanmani Tiwa awọn Kesari ti Ilẹ-ọba Romu mú awọn ìgbì inunibini mẹwaa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá lodisi awọn Kristian akọkọbẹrẹ, ṣugbọn pàbó ni gbogbo rẹ̀ jásí. Awọn wọnni tí wọn tẹle ìṣísẹ̀ Jesu, “pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ,” kọ̀ lati juwọsilẹ àní bi ó tilẹ jẹ́ pe “kinniun tí ń ké ramúramù” yẹn, Eṣu, rí sii pe pupọ ninu wọn ni a jù sẹ́nu awọn kinniun gidi tabi kẹ̀ tí a dálóró titi dé ojú ikú.​—⁠1 Peteru 5:​8, 9; fiwe 1 Korinti 15:32; 2 Timoteu 4:⁠17.

3. Eeṣe tí iwọ fi gbọdọ gbé “gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀”?

3 Niwọn bi ikọlu taarata ti inunibini olójúkojú ti saba maa ń kuna, Eṣu wá ọ̀nà lati dẹkùn mú awọn ọmọlẹhin Jesu nipasẹ awọn ọna tí ó tubọ jẹ́ alarekereke. Ayé onigberaga, oníwà-pálapàla, tí adùn ti yà ní wèrè ni ó yí wọn ká, Satani sì lò eyi ní kíkún ní gbigbiyanju lati yí wọn pada kuro ninu iṣẹ-isin Ọlọrun. Aini naa wà fun wọn lati “duroṣinṣin,” gẹgẹ bi aposteli Paulu ti tẹnumọ ọn nigba mẹta ninu Efesu 6:​11-⁠18, ní ṣiṣalaye kúlẹ̀kúlẹ̀ nipa “ihamọra Ọlọrun” tẹmi tí wọn nilati lò. Iwọ funraarẹ ha ti gbé “gbogbo ihamọra Ọlọrun” yii wọ̀ bi? Iwọ gbọdọ ní in ki o baa lè fàyàrán awọn idanwo ní ‘awọn ọjọ ikẹhin’ wọnyi. (2 Timoteu 3:​1-⁠5) Awọn Kristian lẹhin lọ́hùn-ún ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní nílò rẹ̀. Eeṣe tí ó fi jẹ́ bẹẹ ní gidipàá?

4. Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, awọn otitọ Ijọba pataki wo ni awọn Kristian wá loye rẹ̀?

4 Tiwọn jẹ́ igbagbọ mímọ́gaara kan tí ó rọrun. Ní akoko yẹn gbogbo wọn jẹ́ Kristian ẹni-ami-ororo tí ń fojusọna fun ajinde kan ní ọjọ-iwaju “lati wọ̀ ijọba ainipẹkun ti Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi.” (2 Peteru 1:11; 1 Korinti 15:50) Ó keretan lati nǹkan bii ọdun 96 C.E., nigba tí aposteli Johannu arugbo naa rí Ìfihàn gbà nipasẹ imisi atọrunwa, wọn mọriri rẹ̀ pe iye wọn, gẹgẹ bi “agbo kekere” kan, yoo jẹ́ 144,000. Gẹgẹ bi ajumọ jẹ ‘ọba ati alufaa’ pẹlu Kristi ní ọrun, wọn yoo ṣakoso ilẹ̀-ayé fun 1,000 ọdun. A fihan Johannu pe “lẹhin” tí a bá ti kó 144,000 Israeli tẹmi jọ tán, awọn “ogunlọgọ nla eniyan” aláìníye kan ti awọn ọkunrin ati obinrin aduroṣinṣin, “lati inu orilẹ-ede gbogbo ati ẹya ati eniyan ati ede gbogbo wá,” ni a ó dámọ̀yàtọ̀. Gẹgẹ bi ẹgbẹ kan awọn wọnyi yoo là “ipọnju nla” ikẹhin já lori ilẹ̀-ayé lati di ipilẹ ẹgbẹ-awujọ eniyan tí yoo gbadun awọn ibukun ẹgbẹrun ọdun labẹ iṣakoso Ijọba naa.​—⁠Luku 12:32; Ìfihàn 7:4, 9-⁠17; 20:1-⁠6; 21:1-⁠5.

ÌPẸ̀HÌNDÀ NLA NAA

5, 6. (a) Awọn ẹṣẹ iwe mimọ wo ni ó fihan pe, koda nigba naa lọ́hùn-ún, Eṣu lò ọna tí ó tubọ jẹ́ alarekereke lati ṣatako? (b) Ní kukuru, ki ni ó jẹ́?

5 Nigba naa, ki ni ọna arekereke ikọlu Eṣu? Ní titọka pada sẹhin si Israeli alainigbagbọ, aposteli Peteru kilọ pe: “Awọn wolii eke wà laaarin awọn eniyan naa pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọni eke yoo ti wà laaarin yin, awọn ẹni tí yoo yọ́ mú àdámọ̀ ègbé wọ̀ inu yin wá . . . Ati ninu ojukokoro ni wọn yoo maa fi yin ṣe èrè jẹ nipa ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.” (2 Peteru 2:​1, 3) Awọn olukọni ní ẹkọ iyapa eke wọnyi, pẹlu ayédèrú ẹkọ-igbagbọ isin wọn, ti bẹrẹsi farahan ní opin ọ̀rúndún kìn-ín-ní, nitori pe ní nǹkan bii 98 C.E. ni aposteli Johannu kọwe pe: “Bi ẹyin sì ti gbọ́ pe aṣodisi Kristi ń bọ̀ wá, àní nisinsinyi aṣodisi Kristi pupọ ni ń bẹ . . . Wọn ti ọ̀dọ̀ wa jade, ṣugbọn wọn kii ṣe ara wa.”​—⁠1 Johannu 2:​18, 19.

6 Lẹhin lọ́hùn-ún ní 51 C.E., ninu ohun tí ó dabi lẹta rẹ̀ onimiisi keji, aposteli Paulu ti kilọ nipa awọn ẹkọ eke nipa “ọjọ Jehofa.” Oun kọwe pe: “Ẹ maṣe jẹ́ ki ẹnikankan yí yin léròpada-dẹṣẹ ní iru-ọna eyikeyii, nitori pe ki yoo dé bikoṣe pe ìpẹ̀hìndà naa bá kọ́kọ́ dé tí a sì ṣí ọkunrin aláìlófin naa payá, ọmọ iparun.” Ta ni “ọkunrin aláìlófin” yii lè jẹ́? Ó nilati tọkasi awọn aṣaaju isin apẹhinda tí wọn jẹ́ aláìlófin niti pe, nigba tí wọn jẹ́wọ́sọ pe Kristian ni wọn, wọn “kò mọ̀ Ọlọrun” wọn kò sì “ṣegbọran si ihinrere nipa Jesu Oluwa wa.” (2 Tessalonika 1:6-⁠8; 2:1-⁠3, NW) Bawo ni ẹgbẹ apẹhinda bẹẹ ṣe lè dide ninu ijọ Kristian?

7. Bawo ni a ṣe dẹkùn mú awọn kan lara awọn ọmọlẹhin Jesu, pẹlu iyọrisi wo sì ni?

7 Nigba tí awọn aposteli Jesu Kristi ṣì walaaye, wọn ṣiṣẹ gẹgẹ bi ìdènà fun ìyọ́wọlé ẹkọ eke, ṣugbọn “ohun-ijinlẹ ìwà-àìlófin yii” ti wà lẹ́nu iṣẹ pẹrẹu, “gẹgẹ bi iṣẹ Satani,” ó sì wá si ojútáyé ní ọ̀rúndún keji. Nigba tí ó jẹ́ pe Jesu ti sọ nipa awọn ọmọlẹhin rẹ̀ tẹlẹ pe “ará sì ni gbogbo yin,” ifẹ-ọkàn fun ìyọrí-ọlá ara-ẹni mú ki awọn kan di ẹni tí Eṣu dẹkùn mú. Nisinsinyi wọn wá ṣe ìyàsọ́tọ̀ laaarin alufaa ati ọmọ-ijọ. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ipo-ọran naa tí aposteli Paulu sọtẹlẹ dide: “Igba yoo dé, tí wọn ki yoo lè gbà ẹkọ tí ó yekooro; ṣugbọn bi wọn ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin wọn yoo lọ kó olukọ jọ fun araawọn ninu ifẹkufẹẹ araawọn. Wọn yoo sì yí etí wọn pada kuro ninu otitọ.”​—⁠2 Timoteu 4:3, 4; 2 Tessalonika 2:​6-⁠10, NW; Matteu 23:⁠8.

8. (a) Ki ni awọn orisun pataki meji ti ẹkọ eke? (b) Bawo ni awọn iwe agbedegbẹyọ ṣe ṣapejuwe sisọ isin Kristian dibajẹ?

8 Nigba naa, nibo ni wọn yí eti wọn sí? Sí awọn ẹkọ-igbagbọ tí ó bẹrẹ lati ilẹ-ibilẹ isin eke ní Babiloni igbaani, ati sí awọn imọ-ọran awọn Griki, eyi tí ó lokiki tobẹẹ ní ayé Romu igba yẹn. Gẹgẹ bi iwe agbedegbẹyọ ti M’Clintock and Strong’s Cyclopaedia ti ṣalaye: “Irọrun Ihinrere naa ni a sọdibajẹ; awọn ààtò ati ayẹyẹ aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀ ni a mú wọlé; awọn orukọ oyè ayé ati awọn èrè-àjẹmọ́nú gọbọyi ni a fifun awọn olukọ isin Kristian, lọna titobi, ijọba Kristi ni a sì yipada si ijọba ayé yii.” Si eyi ni iwe agbedegbẹyọ Encyclopaedia Britannica fi kún un pe: “Kò dabi ẹnipe ohunkohun wà ti ó fẹ sọ isin Kristian dibajẹ ni gbogbo ọna ju imuwọle awọn igbagbọ ninu ohun asan ti wọn jẹ ti oriṣa ninu araawọn, tabi ti awọn aṣa oloriṣa ti dabaa wọn. Bi kò tíì ṣe ṣeeṣe fun ibọriṣa, lati ṣe aṣeyọri ni titako isin Kristian, o ti ṣe pupọ lati bà á jẹ́, ati ní awọn ọna aláìlóǹkà, ó ti yọ́ wọnú ìjẹ́mímọ́ rẹ̀.”

9. (a) Awọn igbagbọ tí ó wọpọ wo ni ó jẹyọ lati inu ẹkọ naa pe ọkàn eniyan jẹ́ aileeku? (b) Bawo ni Bibeli ṣe túdìí aṣiri iru awọn ẹkọ-igbagbọ bẹẹ?

9 Ki ni diẹ lara awọn igbagbọ ninu ohun asan ati aṣa olórìṣà wọnyi? Eyi tí ó tayọ julọ ni ẹkọ ọ̀mọ̀ràn Griki naa Plato pe ọkàn eniyan jẹ́ alaileeku. Iru igbagbọ bẹẹ beere pe ọkàn nilati lọ si ibikan nigba iku, si ọrun kan tí ó jẹ́ ti ayọ pípé, pọgatori kan fun ìsọdimímọ́ tabi hẹli oníná kan fun idaloro ayeraye. Eyi tako irufẹ awọn ẹsẹ iwe mimọ ninu Bibeli bii Orin Dafidi 146:4; Oniwasu 9:​5, 10; Matteu 10:28 ati Romu 6:⁠23.

IPILẸṢẸ ISIN KATOLIKI

10, 11. (a) Ki ni Alufaa Agba Newman jẹ́wọ́ rẹ̀ nipa pupọ ninu awọn ẹkọ Ṣọọṣi rẹ̀? (b) Niwọn bi ó ti wi pe awọn aṣa ati ẹkọ Ṣọọṣi “ní ipilẹ olórìṣà,” a ha lè kà awọn wọnyi sí mímọ́ nitootọ bi?

10 Ninu Essays and Sketches rẹ̀, John Henry Newman alufaa agba Roman Katoliki ti ọ̀rúndún kọkandinlogun, fi ipilẹṣẹ ọpọlọpọ ẹkọ ṣọọṣi rẹ̀ hàn, wi pe: “Ohun àrà-mérìírí naa, tí gbogbo eniyan tẹwọgba ni eyi:​—⁠Pe apá tí ó pọ julọ ninu ohun tí gbogbo eniyan gbà gẹgẹ bi otitọ Kristian, ni ipilẹ rẹ̀ tabi ní awọn apá kọọkan rẹ̀, ni a ó rí ninu awọn imọ-ọran ati isin awọn abọgibọ̀pẹ̀. Fun apẹẹrẹ, ẹkọ Mẹtalọkan ni a rí ní Ila-oorun ati Iwọ-oorun; bẹẹ sì ni ayẹyẹ wíwẹ̀; bẹẹ sì ni ààtò irubọ. Ẹkọ Ọ̀rọ̀ Atọrunwa jẹ́ ti Plato; ẹkọ Àtúnwáyé jẹ́ ti India.” Lẹhin naa, nigba tí ó ń fèsì fun lámèyítọ́ kan tí ń jiyan pe, “Awọn nǹkan wọnyi jẹ́ ti awọn abọgibọ̀pẹ̀, nitori naa wọn kii ṣe ti isin Kristian,” alufaa agba naa wi pe: “Kàkà bẹẹ, awa yàn lati wi pe, ‘Awọn nǹkan wọnyi wà ninu isin Kristian, nitori naa wọn kii ṣe ti awọn abọgibọ̀pẹ̀.’” Ṣugbọn orisun wọn jẹ́ ti awọn ẹkọ Babiloni ati ti Griki tí ó ti wà ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣaaju ìbí isin Roman Katoliki. Siwaju sii, a kò lè rí wọn ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli.

11 Pé ìpẹ̀hìndà nla naa pada sí isin awọn olórìṣà fun awọn ẹkọ ati awọn ayẹyẹ rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Alufaa Agba Newman tún tẹnumọ siwaju sii ninu iwe rẹ̀ The Development of Christian Doctrine, nibi tí o ti kọwe pe: “Lati baa lè damọran isin [Roman Katoliki] titun fun awọn abọgibọ̀pẹ̀, Constantine, mú awọn ohun ọ̀ṣọ́ ode eyi tí wọn ti sọ dàṣà funraawọn wọ̀ inu rẹ̀.” Lẹhin naa, lẹhin ṣiṣe akọsilẹ ọpọlọpọ aṣa ṣọọṣi rẹ̀, alufaa agba naa jẹ́wọ́gbà pe gbogbo iwọnyi “ní ipilẹṣẹ olórìṣà, tí a sì sọ di mímọ́ nipa mímú wọn wọ̀ inu Ṣọọṣi.” Ṣugbọn a ha lè “sọ” ẹkọ eke “di mímọ́,” tabi ki a yà á sí mímọ́ bi?

12, 13. (a) Labẹ awọn ipò wo ati pẹlu ìsúnniṣe wo ni Constantine fi ní ọkàn-ìfẹ́ si isin Roman Katoliki? (b) Ki ni fihan boya Constantine ti di Kristian tọkantọkan?

12 Níhìn-ín alufaa agba naa tọkasi Constantine Nla, ọba-nla Romu ti ọ̀rúndún kẹrin. Ki ni idi tí Constantine fi ní ọkàn-ìfẹ́ si isin? Ọpọ ọdun lẹhin ìgbóguntì rẹ̀ si Romu ní 312 C.E., Constantine mú un ṣe kedere pe, ní gẹ́rẹ́ ṣaaju iṣẹgun rẹ̀, ó rí agbelebu tí ń jólala ninu ìran, pẹlu ẹṣin-ọrọ naa tí ó kà pe “Ṣẹgun Nipasẹ Eyi.” Eyi ni ó kọ sara àsíá rẹ̀. Dajudaju idi tí ó fi tẹwọgba awọn ẹkọ ipilẹ isin fun Roman Katoliki ni lati jèrè itilẹhin fun mímú awọn ete iṣelu rẹ̀ tẹsiwaju, ti ó sì mú awọn igbagbọ olórìṣà ti o ṣì famọ ọkan rẹ̀ julọ wọ̀ inu eto-igbekalẹ isin “Kristian.”

13 Encyclopaedia Britannica wí nipa Constantine pe: “Ibọriṣa nilati jẹ́ igbagbọ tí ó ṣi gbeṣẹ sibẹ pẹlu ọkunrin naa tí ó di ọpọ igbagbọ ninu ohun asan mú, titi fẹrẹẹ dé opin igbesi-aye rẹ̀. . . . Constantine lẹ́tọ̀ọ́ lati di ẹni tí a pè ní Nla nitori ohun tí ó ṣe jù ohun tí ó jẹ́ lọ. Nitootọ, bi a bá gbe e ka ori animọ ìwà-ẹ̀dá rẹ̀, ó wà lara awọn wọnni tí ó rẹlẹ julọ ninu awọn tí a ti lò ọrọ-apejuwe naa [“Nla”] fun ní igba atijọ tabi ní ode-oni.” Eyi ni a fihan niti pe ó hùwà àbùkù koda ni pipa pupọ ninu awọn mẹmba idile rẹ̀. Orukọ-oyè keferi rẹ̀, “Pontifex Maximus” (Baba Oloriṣa), ni a sọ di ti awọn popu Ṣọọṣi Roman Katoliki nigba tí ó ṣe.

14. Awọn popu Romu ha ń ṣoju fun Ijọba Ọlọrun nitootọ bi, eesitiṣe tí o fi dahun bẹẹ?

14 Jálẹ̀ gbogbo Sanmani Ojú Dúdú ati Igba Ibẹrẹ Ọ̀làjú, awọn popu Romu ṣakoso lọna pupọ bi awọn ọba lori ilẹ̀-ayé. Wọn kò duro dè Kristi ki ó gbé iṣakoso ẹlẹgbẹrun ọdun rẹ̀ kalẹ lati ọrun. Wọn fẹ́ “ijọba” kan nigba naa, fun anfaani imọtara ẹni-nikan wọn. Iwe agbedegbẹyọ Encyclopaedia Britannica ṣalaye rẹ̀ ninu awọn ọrọ wọnyi: “Ọ̀kan ninu awọn ohun tí ó fa isọdibajẹ isin Kristian ní ibẹrẹ gan-an ni igbiyanju lati tumọ ijọba Ọlọrun ti Kristian si ijọba tí a lè fojuri ninu eyi tí awọn eniyan mímọ́ yoo jogún ilẹ̀-ayé lọna gidi.” Abajọ tí awọn eniyan aláìlábòsí fi fẹ́ lati ṣaifohun ṣọkan pẹlu iru “isọdibajẹ isin Kristian” bẹẹ! Bi ó ti wù ki ó rí, Ìwádìí oníwà-ìkà naa Lati Gbógunti Àdámọ̀, eyi tí ìfinásun lori òpó-igi nikan gbà ẹ̀mí tí ó jù 30,000 lọ, ṣeranwọ fun igba pipẹ lati pa awọn tí a fi pẹlu iṣina pè ní awọn aládàámọ̀ lẹ́numọ́. Ṣugbọn kii ṣe titilọ gbére!

NIPA ISIN PROTẸSTANTI Ń KỌ́?

15. (a) Ki ni Atunṣe isin Protẹstanti dà nitootọ? (b) Lọna wo ni isin Protẹstanti fi wà ní ìgbèkùn titi di òní yii?

15 Ní ọ̀sángangan, ni October 31, 1517, alufaa Roman Katoliki naa Martin Luther kan 95 awọn àbá ilodisi mọ́ ilẹkun ṣọọṣi ní Wittenberg, Germany. Bi Atunṣe isin Protẹstanti ṣe bẹrẹ niyẹn. Àmọ́ ṣáá o, dipo ki ó mú ipadabọ si ògidì ẹkọ-igbagbọ Kristian ati iṣẹ-isin mímọ́ si Ọlọrun wá, Atunṣe naa lọna gbigbooro di ti iṣelu. Jíjèrè ìpínlẹ̀ ni a lepa nipa jíja awọn ogun isin, iru bi Ogun 30 Ọdun ti 1618-1648 ní Europe, ninu eyi tí araadọta ọkẹ ẹmi ṣòfò. Ọpọlọpọ orilẹ-ede gbé isin orilẹ-ede wọn kalẹ, ti awọn wọnyi sì ń báa lọ lati maa kọni ní awọn ẹkọ isin Katoliki ti wọn ṣe pataki julọ, iru bi aileeku ọkàn, iná ìdálóró ti ọrun àpáàdì, Mẹtalọkan, baptismu awọn ọmọ-ọwọ ati pupọ miiran. Wọn ṣì wà ninu ìgbèkùn si awọn ẹkọ ìpẹ̀hìndà titobi wọnyi titi di oní-olónìí.

“BABILONI NLA”

16, 17. (a) Itumọ wo ni Jeremiah 51:6 ní fun wa lonii? (b) Bawo ni isin Babiloni ṣe di ti agbaye ní gbogbogboo?

16 Aṣa isin eke ni a kò fi mọ sọdọ awọn tí wọn sọ pe Kristian ni wọn. Wolii Jeremiah kilọ fun wa pe:

“Ẹ salọ kuro laaarin Babiloni, ki olukuluku eniyan ki ó sì gbà ọkàn rẹ̀ la.” (Jeremiah 51:⁠6)

Eyi ní itumọ fun wa lonii. Àní ní ọjọ Jeremiah paapaa, Babiloni jẹ́ olókìkí-búburú fun ààtò isin rẹ̀ onibajẹ ati ẹgbaagbeje awọn oriṣa rẹ̀. Ṣugbọn Babiloni ti ode-oni kárí igun mẹrẹẹrin ayé niti gbigbooro. Bawo ni eyi ṣe ṣẹlẹ?

17 Lẹhin Ikun-omi ọjọ Noa, ní Babiloni ni Nimrodu olubi, “ògbójú ọdẹ niwaju OLUWA,” ti bẹrẹsi kọ́ ilu ijọba kan, ati boya ile-iṣọ isin naa ti o ga dé awọn ọrun. Jehofa sọ awọn iwewee wọn di asan nipa dída ede araye rú tí ó sì tú wọn ká si “ibi gbogbo lori ilẹ̀-ayé.” Ṣugbọn isin eke wọn bá wọn lọ. Oun ni gbòǹgbò lati inu eyi tí ọpọ julọ ninu isin ayé ti dagbasoke.​—⁠Genesisi 10:8-⁠10; 11:1-⁠9.

18. Lati inu ayédèrú ijọba wo ni a nilati sá àsálà, nibo sì ni a ó sá sí?

18 Gẹgẹ bi a ti ṣakiyesi tẹlẹ, Constantine yọ́ irufẹ isin eke bẹẹ pọ̀ mọ́ awọn ẹkọ Kristian nigba tí ó fi ipilẹ lélẹ̀ fun isin Roman Katoliki. Eyi, ẹ̀wẹ̀, di orisun fun pupọ julọ ninu awọn ẹkọ Protẹstanti. Awọn isin ayé tí kii ṣe “Kristian” pẹlu ní awọn gbòǹgbò wọn ninu Babiloni igbaani. Lapapọ, àdàmọ̀dì isin Kristian ati awọn isin tí kii ṣe “Kristian” parapọ di ilẹ-ọba isin eke agbaye. Ó jẹ́ ayédèrú ijọba tí aposteli Johannu tọkasi gẹgẹ bi “Babiloni Nla . . . ilu-nla nì, tí ń jọba [lọna isin] lori awọn ọba ilẹ̀-ayé.” (Ìfihàn 17:​5, 18) Nitori naa ‘ki olukuluku eniyan baa le gbà ọkàn rẹ̀ là,’ a fun wa ní ìṣíníyè tí ó múnádóko lati sá jade kuro ninu ayédèrú “ijọba” ti Babiloni, bẹẹni, ki a sá wá sinu Ijọba Ọlọrun!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 95]

SATANI Ń KỌLU AWỌN IRANṢẸ IJỌBA ỌLỌRUN NIPASẸ​—⁠

● Atako inunibini ojúkojú​—⁠nipasẹ awọn ibatan, awọn ijọba, awọn onisin tí a fun ní isọfunni òdì

● Ìrélọ sinu ìwà-pálapàla ninu ẹgbẹ awujọ onígbọ̀jẹ̀gẹ̀ tòní

● Mímú igberaga ipò iṣẹ, ọlà, ẹya-iran, orilẹ-ede gbilẹ̀

● Gbigbiyanju lati sọ wọn di olufẹ faaji dipo jíjẹ́ olufẹ Ọlọrun​—⁠didi awọn tí eré ìnàjú gbàlọ́kàn

● Gbígbé ẹkọ àìgba wíwà Ọlọrun gbọ́, ẹfoluṣọn gasiwaju

● Ṣíṣojú isin Kristian tootọ lọna òdì nipasẹ ayédèrú ijọba Kristẹndọm apẹ̀hìndà

● Gbígbé awọn olukọni eke dide lati gbìn iyemeji saaarin awọn Kristian tootọ ati fifi pẹlu arekereke kó irẹwẹsi bá wọn

AWA LÈ ṢẸGUN AYÉ SATANI NIPA IGBAGBỌ WA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́