Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun Alálàáfíà Kan
Nígbà tóo wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìwé àṣàrò kúkúrú yìí, báwo ló ṣe rí lára rẹ? Ọkàn-àyà rẹ kò ha ń yán hànhàn fún àlàáfíà, ayọ̀, àti aásìkí tí o rí níbẹ̀? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n ṣé àlá tàbí ìgbéra-ẹni gẹṣin aáyán lásán ni, tí a bá gbà pé ipò nǹkan wọ̀nyí lè wà lórí ilẹ̀ ayé láé?
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ ènìyàn rò bẹ́ẹ̀. Àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lónìí ni ogun, ìwà ipá, ebi, àìsàn, ọjọ́ ogbó—kí a kàn mẹ́nu kan ìwọ̀nba díẹ̀. Síbẹ̀ ìdí wà fún wa láti ní ìrètí. Ọjọ́ iwájú ni Bíbélì ń wò nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun . . . tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13; Aísáyà 65:17.
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “ọ̀run tuntun” yìí àti “ilẹ̀ ayé tuntun” yìí, kì í ṣe ọ̀run tuntun kan tí a lè fojú rí tàbí ilẹ̀ ayé gidi kan tó jẹ́ tuntun. Pípé ni a dá ilẹ̀ ayé àti ọ̀run tí a lè fojú rí, Bíbélì sì fi hàn pé wọn yóò wà títí láé. (Sáàmù 89:36, 37; 104:5) “Ilẹ̀ ayé tuntun” náà yóò jẹ́ àwùjọ ènìyàn olódodo tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, “ọ̀run tuntun” yóò sì jẹ́ ìjọba tàbí ìṣàkóso pípé látọ̀runwá, tí yóò ṣàkóso lórí àwùjọ ènìyàn ilẹ̀ ayé yìí. Ṣùgbọ́n, ṣé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé “ilẹ̀ ayé tuntun,” tàbí ayé tuntun ológo kan lè wà?
Ó dára, ronú lórí òtítọ́ náà pé irú ipò pípé bẹ́ẹ̀ jẹ́ ara ète Ọlọ́run fún ayé yìí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ó fi tọkọtaya àkọ́kọ́ sínú Párádísè ilẹ̀ ayé ní Édẹ́nì, ó sì yan iṣẹ́ àgbàyanu kan fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Bẹ́ẹ̀ ni o, ète Ọlọ́run fún wọn ni pé kí wọ́n bímọ kí wọ́n sì mú kí Párádísè wọn gbilẹ̀ kárí gbogbo ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nígbà tó yá, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tí kò yẹ láti wà láàyè títí láé, ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ kò yí padà. Ó sì di dandan pé kó ní ìmúṣẹ nínú ayé tuntun!—Aísáyà 55:11.
Ní tòótọ́, nígbà tóo bá ń gba Àdúrà Olúwa, tàbí Baba Wa tí Ń Bẹ Lọ́run, tóo ń sọ pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ńṣe lò ń gbàdúrà pé kí ìṣàkóso rẹ̀ àtọ̀runwá mú ìwà ibi kúrò ní ilẹ̀ ayé kí ó sì máa ṣàkóso ayé tuntun yìí. (Mátíù 6:9, 10) A sì ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò dáhùn àdúrà yẹn, níwọ̀n bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti ṣèlérí pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.
Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun Ọlọ́run
Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣàǹfààní fún ilẹ̀ ayé lọ́nà tí kò láfiwé, yóò sì ṣe gbogbo ohun rere tí Ọlọ́run pète ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ gbádùn lórí ilẹ̀ ayé. Ìkórìíra àti ẹ̀tanú yóò dópin, tí gbogbo ènìyàn orí ilẹ̀ ayé yóò sì wá di ọ̀rẹ́ tòótọ́ fún ara wọn pátá. Nínú Bíbélì, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” “Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Sáàmù 46:9; Aísáyà 2:4.
Níkẹyìn, a óò wá sọ gbogbo ilẹ̀ ayé dà bí ọgbà Párádísè. Bíbélì sọ pé: “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì. . . . Nítorí pé omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀. Ilẹ̀ tí ooru ti mú gbẹ hán-ún hán-ún yóò sì ti wá rí bí odò adágún tí ó kún fún esùsú, ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò sì ti wá rí bí àwọn ìsun omi.”—Aísáyà 35:1, 6, 7.
Kò sí ìdí tí a kò fi ní láyọ̀ nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. Kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́ láé pé ebi yóò máa pa àwọn èèyàn nítorí àìsí oúnjẹ. Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá.” (Sáàmù 67:6; 72:16) Gbogbo ènìyàn yóò jadùn èso iṣẹ́ ọwọ́ wọn, nítorí Ẹlẹ́dàá wa ṣèlérí pé: “Dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. . . . wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.”—Aísáyà 65:21, 22.
Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, a kò ní fún àwọn ènìyàn mọ́nú àwọn ilé bínúkonú jìnmọ̀wò tàbí mọ́nú àwọn ẹgẹrẹmìtì ilé, nítorí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn . . . Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé.” Bíbélì tún ṣèlérí pé: “Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán.” (Aísáyà 65:21-23) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ènìyàn yóò ní iṣẹ́ alálùbáríkà, tó tẹ́ni lọ́rùn. Ìgbésí ayé kì yóò súni.
Bí àkókò ti ń lọ, Ìjọba Ọlọ́run yóò tilẹ̀ mú ipò alálàáfíà tó wà láàárín àwọn ẹranko, àti láàárín ènìyàn àti ẹranko nínú ọgbà Édẹ́nì bọ̀ sípò. Bíbélì sọ pé: “Ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n.”—Aísáyà 11:6-9; Hóséà 2:18.
Sá rò ó wò ná, nínú Párádísè ilẹ̀ ayé, gbogbo àìsàn àti àìlera ara ni a óò wò sàn pẹ̀lú! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) “[Ọlọ́run] yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.
Bí Ó Ṣe Lè Tẹ̀ Ọ́ Lọ́wọ́
Ó dájú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run nípa ìwàláàyè nínú ayé tuntun òdodo rẹ̀ ti ní láti wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè ka rírí ìmúṣẹ àwọn ìbùkún wọ̀nyẹn gbà sí àlá tí kò lè ṣẹ, wọn kò dára ju ohun tí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ lè ṣe.—Sáàmù 145:16; Míkà 4:4.
Lóòótọ́, àwọn nǹkan kan wà tí a ní láti ṣe bí a óò bá wà láàyè títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀. Jésù fi ọ̀kan tó ṣe pàtàkì hàn nígbà tó sọ nínú àdúrà sí Ọlọ́run pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Nítorí náà, bí a bá fẹ́ gbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run lóòótọ́, a ní láti kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run kí a sì máa ṣe é. Nítorí òdodo ọ̀rọ̀ ni pé: ‘Ayé yìí ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé,’ láti máa gbádùn àwọn ìbùkún tí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ yóò tú jáde lọ́pọ̀ yanturu, títí ayérayé.—1 Jòhánù 2:17.
Bí a kò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí a fà yọ wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.