ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ws orí 2 ojú ìwé 13-20
  • “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa Dojukọ Armageddoni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa Dojukọ Armageddoni
  • Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Majẹmu fun Ijọba Tí Alaafia Rẹ̀ Kò Ní Opin
  • “Oke-Nla Megiddo” Afiṣapẹẹrẹ
  • A Ń Kó Awọn Orilẹ-Ede Jọpọ̀ Si Armageddoni
  • Amágẹ́dọ́nì Yóò Ṣínà Ayọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Amágẹ́dọ́nì Ogun Ọlọ́run Tó Máa Fòpin Sí Gbogbo Ogun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣé Orílẹ̀-Èdè Israel Ni Amágẹ́dọ́nì Ti Máa Bẹ̀rẹ̀?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
ws orí 2 ojú ìwé 13-20

Ori 2

“Ọmọ-Aládé Alaafia” naa Dojukọ Armageddoni

1, 2. (a) Awọn ọ̀rọ̀ amóríyágágá wo ni Ọlọrun misi wolii Isaiah lati sọ? (b) Nigba wo ni awọn ọ̀rọ̀ wọnyi bẹrẹsii ní imuṣẹ?

NÍ Ọ̀RÚNDÚN kẹjọ ṣaaju Sanmani Tiwa, wolii Isaiah ni a misi lati sọ fun awọn eniyan Ọlọrun pe: “Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yoo si wà ní ejika rẹ̀: a o si maa pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọran, Ọlọrun Alagbara, Baba Ayeraye, Ọmọ-Aládé Alaafia. Ijọba yoo bisii, alaafia ki yoo ní ipẹkun: lori itẹ Dafidi ati lori ijọba rẹ̀, lati maa tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isinsinyi lọ, ani titi lae.”​—⁠Isaiah 9:​6, 7.

2 Awọn ọ̀rọ̀ amóríyágágá wọnyẹn bẹrẹsii ní imuṣẹ ni apa ti ó kẹhin ọdun 2 B.C.E. Eyi jẹ́ nigba ti a bi Jesu gẹgẹ bi atọmọdọmọ Ọba Dafidi, ẹni ti o ti jọba ní ilu Jerusalemu lori awọn ẹ̀yà Israeli 12.

Majẹmu fun Ijọba Tí Alaafia Rẹ̀ Kò Ní Opin

3. (a) Majẹmu wo ni Ọlọrun bá Ọba Dafidi dá? (b) Atọmọdọmọ Ọba Dafidi wo ni Jehofa ti fi orukọ oyè naa “Ọmọ-Aládé Alaafia” dálọ́lá?

3 Nitori itara Dafidi fun ijọsin Ọlọrun Israeli, Jehofa bá a dá majẹmu Ijọba ainipẹkun ninu ìlà àtìrandíran rẹ̀. (2 Samueli 7:​1-⁠16) Majẹmu yẹn ni a fi ìbúra Ọlọrun tì lẹhin. (Orin Dafidi 132:​11, 12) Ni ibamu pẹlu majẹmu yẹn, ijọba Dafidi nilati pese ipilẹ fun Ijọba “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ti ń bọ̀ wá. “Jesu Kristi, ọmọ Dafidi,” ni ẹni naa tí Jehofa fi orukọ oyè naa “Ọmọ-Aládé Alaafia” dálọ́lá.”​—⁠Matteu 1:⁠1.

4. (a) Ta ni o di iya Jesu lori ilẹ̀-ayé? (b) Ki ni angẹli Gabrieli sọ fun un nipa eyi?

4 Iya Jesu jẹ́ obinrin kan ti a bi sinu ìlà ọlọba ti Ọba Dafidi. Wundia ni nigba ti ó loyun ọmọkunrin rẹ̀ ti a ṣeleri, ẹni ti yoo di ajogun wíwà titilọ fun itẹ Dafidi. Iloyun yii ṣẹlẹ ṣaaju ki Josefu tó mu un sọdọ bi aya rẹ̀. (Matteu 1:​18-⁠25) Angẹli Gabrieli ti sọ fun Maria wundia naa pe: “Sa si kiyesi i iwọ o loyun ninu rẹ, iwọ o si bi ọmọkunrin kan, iwọ o si pe orukọ rẹ̀ ní Jesu. Oun o pọ̀, Ọmọ Ọga-Ogo julọ ni a o si maa pe e: Oluwa Ọlọrun yoo si fi itẹ Dafidi baba rẹ̀ fun un: Yoo si jọba ni ile Jakọbu titi ayé; ijọba rẹ̀ ki yoo si ní ipẹkun.”​—⁠Luku 1:​31-⁠33.

5. Ki ni wolii Isaiah sọtẹlẹ nipa iṣakoso “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa?

5 Idi niyẹn ti wolii Isaiah fi sọtẹlẹ nipa “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa pe “gbigbooro ni agbegbe iṣakoso rẹ̀ ninu alaafia kan ti kò lopin, nitori itẹ Dafidi ati agbara ọba rẹ̀.” (Isaiah 9:​6, 7, The Jerusalem Bible) Nipa bayii, ní ibamu pẹlu majẹmu naa ti a fidi rẹ̀ mulẹ pẹlu Dafidi, Ijọba yii yoo jẹ́ ijọba ayeraye tí alaafia rẹ̀ ki yoo ní opin. “Titi ayé” ní itẹ rẹ̀ gbọdọ duro!

6. (a) Lati mu majẹmu Ijọba naa ṣẹ, ki ni Ọlọrun ṣe ní ọjọ kẹta iku Jesu? (b) Nigba wo ni Jesu bẹrẹsii jọba gẹgẹ bi “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa?

6 Nitori mimu majẹmu Ijọba yii ṣẹ, Ọlọrun Olodumare jí Jesu dide kuro ninu oku ní ọjọ kẹta iku ajẹriiku rẹ̀. Eyi jẹ́ ní ọjọ kẹrindinlogun oṣu Nisan, ti awọn Ju, ní ọdun 33 ninu Sanmani Tiwa. Gẹgẹ bi ẹlẹ́rìí ti ọran Ọmọkunrin Ọlọrun ti a ji dide ṣoju rẹ̀, aposteli Peteru sọ pe Jesu ni “a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ààyè ninu ẹmi.” (1 Peteru 3:18) Ọlọrun Ọga-Ogo gbe e ga soke si ọwọ ọtun oun funraarẹ. Nibẹ, lati opin Akoko Awọn Keferi, tabi “awọn akoko ti a yankalẹ fun awọn orilẹ-ede,” ní ibẹrẹ October ọdun 1914, oun ti ń jọba gẹgẹ bi “Ọmọ-Aládé Alaafia naa.”​—⁠Luku 21:24, NW.

7. (a) Ki ni Jesu ti dojukọ lati ibẹrẹ ijọba rẹ̀? (b) Awọn wo ni wọn ń pokiki ipo ọba Jesu fun gbogbo orilẹ-ede, eyi si jẹ́ ní imuṣẹ ki ni?

7 Lati ibẹrẹ ijọba rẹ̀ ní oke ọ̀run, oun ti dojukọ ayé akoguntini kan, gẹgẹ bi awọn ogun agbaye meji ti jẹ́rìí sii lori ariyanjiyan ti ẹni ti yoo ṣakoso ilẹ̀-ayé. Ètò-àjọ Iparapọ Awọn Orilẹ-Ede ni ó kò ó loju nisinsinyi. Nipasẹ ipokiki ihinrere Ijọba naa yika ilẹ̀-ayé nipasẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ti wọn ń waasu ní eyi ti ó ju 200 ilẹ lọ, ipo ọba rẹ̀ alakitiyan ninu awọn ọ̀run ni a ń pe afiyesi gbogbo orilẹ-ede si. Eyi jẹ́ ní imuṣẹ ohun ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa funraarẹ sọtẹlẹ, bi a ti kà á ninu Matteu 24:14: “A o si waasu ihinrere ijọba yii ní gbogbo ayé lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo si dé.”

8. Eeṣe ti a fi lè sọ pe a ti rìn jinna sinu “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan”?

8 Ariyanjiyan ijọba lé ayé lori ni a gbọdọ yanju laipẹ. Nisinsinyi, ní eyi ti o ju 70 ọdun lọ lẹhin opin “awọn akoko ti a yankalẹ fun awọn orilẹ⁠-ede” ní 1914, a ti rìn jinna sinu “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.” Iran ti 1914 ri ibẹrẹ awọn iṣẹlẹ agbaye onitumọ ti Jesu sọtẹlẹ. (Matteu 24:​3-⁠14) Iran yẹn, ni Jesu sọ pe, wọn ki yoo rekọja lọ titi gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹ. Ní bayii ó ti sunmọ opin rẹ̀ pẹkipẹki.​—⁠Matteu 24:⁠34.

9, 10. (a) Bawo ni a ṣe fi isọfunni alasọtẹlẹ ti inu iwe Ìfihàn ranṣẹ sí wa? (b) Ki ni Ìfihàn 16:​13, 14, 16 sọtẹlẹ nipa Har–mageddoni, tabi Armageddoni?

9 Fun idi yii, ki ni ohun ti ó wà niwaju ní kete bayii, ki si ni ohun ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa dojukọ? Oun fúnraarẹ̀ ni a lò lati sọ eyi tẹlẹ ninu iwe naa gan-⁠an ti o gbẹhin Bibeli, Ìfihàn, tabi Apokalipsi, ti Ọlọrun fifun un eyi ti oun si fi ranṣẹ sí aposteli Johannu arugbo nipasẹ angẹli kan. (Ìfihàn 1:​1, 2) Iyẹn ṣẹlẹ ní nǹkan bii opin ọrundun kìn-ín-ní Sanmani Tiwa. Ninu Ìfihàn 16:​13, 14, 16, Jesu mu ki aposteli Johannu ṣe itọkasi ti ó ní itumọ pataki yii si Har–mageddoni, tabi Armageddoni:

10 “Mo si ri awọn ẹmi aimọ mẹta bi ọ̀pọ̀lọ́, wọn ti ẹnu dragoni naa ati ẹnu ẹranko naa ati ẹnu wolii eke naa jade wá. Nitori ẹmi eṣu ni wọn, ti ń ṣe iṣẹ-iyanu, awọn ti ń jade lọ sọdọ awọn ọba gbogbo ilẹ̀-ayé, lati gbá wọn jọ sí ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare. O sì gbá wọn jọ sí ibi kan ti a ń pe ní Har–Mageddoni ní ede Heberu.”

“Oke-Nla Megiddo” Afiṣapẹẹrẹ

11. (a) Ki ni orukọ naa Armageddoni tumọsi, ọgangan ibi oju ilẹ eyikeyii ha ti wà ri ti o ń jẹ bẹẹ bi? (b) Eeṣe ti ilu-nla Megiddo igbaani fi ṣe pataki ninu itan? (c) Itumọ onilọpo meji wo ni orukọ naa Megiddo ní?

11 Orukọ Heberu naa Har–mageddoni, tabi Armageddoni, tumọsi “Oke-nla Megiddo.” Kò si ọgangan ibi oju ilẹ eyikeyii ní awọn akoko igbaani tabi ni ode-oni ti a ń pe ní Oke-nla Megiddo. Nipa bayii ninu iwe kan bii ti Ìfihàn ti ó kun fun awọn ede afiṣapẹẹrẹ, ede naa ní itumọ iṣapẹẹrẹ. Ki ni iyẹn nilati jẹ́? O dara, ilu-nla ori oke giga naa Megiddo, orukọ ibikan ti ó tumọsi “apejọ ọ̀wọ́ ọmọ-ogun,” ṣe pataki ninu itan. Ninu awọn itan ti ayé ati ti Bibeli orukọ naa rannileti awọn ija-ogun àjàmọ̀gá. Eeṣe? Nitori pe nigba yẹn ilu-nla naa ni o ń ṣakoso ọna ilẹ àbákọjá ṣíṣekókó fun iwewee ogun jija ti ó wà laaarin Europe, Asia, ati Africa, awọn olugbe ilẹ naa si ní anfaani lati pe awọn agboguntini nija nibẹ ki wọn si da wọn duro jẹẹ. Bayii ni Megiddo ṣe wá ní itumọ onilọpo meji​—⁠ti ìṣẹ́gunṣẹ́tẹ̀ onibanujẹ fun ìhà kan ati ijagunmolu ologo fun ìhà keji.

12, 13. (a) Bawo ni Ọlọrun ti Bibeli ṣe ní isopọ pẹlu Megiddo ati odò ti ó wà nitosi rẹ̀ ní ọjọ Baraki Onidaajọ? (b) Bawo ni orin ijagunmolu Baraki ati Debora ṣe ṣapejuwe ipa tí Ọlọrun kó ninu ijagunmolu naa?

12 Ní sáà awọn onidaajọ Israeli ni Ọlọrun ti Bibeli di eyi ti o ní isopọ pẹlu Megiddo ati odò Kiṣoni ti ó wà nitosi rẹ̀. Ní ọjọ Baraki Onidaajọ ati Debora wolii obinrin, Ọlọrun fun awọn eniyan ayanfẹ rẹ̀ ní ijagunmolu titayọlọla ní adugbo Megiddo. Baraki Onidaajọ ní kiki 10,000 ọkunrin, nigba ti ó jẹ́ pe awọn ọta naa labẹ Ọgagun Sisera ní 900 kẹ̀kẹ́ ogun àfẹṣinfà, laika awọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun ẹlẹ́sẹ̀. Jehofa dásí ija ogun naa nititori awọn eniyan ayanfẹ rẹ̀ ó si mu ki ikun-omi ayalunilojiji kan sọ awọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin àkòtagìrì wọnni ti awọn ọta di alaile-kuro-lojukan. Ninu orin ijagunmolu ti Baraki ati Debora kọ si Ọlọrun lẹhin ìṣẹ́gunṣẹ́tẹ̀ oniṣẹ-iyanu lori ẹgbẹ ọmọ-ogun Sisera, wọn pe afiyesi si ipa ti Ọlọrun kó ninu bibi awọn ọta yii ṣubu pe:

13 “Awọn Ọba wá, wọn jà; nigba naa ni awọn ọba Kenaani jà ní Taanaki leti odo Megiddo: wọn kò sì gba èrè owo. Wọn jà lati ọ̀run wá, awọn irawọ ní ipa wọn bá Sisera jà. Odo Kiṣoni gba wọn lọ, odo igbaani, odo Kiṣoni.”​—⁠Onidajọ 5:​12, 19-⁠21.

14. Awọn ọ̀rọ̀ ipari wo ninu orin ijagunmolu onimiisi yẹn laiṣe aniani ni o jẹ́ adura kan ní isopọ pẹlu ogun Armageddoni ti ń bọ̀wá?

14 Laisi iyemeji, awọn ọ̀rọ̀ onimiisi naa eyi tí Baraki ati Debora fi pari orin wọn lẹhin ijagunmolu igbaani yẹn ní Megiddo ṣiṣẹ gẹgẹ bi adura kan ní isopọ pẹlu ogun Armageddoni ti ń bọ̀wá. Wọn kọrin pe: “Bẹẹni ki o jẹ́ ki gbogbo awọn ọta rẹ ki ó ṣegbe OLUWA: ṣugbọn jẹ́ ki awọn ẹni ti wọn fẹ ọ ki o dabi oorun nigba ti o ba yọ ninu agbara rẹ̀.”​—⁠Onidajọ 5:⁠31.a

A Ń Kó Awọn Orilẹ-Ede Jọpọ̀ Si Armageddoni

15. (a) Iru ibi wo, nigba naa, ní Armageddoni jẹ́? (b) Ki ni ọkan lara awọn orisun ìgbékèéyíde alaimọ ti ń mura awọn orilẹ-ede silẹ fun ogun ní Armageddoni?

15 Nitori naa Megiddo jẹ́ ibi kan nibi tí a ti ja awọn ija ogun àjàmọ̀gá. Nigba naa, lọna ti o ba ọgbọn-ironu mu, Armageddoni yoo jẹ́ pápá ìtẹ́gun eyi ti gbogbo awọn orilẹ-ede agbaye lonii yoo yan lọ labẹ agbara arunilọkansoke ti a ṣapejuwe ninu Ìfihàn 16:​13, 14 (NW). “Awọn ọ̀rọ̀ tí awọn ẹmi-eṣu misi” ti ń mura awọn orilẹ-ede silẹ fun ogun ni awọn ìgbékèéyíde ti ń dun jade bi igbe ọ̀pọ̀lọ́ lonii, ti wọn jẹ́ alaimọ bi ọ̀pọ̀lọ́ alaimọ inu Bibeli. Ọkan lara awọn orisun iru ìgbékèéyíde alaimọ bẹẹ ni “dragoni pupa nla” naa. Ìfihàn 12:​1-⁠9 fi “dragoni” naa han gẹgẹ bi Satani Eṣu.

16. Ninu Ìfihàn 16:13, ki ni “ẹranko ẹhanna naa” ṣapẹẹrẹ?

16 Orisun miiran fun ìgbékèéyíde alaimọ naa ni “ẹranko ẹhanna naa.” Ni Ìfihàn 16:13 (NW) “ẹranko ẹhanna” iṣapẹẹrẹ yii ni a sopọ̀ mọ́ “dragoni” elèṣù naa. Gẹgẹ bi Ìfihàn 20:10 (NW) ti sọ, “ẹranko ẹhanna” yii ni a o parun titi lae nitori ifọwọsowọpọ rẹ̀ pẹlu “dragoni” iṣapẹẹrẹ naa. “Ẹranko ẹhanna naa” ṣapẹẹrẹ gbogbo eto-igbekalẹ iṣelu ti ayé yii lodindi eyi ti “dragoni” naa jẹ́ ọlọrun fun. (2 Korinti 4:⁠4) O kó gbogbo oniruuru awọn ijọba oṣelu ayé yii papọ.​—⁠Fiwe Danieli 7:17; 8:20, 22.

17. Ki ni iyọrisi ìgbékèéyíde bi ti ọ̀pọ̀lọ́ tí ń ti ẹnu “ẹranko ẹhanna naa” jade wá?

17 Iru eto-igbekalẹ ayé ti iṣakoso oṣelu bẹẹ ní ìgbékèéyíde didayatọ tirẹ̀. Ìgbékèéyíde ti ń dun jade bi igbe ọ̀pọ̀lọ́ yii si jẹ́ ọ̀rọ̀ onimiisi ti ń ṣiṣẹ papọ pẹlu ọ̀rọ̀ onimiisi ti “dragoni” naa lati kó “awọn ọba,” tabi awọn alakooso oṣelu ayé, jọpọ si “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” tí a o jà ní Armageddoni.

18. (a) Ki ni orukọ naa Har–mageddoni tọkasi? (b) Ki ni oke-nla kan yoo ṣapẹẹrẹ?

18 Har–mageddoni wa tipa bayii tumọsi ipo ayé kan ti ó mú ogun àjàmọ̀gá kan lọwọ. O tọkasi ipo ipẹkun yẹn ninu eyi ti awọn àlámọ̀rí ayé dé nibi ti awọn alakooso oṣelu ti fi isopọṣọkan tako ifẹ-inu Ọlọrun, ki Ọlọrun baa lè huwapada pẹlu fifi ipá gbejako wọn loju ní ibamu pẹlu ete rẹ̀. Nitori naa abayọri ikoniloju yii ni yoo pinnu ohun ti ẹhin-ọla yoo jẹ́. Ní Megiddo fúnraarẹ̀, ní ọgangan ibi oju-ilẹ naa, ko si oke-nla kankan. Ṣugbọn oke-nla kan yoo ṣapẹẹrẹ ibi apejọ ti o lókìkí kan ti yoo rọrun fun gbogbo awọn agbo ologun ti wọn pejọpọ sibẹ lati dá mọ̀ lati ọna jijin.

19, 20. Ọgbọn iwewee wo ni Ọgagun awọn agbo ọmọogun ọ̀run ti Jehofa yoo lò ní Armageddoni, pẹlu iyọrisi wo si ni?

19 Jesu Kristi, Ọgagun agbo awọn ajagun Jehofa, fun awọn ọdun diẹ ti bojuwo ikojọpọ awọn alakoso ayé ati agbo awọn ajagun wọn sí Armageddoni. Ṣugbọn oun kò tii gbiyanju lati dá ọba eyikeyii kankan ni pato ati awọn agbo ologun rẹ̀ yasọtọ lati lù wọn bolẹ ní awọn nikanṣoṣo ki ó si tipa bẹẹ yanju awọn agbo ọmọ-ogun ọta naa diẹ⁠-diẹ. Kaka bẹẹ, oun ń yọnda akoko pipọto fun wọn lati wọjọpọ lati mu awọn agbo ọmọ-ogun wọn ṣọkan de iwọn gigajulọ ti agbara ologun wọn lè dagbasoke dé. Ete onigboya rẹ̀ ni lati bẹrẹ ija pẹlu gbogbo wọn lẹẹkan naa!

20 Oun yoo tipa bayii jere ijagunmolu ti ó tubọ lokiki lọ-réré lori wọn, si ogo Olori Olupaṣẹ tirẹ̀ fúnraarẹ̀, Jehofa Ọlọrun, ati si fifi ijotiitọ ti oun funraarẹ múlẹ̀ gẹgẹ bi, “Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa” lai ṣee jáníkoro.​—⁠Ìfihàn 19:⁠16.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Awọn itọka miiran si Megiddo ni a ri ninu 2 Ọba 9:27; 23:29, 30; 2 Kronika 35:22; Sekariah 12:⁠11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́