ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ws orí 10 ojú ìwé 82-89
  • Ohun Ti Ọlọrun Búra Lati Ṣe fun Araye—Kù Sí Dẹ̀dẹ̀ Nisinsinyi!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Ti Ọlọrun Búra Lati Ṣe fun Araye—Kù Sí Dẹ̀dẹ̀ Nisinsinyi!
  • Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọrun Gbé Ìbúra kan Wọnú Rẹ̀
  • Titi De Àyè Wo?
  • Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Kí o Sì Jàǹfààní Nínú Àwọn Ìlérí Tó Fi Ìbúra Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Majẹmu Ọlọrun Pẹlu “Ọ̀rẹ́” Rẹ̀ Ti Ṣanfaani fun Araadọta Ọkẹ Nisinsinyi
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • “Ẹ Fìdí Ọkàn-àyà Yín Múlẹ̀ Gbọn-in”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ta Ni Ábúráhámù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
ws orí 10 ojú ìwé 82-89

Ori 10

Ohun Ti Ọlọrun Búra Lati Ṣe fun Araye​—⁠Kù Sí Dẹ̀dẹ̀ Nisinsinyi!

1, 2. (a) Ninu ero itumọ wo ni Ọlọrun fi búra, eesitiṣe? (b) Ki ni ohun ti Ọlọrun sọ ninu Isaiah 45:23? (c) Awọn alaye wolii Isaiah wo ni awa gbọdọ lè fohunṣọkan pẹlu rẹ̀?

ỌLỌRUN a maa búra bi? Bẹẹni, Ọlọrun ń búra, ṣugbọn oun kii lo ọ̀rọ̀ àlùfààṣá, ni fifa ibinu ru ki ó si padanu ikora-ẹni-nijanu. Ìbúra rẹ̀ saba maa ń jẹ titori mimu awọn ète rẹ̀ ti ó ti kede lagbara sii. Eyi ń fun awọn wọnni ti ọran naa yoo kan ní afikun idaniloju. Nitori naa, gbogbo iran eniyan ni yoo ṣe rere lati fiyesi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ninu Isaiah 45:23: “Mo ti fi ara mi búra, ọ̀rọ̀ naa ti ti ẹnu mi ododo jade, ki yoo si pada, pe, Gbogbo eékún yoo kunlẹ fun mi, gbogbo ahọ́n yoo búra.”

2 Lonii, ní eyi ti ó ju 2,700 ọdun lọ lẹhin asọtẹlẹ yẹn, njẹ ó dá wa loju pe otitọ ni ọ̀rọ̀ wolii yẹn ní Isaiah 45:24 pe: “Loootọ, a o wi pe, ninu Oluwa ni emi ní ododo ati agbara: sọdọ rẹ̀ ni gbogbo eniyan yoo wá; oju yoo sì ti gbogbo awọn ti ó binu si i”? Bi ó bá rí bẹẹ, nigba naa a tun lè fohunṣọkan pẹlu awọn ọ̀rọ̀ Isaiah ti ó tẹ̀lé e ní ẹsẹ 25 pe: “Ninu Oluwa ni a o dá gbogbo iru-ọmọ Israeli lare, wọn yoo sì ṣogo.”

3, 4. (a) Eeṣe ti Isaiah 45:25 kò fi yẹ ki ó sun wa lati ronu nipa Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli? (b) Ikuna kankan ha ti wà niti imuṣẹ Isaiah 45:​23-⁠25 bi, eesitiṣe ti ó fi dahun bẹẹ?

3 Nigba ti a ba ń ka Isaiah 45:25, ṣe ki awa maa ronu nipa Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli ni bi? Bẹẹkọ! Awọn ọmọ Israeli wọnni ko gboriyin iṣẹgun wọn fun Ọlọrun Iwe Mímọ́ Lede Heberu. Nititori ọ̀wọ̀ ti wọn gbé gbòdì wọn tilẹ ń kọ̀ lati pe orukọ rẹ̀.

4 Nipa eyi, awa ha ń jiyan pe Isaiah 45:​23-⁠25 ti kuna lati ní imuṣẹ titi di ọdun yii bi? Bẹẹkọ! Kò si ikuna kankan rara niti imuṣẹ asọtẹlẹ naa ní akoko ti Jehofa ti yàn tẹlẹ. Ní tirẹ̀, o doódì pe ki awọn asọtẹlẹ rẹ̀ kuna lati ṣẹ! Kii ṣe kiki pe ọ̀rọ̀ rẹ̀ fúnraarẹ̀ ṣee gbarale ti ó si ṣee gbẹkẹle nikan ni ṣugbọn ó tun wà ju bẹẹ lọ nigba ti Jehofa búra sii, ti ó fi ìbúra rẹ̀ kun un, lati mu awọn ọran daju.

Ọlọrun Gbé Ìbúra kan Wọnú Rẹ̀

5. Bawo ni Heberu 6:​13-⁠18 ṣe ṣalaye bi Ọlọrun ṣe gbé ìbúra kan wọnú ileri rẹ̀ fun Abrahamu?

5 Niti eyi, a kà ninu Heberu 6:​13-⁠18 pe: “Nitori nigba ti Ọlọrun ṣe ileri fun Abrahamu, bi kò ti ri ẹni ti ó pọ ju oun lati fi búra, o fi araarẹ̀ búra, wi pe, Ni tootọ ní bibukun emi o bukun fun ọ, ati ní bibisii emi o mu ọ bisii. Bẹẹ naa si ni, lẹhin igba ti ó fi suuru duro, ó ri ileri naa gbà. Nitori eniyan a maa fi ẹni ti ó pọ ju wọn búra: ìbúra naa a si fi opin si gbogbo ijiyan wọn fun ifẹsẹmulẹ ọ̀rọ̀. Ninu eyi ti bi Ọlọrun ti ń fẹ gidigidi lati fi aileyipada imọ rẹ̀ hàn fun awọn ajogun ileri, o [gbé ìbúra kan wọ inu rẹ̀, NW]. Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyi ti kò ṣeeṣe fun Ọlọrun lati ṣeke, ki awa ti ó ti sá sabẹ aabo lè ní ìṣírí ti ó daju lati di ireti ti a gbekalẹ ní iwaju wa mú.”

6. (a) Isunniṣe wo ni ó wà nibẹ fun Ọlọrun lati fi araarẹ̀ búra niti ileri rẹ̀ fun Abrahamu? (b) Bawo ni Jehofa ṣe lè lo “ọ̀rẹ́” rẹ̀?

6 Ní gbogbogboo, isunniṣe alagbara kan wà fun bibura, fun ṣiṣe ìbúra kan. Eyiini si jẹ́ otitọ lọna ara ọtọ bi ìbúra naa ba wá lati ọdọ Ọlọrun funraarẹ, pẹlu ifinnufindọ ṣe. Iru isunniṣe bẹẹ ni a pese rẹ̀ nihin-⁠in nibi ti a ti rohin pe Jehofa búra, bẹẹni, ó fi araarẹ̀ búra. Ileri ti a fi ìbúra ti lẹhin naa ti Jehofa ṣe fun Abrahamu, “ọ̀rẹ́” rẹ̀, kan gbogbo wa lonii. Jehofa mọriri rẹ̀ nigba ti Abrahamu gbe igbesẹ lori ikesini atọrunwa naa lati fi ilu ibilẹ rẹ̀ silẹ lati lọ si ilẹ naa ti Jehofa yoo fun awọn atọmọdọmọ Abrahamu ní ìní. Jehofa lè wa sọ orukọ “ọ̀rẹ́” rẹ̀ yii di nla láìséwu o si lè lò ó fun bibukun awọn miiran. Jehofa lè tipa bẹẹ sọ fun un pe: “Emi o bukun fun awọn ti ń sure fun ọ, ẹni ti ń fi ọ ré ni emi o si fi ré; ninu rẹ ni a o ti bukun fun gbogbo idile ayé.”​—⁠Genesisi 12:⁠3; Isaiah 41:⁠8.

7. (a) Iṣẹ iyanu wo ni Ọlọrun fi ṣojurere si Abrahamu nigba ti aya rẹ̀ wà ní ẹni 90 ọdun? (b) Bawo ni Abrahamu ṣe ṣaṣefihan igbagbọ ati igbọran rẹ̀ lọna alailẹgbẹ kan?

7 Nigba ti Sara aya Abrahamu di ẹni 90 ọdun, ti ó ti fi pupọ rekọja ọjọ ori ẹni ti ó lè bimọ, Ọlọrun lọna iyanu ṣojurere si i ti ó fi bi ọmọkunrin wọn olufẹ, Isaaki, fun Abrahamu, ní mimu ileri agbayanu Rẹ̀ fun Abrahamu tẹsiwaju. Abrahamu fihan pe oun muratan lati fi ọmọkunrin rẹ̀ iyebiye paapaa ṣe irubọ afeniyan-ṣe kan ní igbọran si aṣẹ Ọlọrun rẹ̀, Jehofa. Aṣefihan igbagbọ ati igbọran alailẹgbẹ yii wu Jehofa lori tobẹẹ ti oun fi sọ fun “ọ̀rẹ́” rẹ̀ Abrahamu pe:

8, 9. (a) Bawo ni Jehofa ṣe huwapada si aṣefihan igbagbọ ati igbọran Abrahamu yii? (b) Ta ni Ọlọrun mu araarẹ̀ wá sabẹ ijihin fun?

8 “Emi tikaraami ni mo fi búra, ni OLUWA wi, nitori bi iwọ ti ṣe nǹkan yii, ti iwọ kò si dù mi ní ọmọ rẹ, ọmọ rẹ naa kanṣoṣo: Pe ní bibukun emi o bukun fun ọ, ati ní bibisii emi o mu iru-ọmọ rẹ bisii bi irawọ oju ọ̀run, ati bi iyanrin eti okun; iru-ọmọ rẹ ni yoo si ni ẹnubode awọn ọta wọn. Ati ninu iru-ọmọ rẹ ni a o bukun fun gbogbo orilẹ-ede ayé: nitori ti iwọ ti gba ohùn mi gbọ́.”​—⁠Genesisi 22:​15-⁠18.

9 Ihin ni ibi akọkọ ninu Bibeli ti a ti sọrọ nipa Jehofa pe o búra. Nitori pe kò si ẹlomiran ti ó ga ju u lọ lati fi búra, ó fi araarẹ̀ búra, ni sisọ ọ di dandangbọ̀n fun araarẹ̀. Ní ọna yii oun kò mu araarẹ̀ wa sabẹ ijihin fun ẹnikẹni miiran bikoṣe araarẹ̀. Ogo rẹ̀ ni yoo jẹ́ pe oun mu awọn ète rẹ̀ ti oun ti kede ṣẹ.

Titi De Àyè Wo?

10. Bawo ni ó ti ṣe pẹ́ tó tí Ọlọrun ti dá majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, ibeere wo ni ó wa dide nigba naa?

10 Abrahamu wọ ilẹ ileri Kenaani ní eyi ti ó fẹrẹẹ to 4,000 ọdun sẹhin. Nitori naa titi di isinsinyi, de àyè wo ni a ti mu majẹmu naa ti a dá ní 1943 B.C.E. ṣẹ?

11. (a) Ki ni jijẹ ti Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli jẹ́ mẹmba UN fihan, pẹlu iyọrisi wo? (b) Awọn atọmọdọmọ abinibi ti Abrahamu ha kun oju ìwọ̀n awọn ohun ti a beere fun lati jẹ “iru-ọmọ” ti a ṣeleri naa bi?

11 Lonii, Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli wà ní Aarin Gbungbun Ila-Oorun Ayé. Nitori ire ti araarẹ̀, ó jẹ́ mẹmba Iparapọ Awọn Orilẹ-Ede. UN duro fun ikọsilẹ Ijọba Jehofa Ọlọrun nipasẹ “iru-ọmọ” Abrahamu naa ti a ti ṣeleri ti a ó si tipa bẹẹ pa a run ninu “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare,” Armageddoni. Gbogbo mẹmba UN, titikan Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli, ni a o parẹ kuro. O banininujẹ pe, awọn atọmọdọmọ abinibi nipa ti ara, ti Abrahamu, kò kunju awọn ohun ti a beere fun lati jẹ́ “iru-ọmọ” Messia naa ti a ṣeleri nipasẹ ẹni ti Jehofa Ọlọrun yoo bukun iran eniyan.​—⁠Ìfihàn 16:​14-⁠16.

12, 13. (a) Laidabi Dafidi babanla rẹ̀, eeṣe ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ki yoo fi danikan ṣakoso? (b) Awọn Kristian ti a fi ẹmi bi ha nilati duro titi di igba ti a fi idi Ijọba naa kalẹ ní 1914 ki wọn tó lè gba ibukun ti a ṣeleri naa bi, bawo ni a ṣe mọ̀?

12 Ní ṣiṣe kedere tó fun gbogbo eniyan lati ṣakiyesi, Messia naa ti a ṣeleri kò ṣakoso ní Jerusalemu ti ori ilẹ̀-ayé ní Aarin Gbungbun Ila-Oorun Ayé, lati lè mu majẹmu Abrahamu ṣẹ. Laidabi babanla rẹ̀ igbaani Dafidi, Messia ati “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ki yoo danikan ṣakoso. O ṣeleri lati mú awọn aposteli rẹ̀ 12 oluṣotitọ ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ miiran ti a fi ẹmi bi, ti iye wọn yoo jẹ́ 144,000, papọ pẹlu araarẹ̀ ninu iṣakoso rẹ̀. (Ìfihàn 7:1-⁠8; 14:1-⁠4) Àṣẹ́kù iru awọn ọmọ-ẹhin bẹẹ ṣì wà lori ilẹ̀-ayé. Ki ni ohun ti a ti ṣe fun wọn lati mu ki itẹsiwaju bá imuṣẹ majẹmu Abrahamu naa eyi ti Ọlọrun ti búra? Ẹnikan ti ó jẹ́ òléwájú ní fifojusọna lati darapọ ninu Ijọba naa, aposteli Paulu, kọwe ninu Galatia 3:8 pe: “Bi iwe mímọ́ si ti ri i tẹ́lẹ̀ pe, Ọlọrun yoo dá awọn keferi lare nipa igbagbọ, o ti waasu ihinrere ṣaaju fun Abrahamu, o ń wi pe, Ninu rẹ ni a o bukun fun gbogbo orilẹ-ede.”

13 Awọn Kristian ti a ṣàyàn laaarin awọn orilẹ-ede kò nilati duro titi di igba ti a ba gbé Ijọba naa kalẹ ní ọ̀run ní 1914 ki wọn tó lè gba ibukun ti a ṣeleri naa, nitori aposteli Paulu ń baa lọ lati wi pe: “Gẹgẹ bẹẹ ni awọn tii ṣe ti igbagbọ jẹ́ ẹni alabukun fun pẹlu Abrahamu olododo.” (Galatia 3:⁠9) Paulu jẹ́ Kristian kan ti a bukun fun, bẹẹ sì ni gbogbo awọn Kristian miiran ti a fi ẹmi bi ní akoko rẹ̀.a Bakan naa lonii, àṣẹ́kù naa, ti ó jẹ apapọ awọn Kristian ti a fi ẹmi bi ti wọn dìrọ̀mọ́ igbagbọ ninu Messia bi olori “iru-ọmọ” Abrahamu fun bibukun gbogbo iran eniyan, ń ní iriri ibukun ti a ti ṣeleri naa.

14. (a) Bawo ni a ṣe bukun fun awọn Kristian ti a fi ẹmi bi lọna akanṣe ní ibamu pẹlu majẹmu Abrahamu? (b) Ní ọna wo ni eyi gbà dá Jehofa lare?

14 Nipa yiya araawọn si mímọ́ fun Jehofa ati fifi apẹẹrẹ iyasimimọ naa hàn nipa iribọmi ati lẹhin naa ti a fi ẹmi Ọlọrun bi wọn sinu ipo ohun-ìní tẹmi kan, awọn Kristian wọnyi ti wá di awọn ọmọkunrin tẹmi ti Abrahamu Gigaju naa, Jehofa Ọlọrun. Wọn tun ti di ajumọjogun pẹlu Jesu Kristi, Isaaki Gigaju naa. (Romu 8:17) Niti tootọ ni a bukun wọn lọna akanṣe ní ibamu pẹlu majẹmu Abrahamu. Jehofa ti ń mu ohun ti oun búra lati ṣe ṣẹ, ti ó tipa bayii ń da araarẹ̀ lare bi asòótọ́, Ẹni naa ti ó ṣeeṣe fun lẹkun-unrẹrẹ lati mu ohun ti ó ti fi orukọ rẹ̀ búra lati ṣe ṣẹ.

15. Ki ni ohun ti aposteli Paulu sọ pe mẹmba kọọkan ti àṣẹ́kù awọn Kristian ti a fi ẹmi bi jẹ?

15 Mẹmba kọọkan ti àṣẹ́kù awọn Kristian ti a fi ẹmi bi naa jẹ́ Ju kan ninu oju iwoye tẹmi. Gẹgẹ bi aposteli Paulu ti wi: “Kii ṣe eyi ti ó fi ara hàn ni Ju, bẹẹ ni kii ṣe eyi ti ó fi ara hàn ní ara ni ikọla: Ṣugbọn Ju ti inu ni Ju, ati ikọla ti ọkan, ninu ẹmi ni, kii ṣe ti ode ara.”​—⁠Romu 2:​28, 29.

16. Awọn Ju nipa tẹmi parapọ di ẹgbẹ wo ti a sọ tẹ́lẹ̀ ninu Sekariah 8:⁠23?

16 Ní “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi,” awọn Kristian ti a fi ẹmi bi wọnni, ti wọn jẹ́ Ju ti inú pẹlu ikọla ti ọkan-aya, ni wọn parapọ di ẹgbẹ Ju naa ti a sọ tẹ́lẹ̀ ninu Sekariah 8:23, nibi ti a ti kọ ọ pe: “Bayii ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi pe, ní ọjọ wọnni yoo ṣẹ, ni ọkunrin mẹwaa lati inu gbogbo ede ati orilẹ-ede yoo di i mu, àní yoo di eti aṣọ ẹni tii ṣe Ju mu, wi pe, A o ba [ẹyin eniyan wọnyi, NW] lọ, nitori awa ti gbọ́ pe, Ọlọrun wà pẹlu [ẹyin eniyan wọnyi, NW].”

17. (a) Ta ni “ọkunrin mẹwaa” ti ń fẹ jọsin Jehofa pẹlu àṣẹ́kù awọn Ju nipa tẹmi lọjọ oni duro fun? (b) Ní didarapọ mọ́ awọn Ju nipa tẹmi ninu ijọsin Jehofa, ki ni awọn mẹmba “agutan miiran” ń gbadun rẹ̀ nisinsinyi?

17 Awọn “eniyan” tí awọn “ọkunrin mẹwaa” yẹn fẹ ba lọ jọsin Jehofa Ọlọrun ni àṣẹ́kù awọn ti wọn jẹ Ju nipa tẹmi lọjọ oni, ẹgbẹ ti o parapọ jẹ́ “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” inu Matteu 24:​45-⁠47 (NW). Niwọn igba ti iye naa mẹwaa duro fun ijẹpipe ninu nǹkan ti ilẹ̀-ayé, “ọkunrin mẹwaa lati inu gbogbo ede ati orilẹ-ede” yoo duro fun gbogbo awọn agutan iṣapẹẹrẹ ti a ti sọ tẹ́lẹ̀ ninu Matteu 25:​32-⁠46. Awọn wọnyi ni ẹgbẹ “awọn agutan miiran” eyi ti Jesu sọ wi pe oun yoo mu wa sinu ibakẹgbẹpọ pẹlu àṣẹ́kù ẹni bi agutan lati parapọ di “agbo” kan labẹ itọju “oluṣọ agutan” kan naa fúnraarẹ̀. (Johannu 10:16) Ní ọna yii wọn bẹrẹsii gbadun ìtọ́wò awọn ibukun majẹmu Abrahamu nipasẹ “iru-ọmọ” Abrahamu Gigaju, Jehofa Ọlọrun. Dajudaju, nigba naa, ohun ti Ọlọrun búra lati ṣe fun iran eniyan sunmọle!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ni titọkasi orukọ naa “Awọn Kristian,” alaye isalẹ iwe Reference Bible ní Iṣe 11:26 sọ wi pe: “Heberu, Meshi·chi·yim΄, ‘Messianists.’”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 89]

Bibeli sọ tẹ́lẹ̀ pe awọn eniyan lati inu orilẹ-ede gbogbo yoo wọnú ibakẹgbẹpọ pẹlu Israeli tẹmi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́