ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ws orí 22 ojú ìwé 180-189
  • Ọlọrun “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa Di “Ohun Gbogbo fun Olukuluku Eniyan”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọrun “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa Di “Ohun Gbogbo fun Olukuluku Eniyan”
  • Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Idanwo Ikẹhin Lori Gbogbo Iran Eniyan
  • Awọn Serafu, Kerubu, Angẹli
  • Ète Jèhófà Ń Ṣàṣeyọrí Ológo
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
    “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
  • Ayọ̀ Tí Kò Lópin—Ṣé Lọ́run Ni Àbí Lórí Ilẹ̀ Ayé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Jèhófà Ọlọ́run Wà Nínú Tẹ́ńpìlì Mímọ́ Rẹ̀
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
ws orí 22 ojú ìwé 180-189

Ori 22

Ọlọrun “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa Di “Ohun Gbogbo fun Olukuluku Eniyan”

1. Ninu ki ni Jesu Kristi fi apẹẹrẹ lélẹ̀ fun gbogbo awọn ẹ̀dá yooku ní ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé?

KETE lẹhin ajinde rẹ̀, “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa sọ fun ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Emi ń goke lọ sọdọ Baba mi, ati Baba yin; ati sọdọ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun yin.” (Johannu 20:17) Pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wọnyẹn oun gbà pe Baba rẹ̀ ọ̀run tun jẹ́ Ọlọrun rẹ̀, Ẹni kanṣoṣo naa ti oun ń jọsin. Ninu iru ijọsin bẹẹ oun fi apẹẹrẹ lélẹ̀ fun gbogbo awọn ẹ̀dá yooku jakejado gbogbo ọ̀run ati ilẹ̀-ayé.

2, 3. (a) Bawo ni 1 Korinti 15:​24-26, 28 ṣe ṣapejuwe ìṣe akanṣe Jesu ní jijọwọ araarẹ̀ silẹ fun Baba rẹ̀? (b) Ki ni yoo jẹ́ abajade titobilọla rẹ̀?

2 Ẹ wo iru apẹẹrẹ titobilọla ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” yoo jẹ́ fun gbogbo iran eniyan ti a ti sọ di pipe nigba ti ó ba fi pẹlu iṣotitọ jọ̀wọ́ araarẹ̀ silẹ ní ọna akanṣe kan fun Ẹni naa ti ó jẹ́ Ọba-alaṣẹ yiyẹ fun gbogbo agbaye! Eyi ni a o ṣipaya lọna alailẹgbẹ ní opin Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun rẹ̀ lori iran eniyan, nigba ti oun yoo ti mu alaafia, àìléwu, ati iṣọkan padabọsipo fun gbogbo ilẹ̀-ayé. Ninu asọtẹlẹ alaiṣina naa, a mu eyi dá wa loju:

3 “Lẹhin eyiini, opin naa, nigba ti ó ba fa ijọba naa lé Ọlọrun ati Baba rẹ̀ lọwọ, nigba ti ó ba ti sọ gbogbo ijọba ati gbogbo aṣẹ ati agbara di asan. Nitori oun nilati ṣakoso bi ọba titi Ọlọrun yoo fi fi gbogbo awọn ọta sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Bi ọta ikẹhin, a o sọ iku di asan. Ṣugbọn nigba ti ó ba ti tẹ ohun gbogbo loriba fun un tan, nigba naa Ọmọ tikaraarẹ yoo tẹ ori araarẹ̀ ba fun Ẹni naa ti ó tẹ ohun gbogbo loriba fun un, ki Ọlọrun baa lè jẹ́ ohun gbogbo fun olukuluku eniyan.” (1 Korinti 15:​24-26, 28, NW) Tabi bi The Amplified Bible ṣe tumọ apa ti ó kẹhin ẹsẹ 28: “Ki o baa lè jẹ́ pe Ọlọrun di ohun gbogbo ninu ohun gbogbo​—⁠iyẹn ni pe, jẹ́ ohun gbogbo fun olukukulu eniyan, ga julọ, ipa isunniṣe ti inu ati agbara ti ó ń ṣakoso igbesi-aye.”

4. (a) Bawo ni awọn olugbe ilẹ̀-ayé yoo ṣe huwapada si apẹẹrẹ àgbàfiṣe Baba wọn? (b) Apa titun miiran wo ninu ọran itẹriba ni yoo wà nigba naa?

4 Nigba ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ba fa Ijọba lé Ọlọrun rẹ̀ lọwọ ní opin Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun naa, awọn olugbe ori ilẹ̀-ayé ni a o jẹ́ ki wọn mọ̀ nipa igbesẹ àgbàfiṣe Baba wọn yii. Pẹlu rẹ̀ niwaju wọn bi Apẹẹrẹ Ọlọba wọn, awọn bakan naa yoo jọ̀wọ́ araawọn silẹ fun Ọlọrun Ọga Ogo naa ní ọna titun kan. Nisinsinyi fun igba akọkọ wọn yoo fun Jehofa ní itẹriba onifẹẹ ní taarata, bẹẹ ni, ijọsin, ní gbogbo otitọ-inu ati ododo, laiko beere fun iṣẹ-isin alufaa Jesu mọ́, ani kii tilẹ ṣe nigba ti wọn bá ń gbadura paapaa.

5. Ki ni yoo jẹ́ iṣarasihuwa 144,000 awọn ajumọ jẹ́ ọba pẹlu Jesu Kristi?

5 Ní ọna yii, Ọlọrun Ọga Ogo naa lẹẹkan sii tun wa di Ọba gbogbo agbaye laisi aṣoju ipo ọba fun un ìbáà ṣe ní ọ̀run tabi lori ilẹ̀-ayé. O tumọsi pe awọn 144,000 alájùmọ̀jọba tí Jesu Kristi ti rà pada lati inu ayé yoo tun fi eekun wọn kunlẹ niwaju Ọba Alakoso giga julọ naa ti wọn yoo si, ni ero-itumọ siwaju sii yii, jẹwọ rẹ̀ pe o jẹ́ Ọba-Alaṣẹ Agbaye.

Idanwo Ikẹhin Lori Gbogbo Iran Eniyan

6. (a) Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn eniyan alaigbọran nigba Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti Jesu? (b) Ipo wo ni awọn wọnni ti Jesu yoo fà lé Baba rẹ̀ ọ̀run lọwọ yoo wà?

6 Ní mímọ Jehofa daju bi Onidaajọ Giga Julọ, Jesu Kristi ní ifẹ pe ki gbogbo itẹwọgba atọrunwa yiyẹ di eyi ti a fihan sori iṣẹ ti Jesu ṣe aṣepari rẹ̀ laaarin Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun rẹ̀. Nigba iṣakoso yẹn, gbogbo awọn eniyan wọnni ti wọn kọ̀ lati mu araawọn bá awọn ohun abeere fun ti ilana ododo mu ti wọn si fi aigbọran hàn si Ọba naa ni a o ti parun. Nipa bayii, awọn wọnni ti Jesu Kristi yoo fa lé Jehofa Ọlọrun, Onidaajọ ikẹhin, lọwọ yoo jẹ́ awọn onigbọran ti wọn ti dé ijẹpipe eniyan.

7. (a) Ki ni a o fi sabẹ idanwo oniwadii lẹhin igba ti Jesu bá ti dá Ijọba naa pada? (b) Bawo ni a o ṣe fi iran eniyan ti a ti sọ di pipe sabẹ idanwo yẹn?

7 Ní ọgangan yẹn ni ó ti wá tó akoko fun fifi bi ifọkansin eniyan ti wà pẹ́ titi ninu ọran ti ỌbaAlaṣẹ Agbaye naa, Jehofa Ọlọrun, sabẹ idanwo. Gẹgẹ bi o ti ri ninu ọran Jobu, ibeere naa ni pe: Wọn ha fẹran ti wọn si ń jọsin Ọlọrun kiki nitori gbogbo ohun rere ti ó ti ṣe fun wọn, tabi wọn ha fẹran rẹ̀ nitori ohun ti oun jẹ́ ninu araarẹ̀ gan-⁠an​—⁠ẹni ti o fi pẹlu Ẹ̀tọ́ jẹ Ọba-Alaṣẹ agbaye? (Jobu 1:​8-⁠11) Ṣugbọn bawo ni a o ṣe dan iran eniyan ti a ti sọ di pipe wò niti iduroṣinṣin ọkan-aya wọn? Bibeli dahun: Satani Eṣu ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ ni a o tusilẹ “fun ìgbà diẹ” lati inu ọgbun ainisalẹ nibi ti a ti sé wọn mọ́ fun ẹgbẹrun ọdun. (Ìfihàn 20:3) Nipa gbigba Eṣu laaye lati dan iran eniyan ti a ti mupadabọsipo wò, awọn mẹmba iran eniyan ti a ti sọ di pipe naa ni yoo lè fi iwatitọ wọn si Ọlọrun hàn lẹnikọọkan ni ero-itumọ pipe kan.​—⁠Fiwe Jobu 1:⁠12.

8. (a) Lẹhin ti a ba ti tu wọn silẹ kuro ninu ọgbun ainisalẹ, ki ni Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ yoo gbidanwo lati ṣe? (b) Awọn wọnni ti wọn jẹ́ ki Eṣu ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ ṣi wọn lọna yoo maa tọ iru ọna igba gbégbèésẹ̀ wo?

8 Ní ẹgbẹrun ọdun meje ṣaaju, o ti ṣeeṣe fun Satani Eṣu lati sun Adamu ati Efa awọn ẹni pipe sinu ẹṣẹ nipa gbigba ipa ọna igbesẹ wíwá ti ara-ẹni-nikan. Iru awọn ọna idanwo ti Jehofa yoo gba Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ laaye lati lò lẹhin itusilẹ wọn kuro ninu ọgbun ainisalẹ ni Iwe Mímọ́ kò sọ. Ṣugbọn laisi aniani ifọranlọ imọtara-ẹni-nikan ati idaniyan fun idadurolominira kuro lọdọ Ọlọrun yoo wà. Niwọn bi oun fúnraarẹ̀ sì ti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ lodisi ipo ọba-alaṣẹ Jehofa sibẹsibẹ, Eṣu yoo tẹpẹlẹ mọ igbero naa lati sọ iran eniyan di ọlọ̀tẹ̀ pẹlu. Bi awọn ikẹsẹjari ẹgbẹ ogun ẹmi eṣu ti a tusilẹ naa yoo ti pọ̀ tó ni pato ni a kò sọ pẹlu, ṣugbọn awọn ọlọ̀tẹ̀ eniyan yoo pọ̀ tó ohun ti yoo dabi ogunlọgọ titobi kan. Ẹṣẹ niha ọdọ ẹda eniyan eyikeyii, ti a ti sọ di pipe nisinsinyi, yoo jẹ́ ohun ti a fi pẹlu ọgbọn oye dawọle, ati nitori naa, yoo jẹ́ ìmọ̀ọ́mọ̀, ifinnufindọ ṣe. Yoo tọkasi yíyà kuro ninu ijọsin Ọlọrun otitọ ati alaaye kanṣoṣo naa ati mimu iduro niha ọdọ Satani Eṣu. (Ìfihàn 20:​7, 8) Nipa bayii, ninu ọran ti awọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi, Jehofa ki yoo jasi “ohun gbogbo fun olukuluku eniyan.”

9. (a) Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn wọnni ti kò pa iwatitọ si Jehofa Ọlọrun mọ́? (b) Bawo ni a o ṣe fọ gbogbo awọn ọlọ̀tẹ̀ mọ́ kuro ninu ilẹ-ọba ti a kò lè fojuri? (c) Ipo ọlọlanla wo ni yoo wá gbalẹ ní ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé?

9 Bi o ti wu ki o ri, awọn aduroṣinṣin wọnni kọ̀ lati fohunṣọkan pẹlu ijiyan ati ikimọlẹ awọn ti a ti ṣilọna, awọn onifẹẹ orilẹ-ede ẹni wọnni. Láìlọ́tìkọ̀, awọn aduroṣinṣin naa yàn lati jẹ́ ki Jehofa jẹ́ “ohun gbogbo fun olukuluku eniyan” ninu ọran tiwọn. Nitori idajọ ododo fúnraarẹ̀, ipo ọba-alaṣẹ Jehofa ni a gbọdọ mu ṣiṣẹ láìgbagbẹ̀rẹ́. Asẹhinwa asẹhinbọ, gbogbo awọn ọlọ̀tẹ̀ ti Satani sunṣiṣẹ lori ilẹ̀-ayé ni a o parẹ́ titilae. Àfẹ́kù wọn lae! Ilẹ-ọba ti a kò lè fojuri ti ìṣẹ̀dá ni a o fọ gbogbo awọn ọlọ̀tẹ̀ inu rẹ̀ mọ́ kuro pẹlu. Nitori naa, lati mu isọdimimọ agbaye naa wa si opin, Satani Eṣu ati ẹgbaagbeje awọn ẹmi eṣu rẹ̀ ni a o parẹ raurau, ni sisọ wọn di alaisi mọ́ patapata. Nipa bayii, a o fọ gbogbo àbàwọ́n ẹṣẹ eyikeyii mọ́ kuro ní awọn ọ̀run ati ayé. (Ìfihàn 20:​9, 10) Ijẹmimọ Jehofa yoo gbalẹ̀ nibi gbogbo. (Fiwe Sekariah 14:20) Orukọ mímọ́ Ọlọrun Ọga Ogo ni a o yasimimọ ní ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé. Gbogbo awọn ti ń gbe ní ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé yoo fi pẹlu idunnu ṣe ifẹ-inu rẹ̀ giga julọ.

10. Ní awọn ọna wo ni ilẹ̀-ayé yoo ṣe ni iyatọ titayọ julọ kan titi ayeraye eyi ti planẹti eyikeyii miiran kò lè gbadun rẹ̀?

10 Titi ayeraye ni ilẹ̀-ayé wa yoo ní iyatọ titayọ julọ kan tí planẹti eyikeyii miiran jakejado gbalasa ofuurufu alailopin ki yoo gbadun rẹ̀, bi o tilẹ jẹ pe ilẹ̀-ayé lè má jẹ́ planẹti kanṣoṣo ti yoo ní olugbe lae. Laini ẹlẹgbẹ, yoo jẹ́ ibi ti Jehofa ti fi aiṣeejanikoro da ipo ọba-alaṣẹ agbaye rẹ̀ lare, ní fifi idi ilana ofin awofiṣapẹẹrẹ kan ti ayeraye ati ti agbaye mulẹ. Yoo jẹ́ planẹti kanṣoṣo naa nibi ti Jehofa awọn ọmọ ogun yoo ti ja “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare.” Yoo jẹ́ planẹti kanṣoṣo naa ti Ọlọrun ran Ọmọkunrin rẹ̀ ọ̀wọ́n julọ si lati di eniyan ki ó sì kú ki ó ba lè jere awọn olugbe planẹti naa pada kuro lọwọ ẹṣẹ ati iku. Yoo jẹ́ planẹti kanṣoṣo naa lati inu eyi ti Jehofa yoo ti mú 144,000 ninu awọn olugbe rẹ̀ lati di “ajogun Ọlọrun, ati ajumọjogun pẹlu Kristi.”​—⁠Romu 8:⁠17.

Awọn Serafu, Kerubu, Angẹli

11, 12. (a) Iru awọn ẹ̀dá ẹmi wo ni Isaiah ri ninu iran kan? (b) Iru ọkan-ifẹ wo ni awọn wọnyi ní ninu awa eniyan?

11 Ọlọrun, Orisun ologo fun gbogbo ìṣẹ̀dá, ní ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé, yoo di “ohun gbogbo” kii ṣe kiki fun 144,000 ajogun pẹlu Kristi nikan ni ṣugbọn pẹlu fun awọn miiran ninu ilẹ-ọba ti ọ̀run. Ninu ori 6 iwe Isaiah, a fun wa ní iran awọn àgbàlá ọ̀run wò ní fìrí. Nibẹ ni a kà pe: “Emi ri Oluwa jokoo lori itẹ ti ó ga, ti ó si gbé ara soke, iṣẹti aṣọ igunwa rẹ̀ kún tẹmpili. Awọn serafu duro loke rẹ̀: ọkọọkan wọn ní iyẹ mẹfa, o fi meji bo oju rẹ̀, o fi meji bo ẹsẹ rẹ̀, o si fi meji fò. Ikinni si ke si ekeji pe, Mímọ́, mímọ́, mímọ́, ni Oluwa awọn ọmọ ogun, gbogbo ayé kun fun ogo rẹ̀.”​—⁠Isaiah 6:​1-⁠3.

12 Ẹ wo bi a ti ṣe ojurere si Isaiah tó lati ri Ẹni mímọ́ julọ ní gbogbo agbaye ti ó jokoo lori itẹ rẹ̀ ọ̀run ti awọn serafu ologo si ń ṣe iṣẹ iranṣẹ fun un! Iru iran onibẹru ọlọwọ wo ni eyi jẹ́, ti ó ń ṣi ipo ojurere nla ti awọn serafu wọnni wà paya, nitori oun ni Ẹni Mímọ́ Julọ Latokedelẹ ti wọn ń polongo ijẹmimọ ọlọwọ rẹ̀ bi wọn ti ń jẹrii si jijẹ mímọ́ rẹ̀ nipa titẹnumọ ọn ní ọna ilọpo mẹta! Awọn serafu lọkan-ifẹ si riran awọn olujọsin Jehofa lọwọ lati jẹ́ mímọ́ gẹgẹ bi Ọlọrun ti jẹ́ mímọ́.​—⁠Isaiah 6:​5-⁠7.

13. (a) Iru awọn ẹda ẹmi miiran wo ni Bibeli tun ṣipaya fun wa? (b) Bawo ni a ṣe ṣapejuwe Jehofa ni isopọ pẹlu wọn?

13 Gan-an gẹgẹ bi oniruuru awọn ẹ̀dá abẹmi ti wà nisalẹ nihin-⁠in lori ilẹ̀-ayé, ti ń fi ẹri agbara Jehofa Ọlọrun hàn, bakan naa ni awọn ẹ̀dá iru miiran wà ní ilẹ-ọba ẹmi. Bibeli fihan pe awọn wọnyi jẹ́ awọn kerubu ologo, ti wọn gbọdọ jẹ́ ọ̀jáfáfá ní fifo. (Orin Dafidi 18:10; fiwe Heberu 9:​4, 5.) Genesisi 3:24 fihan pe lẹhin ti Adamu ati Efa ti ṣẹ̀ lodisi Ọlọrun ọ̀run mímọ́ nipa ṣiṣajọpin jijẹ eso ìkàléèwọ̀ naa, Ẹlẹ́dàá yan awọn kerubu pẹlu “ida iná . . . ti ń ju kaakiri” leralera si oju-ọna ila-oorun ti ó lọ sinu Paradise igbadun naa. A sọrọ Jehofa bi ẹni ti “o jokoo lori awọn kerubu.” (Orin Dafidi 99:1; Isaiah 37:16) Nipa bayii a fi i han gẹgẹ bi ẹni ti ó gúnwà sori itẹ lori awọn kerubu.

14. (a) Iru awọn ẹ̀dá ẹmi miiran wo ni a kò nilati gbojufoda? (b) Bawo ni wọn ṣe pọ̀ yamura tó?

14 Awọn ti a kò nilati gbojufoda laaarin ogunlọgọ awọn ẹ̀dá ẹ̀mí ni awọn angẹli. Araadọta ọkẹ wọn ni o wa. (Danieli 7:​9, 10) Laaarin wọn ni awọn angẹli ti a yàn lati maa ṣiṣẹsin awọn olujọsin Jehofa lori ilẹ̀-ayé. Jesu kilọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ mu eyikeyii ninu awọn olujọsin Jehofa kọsẹ fun idi naa pe “nigba gbogbo ní ọ̀run ni awọn angẹli wọn ń wo oju Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run.” (Matteu 18:10; Heberu 1:14) Lẹhin ààwẹ̀ Jesu fun 40 ọjọ ninu aginju ati lẹhin fifi ijagunmolu dènà awọn idanwo pataki mẹta ti Eṣu gbe kalẹ, ẹ wo bi o ti jẹ́ anfaani tó fun awọn angẹli lati ṣiṣẹsin fun aini nipa ti ara Jesu, ti ó ti joro ti ebi si ń pa!​—⁠Matteu 4:⁠11.

15, 16. (a) Ṣapejuwe iṣọkan bii ti idile ti yoo wà ní ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé. (b) Èrè wo lati ọdọ Jehofa ni a o fi fun awọn eniyan ti a sọ di pipe wọnni ti wọn yege ninu idanwo naa? (c) Bawo ni Jehofa yoo ṣe bojuwo iṣaṣeyege ète rẹ̀ ipilẹṣẹ?

15 Loke ninu ilẹ-ọba ti ọ̀run, awọn ẹni ẹmi ologo olugbe ibẹ yoo jẹ́ arakunrin si ẹnikinni keji wọn, nigba ti ó si jẹ́ pe nisalẹ nihin-⁠in lori ilẹ̀-ayé idile iran eniyan ti a ti sọ di pipe ni a o sọ di arakunrin ati arabinrin si ẹnikinni keji wọn. Wọn yoo wà ní aworan ati ìrí Ọlọrun titi de àyè titobilọla tí Adamu ati Efa wà nigba tí Jehofa Ọlọrun ṣẹṣẹ dá wọn, ‘ni aworan ati ìrì’ Ẹlẹ́dàá wọn. (Genesisi 1:​26, 27) Lẹhin yiyege ninu idanwo ikẹhin, awọn eniyan ti a ti sọ di pipe naa ni a o fi ẹ̀tọ́ lati maa gbe titilae jinki ti a o si fi pẹlu ifẹ gba wọn ṣọmọ bii “awọn ọmọ Ọlọrun,” ti wọn yoo maa yọ ayọ̀ ninu ominira ologo, ti wọn yoo si di apakan idile Jehofa oniṣọkan ní ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé.​—⁠Romu 8:⁠21.

16 Ẹ wo iru igbadunmọni ati iru irusoke ayọ̀ nla ti Jehofa Ọlọrun yoo mọ̀lára latokedelẹ bi o ti ń bojuwo iṣaṣeyege ète rẹ̀ ipilẹṣẹ​—⁠iṣẹ oniyanu alailẹgbẹ ti mimu gbogbo awọn nǹkan wà ní ibamu pẹlu ipinnu rẹ̀ atetekọṣe​—⁠gbogbo ẹ̀dá wà ní iṣọkan onifẹẹ ti kò ṣee já pẹlu rẹ̀!

17. Ní ríronú lori gbogbo eyi, ta ni yoo lè fasẹhin ninu ṣiṣe ki ni, ní ibamu pẹlu awọn ọ̀rọ̀ olorin naa?

17 Ni ríronú lori gbogbo eyi, ta ni yoo lè fasẹhin ninu fifi ibukun fun Olupete agbayanu ti ọrun yii? Ti kì yoo gbé awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ soke daadaa ní ìdarí si awọn ẹ̀dá ẹmi ti wọn lagbara ju eniyan lọ, olorin naa sọ pe: “Ẹ fi ibukun fun Oluwa, ẹyin angẹli rẹ̀, ti ó pọ̀ ní ipa, ti ń ṣe ofin rẹ̀, ti ń fetisi ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ibukun fun Oluwa, ẹyin ọmọ ogun rẹ̀ gbogbo; ẹyin iranṣẹ rẹ̀, ti ń ṣe ifẹ rẹ̀.”​—⁠Orin Dafidi 103:​20, 21.

18. Bawo ni olorin naa ṣe pari iwe Orin Dafidi?

18 Olorin ti a misi naa, ninu ẹmi ti a rusoke, pari iwe Orin Dafidi naa pẹlu awọn ọ̀rọ̀ igbaniniyanju wọnyi pe: “Ẹ fi iyin fun Oluwa. Ẹ fi iyin fun Ọlọrun ninu ibi mímọ́ rẹ̀; yin in ninu ofuurufu oju ọ̀run agbara rẹ̀. Yin in nitori iṣẹ agbara rẹ̀: yin in gẹgẹ bi titobi nla rẹ̀. Fi ohùn ipe yin in: fi ohun-eelo orin ati duuru yin in. Fi ilu ati ijo yin in: fi ohun ọna orin olokun ati fèrè yin in. Ẹ yin in lara aro olohun oke: ẹ yin in lara aro olohun gooro. Jẹ ki ohun gbogbo ti ó ní ẹmi ki o yin Oluwa. Ẹ fi iyin fun Oluwa.”​—⁠Orin Dafidi 150:​1-⁠6.

19. (a) Ninu ìdè wo ni a o ti so agbaye pọ̀ ṣọkan nigba naa? (b) Ki ni gbogbo ẹ̀dá oloye, niti tootọ, yoo wá sọ?

19 Gbogbo agbaye lapapọ ni yoo sopọṣọkan nigbẹhin gbẹhin ninu ìdè pipe kan ti yoo wà bẹẹ fun gbogbo ayeraye, ìdè ijọsin kanṣoṣo ti Baba ọ̀run naa nitori pe awọn ọmọ rẹ̀ fẹran rẹ̀ wọn si bọla fun un ju ohun gbogbo lọ. Bẹẹni, nigba naa ni yoo ṣẹlẹ pe gbogbo ẹ̀dá oloye yoo sọ, niti tootọ, gẹgẹ bi awọn serafu ti wi pe: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́, ni Oluwa awọn ọmọ ogun, gbogbo ayé kun fun ogo rẹ̀.” Nigba naa, niti tootọ, Ọlọrun “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa yoo ti wá di “ohun gbogbo fun olukuluku eniyan”​—⁠titilae lae.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 188, 189]

Gbogbo agbaye lapapọ ni yoo sopọṣọkan ninu ijọsin alalaafia ti Ọba-Alaṣẹ Agbaye Naa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́