Kí Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?
“Àwa ronú pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu láti gbọ́ láti ẹnu rẹ ohun tí àwọn ìrònú rẹ jẹ́, nítorí pé lóòótọ́, ní ti ẹ̀ya ìsìn yìí, a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” (Ìṣe 28:22) Àwọn abẹnugan láwùjọ wọ̀nyí, ní Róòmù ọ̀rúndún kìíní, fi àpẹẹrẹ tí ó dára lélẹ̀. Wọ́n ń fẹ́ gbọ́ látẹnu ọlọ́ràn, dípò gbígbọ́ látẹnu àwọn tí ń ṣe lámèyítọ́ lásán láìmọ̀dí ọ̀ràn.
Bákan náà, wọ́n sábà máa ń sọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìda lónìí, àṣìṣe ni yóò sì jẹ́ bí èèyàn bá retí pé òun lè mọ òtítọ́ nípa wọn látọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́tanú. Nítorí náà, ó dùn mọ́ wa láti ṣàlàyé nípa díẹ̀ lára lájorí ìgbàgbọ́ wa fún ọ.
Bíbélì, Jésù Kristi, àti Ọlọ́run
A gbà gbọ́ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.” (2 Tímótì 3:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan sọ pé a kì í ṣe Kristẹni gidi, ìyẹn kì í ṣòótọ́. A fọwọ́ sí gbogbo ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa Jésù Kristi pé: “Kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.”—Ìṣe 4:12.
Àmọ́, níwọ̀n bí Jésù tí sọ pé “Ọmọ Ọlọ́run” ni òun àti pé ‘Baba ti rán òun jáde,’ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé Ọlọ́run tóbi ju Jésù lọ. (Jòhánù 10:36; 6:57) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28; 8:28) Nítorí náà, a kò gbà pé Jésù bá Baba rẹ̀ dọ́gba, bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ṣe sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbà pé Ọlọ́run ni ó dá a àti pé ó rẹlẹ̀ sí Ọlọ́run.—Kólósè 1:15; 1 Kọ́ríńtì 11:3.
Ní èdè Yorùbá, Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Iwọ, orukọ ẹni-kanṣoṣo ti ijẹ Jehofah, iwọ li Ọga-ogo lori aiye gbogbo.” (Orin Dáfídì 83:18, Bíbélì Mímọ́) Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yìí, Jésù tẹnu mọ́ ọn pé orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” Òun fúnra rẹ̀ sì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn ènìyàn tí ìwọ fi fún mi.”—Mátíù 6:9; Jòhánù 17:6.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé àwọn ní láti dà bí Jésù ní ti mímú kí orúkọ Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ hàn kedere sí àwọn ẹlòmíràn. Ìdí èyí ni a ṣe ń jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nítorí pé a fara wé Jésù, tí ó jẹ́ “Ẹlẹ́rìí Aṣeégbíyèlé.” (Ìṣípayá 1:5; 3:14) Lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú, Aísáyà 43:10 sọ fún àwọn ènìyàn tó jẹ́ aṣojú Ọlọ́run pé: “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn.’”
Ìjọba Ọlọ́run
Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé, “Kí ìjọba rẹ dé,” ó sì fi Ìjọba yẹn ṣe lájorí ẹṣin ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni. (Mátíù 6:10; Lúùkù 4:43) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé Ìjọba yìí jẹ́ ìjọba gidi látọ̀runwá, pé yóò ṣàkóso lórí ayé, àti pé Jésù Kristi la fi jẹ Ọba rẹ̀ tí a kò lè fojú rí. Bíbélì sọ pé: “Ijọba yio si wà li ejika rẹ̀ . . . Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun.”—Isaiah 9:6, 7, Bíbélì Mímọ́.
Àmọ́ ṣá o, Jésù Kristi nìkan kọ́ ni yóò jẹ́ ọba ìjọba Ọlọ́run. Àwọn púpọ̀ yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run tí wọn yóò jùmọ̀ ṣàkóso. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí a bá ń bá a lọ ní fífaradà, a ó jọ ṣàkóso pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ọba.” (2 Tímótì 2:12) Bíbélì fi hàn pé a fi iye àwọn ènìyàn tí a jí dìde láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run mọ sí “ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì . . . , tí a ti rà láti ilẹ̀ ayé wá.”—Ìṣípayá 14:1, 3.
Dájúdájú, ìjọba èyíkéyìí ní láti ní àwọn ọmọ abẹ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì gbà gbọ́ pé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù sí i, yàtọ̀ sí àwọn olùṣàkóso ti ọ̀run wọ̀nyí, ni yóò gba ìyè àìnípẹ̀kun. Láṣẹ̀yìnwá-àṣẹ̀yìnbọ̀, ilẹ̀-ayé táa yí padà di párádísè ẹlẹ́wà, yóò wá kún fún àwọn tí wọ́n yẹ láti jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run wọ̀nyí, tí gbogbo wọn ń tẹrí ba fún ìṣàkóso Kristi àti àwọn alájùmọ̀ṣàkóso rẹ̀. Nípa báyìí, ó dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú hán-únhán-ún pé a kò ní pa ilẹ̀ ayé run láé, àti pé, ìlérí Bíbélì náà yóò ní ìmúṣẹ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29; 104:5.
Ṣùgbọ́n báwo ni Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe dé? Ṣé nípa pé gbogbo ènìyàn yóò fínnúfíndọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún ìṣàkóso Ọlọ́run ni? Ó tì o, kedere ni Bíbélì fi hàn pé, dídé Ìjọba Ọlọ́run yóò béèrè pé kí Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn ayé ní tààràtà: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà . . . yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run yóò dé? Látàrí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń ní ìmúṣẹ nísinsìnyí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé yóò dé láìpẹ́. A ké sí ọ láti ṣàyẹ̀wò mélòó kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn àmì “ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí. Wọ́n wà lákọọ́lẹ̀ nínú Mátíù 24:3-14; Lúùkù 21:7-13, 25-31; àti 2 Tímótì 3:1-5.
Nítorí pé àwa ‘nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú wa àti pẹ̀lú gbogbo okun wa, tí a sì nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa,’ a ò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè wa tó yàtọ̀ síra, kẹ́lẹ́yà mẹ̀yà, tàbí kẹ́lẹ́gbẹ́ mẹgbẹ́ fa ìpínyà láàárín wa. (Máàkù 12:30, 31) A mọ̀ wá nílé lóko pé àwùjọ Kristẹni ará wa tí wọ́n wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè fẹ́ràn ara wọn. (Jòhánù 13:35; 1 Jòhánù 3:10-12) Nípa báyìí, a kì í dá sí tọ̀tún tòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn. A ń gbìyànjú láti dà bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, tí Jésù sọ nípa wọn pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) A gbà gbọ́ pé ṣíṣàìjẹ́ apá kan ayé túmọ̀ sí yíyẹra fún àwọn ìwàkiwà tó wọ́pọ̀ gan-an lónìí, títí kan irọ́ pípa, olè jíjà, àgbèrè, panṣágà, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, àṣìlò ẹ̀jẹ̀, ìbọ̀rìṣà, àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tí Bíbélì kà léèwọ̀.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11; Éfésù 5:3-5; Ìṣe 15:28, 29.
Ìrètí Wa Nípa Ọjọ́ Ọ̀la
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé ìgbésí ayé kò mọ sí kìkì èyí tí a ń gbé lọ́wọ́ nínú ayé yìí. A gbà gbọ́ pé Jèhófà rán Kristi wá sáyé láti fi ẹ̀jẹ̀ ìwàláàyè rẹ̀ ṣe ìràpadà kí aráyé lè jẹ́ olódodo lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà nínú ètò àwọn nǹkan tuntun. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn àpọ́sítélì Jésù ṣe wí: “A ti polongo wa ní olódodo nísinsìnyí nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.” (Róòmù 5:9; Mátíù 20:28) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ fún ìpèsè ìràpadà yìí tó mú kí ìwàláàyè ọjọ́ iwájú ṣeé ṣe.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìgbọ́kànlé pátápátá nínú ìwàláàyè ọjọ́ ọ̀la, tó dá lórí àjíǹde àwọn òkú lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi kọ́ni, a gbà gbọ́ pé, nígbà tí ènìyàn bá kú, ṣe ni ìwàláàyè rẹ̀ dópin ní ti gidi, pé “ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” (Sáàmù 146:3, 4; Ìsíkíẹ́lì 18:4; Oníwàásù 9:5) Bẹ́ẹ̀ ni, bí àwọn òkú yóò bá wà láàyè lọ́jọ́ ọ̀la, ó sinmi lórí rírántí tí Ọlọ́run bá rántí wọn nígbà àjíǹde.—Jòhánù 5:28, 29.
Àmọ́, ó dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n wà láàyè nísinsìnyí yóò là á já nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá mú gbogbo ìjọba ìsinsìnyí wá sópin, àti pé, gẹ́gẹ́ bí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe la Ìkún Omi já, wọn yóò máa wà láàyè lọ láti máa gbádùn ìwàláàyè títí láé nínú ayé kan tí a ti fọ̀ mọ́. (Mátíù 24:36-39; 2 Pétérù 3:5-7, 13) Ṣùgbọ́n a gbà gbọ́ pé lílà á já sinmi lórí ṣíṣe àwọn ohun tí Jèhófà béèrè, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí pé: “Ayé ń kọjá lọ . . . , ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17; Sáàmù 37:11; Ìṣípayá 7:9, 13-15; 21:1-5.
Dájúdájú, kò ṣeé ṣe láti kárí gbogbo ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ níhìn-ín, àmọ́, a ké sí ọ láti gba ìsọfúnni síwájú sí i.
Bí a kò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí a fà yọ wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
A ń jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nítorí pé a ń fara wé Jésù